Awọn Onidajọ 2:1-23; Numeri 33:50-53; Joṣua 23:11-13

Lesson 188 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ẹ kiyesara nyin gidigidi, ki ẹ fẹ OLUWA Ọlọrun nyin” (Joṣua 23:11).
Notes

Ṣiṣẹgun Kenaani

Nigba ti Joṣua wà laaye awọn Ọmọ Israẹli bẹrẹ si i mu eto Ọlọrun ṣẹ lati ṣẹgun awọn eniyan Kenaani. Wọn pa awọn oriṣa run, wọn kò si dá awọn abọriṣa si, gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ, ki a ma ba dán wọn wò lati yà kuro lọdọ Ọlọrun alaaye ati otitọ lati sin awọn ọlọrun miiran.

Ẹya Juda ati ẹya Simeoni ṣe adehun lati ran ara wọn lọwọ ninu ija naa. Wọn so ọwọ pọ, wọn si bori ni pipa awọn ọta wọn run. Awọn ẹya iyoku kò so wọpọ lati bá awọn ọta jà. Pupọ ninu wọn ni ko gbọran si aṣẹ Ọlọrun ti o sọ fun wọn pe ki wọn lé awọn ọta wọn jade. Wọn gba awọn ará Kenaani laye lati ba wọn gbé ilẹ naa. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli tilẹ di alagbara, wọn gba awọn ọta láyè lati maa gbé ilẹ naa. Dipo ki wọn gbọran si aṣẹ Ọlọrun, awọn Ọmọ Israẹli fi agbara mu awọn ará Kenaani lati san owo-ode (gẹgẹ bi owo ori) fun wọn – dipo ki wọn lé wọn jade patapata.

Ikilọ

Ni ọpọlọpọ ọdun ṣaaju akoko yii, Mose sọ fun wọn pe awọn ará Kenaani yoo mu wahala ba wọn bi wọn ba gbà wọn laaye lati wà ni ilẹ naa. “Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni iha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé” (Numeri 33:55).

Ki Joṣua to kú, o tun kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli nipa awọn ará Kenaani. O wi fun wọn pe bi awọn eniyan naa bá wà laaarin wọn, wọn o jẹ okùn didẹ ati ẹgẹ fun awọn Ọmọ Israẹli titi wọn o fi run kuro lori ilẹ rere ti Ọlọrun fi fun wọn (Joṣua 23:13).

Lati Fẹ Oluwa

Joṣua sọ fun awọn Ọmọ Israẹli bi o ti jẹ ohun pataki fun wọn tó lati fẹ Oluwa. Bi eniyan ba fi gbogbo ọkàn rẹ fẹ Oluwa, ki yoo bọ sinu idẹkun ati ẹgẹ ọta nì. Nigba ti eniyan kan kò ba si fẹ Oluwa, oun yoo fi ifẹ rẹ fun ọlọrun eke -- yoo si ṣegbe.

Amọran – lati fẹ Oluwa – eyi ti Joṣua fun awọn Ọmọ Israẹli dara fun wa lonii. Awa paapaa ni lati ṣọra, ki a si kiyesara, ki a si pa ara wa mọ lati fẹ Oluwa. Awọn Ọmọ Israẹli ṣe aṣeyọri niwọn igba ti wọn fẹran Ọlọrun. Akoko kan de nigba ti wọn ko tun fẹran Oluwa mọ. Lẹyin eyi, wọn bẹrẹ si i fẹ awọn Ọlọrun eke, wọn si n sìn wọn. Ko ṣeeṣe fun eniyan lati fẹran Ọlọrun ati aye pọ nigba kan naa. A sọ fun wa ninu Iwe l Johannu 2:15 pe, “Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikeni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rẹ.”

Ẹni ti eniyan ba fẹran ni yoo gbọran si lẹnu ti yoo si maa sìn. Eyi ni idi kan ti o fi jẹ ohun pataki fun wa lati fẹran Oluwa pẹlu gbogbo ọkàn wa, pẹlu gbogbo aya wa, pẹlu gbogbo ẹmi wa, ati pẹlu gbogbo agbara wa.

