Awọn Onidajọ 4:1-24; Heberu 11:32-40

Lesson 190 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA mbẹ fun mi, emi kì yio bẹru; kili eniyan le ṣe si mi” (Orin Dafidi 118:6).
Notes

Itẹlọrun ninu Ara Wọn ati Alailọpẹ

O yẹ ki awọn Ọmọ Israẹli mọ pe nigba gbogbo ni wahala i maa de ba wọn bi wọn ba ti yipada kuro lẹyin Ọlọrun, ṣugbọn o dabi ẹni pe iran kọọkan ni o ni lati kọ ẹkọ yii tikara wọn. Ilẹ Israẹli ti ni isimi fun igba pipẹ nigba ti iran awọn ọdọ bẹrẹ si dagbà.

Nigba pupọ ni ọrọ a maa mu ki eniyan gbagbe Ọlọrun. Ẹni naa yoo rò pe ohun gbogbo n lọ deedee oun kò si ni ṣẹṣẹ ni i wá iranlọwọ Ọlọrun. Ipo ti o lewu ni eyi fun eniyan lati wà. A ni lati ranti pe lọdọ Ọlọrun ni gbogbo ibukun wa ti wá, a ni lati mọ riri wọn ki a si dupẹ lọwọ Rẹ fun wọn.

Dipo ti wọn i ba fi mọ riri ohun ti wọn ri gbà, awọn ẹlomiran a di amọ-ti-ara-wọn-nikan, wọn ko si ni fẹ lati bá ẹnikẹni pín ninu rẹ. Niwọn igba ti Ọlọrun n tu ibukun le wa lori, O n fẹ ki a ran awọn ẹlomiran lọwọ. Ju gbogbo rẹ lọ, a ni lati maa dupẹ lọwọ Ẹni ti o fun wa ni ohun ti o pọ bẹẹ.

Nigba ti Israẹli di ẹni ti o ni itẹlọrun ninu ara rẹ ati alailọpẹ, wọn yipada kuro lẹyin Ọlọrun, wahala nla de bá wọn. Jabini ọba awọn ara Kenaani kó wọn lẹru -- ọkan ninu awọn ti Ọlọrun ti paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati parun, ṣugbọn ti wọn gbà laye lati maa jọba sibẹ. Awọn Ọmọ Israẹli pa ilu rẹ ti a n pe ni Hasori run nigba kan, ṣugbọn wọn ko kiyesara, o si ti tún un kọ loju wọn.

Ẹẹdẹgbẹrun (900) Kẹkẹ Ogun Onirin

Sisera jẹ olori ogun ọba Jabini, o si ni agbara nlá. Awọn isansa lati orilẹ-ède miiran wá si odi alagbara nibi ti o gbé tẹdo si, wọn si dapo mọ awọn-ogun rẹ titi o fi di alagbara nlá ninu ogun, o si ni ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹkẹ ogun onirin.

Nisisiyii ti Jabini bẹrẹ si jọba lori awọn Ọmọ Israeli ipọnjú nlá dé bá awọn eniyan naa. Kò si ofin tabi akoso. Ẹrù n ba awọn eniyan lati rìn tabi gun kẹkẹ ni ìgboro nitori ọpọlọpọ awọn olè ti n kaakiri ti a kò si jẹ niyà. O tilẹ jẹ ewu fun wọn lati jade lọ si ẹyìn odi ìlú lati pọn omi, wọn si ni lati lo omi. Fun ogun ọdún ni awọn Ọmọ Israẹli jiyà ninu ipò ailofin yii, ati nikẹyìn, wọn ké pe Oluwa ki O ràn wọn lọwọ. Wọn kò sọrọ nipa kikaanu fun ẹṣẹ wọn, ṣugbọn wahala wọn tobi ju eyi ti wọn lè rù lọ.

Ìyá Ní Israeli

Oluwa ṣaanu fun wọn, O si fi Debora fun wọn, oloootọ wolii obinrin, ẹni ti o fẹran Ọlọrun ti o si n ṣe ohun ti O bá palaṣẹ. Awọn eniyan lati gbogbo ìlú Israeli ni o n tọ ọ wá fun amọràn. Ni ọjọ kan, Ọlọrun paṣẹ fun un pé ki o rán awọn Ọmọ Israẹli lati dide ogun si Ọba Jabini. Nitori o jẹ obinrin, kò rọrùn fun un lati ṣe aṣaajú awọn ọmọ-ogun lọ si ogun, nitori naa o pe Baraki lati ṣe olori-ogun. O ni lati lọ bá Sisera jà, ẹni ti o ni ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹkẹ ogun onirin.

