Matteu 20:20-28

Lesson 184 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu nyin, jẹ ki o ma ṣe ọmọ-ọdọ nyin” (Matteu 20:27).
Notes

Ipe Jakọbu ati Johannu

Ninu awọn ọmọ-ẹyin mejila Jesu ní awọn meji kan ti a n pè ni Jakọbu ati Johannu wà. Jesu pe wọn lati maa tọ Oun lẹyin ni ọjọ kan nígbà ti O kọja nibi ti wọn ti n tún àwọn wọn ṣe. Wọn fi iṣẹ wọn silẹ lati di apẹja eniyan.

Fun ọdun mẹta Jakọbu ati Johannu ti fi itara tẹle Jesu. O pe wọn ni ọmọ aara, boya nitori igboya ti wọn fi n gbeja Rẹ. Wọn ti fẹ pe ina sọkalẹ lati Ọrun wá lati pa awọn ara Samaria kan run ti wọn fi igba kan ṣai bọwọ fun Jesu. Nigba ti wọn si ri ọkunrin kan ti o n fi orukọ Jesu le awọn ẹmi eṣu jade, ti kò si ba wọn rin, wọn wi pe ki Jesu ba a wi.

Jesu mọ pe Jakọbu ati Johannu fẹran Oun pupọ, ohun ti wọn si ro pe o tọ ni wọn n ṣe lati gbiyanju lati wu U ati lati ran An lọwọ; ṣugbọn Jesu ki ṣe nnkan ni ọna ti eniyan nipa ti ara. O ṣe alaye pe Oun ko ni ikorira fun awọn ara Samaria, ati pe n ṣe ni Oun wá lati fihàn wọn bi wọn ṣe le ri igbala, ki i ṣe lati pa wọn run. O si fi ye wọn pe ọkunrin ti o n le awọn ẹmi eṣu jade yii ni lati wà níhà ti wọn bi kò bá ti ṣe lodi si wọn.

Agbo ti Inu

Jesu fẹran Jakọbu ati Johannu, awọn pẹlu Peteru si jẹ ẹgbẹ kan ti a le pe ni “agbo ti inu.” Wọn maa n bá Jesu rìn ju eyikeyi ninu awọn ọmọ-ẹyin iyoku. Wọn ti wà pẹlu Rẹ lori Oke Ipalarada, nigba ti a ṣe E logo; wọn si ti gbọ ti Mose ati Elijah n bá Jesu sọrọ.

Ni ìgbà miiran Peteru, Jakọbu ati Johannu nikan ni Jesu maa n mu lọ pẹlu ara Rẹ nigba ti O ba ṣe iṣẹ-iyanu nla. Ni akoko kan a pe E lati wa wo ọmọbinrin kan ti o ti kú sàn. O mu ki gbogbo eniyan iyoku jade kuro ninu yara naa, kiki Peteru, Jakọbu ati Johannu nikan ni wọn ri I ti O fi ọrọ Rẹ pe ọmọbinrin naa pada si ayé.

Ju iwọnyi lọ, a pe Johannu ni ayanfẹ Ọmọ-ẹyin. Inu rẹ ni lati dùn pupọ-pupọ lati ri ojurere ifẹ ti o tayọ bayii gbà lọdọ Jesu.

Ijọba ninu Ọkàn

Ṣugbọn pẹlu gbogbo nnkan wọnyi, Jakọbu ati Johannu ko i ti kọ ohun ti Jesu kà si titobi ni tootọ. Oye kò yé wọn pe Ijọba Rẹ ní lati bẹrẹ ninu ọkàn wọn nibi ti ẹnikẹni kò le ri i, ati pe kò ni jẹ iru ijọba bi ti Kesari. Wọn ro pe dajudaju Jesu yoo jẹ ọba nla ati alagbara nígbà ti O ba gbe itẹ Rẹ kalẹ, ati pe yoo si fẹ awọn alakoso ati awọn olori ogun lati ṣe iranwọ fun Un lati ṣe akoso -- ati lati pin ninu ọlá Rẹ. Wọn si gbero pe, ẹlomiran wo ni i ba tun tọ si ju awọn lọ lati gbadun iru ojurere bayii pẹlu Jesu?

Ẹbẹ ti Kò Tònà

Iya Jakọbu ati Jahannu le ti maa ṣogo pe Jesu ti pe awọn ọmọ oun lati ba A rin timọtimọ; lai ṣe aniani o rò pe ibeere oun tọna nigba ti o wi fun Un pe: “Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ òsi ni ijọba rẹ.”

