Lesson 185 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Mã lọ; igbagbọ rẹ mu ọ larada” (Marku 10:52).Notes
Lẹba Opopo ọna
Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rẹ n rin kọja laaarin ilu Jẹriko bi wọn ti n kọja lọ si Jerusalẹmu. Eyi ni irin-ajo ikẹyin ti Jesu yoo rin la ilu Jẹriko kọja, nitori akoko sunmọ etile ti Jesu yoo fi “ẹmi rẹ ṣe irapada fun ọpọlọpọ enia” (Marku 10:45). Ọpọlọpọ eniyan ni wọn tẹle Jesu.
Bartimeu, ọmọ Timeu jẹ afọju. O jokoo ni ẹba ọna o n ṣagbe. Kò si ọna miiran fun un lati ri ounjẹ oojọ rẹ. Bi o ti gbọ iro ọpọ eniyan ti wọn n tẹle Jesu, o wadii ohun ti o ṣẹlẹ. Nigba ti o gbọ pe “Jesu ti Nasareti ni”. Bartimeu bẹrẹ si kigbe pè E.
Anfaani Kan
Kò si ọna fun ọkunrin afọju yii lati mọ daju pe Jesu ni. O gba iroyin naa gbọ; o si gbagbọ jinlẹ ninu ọkàn rẹ lọhun pe Jesu yoo ran oun lọwọ.
Ọpọlọpọ eniyan ti wọn wà ninu ipọnju ti ara ati ti ẹmi, ni wọn ti ni iru anfaani kan naa ti Bartimeu ni. Awọn miiran kò gbà pe awọn n fẹ iranwọ lati ọdọ Oluwa, bi o tilẹ jẹ pe ko si oluranlọwọ fun wọn nipa ti ara, ti oju wọn si fọ si awọn ohun ti ẹmi. Ọpọlọpọ ni wọn ti gbọ iroyin pe Jesu ti Nasareti wà nitosi, ṣugbọn wọn kò gbagbọ. Awọn miiran ti wọn si mọ pe wọn kò le ran ara wọn lọwọ ti gbọ iroyin otitọ yii, sibẹ wọn kò ké pe Jesu fun iranlọwọ. Nitori eyi wọn kò ri iranlọwọ gbà yala nipa ti ara tabi nipa ti ẹmi. A kà ninu Iwe Jakọbu ori 4 ẹsẹ 2 pe, “Ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kò bère.”
Awọn ẹlomiran wà ti wọn nireti lati gbadura ni ọjọ kan: wọn n reti lati beere fun aanu lọdọ Jesu ni ọjọ kan, ni “akoko ti o wọ”, ni wọn n wi (Iṣe Awọn Aposteli 24:25). Ẹkọ yii n fihàn bi fifi ọran falẹ ti lewu tó: Jesu kò gba Jẹriko kọja mọ. Anfaani kan ṣoṣo ti o kù fun Bartimeu lati ri iranlọwọ gba ni eyi: “igba miiran” ko tun dé mọ. Bi Bartimeu ba ti fi akoko adura rẹ falẹ, boya ki ba ti le riran mọ, boya ki ba tun ni anfaani miiran lati beere fun aanu mọ, tabi anfaani lati tẹle Jesu.
Aanu
Nipa pipe ti Bartimeu pè, o fihàn pe o gbàgbọ pe Jesu ni Ọmọ Ọlọrun ti a ṣeleri. Nigba ti Bartimeu pe Jesu ni “ọmọ Dafidi” eyi jẹ ọkan naa bi igba ti o wi pe “Jesu, Olugbala ti a ṣeleri.” Bartimeu beere fun aanu. Oun kò wi pe o yẹ ki oun riran, tabi pe oun ti ṣe ohun ti o yẹ ki a fi eyi san an pada fun oun, tabi pe ẹtọ oun ni. Adura rẹ ni pe ki Ọlọrun ṣaanu fun oun. Igbe rẹ jẹ ti ẹbẹ fun iranwọ fun ara rẹ -- “Ṣãnu fun mi.”
Kò Rẹwẹsi
A kò sọ fun wa pe Jesu fihàn pe Oun gbọ igbe àkọkọ ti ọkunrin afọju yii ké. Awọn ti o yi Bartimeu ka n fẹ lati dá a lẹkun ẹbẹ ti o n bẹ. Boya wọn n sọ fun un pe o n di awọn ẹlomiran lọwọ lati gbọran tabi pe Jesu kò ri ayè fun iru eniyan bi ti rẹ. Awọn ẹlomiran ti ni iru iriri bẹẹ nigba ti wọn kọkọ ke pe Jesu fun aanu. Boya o dabi ẹni pe a kò gbọ adura wọn ni akọkọ. Boya awọn ti o wà ni ayika wọn gbiyanju lati mu wọn rẹwẹsi. O daju pe Satani yoo wá sọdọ wọn lati mu wọn gbagbọ pe Jesu kò ri àyè fun wọn, pe kò ni gbọ adura wọn.
