Lesson 191 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Jẹ ki awọn ẹniti o fẹ ẹ ki o dabi õrùn nigbati o ba yọ ninu agbara rẹ” (Awọn Onidajọ 5:31).Notes
Iṣẹgun
A ti kà nipa iyà awọn ọmọ Israẹli, eyi ti aigbọran wọn si Ọlọrun fà. Wọn bá ijatilẹ pade nigba ti wọn kò sin Oluwa. Ṣugbọn iṣẹgun maa n jẹ ti wọn nigba ti wọn ba yipada si ọdọ Ọlọrun ti wọn ba si tẹle E. Ninu ẹkọ Ọjọ Isinmi ti o kọja a kà nipa Debora, wolii obinrin, ẹni ti Ọlọrun fi ṣe onidajọ ni Israẹli. Oun pẹlu Baraki kó awọn ogun Israẹli jade lati ni iṣẹgun. A darukọ Baraki ninu Heberu ori kọkanla gẹgẹ bi ẹni ti o ni igbagbọ ti n ṣẹgun. Nitori wọn gba ohùn Ọlọrun gbọ, O fi ọta lé wọn lọwọ.
Orin Idupẹ
Debora ati Baraki mọ pe Ọlọrun ni o fun wọn ni iṣẹgun. Wọn ko gba ogo naa fun ara wọn. Nitori ki ogo ati ọla ba le jẹ ti Ọlọrun, a fun wọn ni imisi lati kọ orin idupẹ ati iṣẹgun si Oluwa fun aanu Rẹ si wọn. Wọn ni ẹmi imoore to bẹẹ ti o fi jẹ pe, lai si aniani, ni ọjọ naa gan an ni wọn ti fẹ fi orin yin Ọlọrun logo. Wọn kò duro de ọpọlọpọ oṣù lẹyin naa ki wọn to yin Ọlọrun logo. Eyi le jẹ ẹkọ fun wa. Njẹ awa ha n jẹ oloootọ lati yin Ọlọrun, a ha si maa n ṣe bẹẹ lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bi Debora ati Baraki ti ṣe?
Jẹ ki a ṣe aṣaro lori orin iyin yii. Boya o le jẹ apẹẹrẹ fun wa. Debora ati Baraki ni ẹtọ lati kọrin si Oluwa; awa naa ni ẹtọ yii pẹlu. A kà ninu Jakọbu 5:13 pe, “Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ.” Orin jẹ ọna daradara lati fi tan ihin naa kalẹ, ati lati mu un wà ni iranti. ọkan ninu awọn orin Dafidi sọ pe “iran kan yio ma yin iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọrọ iṣẹ agbara rẹ (Orin Dafidi 145:4).
Isin Atinuwa
Ki ni ṣe ti Ọlọrun gbeja awọn eniyan Rẹ? Nitori wọn fi tinutinu wọn sin In. Aṣiiri ni yii lati jẹ aṣẹgun nipa agbara Ọlọrun -- “awọn enia ti fi tinutinu wá.” Ohun ti wọn ṣe, fun Oluwa ni wọn ṣe e; ki i ṣe nitori a ni ki wọn ṣe e, tabi nitori awọn eniyan yoo maa reti pe ki wọn ṣe bẹẹ, wọn ko fi aabọ ọkàn beere pe, “A ha gbọdọ wá?” Awọn ogun Debora ati Baraki ṣẹgun nitori wọn fi tinutinu jade. Awa le jẹ aṣẹgun bi iṣẹ-isin wa fun Ọlọrun ba jẹ atọkanwa. Iru iṣẹ-isin wo ni a n ṣe fun Oluwa?
Oluwa Ọlọrun Israẹli ni wọn dari iyin orin yii sí. Dajudaju, ni igba atijọ, nigba ti awọn Ọmọ Israẹli sin awọn ọlọrun miiran, sí awọn ọlọrun eke ni wọn n kọ orin wọn.
Bi wọn ti n yin Ọlọrun fun iṣẹgun ti wọn ṣẹṣẹ ní, bẹẹ ni wọn ranti ọpọlọpọ ibukun ti wọn ti ri gbà ni atẹyinwa. Bi wọn ba ti sin Ọlọrun pẹ tó, fun saa naa ni Ọlọrun ti wà pẹlu wọn. Nigba pupọ, lode oni, nigba ti awọn eniyan Ọlọrun ba n yin In fun ohun ti O n ṣe, wọn a maa ranti awọn ibukun atẹyinwa nipa aanu ati iranlọwọ Rẹ fun wọn.