Lai Ni Aṣaaju

Niwọn igba ti Joṣua wa ni ayé, awọn Ọmọ Israẹli n sin Oluwa. Fun igba diẹ lẹyin iku Joṣua wọn kò ni aṣaaju. Nigba ti iran miiran si dide, wọn kò tẹ siwaju ni sinsin Ọlọrun. O ni lati jẹ pe wọn kọ isin Oluwa silẹ, nitori awọn ọmọ wọn kò mọ ohunkohun nipa rẹ. O le jẹ pe ogun ti wọn n jà lati gba ilẹ naa ni o gbà wọn ni akoko to bẹẹ ti wọn kò fi ni àye lati kọ awọn ọmọ wọn. Ni kikọ Ọlọrun silẹ awọn ọmọ wọn “kò mọ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israẹli.” Ki Oluwa gbà wa lọwọ ẹbi kíkùnà lati sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun wa. Awọn ọmọde paapaa le sọ fun awọn ti o yí wọn ká nipa Oluwa. Nigba pupọ ti awọn ọmọde ba ṣe itọju awọn arakunrin ati awon arabinrin wọn ti o kere ju wọn lọ tabi awọn orẹ wọn ni adugbo, wọn le kọ awọn èwe nipa Oluwa ati nipa Bibeli. Nigba naa wọn ki yoo dabi iran awọn Ọmọ Israẹli ti kò mọ nipa Ọlọrun ati iṣẹ-iyanu ti O ṣe fun wọn.

A Ranṣẹ Kan

Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ṣe aigbọran si aṣẹ Oluwa, si aṣẹ Mose ẹni ti o fun wọn ni Ofin, ati si aṣẹ aṣaaju wọn Joṣua ẹni ti akoko rẹ tó nisisiyii lati kú, Ọlọrun rán angẹli kan lati Gilgali lati lọ jẹ iṣẹ kan fun Israẹli. A rán wọn leti aanu Ọlọrun si wọn ni mimu awọn baba wọn kuro ninu oko ẹrú ati làálàá wọn ni Egipti sinu isinmi ati ọpọlọpọ ohun rere ti o wà ni Ilẹ Ileri. A sọ fun wọn pe wọn ti ṣelẹri lati gbọran -- lati wó pẹpẹ awọn ọlọrun eke ati lati lé awọn ará Kenaani jade. Ṣugbọn wọn ti ṣe aigbọran.

Angẹli Oluwa wi pe; “Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi?” Awọn Ọmọ Israẹli kò fesi kan. Awọn ẹlomiran ro pe awọn ni alaye lati ṣe fun ohun gbogbo, paapaa fun ẹṣẹ ti o wà ni igbesi aye wọn. Wọn a maa gbiyanju pupọ lati ṣe awawi fun un. Nigba ti akoko ba to fun wọn lati duro niwaju Ọlọrun ni idajọ, wọn ki yoo le sọ ohunkohun. Wọn ki yoo le sọ ọrọ kan gẹgẹ bi ọkunrin ti a sọ nipa rẹ ninu owe ni, ẹni ti kò ni ohunkohun ti yoo sọ nigba ti o lọ si ibi igbeyawo kan lai ni aṣọ iyawo (Matteu 22:12). Wo Ẹkọ 148.

Ijiya

Angẹli Oluwa naa sọ fun awọn Ọmọ Israeli pe awọn ara Kenaani yoo jẹ gẹgẹ bi ẹgún ni iha wọn, awọn ọlọrun eke wọnni yoo si jẹ idẹkun fun wọn. Boya wọn tilẹ gbà ni tootọ pe awọn ti ṣe aigbọran ati pe ẹṣẹ wà ni igbesi-ayé wọn. Bi o tilẹ jẹ pe wọn sọkun, wọn si rubọ si Oluwa, a kò ri i kà pé wọn ronupiwada. A kò si sọ fun wa pe wọn pa awọn oriṣa ti o wà ni ilẹ naa run.

O ṣe e ṣe fun eniyan lati gbà pe ẹṣẹ wa ni igbesi-aye oun, sibẹ ki o má ronupiwada. O le sọkun nitori awọn ẹṣẹ rẹ ki o si ṣe irubọ si Ọlọrun; ṣugbọn bi ẹni naa kò ba mura tan lati yi pada kuro ninu ẹṣẹ rẹ ki o si kọ olukuluku wọn silẹ, ko ti i ronupiwada ni tootọ. Wolii Isaiah wi pe: “Jẹ ki enia buburu kọ ọna rẹ silẹ, ki ẹlẹṣẹ si kọ ironu rẹ silẹ: si jẹ ki o yipada si OLUWA, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ” (Isaiah 55:7).