A ti tẹrí awọn Ọmọ Israeli ba fun ìgbà pípẹ to bẹẹ ti wọn kò fi ni ẹṣin ati kẹkẹ tabi awọn ohun ìjà. O dabi ẹni pe wọn kere pupọ ni agbara si awọn ti wọn yoo bá jà. Eyi i ba si ri bẹẹ bi o bá ṣe pe ki i ṣe Ọlọrun ni O paṣẹ fun awọn Ọmọ Israeli lati tẹ siwajú. Nigbà ti Ọlọrun bá paṣẹ fun wa lati ṣe ohun kan, Oun a maa fun wa ni gbogbo ipá ati agbara ti a ni lati lò lati mú àṣẹ Rẹ ṣẹ.

Inú Baraki dùn pé àyè ṣi silẹ fun Israẹli lati bọ àjàgà igbekun silẹ, ṣugbọn o mọ pe oun kò le gbẹkẹle ẹgbaa marun un (10,000) awọn ọmọ-ogun rẹ nikan lati ṣẹgun ninu ìjà naa. Ọlọrun ni lati bá a lọ. Niwọn ìgbà ti Debora si jẹ aṣojú Ọlọrun, o tẹnu mọ ọn pe ki o bá oun lọ si ogun naa.

Inú Debora dùn lati ṣe ohun gbogbo ti o wà ni ipá rẹ fun iṣẹ Ọlọrun, o si fi tọkantọkan fi ile ati ẹbí rẹ silẹ lati lọ jà fun orilẹ-ède rẹ. Kò beere ọlá kan fun ara rẹ, ṣugbọn o fẹ ki a pa orilẹ-ède awọn abọriṣa run ki Ọlọrun ba le gba ogo. O si n fẹ alaafia ati aabo fun awọn eniyan Ọlọrun. Eyi ni ẹdùn ti o gbọdọ wà ninu ọkàn Onigbagbọ tootọ; o ni lati gbagbé ohun ti ara rẹ ki o ba le sa ipá rẹ fun itẹsiwaju ipa ododo ti Ọlọrun. Debora wí fun Baraki pé oun ki yoo gba ọlá ti iṣẹgun naa nitori Ọlọrun yoo fi Sisera, ọgagun awọn ọtá, lé obinrin lọwọ.

Ogun Ní Orí Okè Tabori

Awọn jagunjagun lati inú ẹya Sebuluni ati Naftali fi ọkàn ijolootọ si orilẹ-ède wọn jẹ ipè si ogun naa, wọn si pejọ si Okè Tabori sọdọ Baraki ati Debora lati jà. Nigbà ti Sisera gbọ pé awọn Ọmọ Israeli n gbá ogun jọ, o yara gbá ogun ti rẹ jọ o si jade pẹlu ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹkẹ irin naa lati tẹrí ọtẹ naa ba. Dajúdajú o ni idanilojú ninu ọkàn rẹ pé kò ṣe e ṣe fun ẹnikẹni lati bori agbara rẹ. Debora kò duro pé kí o wá pade wọn ni Okè Tabori, ṣugbọn oun rán Baraki ati ẹgbaa marun un (10,000) ọkunrin sọkalẹ lati lọ pade Sisera.

Ogun naa pọ ni ọjọ naa, Ọlọrun si jà fun Israeli. A pa awọn ara Kenaani run patapata. Sisera ti ni igbẹkẹle nlá ninu ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹkẹ irin wọnni; ṣugbọn nigbà ti a pa awọn ọmọ-ogun rẹ run, o fò jade lati inú kẹkẹ ti rẹ o si sá asalà fun ẹmi rẹ.

Aabò Èké

Ẹlẹṣẹ le gbẹkẹle owó ti o fi pamọ, ile ti o ṣètò rẹ daradara fun ara rẹ, orukọ rere ti o ni fun ara rẹ; ṣugbọn nina apá Ọlọrun lẹẹkan ṣoṣo le gbá gbogbo rẹ lọ. Wolii Isaiah tilẹ sọrọ nipa awọn eniyan kan ti o bá ikú dá majẹmu. Ṣugbọn Ọlọrun wi pe: “Majẹmu nyin ti ẹ ba ikú dá li a o sọ di asan, imulẹ nyin pẹlu ipò-okú ki yio duro; nigbati paṣán gigun yio rekọja; nigbana ni on o tẹ nyin mọlẹ” (Isaiah 28:18). Ọlọrun yoo dá awọn eniyan lẹjọ, bi wọn ba si kọ lati ronupiwada wọn yoo bá ara wọn ninu ibinu Ọlọrun, wọn ki yoo si le gba ara wọn silẹ.

