Lesson 189 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nigbati awọn ọmọ Israẹli kigbe pè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn” (Awọn Onidajọ 3:15).Notes
Eniyan ọtọNigba ti Ọlọrun ṣe ileri ilẹ Kenaani fun awọn Ọmọ Israẹli, O wi pe Oun yoo maa lọ niwaju wọn, ati pe Oun yoo lé awọn orilẹ-ède Keferi naa jade ni ikọọkan, bi awọn Ọmọ Israẹli yoo ti maa tẹ siwaju. Ifẹ Ọlọrun ni pe ki Israẹli jogun gbogbo ilẹ naa, ki wọn si le awọn ti n gbe ibẹ jade. Kàkà bẹẹ, wọn bá awọn ará Kenaani ṣe ọrẹ, awọn ọmọkunrin wọn pẹlu fẹ iyawo ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, ati awọn ọmọbinrin wọn si gbeyawo pẹlu awọn ọkunrin ilẹ naa.
Fun ijiya, Ọlọrun wi pe Oun yoo dá ninu awọn orilẹ-ede ti Oun ti ṣeleri lati le jade duro. Oun yoo wa maa wò bi wọn o ti ṣe: yala wọn o ronupiwada ni, ki wọn si ke pe Ọlọrun fun iranwọ, tabi yoo tẹ wọn lọrun pe ki awọn ara Kenaani maa jọba le awọn lori.
Oriṣa ni awọn eniyan ilẹ Kenaani n bọ. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli dara pọ mọ wọn, ti wọn si mu wọn wọ inu ile wọn ti wọn si sọ wọn di ẹbí, lai pẹ jọjọ, awọn Ọmọ Israẹli naa di abọriṣa. Dajudaju Ọlọrun kò fẹ eyi. Eniyan ti Rẹ ni wọn jẹ, ati pe Oun nikan ṣoṣo ni wọn jẹ ni igbese lati máà sin ati lati máà jubà Rẹ.
Idajọ
Awọn Ọmọ Israẹli jiya ẹṣẹ wọn gẹgẹ bi olukuluku ẹlẹṣẹ ti n jiya ẹṣẹ rẹ lonii. Ọlọrun jẹ ki Kuṣani-riṣataimu, ọba Mesopotamia, ba wọn jà ki o si bori wọn: fun ọdun mẹjọ gbako ni awọn Ọmọ Israẹli fi sin ọba naa. Wọn kò fẹ wà ninu isinru labẹ ọba miiran, wọn si mọ ọnà ati gba ominira. Wọn ke pe Ọlọrun otitọ.
Awọn ẹlẹṣẹ jẹ iranṣẹ Satani, oun si jẹ ìkà akoniṣiṣe. Ni ikẹyin ikú ayeraye ni ere wọn. Ṣugbọn gbogbo ẹlẹṣẹ ni wọn le ṣe ohun ti awọn Ọmọ Israẹli ṣe lati ri aanu gbà; wọn le ke pe Ọlọrun pẹlu ironupiwada, Oun yoo gbọ, Oun yoo si dá wọn silẹ. Nigba ti ẹleṣẹ ba ronupiwada ti o ba si gbagbọ pe Jesu gba oun là, Satani kò ni agbara mọ lori rẹ. O bọ lọwọ ẹṣẹ, yoo si lọ si Ọrun nigba ti o ba kú.
Idasilẹ
Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ke pe Ọlọrun, O gbohùn wọn, O si rán Otniẹli ọmọ aburo Kalẹbu ẹni ti i ṣe onidajọ ododo, lati jẹ alakoso orilẹ-ede wọn. O mu wọn lọ doju ija kọ ọba Mesopotamia, ó si dá awọn Ọmọ Israẹli nide kuro ninu isinru.
Fun ogoji ọdun, alaafia wà ni ilẹ naa. Awọn Ọmọ Israẹli gbọran si Ọlọrun lẹnu, Oun si ràn wọn lọwọ lati doju ija kọ gbogbo awọn ọtá wọn. Ọlọrun kò jẹ dẹkun lati maa tọju awọn eniyan ti wọn ba fẹran Rẹ ti wọn si n sin In pẹlu gbogbo ọkàn wọn.