Gbogbo ohun ti awọn eniyan wọnyii n sọ ko jamọ nnkan kan lati mu irẹwẹsi bá Bartimeu. O n fẹ iranwọ, o si mọ pe oun n fẹ ẹ. O si mọ pe Jesu le ran oun lọwọ, nitori naa o kigbe ju bẹẹ lọ -- dajudaju ni ohun rara ju ti àkọkọ lọ.
Jesu a maa gbọ, a si maa dahun adura ẹni ti o ba pinnu tán. O gbọ ti Bartimeu. Jesu kò tọ ọ lọ ki O si wò ó san nipa pipọfọ, gẹgẹ bi awọn miiran ti le ro pe Jesu yoo ṣe. O paṣẹ pe ki wọn pe Bartimeu wá. Dajudaju ireti nla sọ jade ninu ọkàn Bartimeu nigba ti o gbọ awọn ọrọ wọnyii, “O npè ọ.”
O Sa Ipá Rẹ
Bartimeu bọ agbada rẹ sọnu, gẹgẹ bi eniyan ti ṣe i bọ ẹwu rẹ, ki ohunkohun ma baa di i lọwọ ati ki ohunkohun ma baa fà á sẹyin. Bartimeu lọ si ọdọ Jesu. Kò ṣe awawi. Kò wi pe oun fẹ ki a fa oun lọwọ lọ, fifọju ti oun fọju jẹ idiwọ fun oun. O ṣetán lati lọ nígbà ti Jesu pe e. Boya kò mọ ọna ti yoo gbà lati de ọdọ Jesu, ṣugbọn o dide o si n lọ. Ko daju pe o kọsẹ tabi ki o maa fi ọwọ wá ọnà kiri, nitori ohùn Jesu ni o pe e, o si n fẹ lati dahun ipè naa.
Ojurere Pataki Kan
Jesu beere lọwọ ọkunrin afọju naa ohun ti o n fẹ. Bartimeu afọju kò wi pe Oluwa ti mọ ohun ti oun n fẹ. Ọkunrin afọju naa beere fun oju rere kan, “Rabboni, ki emi ki o le riran.” A le ro pe Jesu mọ ohun ti ẹni ti oju rẹ fọ n fẹ. Jesu mọ ọn ni toootọ. Jesu n fẹ lati gbọ ẹbẹ naa ni ẹnu ọkunrin naa.
Ninu Iwaasu Lori oke (Ẹkọ 21). Jesu kọ ni pe, “Bère, a o si fifun nyin” (Matteu 7:7). Lonii, bi awọn eniyan ba ni nnkan kan lati beere, inu Oluwa a maa dùn pe ki wọn sọ ibeere wọn. Bi eniyan ba n fẹ aanu lọdọ Oluwa nitootọ yoo beere fun un. Bi o ba ti n gba adura, ti o si n reti iwosan fun ara rẹ, tabi iriri kan fun ọkan rẹ, boya iwọ ko i ti i rii gbà nitori iwọ ko beere. “Ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ nyin ki o le kún.” (Johannu 16:24).
Igbagbọ
Jesu wi fun Bartimeu pe, “Mã lọ; igbagbọ rẹ mu ọ larada.” Ki i ṣe “Igbagbọ rẹ yoo mu ọ larada.” Jesu wi pe, “Igbagbọ rẹ mu ọ larada,” tabi igbagbọ rẹ ti mu un larada -- lẹsẹkẹsẹ ti o ti gbàgbọ. “Lojukanna, o si riran.”
Wo bi ọjọ yi yoo ti jẹ ọjọ iyanu fun Bartimeu! O di ẹni ti o n riran! Ki i ṣe pe o kọkọ ṣe baibai, tabi diẹdiẹ; ṣugbọn lẹsẹ kan naa ni o riran. Igbagbọ rẹ ninu Jesu mu imọlẹ wá si ibi ti okunkun ti wà tẹlẹ ri. O mu idasilẹ kuro ninu ibẹru ati aini wá. Oun ki i tun ṣe ẹni ti kò ni iranlọwọ tabi ti kò ni ireti. Wo o bi ayọ rẹ ti pọ to pé o beere fun aanu lọdọ Jesu! Wo iru iyipada ti o ṣẹlẹ nigba ti Bartimeu gbagbọ!
A kò sọ fun wa bi o ti pẹ to ti Bartimeu ti fọju tabi boya o tilẹ ti riran nigba kan ri. A ko sọ ohun ti o fa a ti o di afọju. Awọn nnkan bẹẹ kọ ni Kristi n wò. Jesu n fẹ igbagbọ ninu ọkàn. Jesu sọ fun ọkunrin miiran pe: “Bi iwọ ba le gbagbọ, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ” (Marku 9:23).
Awọn Miiran ti A Mu Laradá
Bartimeu nikan kọ ni ẹni ti o ri iwosan gba fun ara rẹ nitori o gbagbọ. A ti kà nipa obinrin kan ti o ri imularada nígbà ti o fi ọwọ kan eti aṣọ Jesu (Ẹkọ 80), ẹni ti Jesu sọ fun pe, “Ọmọbinrin, igbagbọ rẹ mu ọ larada” (Marku 5:34). A ti kà nipa ọmọ-ọdọ balogun ọrún (Ẹkọ 32) ẹni ti o ri imularada “ni wakati kanna,” ti Jesu sọ ọrọ wọnyii fun balogun ọrún naa: “Mã lọ, bi iwọ si ti gbagbọ, bẹẹni ki o ri fun ọ” (Matteu 8:13).