Sisera sare jade ninu kẹkẹ rẹ lai ni iranwọ. O ti doju ìjà kọ awọn eniyan Ọlọrun, o si ti padanu gbogbo awọn ọmọ-ogun rẹ ati kẹkẹ rẹ. O sare lọ sinu agọ obinrin kan nibi ti o ti ni ireti pé oun o wà lailewu. Awọn ọkunrin kò gbọdọ lọ si àyè awọn obinrin, nitori naa o rò pé ẹnikẹni ki yoo wá oun wá si ibẹ. Obinrin ti a n pè ni Jaeli, ki i ṣe Ọmọ Israeli, ṣugbọn o dajú pé Ọlọrun ni o fi si i lọkàn lati ran awọn eniyan Rẹ lọwọ ni ọjọ naa. O fun Sisera layé lati wọle o si fun un ni wara mu. O si fi aṣọ bo o lati fi i pamọ.

Sisera rò pé kò si ewu fun oun. O wí fun Jaeli pé ki o má ṣe jẹ ki ẹnikẹni mọ pé oun wà nibẹ. Aarẹ ti mu un pupọ nitori ogun naa; lẹyìn ti o si ti jẹun tán, o sùn lọ.

Ọpọlọpọ awọn ẹlẹṣẹ ni o ti sùn lọ ninu igbẹkẹle eniyan. Wọn rò pé nitori wọn ni afarawe ẹsìn kan, awọn yoo wà ni imurasilẹ lati pade Jesu, pẹlu ẹṣẹ wọn. Awọn ẹlomiran kò tilẹ ni ẹsìn kan, wọn a si wi pe: “Emi kò ṣe ibi si ẹni kan rí. Emi a maa ṣe si awọn ẹlomiran gẹgẹ bi mo ti n fẹ ki wọn ṣe si mi. Ọlọrun oloootọ yoo ha dá mi lẹbi fun eyi ni?” Ọlọrun ki yoo dá eniyan lẹbi fun iṣẹ rere rẹ, ṣugbọn o dajú pé yoo dá eniyan lẹbi nitori o kọ igbala nlá Rẹ silẹ. Jesu wi pé “A kò le ṣe alaitún nyin bi” (Johannu 3:7). Kò si ẹni ti yoo le lọ si Ọrun afi bi o bá ronupiwada awọn ẹṣẹ rẹ ti a si fi Ẹjẹ Jesu wẹ ẹṣẹ rẹ nù.

Ọtá Ọlọrun Kú

Bí Sisera ti sùn, Jaeli mú ìṣó àgọ kan, o si kan ìṣó naa mọ ẹbati rẹ, o si wọle ṣinṣin. Bẹẹ ni o si kú. Baraki olori ogun Israeli si n wá Sisera kiri; bí o si ti dé itosi àgọ Jaeli, o jade lati pade rẹ o si wi pé “Wá, emi o si fi ọkọnrin ti iwọ nwá hàn ọ.” Wo o bi yoo ti jẹ iyalẹnu fun Baraki to nigbà ti o rí Sisera ti o ti kú ni ilẹ, pẹlu ìṣó ti a gbá wọ ẹbati rẹ mọlẹ!

Ogun naa ti pari; a si ti fi iṣẹgun fun Israeli. ọgá awọn ọtá ni a si ti fi le ọwọ obinrin, gẹgẹ bi Debora ti wí. Ọba awọn ara Kenaani, ti a n pé ni Jabini kò le ṣe ohunkohun lai si awọn ọmọ-ogun rẹ, nitori naa lai pẹ, a pa oun paapaa run. Lẹẹkan si i ilẹ naa tún ni isinmi. Ọlọrun fun wọn ni iṣẹgun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni onidajọ titun ni Israeli?
  2. Ta ni a yàn lati jẹ olori ogun ni Israeli?
  3. Ki ni ohun ti o wí nigbà ti obinrin naa ni ki o wá ṣe olori ogun lati lọ bá Sisera jà?
  4. Ki ni ohun ti Debora ṣe lati ran awọn Ọmọ Israeli lọwọ lati bori ninu ogun naa?
  5. Nibo ni wọn ti ja ogun naa?
  6. Ki ni Sisera fi ṣe igbẹkẹle rẹ?
  7. Ki ni ohun-ìjà Israeli ti o jẹ aabo fun wọn?
  8. Ki ni ṣẹlẹ si Sisera lẹyìn ti o fi kẹkẹ rẹ silẹ?
  9. Ta ni ẹni ti o borí ninu ogun naa? ọwọ ta ni a si fi Sisera lé?