Ṣugbọn nigba ti o ṣe, Otniẹli kú, awọn Ọmọ Israẹli si gbagbe Ọlọrun -- lẹẹkan sii, Ọlọrun tun jẹ ki idajọ wá sori wọn. Ọlọrun fi agbara fun ọba Keferi kan to bẹẹ ti o fi ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli. Ọlọrun ki ba ti jẹ ki iru nnkan bayii ṣẹlẹ laelae bi o ba jẹ pe awọn Ọmọ Israẹli fi gbogbo ọkàn wọn si In, ti wọn si gbọ ti Rẹ. Ṣugbọn nitori awọn eniyan naa ṣe eyi ti o buru loju Oluwa, Ọlọrun jẹ ki Ọba Egloni ti Moabu, gba ọkan ninu awọn ilu wọn, o si jọba lori awọn Ọmọ Israẹli. Fun odindi ọdun mejidinlogun ni wọn wà labẹ isinru.
Olugbala Ọlọwọ-òsì
Lọjọ kan, ajaga isinru naa wá wuwo jù, awọn Ọmọ Israẹli si ranti pe Ọlọrun ni iranwọ wọn, wọn si kigbe pe E. O tun gbé onidajọ rere kan dide, Ehudu. O jẹ ọlọwọ-osi. O le yà lẹnu pe Bibeli mẹnu ba a pe ọlọwọ-osi ni Ehudu i ṣe. A kò ni pẹ ri bi o ti lo eyi fun iranwọ lati gba awọn Ọmọ Israẹli kuro ni oko ẹrú.
Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli wà labẹ akoso awọn ara Moabu, wọn ni lati san owo ibode tabi owo ori ti o pọ fun ọba Moabu. Nigba miiran wọn ni lati fun un ni ẹbun pẹlu ki o ba le ṣe rere si wọn.
Ọrọ Ikọkọ
Nigba ti Ehudu di onidajọ, awọn Ọmọ Israẹli fi ẹbun ran an si ọba Egloni. Nigba ti Ehudu de ọdọ ọba naa ti o si ti fi ẹbun rẹ jiṣẹ, o wi fun ọba pe oun ni ọrọ aṣiiri kan ti ẹlomiran kò gbọdọ gbọ. Nitori bẹẹ ọba rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ jade o si dá nikan pade Ehudu ninu yara itura rẹ.
Ehudu sọ fun ọba pe lati ọdọ Ọlọrun wa ni ọrọ naa. Ọlọrun fẹ gba awọn eniyan Rẹ la kuro labẹ ijọba ọba yii. ọnà ti o rọrun ju lọ si ni nipa pipa ọba. Pẹlu ọwọ osi rẹ, Ehudu fa ida yọ ni itan ọtun rẹ. Boya ọba ro pe iwe ni o fẹ mu jade ni apo rẹ, lai ro pe o le jẹ fi ọwọ osi fa ida yọ. Ṣugbọn ida oloju meji ni o fà yọ; lọwọ ọkunrin alagbara, ida naa kò ṣina rara. Ọba kò lè gba ara rẹ silẹ rara. Oun nikan ni o wà nibẹ pẹlu ọta rẹ, ninu yara itura. Ẹni ti o sanra pupọ ni ọba naa jẹ, lẹyin ti ida si ti wọ ikun rẹ, Ehudu kò le fa a yọ mọ.
Lẹyin ti Ehudu ti jẹ “iṣẹ rẹ” -- ida si inu ikùn ọba Egloni -- o yipada, o si rin jade kuro ninu yara naa. Gbogbo ilẹkun ti Ehudu bá kọja ni o tì bi o ba ti kọja si odi keji. Kò si ẹni ti o fura pe o ti pa ọba wọn, nitori bẹẹ, ẹnikẹni ko gbiyanju lati dá a duro. Nigba ti awọn iranṣẹ ọba pada bọ ti wọn si ba ilẹkun ni titi pinpin, wọn ro pe ọba ni o ti ilẹkun ti kò si fẹ ki a yọ oun lẹnu rara. Awọn iranṣẹ naa duro fun igba pipẹ, sibẹ ọba kò jade. Wọn ro pe o to akoko ti wọn ni lati ṣe iṣẹ iranṣẹ fun un, nitori naa wọn wá kọkọrọ miiran wọn si ṣi ilẹkun. Sa wo o ọba wọn wà lori ilẹ o ti kú. Paga! Wọn si ti jẹ ki ẹni ti o pa á sá lọ!
Iṣẹgun fun Israẹli
Ki awọn eniyan to mọ ohun ti o ṣelẹ si ọba, Ehudu ti fẹrẹ pada de ọdọ awọn eniyan ti rẹ. O fun ipè lati pe awọn ọmọ Efraimu jade si ogun pẹlu awọn ara Moabu. O wi pe: “Ẹ mã tọ mi lẹhin: nitoriti OLUWA ti fi awọn ọtá nyin awọn ara Moabu lé nyin lọwọ.” Ogun naa ko i ti bẹrẹ, ṣugbọn Ehudu ti ṣe ifẹ Ọlọrun tọkantọkan, o si ni igboya pe ti wọn ni iṣẹgun.
