Luku 19:1-10

Lesson 186 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọmọ-enia ko wá lati pa ẹmi enia run, bikoṣe lati gbà a là” (Luku 9:56).
Notes

Ọfintoto

Okiki Jesu ati iṣẹ-iyanu ti O ṣe ti tàn ká gbogbo Judea ati Galili. Ibikibi ti Jesu ba lọ ni ogunlọgọ eniyan maa n tẹle E, ti wọn si n fẹ lati ri I ki O ṣe ohun abami, bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ ninu awọn eniyan wọnyii kò fẹ lati sin In.

Ninu ọkan ninu awọn irin-ajo Jesu lọ si Jẹriko, agbowo-ode kan, Sakeu wà laaarin awọn ero ti wọn n rọlu ara bi wọn ti n ṣe aapọn lati ri iṣẹ-iyanu ti yoo ṣe. Boya ko tilẹ ro nipa jijẹ ọmọ-ẹyin Jesu, ṣugbọn gbogbo eniyan ni o dabi ẹni pe wọn n fẹ lati ri Ara Nasereti nì, nitori naa oun paapaa n ṣe aapọn lati sunmọ Ọn. Ṣugbọn o ti kuru jù lati riran kọja ori awọn ti o wà niwaju rẹ, ọpọlọpọ eniyan si duro ni ifẹgbẹ-ko¬-ẹgbẹ to bẹẹ ti ko si àyè fun un lati lọ si iwaju. Nitori naa, Sakeu sare lọ gun igi sikamore kan ti o wà lẹba ọnà ti Jesu yoo gbà kọja. Lati ibẹ oun yoo le rí Jesu daradara nigba ti O ba n kọja, a ki yoo si ri oun tikara rẹ paapaa.

Ọrọ

Sakeu jẹ ọlọrọ, Jesu si ti kọ ni pe o ṣoro fun awọn ọlọrọ lati wọ Ọrun Rere. Ki i ṣe pe Jesu kò fẹran awọn ọlọrọ gẹgẹ bi O ti fẹran awọn talaka, ṣugbọn awọn ọlọrọ ni ko fẹran Jesu. Nigba pupọ ni awọn ọlọrọ maa n rò nipa owó wọn ju Ọlọrun lọ. Nitori naa awọn Farisi rò ninu ọkàn wọn pe kò ṣe i ṣe fun ọkunrin agbowo-ode kukuru ti o sare gun igi yii lati ri igbala. Awọn Ju si korira rẹ nitori o jẹ agbowo-ode. Ninu ero ti wọn, kò si ireti fun iru awọn eniyan bẹẹ lati ri idande. Boya eyi tilẹ jẹ idi kan ti wọn kò fi gba Sakeu laaye lati la aarin awọn ero kọja lati sunmọ Jesu.

Itọni Ọlọrun

Ta ni le ro pe gigun ti Sakeu gun ori igi yoo mu un wa si ironupiwada? Boya a le bojuwo ẹyin ki a si wo awọn iṣẹlẹ ti o ṣelẹ ninu igbesi-aye wa bẹẹ, tabi pe awọn ohun ti o ṣẹlẹ ṣeeṣi wá bẹẹ ni; ṣugbọn nígbà ti ọkàn wa bẹrẹ si pongbẹ fun igbala, Ọlọrun ṣamọna wa ni ọna ti Rẹ titi a fi gbọ otitọ ti a si gba a gbọ.

“Ẹnikẹni Ti O Ba Fẹ”

Ẹkọ Jesu ni: “Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.” Niwaju Rẹ, ẹnikẹni ti kò ba ti i ronupiwada awọn ẹṣẹ rẹ, ẹlẹṣẹ ni. I baa jẹ ọlọrọ tabi talaka, Ju tabi Keferi, ọmọ-ọdọ tabi ọga, ọmọwé tabi alaimọwe; olukuluku ni o ni anfaani kan naa lati ri igbala bi o ba le ronupiwada ki o si gba Jesu gbọ.

Awọn onigbagbọ tootọ mọ pe enikẹni ti o ba fẹ ni o le rí igbala, ṣugbọn ki i ṣe gbogbo eniyan ni o ti gbọ ẹkọ yii. Igba kan wà ni igba akọkọ bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ John Wesley ti awọn eniyan gbàgbọ pe kiki awọn eniyan diẹ ni wọn ni anfaani lati le ri igbala. Awọn ti wọn n ro oko, awọn ọmọkunrin ti wọn n ṣe itọju awọn ẹṣin ni ibùso wọn, awọn akọṣẹ ti wọn n ṣiṣẹ ni ile ẹrọ nla ati awọn ti n wa ohun alumọni inu ilẹ ni wọn ro pe ireti kò si fun. Ṣugbọn lẹyin ti John Wesley ri igbala ati isọdimimọ, Ọlọrun rán an lati waasu jakejado gbogbo agbegbe England ati opopo ilu London, pe “ẹnikẹni ti o ba fẹ” le wá ki o si ri igbala: àgbẹ ati ọmọ ọba, ẹni ti o n tọju awọn ẹran ati oniwaasu, ẹni ti o n pafọ ninu ẹrẹ ẹṣẹ ati ọgbẹni ọlọla ti o n lọ si ile-isin.

Eyi ni o mu ki ayọ nla gba gbogbo ilẹ kan! Aini kò tun nipá mọ. Ayọ ti o wà ninu ọkàn awọn eniyan mu ki wọn gbagbe aini wọn. Isọji nla nla bẹ silẹ, ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan ni a si bi sinu Ijọba Ọlọrun. Wọn kọrin iyin si Ọlọrun ti O fẹran wọn ti O si fi Ẹjẹ Rẹ iyebiye rà wọn. Bi wọn si ti n gbadura ti wọn si n sọ fun Jesu bi wọn ti fẹran Rẹ to, a sọ wọn di mimọ pẹlu.