Bẹẹ ni, awọn Ọmọ Israẹli sọkun wọn si rubọ si Oluwa -- lẹyin naa wọn ṣe buburu niwaju Rẹ, wọn si yipada si awọn ọlọrun miiran. Ni ṣiṣe eyi, wọn ṣe ohun buburu meji: ekinni, wọn kọ Ọlọrun alaaye ati otitọ silẹ; ekeji, wọn yipada si ọlọrun èké. Awọn Ọmọ Israẹli kò tun fẹran Oluwa mọ. Wọn fi ifẹ wọn, isin wọn ati iṣẹ-isin wọn fun awọn oriṣa - Baali ati Aṣtarotu.

Ijatilẹ

Awọn Ọmọ Israẹli kọ Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, Ẹni ti o ti ṣe ọpọlọpọ oore fun wọn. Wọn ṣaigbọran nipa kíkọ lati pa awọn ọlọrun èké, a si pada dan wọn wò lati sin awọn ọlọrun wọnni ti wọn dá si. Iru ikùnà bẹẹ mu ki wọn padanu anfaani wọn lati ni ojurere ati agbara Ọlọrun. Dipo ti wọn i ba fi bori awọn ọta wọn, awọn ọta bori awọn Ọmọ Israẹli. Wọn kò tun lagbara lati lé awọn ara Kenaani jade mọ. Wọn di alailagbara ninu ogun, a si fi wọn lé ọwọ awọn ọta wọn. Bẹẹ ni awọn Ọmọ Israẹli jiya nitori aigbọran wọn. Ẹṣẹ ni o kọ tan wọn jẹ lati dá awọn ará Kenaani si; lẹyin eyi, ẹṣẹ tun pada wa pọn wọn loju – a si fi wọn “lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrú.” Oju pọn awọn Ọmọ Israẹli lọpọlọpọ nitori ẹṣẹ wọn.

Awọn Onidajọ

Ọlọrun, ninu aanu nla Rẹ, gbe awọn onidajọ dide laaarin awọn Ọmọ Israẹli. Awọn onidajọ wọnyii ni awọn aṣaaju nipasẹ awọn ti Ọlọrun gbà wọn silẹ lọwọ awọn ti o n kó wọn lẹrú. Nigba ti Israẹli tun bọ lọwọ ipọnju, wọn tun ṣe aigbọran. Wọn sin awọn ọlọrun miiran, awọn ọta wọn si tun ni wọn lara. Lati igba de igba, nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba ke pe Ọlọrun, Oun yoo rán onidajọ kan si wọn ti yoo gbà wọn, sibẹ Israẹli kò dẹkun lati maa ṣe ori kunkun. Wọn tilẹ ba ara wọn jẹ ju awọn baba wọn lọ.

Nikẹyin, Ọlọrun ninu ibinu mú idajọ wá sori awọn Ọmọ Israẹli nitori wọn ré Majẹmu Rẹ kọja. Lati fi mọ bi Israẹli yoo rìn ni ọnà awọn baba wọn ki wọn si pa ofin Ọlọrun mọ, Oluwa kò yara lé awọn orilẹ-ede Kenaani jade. Ọlọrun gba ninu wọn laaye lati wà ni Kenaani lati dán Israẹli wò lati mọ igbọran wọn.

A o tubọ kọ ẹkọ si i nipa awọn onidajọ wọnyii, awọn ti Ọlọrun yàn lati gba awọn Ọmọ Israẹli silẹ. Bi a ti n kẹkọọ yii, ẹ jẹ ki a fi i sọkan pe awọn Ọmọ Israẹli bọ sinu wahala nitori wọn n bá awọn ọta Ọlọrun ṣe ọrẹ. Ninu Jakọbu 4:4 a kà bayii, “Ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.” O ni lati jiya fun un gẹgẹ bi awọn Ọmọ Israẹli ti jiya.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti angẹli Oluwa ba awọn Ọmọ Israẹli sọrọ?
  2. Ki ni ọrọ ti angẹli naa sọ?
  3. ọna wo ni ọrọ naa ṣe gbà kàn wọn?
  4. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si awọn Ọmọ Israẹli nigba ti wọn sin awọn ọlọrun miiran?
  5. Ki ni ṣe ti wọn sin awọn ọlọrun miiran?
  6. Ta ni Ọlọrun yàn lati gba awọn Ọmọ Israẹli silẹ lọwọ awọn ọta wọn?
  7. Ki ni ohun ti o n ṣẹlẹ ni ọjọ oni si ẹni ti o ba ṣe aigbọran?