Wọn jade lọ si oju ogun. Fun ọdun mejidinlogun ni wọn ti wà ninu igbekun; ṣugbọn nisisiyii ti Ọlọrun wà nihà wọn, agbara dé lojiji fun wọn lati pa ẹgbaa-marun (10,000) akọni ati alagbara ọkunrin ogun. Kò si ẹnikan ti o sala. Si kiyesi i, awọn Ọmọ Israẹli tun di ominira! Woye ohun ti Ọlọrun ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli lẹsẹ kan naa ti wọn yipada si ọdọ Rẹ! Wọn ni isimi fun igba pipẹ. Fun ọgọrin ọdun wọn kò gburo ogun ni Israẹli.
Ṣamgari Onidajọ
Onidajọ ti o kàn ni Ṣamgari, lẹẹkan si i wahala tun de. Awọn ará Filistini dide si awọn Ọmọ Israẹli, ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu Ṣamgari to bẹẹ ti o fi fi ọpa ti a fi n da akọ-maluu pa ẹgbẹta (600) ọkunrin. Ọpa yii ni a fi n da akọ-malu rin nigba ti wọn ba fẹ takú. Boya kò si ẹni ti i ba ka a si ohun ti a le fi jagun, ṣugbọn Ọlọrun ran Ṣamgari lọwọ lati fi pa ẹgbẹta (600) eniyan.
Bi a ba mu ohun ti Ọlọrun fi fun wa lati lò, lò, bi o tilẹ dabi eyi ti kò to nnkan, Ọlọrun yoo fun wa ni iṣẹgun. Awọn ẹlomiran le ro pe nitori talẹnti wọn kere, kò ni ṣe nnkan kan taara yala wọn mu un lò tabi wọn kò mu un lò.
Ọmọdekunrin Kan, Kànnakànna Kan, ati Ọlọrun Ro nipa okuta marun un ti o jọlọ eyi ti Dafidi kekere fi sinu kànnakànna rẹ lati fi pa Goliati, nipa eyi ti awọn Ọmọ Israẹli si fi ni iṣẹgun lori awọn Filistini. Dafidi i ba ti wi pe: “Ṣebi ọmọde lasan ni mi? Ki i ṣe iṣẹ temi lati dojukọ Goliati.” Ṣugbọn o ri pe Ọlọrun fẹ ki oun sa ipá kan. O ni iwuwo lọkàn fun idabo bo Israẹli, o si wi pe, “Kò ha ni idi bi?” Nigba ti o tilẹ gbọ ipe Ọlọrun si iṣe naa, oun i ba ti wi pe: “Boya ki i ṣe emi gan an ni Ọlọrun n fẹ ki o lọ. Awọn ẹgbọn mi jù mí lọ, wọn lagbara jù mi lọ, wọn si mọ nipa ogun. Emi kò le lo awọn ohun-ija Saulu, anfaani ki ni kànnakànna mi kekere le ṣe lati bá omiran naa jà? Boya adabọwọ èrò temi ni lati maa rò pe emi ni Ọlọrun n fẹ lati bá omiran naa jà.” Ṣugbọn Dafidi kò gbèrò bẹẹ. O gbagbọ pe, pẹlu kànnakànna oun, okuta marun-un (ọkan tilẹ ti to), ati Ọlọrun niha oun, oun le bori ẹnikẹni; o si ni iṣẹgun nlá nlà fun Israẹli lori awọn Filistini. “Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa?” Gẹgẹ bi awọn Ọmọ Israẹli ti ṣẹgun awọn ọta wọn nigbakugba ti wọn ba gbẹkẹle Ọlọrun lati jà fun wọn, bẹẹ naa ni awa le bori gbogbo idanwo, gbogbo iwuwo tabi wahala ti o ba de ba wa, bi a ba n gbé igbesi-aye wa lati wu Ọlọrun ti a si gbẹkẹle E lati mu wa là á já.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli wà ni igbekun?
- Bawo ni a ṣe dá wọn silẹ?
- Bawo ni o ti pẹ to ti wọn fi wà ni ominira labẹ onidajọ Otniẹli?
- Ki ni ṣẹlẹ nigba ti Otniẹli kú?
- Onidajọ wo ni o tẹle e?
- Ki ni o yatọ nipa Ehudu?
- ọrọ ikọkọ wo ni Ehudu mú wá?
- Ohun ija wo ni Ṣamgari lò lati fi bá awọn Filistini jà?
- Ki ni Dafidi lò nigba ti o bá Goliati jà?
- Ki ni ṣe ti Dafidi ati Ṣamgari fi ṣẹgun?