Matteu 20:1-16

Lesson 183 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “ọpọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a o ri yàn” (Matteu 20:16).
Notes

Awọn Oṣiṣẹ Fun Ọgbà-Ajara

Owe yii ti Jesu kọ ni jẹ nipa Ijọba Ọlọrun. Dajudaju Oluwa funra Rẹ ni ọkunrin ti o n wá awọn oṣiṣẹ fun ọgba-ajara rẹ duro fún. Ọlọrun maa n lo ọkunrin ati obinrin, ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin lati tan Ihinrere kálẹ, lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa itan igbala nipa Ẹjẹ Jesu. Ọlọrun i ba ti lo awọn angẹli tabi ohun miiran, ṣugbọn O fi anfaani naa silẹ fun awọn eniyan Rẹ. O n fẹ awọn oṣiṣẹ sibẹ. Aye n bẹ ninu ọgbà-ajara Rẹ fun olukuluku ẹni ti yoo ba jẹ ipe Rẹ.

Ninu owe yii, ọkunrin naa jade lọ ni kutukutu owurọ lati pe awọn ọṣiṣẹ. O ba awọn oṣiṣẹ kan ṣe adehun lati san owo-idẹ kọọkan fun wọn ni oojọ. A sọ fun ni pe owo-idẹ kan jẹ owo ijọba Romu ti a le fi wé kọbọ meje ati aabọ ninu owó ti wa, o si jẹ owo-ọya ti o tọ ti o si yẹ ni ijọ wọnni. Nigba ti wọn ti pari àdéhun wọn, awọn oṣiṣẹ naa wọ inu ọgbà-ajara lọ.

Diduro Lai Ri Ṣe

Baale ile naa tun jade lọ lati pe awọn oṣiṣẹ miiran. Ni wakati ẹkẹta ọjọ (agogo mẹsan owurọ) o ri awọn miiran ti wọn duro nibi ọja lai ri ṣe. O pè wọn lati ṣiṣẹ ninu ọgbà-ajara rẹ, o si ṣe ileri lati san ohunkohun ti o ba tọ fun wọn.

Ni wakati kẹfa ati kẹsan ọjọ (ni agogo mejila ati agogo mẹta ọsan) o tun jade lọ. O ri awọn alairiṣe miiran ti o duro, awọn ẹni ti o sọ fun pe ki wọn lọ ṣiṣẹ fun oun. Ni wakati kọkanla, o kù diẹ ki iṣẹ oojọ pari, o tun jade lọ. O wi fun awọn alairiṣe pe ki wọn lọ si inu ọgbà-ajara oun gẹgẹ bi alagbaṣe. O ṣeleri lati san ohun ti o ba tọ fun wọn.

Fun Ju Ṣaaju ati fun Helleni Pẹlu

Ipe Ọlọrun fun awọn oṣiṣẹ ti n jade lọ fun ọpọlọpọ ọdun. Boya ipe ti kutukutu owurọ dabi eyi ti a rán si awọn Ju, awọn eniyan ti Oluwa kọ pè. Awọn Ju ni Jesu kọkọ tọ lọ. Nigba ti Jesu rán awọn ọmọ-ẹyin mejila jade lati waasu Ihinrere (Ẹkọ 81), àṣẹ Rẹ ni pe, “Ẹ máṣe lọ si ọna awọn Keferi.” Awọn Ju ni wọn gbọdọ waasu fun (Matteu 10:5, 6).

Bi o tilẹ jẹ pe awọn Ju ni a kọ pè, ki i ṣe awọn nikan ni Ọlọrun pè. Lẹyin naa, ipe naa jade si awọn Keferi pẹlu. Ninu ori kọkanla iwe Iṣe Awọn Aposteli, Peteru sọ iriri rẹ nipa pe Ọlọrun rán oun lati waasu fun idile Korneliu, Keferi balogun ọrún, ni Kesarea. Peteru wi pe: “Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun ki iṣe ojusaju enia: ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bẹru rẹ, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ” (Iṣe Awọn Aposteli 10:34, 35). Lẹyin ti wọn gbọ iroyin iriri Peteru, awọn ọmọ-ẹyin wi pe, “Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si iye fun awọn Keferi pẹlu” (Iṣe Awọn Aposteli 11:18).