Ninu Wahala
Debora kọrin nipa ipò ti Israẹli wà ki Ọlọrun to gbé oun dide lati jẹ onidajọ. O ṣe eyi lati fihan bi idande Ọlọrun ti tobi to. Awọn ọna òpópó dá; nibo ni awọn oniṣowo, awọn kẹkẹ ẹrù ati ọjà títà wa? ọnà ikọkọ ni awọn ero n rìn, dipo opopo; i ha ṣe awọn olè ati ọlọṣa ni o mu ki awọn opopo lewu? Kò si ẹni ti o wà ninu awọn abule, ṣe wọn sá pamọ sinu awọn ilu olodi ni, nibi ti wọn ko ti le wá maa tọju awọn ohun-ọgbin? Ogun wa ni ibode ti awọn onidajọ ati awọn ijoye wọn n jokoo sí; kò ha si ibi ti wọn le mú ọrọ wọn lọ fun idajọ ododo? A kò ri asà tabi ọkọ kankan; a ha ṣẹgun wọn, a ha si gba ohun ija wọn lọwọ wọn? Nibi ti wọn ti i maa fa omi ni a gbọ ariwo awọn tafatafa; eyi ni pe eniyan kò tilẹ le fa omi pelu ifọkanbalẹ?
Ki ni ṣe ti gbogbo wahala yii de ba wọn? “Nwọn ti yàn ọlọrun titun.” Lẹyin ti awọn baba wọn ti yàn lati sin Oluwa, nigba ti Joṣua ti sọ pe, “Ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sin li oni,” (Joṣua 24:15), wọn ti kọ Ọlọrun silẹ wọn si ti n sin awọn ọlọrun titun. Nitori bẹẹ ni gbogbo rogbodiyan yii ṣe de ba Israẹli. Lonii pẹlu, awọn ọmọde ni lati yan ẹni ti wọn o maa sìn, ohunkohun ti o wù ki awọn obi wọn ti yàn. Ṣe Ọlọrun ni o n sin, tabi ọta ẹmi rẹ?
Iṣẹ Agbara Ọlọrun
Debora kọrin si Oluwa fun awọn ohun nlá ti O ti ṣe. Nisisiyii, wọn le rin ọna, wọn si le jokoo ni alaafia lati ṣe idajọ. Nisisiyii wọn le fa omi lai si ibẹru. Debora royin iṣẹ agbara Ọlọrun – ki i ṣe ti eniyan. Oluwa ni O ṣe e.
Debora ri pe oun ni idi lati yin Oluwa. O tilẹ tun rú ara rẹ soke lati tubọ kọrin iyin siwaju sii, nitori lori ọta ti o ni ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹkẹ irin, ti o si ti pọn awọn Ọmọ Israẹli loju fun ogun ọdun (Awọn Onidajọ 4:3), ni Ọlọrun ti fun Israẹli ni iṣẹgun. Ọlọrun ti fun Debora, iya kan ni Israẹli, ni aṣẹ lori awọn ọmọ ogun alagbara. Boya ni akoko naa, a kò ri ọkunrin kan ti Ọlọrun le fi ọkàn tán pẹlu iṣẹ ribiribi lati jẹ onidajọ. Ṣugbon, a rí obinrin kan, Debora, wolii obinrin ẹni ti o ni igboya ti o si jẹ oloootọ, ẹni ti Ọlọrun le fi ọkan tan. Ọlọrun ti lo awọn obinrin miiran pẹlu lati mu ipinnu Rẹ ṣẹ. Bi Jesu ba fa bibọ Rẹ ṣẹyin, Ọlọrun yoo lo gbogbo eniyan ti o ba jẹ oloootọ ati akinkanju ti o ba si n gbọran.
Ẹ jẹ ki a rú ifẹ ọkàn wa soke lati maa yin Ọlọrun si i fun iṣẹ agbara Rẹ si wa. Ta ni mọ, boya laaarin awọn ẹgbẹ ti rẹ gan an, Ọlọrun yoo gbe ẹnikan dide -- ọdọmọkunrin tabi ọdọmọbinrin -- nipasẹ ẹni ti O le ṣe iṣẹ iyanu?
Awọn ti O Jà fun Israẹli
Debora mọ awọn ọta wọn, bẹẹ ni ko ṣai kiyesi awọn ti wọn jà ni iha Israẹli. Oju rẹ ko fo awọn ti wọn duro lagbedemeji, awọn ti wọn jokoo lẹyin lai ṣe nnkan kan. Nipa iṣẹgun yii, Ọlọrun gba ogo, ṣugbọn awọn eniyan ti O lò gba iyin ti o tọ si wọn ninu orin Debora.
Ẹya Ẹfraimu, laaarin awọn ti Debora n gbe, pẹlu awọn ti wọn jà fun Israẹli (Awọn Onidajọ 4:5). Ẹya Bẹnjamini ba Debora ati Baraki lọ si ogun. Makiri, eyi ni abọ ẹya Manasse ti o wà ni iwọ-oorun, fi awọn alaṣẹ ranṣẹ lati ṣe iranwọ, awọn ọmọ alade Issakari si wà pẹlu Debora. Lati Sebuluni ni awọn ọmọwe eniyan ti wá, boya wọn mọ nipa iwe kikọ ju ogun jija lọ, ṣugbọn wọn yọọda lati ṣe ojuṣe wọn. Awọn, pẹlu awọn ara Naftali (ẹya Baraki), fi ẹmi wọn wewu ni ọna akikanju. Ibugbe wọn kò jinna si awọn ọta, lai si ṣe aniani wọn iba yàn lati kú soju ija ju pe ki a kó wọn lẹrú lọ. Ọlọrun ri gbogbo wọn.
