Awọn Onidajọ 7:9-25; 8:1-35

Lesson 194 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa?” (Romu 8:31).
Cross References

I Idà Oluwa ati ti Gideoni

1. Ọlọrun mú ibẹru Gideoni kuro nipa jijẹ ki ó gbọ nipa ibẹru ti awọn ará Midiani ní fun Ọlọrun Gideoni, Awọn Onidajọ 7:9-14; Joṣua 2:9-11; Gẹnẹsisi 35:5; Ẹksodu 23:27; Deuteronomi 2:25; 11:25

2. Igboya Gideoni ati igbogunti iyanu si awọn Midiani jẹ nipa imisi igbagbọ ninu Ọlọrun, Awọn Onidajọ 7:9-20; Numeri 10:9; Joṣua 6:5; Deuterronomi 32:41, 42; Jeremiah 46:10

3. Agbajọ ogun Midiani ni a run tuutu lati ọwọ Gideoni, Awọn Onidajọ 7:15-23; 8:10; 1 Samuẹli 14:20; 2 Kronika 20:22, 23

4. Awọn ọkunrin Efraimu dara pọ mọ ogun lati bá Midiani jà, Awọn Onidajọ 7:24, 25

II Ilepa Awọn Midiani

1. Gideoni fi idahun pẹlẹ ṣẹgun ibinu ilara Efraimu, Awọn Onidajọ 8:1-3; Owe 15:1; 1 Samuẹli 17:28, 29; Gẹnẹsisi 4:4 – 8; 37:4

2. Awọn ara Ilu Sukkotu ati Penueli kọ lati ran Gideoni lọwọ ninu ija pẹlu awọn Midiani, Awọn Onidajọ 8:4-9; l Samuẹli 25:10, 11; Awọn Onidajọ 5:23; Obadiah 10-14 1 Johannu 3:16-18

3. Gideoni ṣeleri igbẹsan lara Sukkotu ati Penueli, o si mu eyi ṣẹ kankan, Awọn Onidajọ 8:7, 9, 13-17

4. Gideoni mú Seba ati Salmunna, awọn ọba Midiani, o si pa wọn nitori iṣẹ buburu wọn, Awọn Onidajọ 8:10-12, 18-22

5. Alaafia jọba fun ogoji ọdun titi di igba ikú Gideoni, Awọn Onidajọ 8:22-35

Notes
ALAYE

“O si ṣe li oru na, ni OLUWA wi fun u pe, Dide, sọkalẹ lọ si ibudó; nitoriti mo ti fi i lé ọ lọwọ. Ṣugbọn bi iwọ ba mbẹru lati sọkalẹ lọ, ki iwọ ati Pura iranṣẹ rẹ sọkalẹ lọ si ibudo: Iwọ o si gbọ ohun ti nwọn nwi; lẹhin eyi ni ọwọ rẹ yio li agbara lati sọkalẹ lọ si ibudó.” Ọrọ wọnyii ni Ọlọrun fi ki Gideoni laya ni idojukọ ogun awọn Midiani. Nigba ti igbogunti awọn Midiani ba bẹrẹ, a kò gbọdọ bojuwo ẹyin titi a o fi ṣẹgun.

Ọlọrun fẹ gba Israẹli silẹ lọwọ awọn ti n ṣẹ wọn niṣẹ, ani awọn ará Midiani. Ṣugbọn awọn ọmọ-ogun Israẹli ni lati ni balogun, ẹni ti yoo jẹ akin ati akọni ọkunrin, ohunkohun ti o wu ki o de, ati bi o si ti wù ki ogun gbona to. Bi Gideoni ba si gbagbọ pe lootọ ni Ọlọrun ti fi awọn Midiani lé Israẹli lọwọ, wọn ki yoo le bori rẹ. Bayii ni Ọlọrun ki Gideoni laya, O mu un lọkàn le, O si fi idi igbagbọ rẹ mulẹ ṣinṣin.

Ni igbọran si aṣe Oluwa, Gideoni lọ si ibudo Midiani, o si tẹti lelẹ si ohun ti wọn n sọ. O gbọ ti ọmọ-ogun kan n rọ àlá ti o lá fun ẹlẹgbẹ rẹ, eyi jẹ ki o mọ pe ẹrù awọn eniyan Ọlọrun n ba awọn ti o wà ni ibudo. Eyi ki i ṣe igba kin-in-ni ti ẹrù Ọlọrun ba awọn orilẹ-ede Keferi. Awọn ara Kenaani ti o ti kọ mọ nipa agbara ogun Israẹli bi wọn ti n bọ lati Egipti nipa ọna aginju ní òye kikun nipa idajọ Ọlọrun ti o muna. Lai si aniani, awọn eniyan ilẹ naa kò gbagbe nnkan wọnyii, kò si ṣoro fun Ọlọrun lati tun mu un wá si iranti wọn.