Bẹrẹ lati ọjọ ìwà, Ọlọrun ti n rán ipè jade fun awọn ti yoo ṣiṣẹ ninu ọgbà-ajara Rẹ. Awọn ti wọn ti tẹwọgba a “ti rù ẹrù”, wọn si ti “faradà õru ọjọ” lati fi idi Ihinrere mulẹ nigba ti idojukọ lile wà. Wọn ti ṣe wahala, wọn si ti gbadura lati tan ẹkọ Kristi kálẹ de ipẹkun ayé.

A ti sọ fun ni pe igba ikẹyin ikore ni a wà yii. Lai ṣe aniani ipè lonii fun awọn oṣiṣẹ dabi ipe ti wakati kọkanla ọjọ. Ikore ti fẹrẹ pari, ṣugbọn anfaani wà sibẹ lati jẹ ipe Ọlọrun.

Oṣiṣẹ, Ki i Ṣe Alairiṣe

Ọlọrun ki ifi agbara mu ni ṣiṣẹ ninu ọgba-ajara Rẹ. Awọn alagbaṣe Rẹ maa n gba owo-ọyà -- igbala kuro ninu aini nipa ti ẹmi. Olukuluku eniyan ni o gbọdọ yan ipa ti rẹ. Lọjọ kan, olukuluku eniyan ni yoo duro niwaju Ọlọrun lati jihin nipa igbesi-aye rẹ (Romu 14:12) ati awọn ohun ti o ti ṣe, i baa ṣe rere tabi buburu. I ha ṣe pe o kàn duro ni ní gbogbo ọjọ lai ri ṣe, lai wá ohun kan ti o ṣe gùnmọ ṣe fun Ọlọrun, lai ṣe ohun kan ti o ni laari?

Oriṣiriṣi Iṣẹ

Ọlọrun a maa gba oṣiṣẹ si iṣẹ fun idi kan – lati ṣiṣẹ ninu ọgbà-ajara Rẹ. Aye kò si fun awọn ti kò ni ṣiṣẹ; kò si aye fun awọn ti wọn fẹ wà lai ri ṣe. A kò gba awọn oṣiṣẹ inu owe yii fun iṣẹ kan pato bi gbíngbìn, gige ẹka, titu èpò, tabi kikore. Ọlọrun paapaa n fẹ awọn ẹni ti yoo ṣe iṣẹ ti Oun ba yàn le wọn lọwọ.

Ninu ọgbà-ajara, oriṣiriṣi iṣẹ ni o wà ti a ni lati ṣe ki a to le kore ohun ọgbìn. Lakọkọ, a ni lati gbin irugbin ki a maa tọju rẹ, ki a bomi rin in, ki a ge ẹka rẹ, ki a tu èpò ibẹ, ki a fọn oògùn apakokoro si i lara, boya ki a si bu ilẹdu yi i ká pẹlu. Ki a ba le ni ikore ni a ṣe n ṣe gbogbo nnkan wọnyii. Ninu ọgbà-ajara Ọluwa pẹlu, ọpọlọpọ ẹka iṣẹ ni o wà ninu itankalẹ Ihinrere ati igbala ọkàn. Ki i ṣe gbogbo eniyan ti o ba jẹ ipe Ọlọrun ni o le di oniwaasu tabi oṣiṣẹ ti n gba awọn ti n wá igbala ni iyanju. Iru ipade wo ni yoo wà ti awọn alo ohun-elo orin kò ba si tabi lo ohun-elo orin wọn, bi ko ba si ẹni ti o kọrin, ti ẹnikẹni kò jẹri, ti ko si si ẹni ti o gbadura? Iru ile-iṣẹ wo ni yoo wa ni iya-ijọ wa bi kò ba si ẹni ti n ka lẹtà, ti ẹnikẹni ko ba fesi awọn lẹta naa, ti ẹrọ itẹwe kò ba ṣiṣẹ, ti ko si ẹni ti o pín awọn iwe itankalẹ ihinrere pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ, ti ko ba si ẹni ti gbá ilẹ tabi nu ijoko, ti a ko gba ni niyanju tabi fun ni ni ọrọ iṣiri, ti ẹnikẹni ko si gbadura?