Ọlọrun tilẹ lo awọn nnkan ti kò ni ẹmi lati fi ba Sisera jà, ati lati fi ran Debora lọwọ. Ọlọrun lo awọn irawọ; odò Kisoni si gbá ọpọlọpọ awọn ọta lọ.
Awọn ti Kò Jà
Debora tun sọ ninu orin naa nipa awọn ti wọn kò lọwọ ninu ogun lati ṣẹgun Jabini ọba Kenaani, ati Sisera, olori ogun rẹ. A kò darukọ awọn ẹya Juda ati Simeoni. Boya, nitori ilẹ ti wọn jinna si iha guusu, a kò reti wọn lati lọwọ ninu ogun naa. Awọn miiran wà nitosi, ti wọn i ba ti ṣe iranwọ ṣugbọn ti wọn ko ṣe bẹẹ. Awọn ọkunrin Reubẹni jokoo sẹyin pẹlu agbo-agutan wọn, dipo ki wọn ṣe ojuṣe wọn nipa didara pọ mọ awọn iyoku loju ogun. Bi o tilẹ jẹ pe ibi ti wọn n gbe rekọja Jọrdani bi ti Gileadi (Gadi), o yẹ ki wọn ti jẹ oloootọ. Awọn ẹya Dani ati Aṣeri kò naani ipe lati lọ jà. Wọn jokoo si ile wọn leti okun. A fi Merosi bú ìbú kikoro, dajudaju nitori o jẹ ibi kan ti o wà nitosi oju-ogun, ti a si reti pe o yẹ ki awọn olugbe ibẹ “wá si iranlọwọ OLUWA.” A kò tun gburo nipa ilu yii ati awọn olugbe rẹ mọ. A ro pe nipa ifibu yii, ilu naa parun, nitori ikunà rẹ.
Ogun ti Ẹmi
Ogun kan n jà lonii laaarin ododo ati aiṣododo. Awọn eniyan Ọlọrun ni ẹni kan ti i ṣe ọta ẹmi wọn – Satani -ẹni ti yoo pọn wọn loju ti yoo si kó wọn lẹru bi wọn ba fun un laye. Awọn eniyan Ọlọrun jẹ aṣẹgun nipa agbara Ọlọrun, gẹgẹ bi Debora ati Baraki ti ṣẹgun lori ọta. Awọn eniyan Ọlọrun a maa kó ara wọn jọ fun adura, wọn a si ma sowọpọ lati dojukọ Satani. Wọn mọ pe ọta wọn ni Satani jẹ, gẹgẹ bi Debora ti mọ pe ọta wọn ni Jabini ọba Kenaani, ati Sisera olori ogun rẹ.
Ọlọrun mọ, awọn alakoso wa naa si mọ awọn ẹni ti o wà niha ti wọn ninu ijakadi yii laaarin ododo ati aiṣododo. Bẹẹ ni wọn si mọ awọn ti wọn jokoo laaarin ijọ pẹlu, ti wọn fà sẹyin ninu aibikita ati ilọra si iṣẹ, ṣugbọn ti wọn ni itara ninu ọna ti ara wọn, ti wọn kó ilepa ayé lọkàn, ti wọn fẹran faaji ju ogun jija lọ, ti wọn n já Ọlọrun ati iṣẹ Rẹ tilẹ.
Ibukun
Orin Debora bu iyin fun Jaeli ti iṣẹ rẹ mu iṣẹgun naa di kikun. Jaeli ki i ṣe ọmọ Israẹli, sibẹ o jẹ oloootọ si Ọlọrun Israẹli nigba ti i ba fi wá ojurere awọn ara Kenaani. Dajudaju Jaeli ninu agọ rẹ, gba ere ti o tobi to ti Baraki ti o lọ si oju ogun. Iwọ naa ni ere ni ipamọ bi o ba fi tinutinu ati tọkantọkan dí aye ti Ọlọrun fi ọ si mú.
Iya Sisera dabi ẹlẹṣẹ ti oju n kán ti ara rẹ kò si balẹ. Ireti ati igboya rẹ ki i ṣe iru eyi ti n duro pẹ, nitori a gbé wọn lori iṣura aye. Ègbé ati ibanujẹ ni o ri gbà bi o tilẹ jẹ pe ọlá ati ọlà ni o ti n reti.
Debora pari orin rẹ pẹlu adura ati isọtẹlẹ pe lai pẹ jọjọ gbogbo awọn ọta Ọlọrun ni yoo ṣegbe. Orin rẹ jẹ ẹri pe lati ṣiṣẹ tinutinu fun Oluwa ni èrè.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Debora ati Baraki kọ orin yii?
- Iru orin wo ni?
- Ki ni ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli?
- Ta ni Debora ṣe?
- Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli wa ninu wahala?
- Ki ni ṣe ti gbogbo awọn Ọmọ Israẹli kò jade lọ sogun?
- Iru isin wo ni awọn eniyan naa fi fun Oluwa?
- Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli ṣẹgun?