Ariwo Ogun

“Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọn; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara; ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan” (l Kọrinti 1:27, 28). Ogun ti Gideoni gbé ti awọn Midiani fi idi Ọrọ Ọlọrun yii mulẹ. Bawo ni ọnà Ọlọrun ti yatọ si ti eniyan to, bawo ni o si ti dara to! Ainilaari eto ogun Gideoni kò dí iṣẹgun rẹ lọwọ. Nipa imisi Ọlọrun, Gideoni pín awọn ọmọ-ogun rẹ si ẹgbẹ mẹta, a si fun ẹni kọọkan ni ipe, iṣa ati otufu ninu rẹ gẹgẹ bi ohun ija wọn.

Wọn yí ibudo awọn Midiani ká ni oru, Gideoni si paṣẹ fun wọn pe: “Ẹ wò mi, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹẹ gẹgẹ: si kiyesi i, nigbati mo ba dé opin ibudó na, yio si ṣe bi emi ba ti ṣe, bẹẹni ki ẹnyin ki o ṣe.” Gẹgẹ bi alakoso tootọ, Gideoni lọ siwaju ogun, o si paṣẹ fun awọn ọmọ-ogun lati tẹle oun. Bakan naa ni Paulu Aposteli sọ fun awọn ọmọ-lẹyin rẹ pe: “Ẹ mã ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti nṣe afarawe Kristi” (l Kọrinti 11:1). Ẹnikẹni ti o ba n tẹle Balogun wa, Jesu Kristi, ki yoo ṣe aṣeti (Wo Heberu 13:20; l Peteru 5:3, 4).

Bi wọn ti n fun ipe wọn, wọn fọ iṣà wọn, wọn gbé otúfu wọn lọwọ, awọn ọmọ-ogun Gideoni ké ni ohùn kan pe, “Idà OLUWA, ati ti Gideoni,” Igbe awọn ọmọ-ogun Gideoni, fifọ iṣà, iro ipe ati imọlẹ inu otùfu ti o mọlẹ lojiji, fi hàn awọn ara Midiani pe ọwọ awọn ọmọ ogun Israẹli ti tẹ wọn Ninu idaamu yii, wọn fi aladugbo wọn pe ọtá, wọn si doju idà kọ ara wọn, to bẹẹ ti o fi jẹ pe ọkẹ mẹfa eniyan ninu awọn ara Midiani ni o kú ninu ogun naa. Bayii ni Ọlọrun bẹrẹ si fi iṣẹgun fun Gideoni lori awọn ara Midiani.

Bi wọn ti n lepa awọn ọta ti wọn ti lé loju ogun yii, Gideoni rán awọn onṣẹ si Efraimu lati dabùú awọn ara Midiani nigba ti wọn de iwọdo Jordani. Awọn ọkunrin Efraimu si ṣe bẹẹ, awọn okunrin Naftali, Aṣeri ati Manasse si lepa wọn gba ọna miiran. Awọn ọkunrin Efraimu mú meji ninu awọn ọmọ-alade Midiani, Orebu ati Seebu, wọn si pa wọn. Igbagbọ ati igbọran Gideoni si Ọlọrun mu iṣẹgun nla wá fun Israẹli.

Awọn Ojòwú

Nisisiyii awọn ẹya Efraimu n fẹ pín ninu iṣẹgun ti wọn kò sa ipá pupọ lati mu ki o ṣe e ṣe. Bi wọn ba ni ero lati bá awọn ara Midiani jà ni tootọ, wọn i bá ti gbé ọkàn wọn soke si Ọlọrun lati beere iranlọwọ Rẹ, gẹgẹ bi Gideoni ti n ṣe nigba ti angẹli Ọlọrun kọ si i lati gba Israẹli là. Igboya ọsan gangan ti awọn ọkunrin Efraimu fi hàn kò rú Gideoni loju rara. Gideoni si fi ara hàn bi ọmọ Ọlọrun tootọ nipa idahun ti o fi fun wọn.