Boya o n bere ki ni ọmọde le ṣe. A ni lati pe awọn eniyan wá si Ile-ẹkọ Ọjọ-Isinmi ati si awọn isin. Ẹni kan ni lati gbadura fun awọn ọkàn ti n ṣegbe. Orin wa fun kikọ, ati ẹri lati jẹ. Ẹni kan gbọdọ gbadura fun awọn ipade, ati fun awọn iwe itankalẹ Ihinrere pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ. Awọn wọnyii ki ha ṣe iṣẹ ti olukuluku ọmọde ti o ti ri igbala le ṣe? O ha yẹ ki eniyan duro lai ri ṣe nigba ti o jẹ pe, nipa níní awọn iriri wọn ti ẹmi ati mimu talẹnti wọn lò, wọn le ṣe ara wọn yẹ sii, ki wọn si jẹ oṣiṣẹ ti o wulo sii bi Oluwa bá fa bibọ Rẹ sẹyin?

Ipe Ọlọrun si Awọn Ọmọde

Nígbà miiran, a maa n fi ipe owurọ kutukutu ṣe akawe ipe Ọlọrun si awọn ọmọde. Awọn miiran ti jẹ ipe naa, bi Jesu si ti fa bibọ Rẹ sẹyin, wọn ti lo ọpọlọpọ ọdun ninu iṣẹ-isin Oluwa. Awọn miiran kò jẹ ipe naa nigba ti wọn wà ni ọmọde. Boya Ọlọrun ti jẹ oloootọ lati tún wọn pè, ni akoko ọtọọtọ ninu igbesi-aye wọn, sibẹ wọn a ba ara wọn ninu wakati kọkanla igbesi-ayé wọn, boya arugbo ati alairi igbala. Wọn ko ha mọ pe akoko wọn ti fẹrẹ buṣe lati ṣiṣẹ fun Oluwa? O ti ṣe laanu pupọ to nigba ti awọn eniyan ba kọ ipe Ọlọrun! Bawo ni igbesi-ayé wọn ti n gbadun ti o si maa n wulo to nigba ti wọn ba tẹwọgba ipe lati ṣiṣẹ ninu ọgbà-ajara Ọlọrun.

Wakati Ikọkanla

Bawo ni àya eniyan ti n já to nigba ti a ba ri awọn ọdọmọde ti wọn kọ ipe si iṣẹ Ọlọrun! Boya ni wakati ẹkẹta tabi ẹkẹfa, tabi ẹkẹsan ni wọn n gbero lati lọ sinu “ọgba ajara.” Kò si idaniloju pe wọn yoo darugbo ki wọn to ṣe aisi; boya lọwọlọwọ bayii, ni wakati kọkanla igbesi-aye wọn ni wọn wà. O dabi ẹni pe ọpọlọpọ eniyan kò fura pe ikore ti fẹrẹ bu ṣe. Wakati kọkanla n sure kọja tete. Lonii Ọlọrun n nawọ ipe jade lati wọ inu ọgba-ajara Rẹ. Ta ni le mọ boya ipe ikẹyin ni yii?

Owo Ọya

Ohun kan tun wà ninu owe yii ti Jesu kọ ni – sisan owo ọya. Nigba ti o di ọjọ alẹ, a pe awọn oṣiṣẹ naa lati gba owo iṣẹ wọn. Awọn ti wọn ṣiṣẹ fun wakati kan pere gba iye owo kan naa pẹlu awọn ti wọn ti fi gbogbo ọjọ ṣiṣẹ. Owo-idẹ kan ni wọn gbà, wọn si gba a ṣaaju awọn iyoku. Dajudaju eyi jẹ eto owo sisan ti o yatọ si bi a ti n ṣe láyé lode oni. Bẹẹ ni ọna Ọlọrun kò dabi ti eniyan. Bi o tilẹ jẹ pe eniyan ti o ba ri igbala a maa ṣiṣẹ fun Oluwa nitori o wu u lati ṣe bẹẹ, Ọlọrun ní owo ọya fun awọn ti o ba jẹ oloootọ pẹlu.