Bartimeu nikan kọ ni afọju ti o riran nitori o ni igbagbọ. Nigba miran, ọkunrin afọju meji ké pe Jesu fun aanu. O fọwọ kan oju wọn. O si wi pe “Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ nyin,” (Matteu 9:29, 30). Oju wọn si là.
Imularada fun Ọ
Ki i ṣe ni akoko ti a kọ akọsilẹ Bibeli nikan ni Jesu n ṣe iwosan ara ti o ṣe alaida. Ọpọlopọ ní akoko ti wa yii ti wọn ni igbagbọ kan naa ti Bartimeu ni ninu Kristi ni a ti wosan ninu aisan ati arun ti o ṣoro. Agbara wà ninu Ẹjẹ Jesu lati gba ọkàn là ati lati wo ara sàn. Imularada jẹ anfaani kan ti a pese silẹ ninu Ọrọ Ọlọrun. Wolii Isaiah kọ akọsilẹ yii ti o n tọka si Jesu, “Nipa ina rẹ ni a fi mu wa lara da” (Isaiah 53:5). Aṣẹ yii ni a pa fun wa fun imularada: “Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: Adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide... ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada” (Jakọbu 5:14-16).
Ki Jesu to goke lọ si Ọrun, O fi aṣẹ nla lelẹ pe ẹ lọ “si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.” O tun wi bayii pe, “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ…. nwọn o gbé ọwọ le awọn olokunrun, ara wọn ó da” (Marku 16:17, 18). Jesu ṣe iṣẹ-iyanu ti iwosan ti o pọ lọpọlọpọ. O sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe awọn ẹni ti o gbagbọ yoo ṣe ohun wọnni ti Oun ti ṣe “iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe” (Johannu 14:12).
Awọn Ẹri
A ni awọn ẹri ti o pọ gẹgẹ bi akọsilẹ nipa awọn ti wọn ti ṣaisan ti a si ti wosan nipa adura igbagbọ. Awọn ọmọde ti ri iwosan nigba ti awọn obi wọn gbadura pẹlu igbagbọ. Ọlọrun a maa yẹ adura ati igbagbọ awọn ọmọ kekere sí pẹlu. Ọpọlọpọ eniyan ni wọn ti ri imularada nipa adura ati igbagbọ ọmọ kekere.
Lode oni, Jesi ti fi iriran fun awọn ti wọn fọju, gẹgẹ bi O ti ṣe fun Bartimeu. Ọdọmọkunrin kan n jọsin laaarin wa, ẹni ti nnkan ta ba ni oju ti oju rẹ si fọ ni akoko Ogun Ajakaye Keji. Kò si ireti pe yoo riran mọ. Wọn ṣe eto lati rán an pada si ile lai riran. O gbadura o si ni nigbagbọ ninu Jesu kan naa ti O sọrọ fun Bartimeu. Gẹgẹ bi ti Bartimeu, Oluwa si wo oju rẹ sàn. Ẹri ọmọkunrin yii ni a kọ silẹ ninu iwe pẹlẹbẹ ti Ijọ Igbagbọ Aposteli “Lori Ọkọ Oju Omi -Enterprise.”
Ẹkọ wa yii jẹ ẹkọ nipa iwosan afoju nipa ti ara. Adura wa ni pe ki ẹkọ Ọrọ naa le fi ireti ọtun ati igboya sinu ọkàn awọn ti aisan n dá loro ninu agọ ara wọn. Jesu n ṣe iṣẹ-iyanu iwosan sibẹ. Boya o ti gbadura fun iwosan o kò si ti i ri idahun; tun gbadura pẹlu igbagbọ. Ẹyin ọmọde, ẹ lọ gbadura, ki i ṣe fun ara yin nikan ṣugbọn ẹ le gbadura fun awọn ẹlomiran pẹlu. Ọlọrun yoo gbọ, yoo si dahun adura yin.
O daju pe Bartimeu ri iriran nipa ti ẹmi gbà pẹlu, nitori o “tọ Jesu lẹhin.” Ninu ẹkọ wa ti a o ṣe lẹyin eyi a o kọ nipa iwosan ati igbala ẹni ti o fọju nipa ti ẹmi.
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni Bartimeu i ṣe?
- Ki ni ṣe ti eyi jẹ anfaani kan ṣoṣo ti o ni lati ri Jesu?
- Ki ni ẹbẹ Bartimeu?
- Ki ni ohun ti o ṣe nigba ti wọn sọ fun un pe ki o “pa ẹnu rẹ mọ?
- Ki ni ṣe ti Jesu beere ohun ti o n fẹ?
- Bawo ni o ṣe riran?
- Ki ni Bartimeu ṣe lẹyin ti a ti mu un larada?
- Bawo ni eniyan ṣe le ri iwosan gbà lọwọ Oluwa lonii?