O tẹmbẹlu ara rẹ o si fi oju tinrin aṣeyọri ti o ni, o si bu iyin fun wọn ni ti pe wọn mú awọn ọmọ-alade Midiani meji ni igbekun. “Imoye enia mu u lọra ati binu; ogo rẹ si ni lati ré ẹṣẹ kọja” (Owe 19:11). Eyi ni Gideoni ṣe; oun iba ti sọrọ pupọ si awọn ọkunrin Efraimu nipa igboya ojiji wọn yii, ṣugbọn o fi wọn silẹ fun Ọlọrun, ti o mọ ọkàn gbogbo eniyan ti yoo si mu gbogbo iṣẹ wá si idajọ nikẹyin, i baa ṣe rere tabi buburu. Kò pẹ ti awọn ara Efraimu fi ohun ti wọn jẹ gan an hàn. A kò ri i kà pe Efraimu tabi awọn ẹya Israẹli miiran tẹle Gideoni nigba ti o n lepa iyoku awọn ara Midiani pẹlu awọn ọọdunrun oloootọ eniyan ti Ọlọrun yàn fun un.

Aladugbo Ti Kò Nifẹ

Aarẹ ti mú awọn ọmọ-ogun Gideoni ebi si ti n pa wọn pẹlu bi wọn ti n lepa awọn ara Midiani. Gideoni bẹbẹ pe ki awọn ara Sukkotu ati Penueli fun awọn ọmọ-ogun rẹ ni ounjẹ ki wọn ba le ni okun lati maa lepa n ṣó. Wọn kọ lati ṣe iranwọ, wọn si bẹrẹ si fi Gideoni ṣe ẹlẹya pe, “Ọwọ rẹ ha ti itẹ Seba on Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ogun rẹ li onjẹ?”

Idahun yii fihan dajudaju pe awọn ara Sukkotu ati Penueli kò ni igbagbọ ninu Gideoni, tabi Ọlọrun ti o n sin. Ọkan wọn kún fun ẹṣẹ ati aigbagbọ, wọn kò si bẹru lati kọ lati ṣe iranwọ fun ẹni naa ti o n bá ọta gbogbo wọn jà, paapaa ẹni ti i ṣe ara ilu wọn, boya ti o tilẹ le jẹ ẹbi wọn nipa ti ara.

Bi awọn ara Sukkotu ati Penueli kò tilẹ gbàgbọ, ọwọ Gideoni ti tẹ Seba ati Salmunna, nitori Ọlọrun ti fi iṣẹgun fun Gideoni ati ogun rẹ: “Igbagbọ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri” (Heberu 11:1). Gideoni beere iranlọwọ lọwọ awọn arakunrin rẹ ṣugbọn wọn fi dù ú, ṣugbọn eyi kò yẹ igbagbọ rẹ, nitori o ti fi ọkàn tán Ọlọrun.

Gideoni ati awọn ogun rẹ tẹ siwaju, wọn si ṣẹgun fun Ọlọrun ati Israẹli. Ṣugbọn Gideoni pinnu lati pada wa jẹ awọn ara Sukkotu ati Penueli níyà nitori wọn kọ lati ṣe iranwọ. Gideoni mu ileri yii ṣẹ gẹgẹ bi o ti sọ tẹlẹ. Bi èrè awọn eniyan buburu ti ri ni yii.

Iṣẹ ara ati aigbagbọ jẹ ọta igbagbọ ati ododo lati ibẹrẹ wa. Bi agbara okunkun kò ba tilẹ fi tipatipa dojuja kọ iṣẹ Ọlọrun ati awọn eniyan Rẹ, yoo sa gbogbo ipá rẹ lati de iṣẹ Ọlọrun lọna, bi o ti ri fun Gideoni. Ki i ṣe Gideon nikan ni awọn ara Sukkotu ati Penueli kọ lati ran lọwọ, bi ko ṣe Ọlọrun pẹlu, nitori kikọ iranṣẹ Ọlọrun ni lati kọ Ẹni ti o ran an pẹlu. (Wo l Samuẹli 8:7; Matteu 25:41-46).

Jesu Kristi jiya pupọ lọwọ awọn alaigbagbọ ninu iṣẹ-iranṣẹ Rẹ. Awọn ọta Rẹ kò gba A ni Ọmọ Ọlọrun, wọn si sẹ agbara iṣẹ iyanu Rẹ; lopin gbogbo rẹ wọn bẹrẹ si fi ṣe ẹlẹya ti o buru ju lọ bi O ti wà lori igi agbelebu, “Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá” (Matteu 27:40).