Jesu mọ pe oye ohun ti wọn n beere kò yé wọn. Ninu ọkàn wọn, wọn le ri awọn ijọba aye ti n bu ọla fun ẹni kan bi ọba, ti wọn si n yẹ awọn ẹlomiran si ti wọn jẹ balogun ati ijoye labẹ ọba naa. Eniyan nipa ti ara maa n fẹ iyin ati apọnle. Ṣugbọn iru ẹmi ti o yatọ ni Jesu n fẹ ninu ọkàn awọn ọmọ-ẹyin Rẹ. O fẹ fi igbesi-aye Rẹ ṣe apẹẹrẹ bi Oun ti n fẹ ki wọn rin.

Iranṣẹ

Jesu sọ pe Oun wà laaarin wọn bi ẹni ti n ṣe iranṣẹ -- tabi gẹgẹ bi iranṣẹ. Oun wá lati ṣe awọn ẹlomiran loore, Oun kò si reti pe ki wọn ṣe iranṣẹ fun Oun. Awọn ẹni ti o ba fẹ jẹ ẹni nla ninu Ijọba Rẹ, ti wọn si n fẹ maa gbe nitosi Rẹ ni lati ṣe gẹgẹ bi Oun ti ṣe. O wi pe: “Bi ẹnikẹni ba nfẹ ṣe ẹni iwaju, on na ni yio ṣe ẹni ikẹhin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn” (Marku 9:35).

Awọn ọmọ-ẹyin rò gẹgẹ bi iwọ ati emi le ti ṣe, pe ki a to le di eniyan pataki, a gbọdọ ṣe nnkan ninu ayé, boya ki a jẹ aṣiwaju awọn eniyan. Ninu ijọba ti aye, wọn maa n bu ọla fun ọgagun ti o ba ti ṣẹ ọpọlọpọ ogun fun ilu rẹ; eniyan ti o ba si ṣe awari ọgbọn ijinlẹ pataki, tabi ti o ti di ọlọrọ nipa jijẹ akinkanju oniṣowo, maa n ni iyẹsi pẹlu. Oju aye wà lara iru awọn eniyan bẹẹ, ṣugbọn diẹ ninu wa ni o le ti ipa bayii di gbajumọ.

Inu wa ti dun to pe Jesu wi pe: “Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmi: nitori tiwọn ni ijọba ọrun.” “Alabukún-fun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo: nitori tiwọn ni ijọba ọrun” (Matteu 5:3, 10). A ko bikita ohun ti ayé le fi wa pè, niwọn bi igbesi-ayé wa ba ti wu Jesu. Oun yoo fun wa ni èrè nitori iṣẹ oore kekere ti a ṣe bi a ba jẹ oloootọ si eyi ti O pè wa si. “Ẹnikẹni ti o ba fi kiki ago omi tutù fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin, lõtọ ni mo wi fun nyin, ki o padanù ère rẹ” (Matteu 10:42).

O ni lati ya awọn ọmọ-ẹyin lẹnu pupọ nigba ti Jesu gbé ọmọ kekere kan lé ẹsẹ Rẹ ti O wi pe: “Ẹnikẹni ti o ba rẹ ara rẹ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio papọju ni ijọba ọrun” (Matteu 18:4).

A le ri pe iru ero kan naa nipa Ijọba Kristi ni o wà ninu ọkàn awọn ọmọ-ẹyin mẹwaa iyoku bi ti Jakọbu ati Johannu. Inu wọn kò dùn si awọn mejeeji nitori o dabi ẹni pe wọn n fẹ lọ ṣaaju awọn mẹwaa iyoku lati yan ipo ti o dara ju lọ.

Ṣiṣe Oloootọ ninu Ohun Kinnkinni

Ninu owe kan ti Jesu pa, oluwa naa wi fun ọmọ-ọdọ rẹ pe, “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere: nitoriti iwọ ṣe olõtọ li ohun kikini, gbà aṣẹ lori ilu mẹwa” (Luku 19:17). Wo bi iyatọ naa ti tobi to! O ṣe oloootọ ninu ohun kikini a si wá fun un ni àṣẹ lori mẹwaa.

Yiyọọda lati Jiya fun Kristi

Oye ko i ti i ye awọn Aposteli Jesu naa pe ohun ti kò tọna ni wọn n beere fún, nigba ti Jesu si bi wọn bi wọn ba fẹ lati bá Oun jiya ki ipo ti wọn n wá ba le tẹ wọn lọwọ, lọgan ni wọn gbà pe awọn yoo ṣe bẹẹ.