Awọn kan kùn, ṣugbọn a ko dá kikun wọn lare ni iwaju Ọlọrun. A rán wọn leti adehun wọn, a si wi pe ki wọn maa lọ. Ọlọrun ko ni inu didun si awọn eniyan ti wọn ro pe iṣẹ ti awọn n ṣe pọ ju nigba ti awọn ẹlomiran kò ṣiṣẹ tó, tabi pe ibukun Ọlọrun lori wọn kò pọ to nígbà ti ibukun ti awọn ẹlomiran pọ pupọ.

Fun Awọn Oloootọ

Ọlọrun ki i sanwo ti o pọ ju fun awọn ti wọn ti ri igbala fun ọjọ pipẹ tabi fun awọn ti o dabi ẹni pe wọn ti ṣe iṣẹ ti o pọ pupọ fun Un. Odiwọn iṣẹ wa ninu ọgba ajara Oluwa ni iru iṣẹ ti a ṣe, ki i ṣẹ titobi iṣẹ naa. Iwọ yoo gba “owo idẹ kan” ti rẹ bi o ba ti jẹ oloootọ ninu iṣẹ ti Ọlọrun ti fun ọ, ti o ba si sa gbogbo ipá rẹ fun Jesu ati fun ọla ati ogo Rẹ. “Eyi ti o ba tọ li ẹnyin o ri gbà.”

Bi iṣẹ-isin rẹ fun Ọlọrun ba ti jẹ lati polongo talẹnti rẹ dipo lati jẹwọ ifẹ ati aanu Ọlọrun, bi ohun ti o ba ṣe ba jẹ arojuṣe dipo ki o fi: “tọkantọkan ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa,” bi o ba ti fi imọ-ti-ara-ẹni-nikan gba kiki awọn anfaani ti o wu ọ nigba ti o ko ri àyè fun awọn iṣẹ ti o rẹlẹ tabi eyi ti o farasin, o ha tọ si owo-ọya bi?

Awọn ti A ti Pè ti A si Yàn

Owe naa pari pẹlu ọrọ yii “Bẹẹli awọn ẹni ikẹhin yio di ti iwaju, awọn ẹni iwaju yio si di ti ikẹhin: nitori ọpọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a o ri yàn.” Awọn ti o kẹhin lati ri igbala, sibẹ ti wọn fi tọkantọkan ṣiṣẹ fun Ọlọrun, yoo ri “eyi ti o ba tọ” gbà gẹgẹ bi awọn ti wọn kọkọ rí igbala.

Ipe lati jẹ alagbaṣe ninu ọgba-ajara Ọlọrun jade si gbogbo eniyan. Ọpọlọpọ ni a pè: ṣugbọn ki i ṣe gbogbo eniyan ni wọn n jẹ ipe naa, nitori bẹẹ a ko yàn wọn. Ti Ọlọrun ni lati pè; lati jẹ ẹni ti a yàn wa lọwọ rẹ. Oluwa le pè ọ, ki O si yàn ọ. A ti pè ọ. A ha ti yàn ọ?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Fun eredi wo ni a ṣe gba awọn alagbaṣe naa?
  2. Ki ni ṣe ti awọn kan duro ni airiṣe?
  3. Èló ni ọkunrin naa pinnu lati san?
  4. Iru owo ọyà wo ni Ọlọrun maa n san?
  5. Awọn wo ni Ọlọrun maa n fun ni “owo idẹ kọọkan li õjọ”?
  6. ọnà wo ni ẹni ikẹyin ṣe le di ẹni iṣaaju?
  7. Ki ni iyatọ ti o wà laaarin jijẹ ẹni ti a pè ati ẹni ti a yàn?