A gbẹsan lara awọn ọta Gideoni, bakan naa ni a o ṣe si ọta kọọkan ti o dó ti ọmọ Ọlọrun. Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ pe: “Ko le ṣe ki ohun ikosẹ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rẹ de. Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọ ọ li ọrùn, ki a gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsẹ” (Luku 17:1, 2).

Awọn Eso Iṣẹgun

Awọn Ọmọ Israẹli n fẹ ki Gideoni ati awọn ọmọ rẹ jẹ alaṣẹ lori wọn, ṣugbọn o kọ. Gideoni mọ ibi ti iranwọ rẹ gbe ti wá. Ki i ṣe nipa ipá tabi agbara rẹ ni a fi gba Israẹli silẹ lọwọ inilara awọn ará Midiani. Lẹẹkan sii, Ọlọrun fi orukọ nla ati awamaridi agbara Rẹ hàn fun anfaani awọn eniyan Rẹ. Gideoni sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe: “OLUWA ni yio ma ṣe alaṣẹ nyin”; Ọlọrun si ṣe alaṣẹ wọn fun ogoji ọdún lati ọwọ Gideoni. “Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún.”

Iṣẹgun agbayanu ni Ọlọrun fun Israẹli lori awọn ara Midiani. Oye bi awọn Ọmọ Israẹli ti mọ iyi iṣẹgun yii to ye wa si i nipa kika awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun lori iwe miiran ninu Bibeli, eyi ti a kọ ni ọjọ pupọ lẹyin iṣẹgun nla yii. A kọ akọsilẹ adura Asafu nipa awọn ọta Israẹli ti wọn tun n dide lati dojuja kọ wọn, ninu Orin Dafidi ikẹtalelọgọrin. Ninu Saamu yii, Asafu gbadura ki Ọlọrun ki o “ṣe wọn bi o ti ṣe awọn ara Midiani:….Ṣe awọn ọlọla wọn bi Orebu ati bi Seebu: ani, gbogbo awọn ọmọ-alade wọn bi Seba ati Salmuna. Awọn ti o wipe, Ẹ jẹ ki a gbà ibugbe Ọlọrun wọnni fun ara wa ni ini” (Orin Dafidi 83:9-12).

Adura yii fi ye wa pe ki i ṣe pe Midiani gbogun ti Israẹli nitori ati le ri ikogun kó nikan, ṣugbọn nipa ṣiṣe bẹẹ wọn dojuja kọ Ọlọrun. Wọn gbà pe Ọlọrun ni o ni ilẹ wọnni, ṣugbọn wọn gboju-gboya to bẹẹ ti wọn fẹ já wọn gbà lọwọ Ọlọrun. Eredi rẹ ti Ọlọrun fi dide si wọn ni yii. Asafu n bẹbẹ fun iru iṣẹgun kan naa, nitori o ranti iṣẹgun ti Ọlọrun ti fi fun awọn eniyan Rẹ ni iru akoko bayii.

Itumọ orukọ Orebu ni “ẹyẹ iwo,” itumọ ti Seebu si ni, “ikookò.” Ṣugbọn awọn ajẹ-loju-onile ti o n fẹ ikogun wọnyii, kò jẹ nnkan lọwọ Ọlọrun nigba ti O ba pinnu lati bì wọn wó. Ẹsin ati itiju ni o gbẹyin awọn ọmọ-alade Midiani. Ninu awọn asọtẹlẹ Isaiah si Israẹli, o tọka si bi a ti ṣẹgun awọn ara Midiani lati ọwọ Ọlọrun (Wo Isaiah 10:26; 9:4).

Questions
AWỌN IBEERE

1. Bawo ni Ọlọrun ṣe ki Gideoni laya lati bá awọn ara Midiani jà?

2. Ṣe apejuwe bi Gideoni ṣe wewe ogun naa.

3. Ki ni ṣe ti awọn ọkunrin Efraimu fi n ṣe ilara Gideoni?

4. Bawo ni Gideoni ṣe paná ibinu wọn?

5. Ki ni ẹṣẹ awọn ara Sukkotu ati Penueli?

6. Lọna wo ni Jesu paapaa gba jiya ẹsìn bakan naa?