Ọpọlọpọ awọn eniyan wọnni ti a n bu ọlá fun ti wọn si ro pe awọn nikan ni o le ri igbala ni awọn ẹkọ John Wesley bí ninu. Wọn ya ara wọn sọtọ kuro laaarin awọn ọpọ eniyan ti wọn kun fun ayọ, awọn ti wọn ti kọ ti wọn si ti ni iriri igbala kíkún, wọn si sọ ibukun ti iba jẹ ti wọn nù bi o ba ṣe pe wọn ti gbọran si awọn ẹkọ eniyan nla Ọlọrun yii. Wọn dabi awọn Farisi ti wọn n gan Jesu pe O lọ si ile Sakeu.

Nigba ti Jesu de ẹba igi ti ọkunrin agbowo¬-ode kukuru yii fara pamọ si, O gboju soke wo Sakeu taara bi ẹni pe O ti ri Sakeu nígbà ti o gun igi naa. Jesu mọ ohun gbogbo O si mọ pe ọkunrin kekere yii wà lori igi naa. O mọ paapaa pe Sakeu n fẹ lati gba Oun ni alejo si ile rẹ.

Atunṣe

Jesu sọ fun Sakeu pe: “Yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni.” ọpọlọpọ ninu awọn Farisi wọnni ti wọn kún fun ododo ti ara wọn ni kò fẹ ki Jesu wá si ile wọn, ṣugbọn pẹlu gbogbo yiyara kankan ti o le yara ni Sakeu fi sọkalẹ lati ori igi naa. Oun kò wi pe Jesu ti talaka pupọ ju lati wá jẹun ni ile Sakeu daradara ni. O mọ pe Jesu ju eniyan lọ. Ifarahan Jesu ti mu idalẹbi wọ inu ọkan rẹ fun awọn ẹṣẹ rẹ, nígbà ti o si ni anfaani lati sọrọ, o wi fun Jesu pe, “Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹsun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.”

Ki ni ṣe ti Sakeu wi bẹẹ? Ninu ọkàn Sakeu, oun rò pe Jesu ko mọ ohunkohun ninu gbogbo iwa aitọ ti o ti hù. Ṣugbọn Sakeu fi tayọtayọ gba Oluwa, ki i ṣe gẹgẹ bi alejo ni ile rẹ nikan, ṣugbọn gẹgẹ bi Olugbala ninu ọkan rẹ. Nigba ti Jesu ba si wọ inu ọkàn ẹni kan, gbogbo ẹṣẹ ti o wà nibẹ ni lati jade patapata. Nigba ti ẹṣẹ jade kuro ninu ọkàn rẹ, a gba ọkàn rẹ là, o si mọ pe oun ni lati ṣe atunṣe. Ko ṣẹṣẹ tọ pe ki ẹni kan sọ fun ẹni ti a ti gba ọkàn rẹ la pe o ni lati ṣe atunṣe gbogbo iwa aitọ ti o ti hù sẹyin; Ẹmi Ọlọrun ati ọrọ Rẹ ni o n kọ ọ lati ṣe eyi. Ọlọrun ti dari ẹṣẹ ji Onigbagbọ, oun si n fẹ ki eniyan dariji oun bakan naa.

A Dariji I

Bẹẹni Sakeu bẹrẹ si lọ tayọtayọ ni ẹgbẹ Olugbala rẹ, inu rẹ dun nitori a ti dari ẹṣẹ rẹ ji. Awọn ti o n ṣọ ohun ti o n ṣẹlẹ yii n kọ? Njẹ inu wọn dùn pe a ti gba ẹlẹṣẹ kan là bi? Njẹ inu wọn dun pe agbowo-ode ni ki yoo tun rẹ wọn jẹ mọ? Rara o. Wọn ko tilẹ kiyesi iyipada yii. Ododo ti ara wọn ti fọ wọn ni oju. Ẹlẹṣẹ ni wọn n pe e sibẹ, wọn si ro pe Jesu yoo sọ ara Rẹ di alaimọ nipa lilọ wọ ni ile irú ẹlẹṣẹ bẹẹ. Wọn ka awọn akọwe ati awọn Farisi si awọn eniyan ọtọ fun Ọlọrun, awọn ọmọ Abrahamu, nitori wọn a maa ṣe laalaa pupọ lati pa Ofin mọ. Ṣugbọn Jesu ti sọ fun wọn nigba kan ri pe bi wọn ba jẹ ọmọ Abrahamu, wọn yoo ṣe iṣẹ ti Abrahamu ṣe.

Abrahamu gba Jesu gbọ, o si ti gbe igbesi-aye ẹni iwa-bi-Ọlọrun. Jesu sọ fun wọn gbangba pe: “Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe” (Johannu 8:44). Awọn ti o n ṣe ifẹ Jesu ni ọmọ Abrahamu tootọ, wọn i ba jẹ Ju tabi Keferi. “Bi ẹnyin ba si jẹ ti Kristi, njẹ ẹnyin ni irú-ọmọ Abrahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri” (Galatia 3:29).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Sakeu i ṣe?
  2. Ki ni ṣe ti awọn Ju korira rẹ?
  3. Ki ni ohun ti ó ṣe lati le ri Jesu?
  4. Ki ni Jesu ṣe nigba ti O de idi igi naa?
  5. Bawo ni Sakeu ṣe dá Jesu lohun?
  6. Ki ni atunṣe?
  7. Ki ni ẹkọ ti John Wesley kọ ni ti o jẹ iyalẹnu fun awọn ara England?
  8. Bawo ni a ṣe le fihàn pe a fẹran Jesu?