Jesu mọ ọkàn wọn. O si wi pe: “Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi….ṣugbọn lati joko li ọwọ ọtún ati li ọwọ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kiki awọn ẹniti a ti pèse rẹ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá.” Lati kú nitori Kristi kò ni fun wọn ni ẹtọ lati ni ayè ni Ọrun bi Ẹjẹ Jesu kò ba wẹ ọkàn wọn mọ. Olukuluku eniyan gbọdọ kọ ni igbala ná ki o to le ri èrè gbà ni Ọrun fun iṣẹ rẹ.

Jakọbu ni o wá di ajẹriku kin-in-ni ninu awọn mejila. Oun pẹlu awọn Aposteli iyoku mu aṣẹ Kristi ṣẹ lati lọ si ibi gbogbo lati maa waasu pe Jesu ti kú ki O ba le ṣe etutu fun ẹṣẹ, O si ti tun ji dide. Ẹkọ yii bí eniyan pupọ ninu gidigidi nitori wọn kò fẹ gbagbọ pe nitootọ ni Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun ati pe O jinde kuro ninu òkú. Ọba Herọdu fẹ tẹ awọn Ju ti wọn korira Jesu lọrun, nitori bẹẹ o mu Jakọbu o si fi ida bẹ ẹ ni ori sọnu. Jakọbu ti wi pe oun gbà lati jiya fun Kristi; nígbà ti a dan an wo, kò sá padà.

Johannu paapaa, ni iriri ẹkọ ti Jesu kọ wọn ni akoko naa. Oun ni Aposteli ti a lé lọ si erekuṣu adado ti a n pe ni Erekuṣu Patmo nitori iwaasu rẹ. Nibẹ ni Ọlọrun ti yẹ ijolootọ rẹ si nipa fi fun un ni iran ọjọ iwaju. Johannu ri Jerusalẹmu Titun, orukọ ti rẹ si pẹlu ti awọn Aposteli mejila lara awọn okuta ipilẹ. Ni akoko naa oun kò bikita nipa gbigbe ara rẹ soke mọ, ọkàn rẹ kò si ni ṣai rẹlẹ pupọ nigba ti o ri ogo ti Ọlọrun yoo fi fun oun. Johannu kọ gbogbo nnkan ti o ri silẹ, o si wà ninu Bibeli gẹgẹ bi Iwe Ifihan.

Isin Atọkanwa

Gbogbo wa ni a le ni ẹmi ti o n fẹ ṣe iranṣẹ fun ẹlomiran dipo pe ki gbogbo nnkan jẹ ti wa. Lẹyin ti a ba ti ri igbala, a ni lati tẹsiwaju lati maa gbadura ki a si maa ka Ọrọ Ọlọrun. Bi a ba ti n fi aye wa rubọ fun Ọlọrun to, bẹẹ ni yoo rọ wa lọrun to lati fẹ ṣe ohun ti Jesu n fẹ ki a ṣe, bi o tilẹ jẹ pe lakọkọ, a le rò pe a kò ni le ṣe ohun naa gan an. A le ri ki awọn ọrẹ wa kó nnkan aye jọ ju eyi ti awa ni: awọn eniyan le maa yẹ wọn si nigba ti o jẹ pe kò si ẹni ti o bikita fun wa. Ṣugbọn Jesu mọ ọkàn wa, bi a ba si n dù lati wu U lọnakọna, lọjọ idajọ Oun o sọ fun wa pe: “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ sinu ayọ oluwa rẹ” (Matteu 25:23).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni awọn ọmọ-ẹyin rò nipa ijọba Kristi?
  2. Ta ni Jakọbu ati Johannu i ṣe?
  3. Ki ni Jakọbu ati Johannu n fẹ?
  4. Ninu ẹkọ yii, ki ni Jesu kà ara Rẹ sí, oluwa tabi iranṣẹ?
  5. Iru ipo wo ni O n fẹ ki awọn ọmọ-ẹyin Rẹ fi ara wọn si?
  6. Ki ni awọn ọmọ-ẹyin naa wi pe awọn ti mura tán lati ṣe fun Jesu?
  7. Bawo ni Jakọbu ṣe fihan pe oun yoo fi gbogbo aye rẹ fun Jesu?
  8. Iya wo ni Johannu jẹ fun wiwaasu nipa Jesu?
  9. Ere wo ni Johannu ri fun ara rẹ nigba ti o ri Jerusalẹmu Titun?
  10. Bawo ni Oluwa yoo ṣe san èrè fun awọn ọmọlẹyin Rẹ oloootọ?