Lesson 192 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ rẹ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga” (Jakọbu 4:10).Notes
Ninu Ihò ati ọgbun
A ranti pe Ọlọrun ti ṣeleri fun awọn Ọmọ Israẹli pe ti wọn ba pa awọn Ofin Oun mọ Oun yoo bukun wọn ni ilu; Oun yoo bukun wọn ni oko; Oun yoo fun wọn ni ile daradara ati eso oko lọpọlọpọ; nigba ti awọn ọta ba si yọ si Israẹli ni ọna kan, wọn o si sá niwaju wọn ni ọna meje nitori Ọlọrun ni yoo jà fun Israẹli.
Ṣugbọn nisisiyii a ri i pe awọn Ọmọ Israẹli n gbé ninu iho lori oke, ati ninu ọgbun, bi ẹranko. Nibo ni awọn ile ti wọn i ba maa gbadun ninu ilu wà? Eso oko wọn n kọ? Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba gbin irugbin, ti akoko ba to fun ikore, awọn ara Midiani ati awọn ara Amaleki, awọn ọta Israẹli, a wá pẹlu awọn ẹran wọn ati ibakasiẹ wọn, wọn a si jẹ ẹ tabi ki wọn fẹrẹ pa gbogbo ohun-ọgbin awọn Ọmọ Israẹli run to bẹẹ ti o fẹrẹ má si ounjẹ fun wọn lati jẹ.
Igbe si Ọlọrun
Nigbakuugba ti awọn Ọmọ Israẹli ba ba ara wọn ninu wahala nla, wọn a maa ranti Ọlọrun, wọn a si kigbe si I fun iranwọ. Ni akoko yii nigba ti wọn beere fun iranwọ lati gbà wọn lọwọ awọn ara Midiani, Ọlọrun rán wolii kan lati sọ ohun ti o mú ijiya yii wá sori wọn. O rán wọn leti awọn iṣẹ-iyanu ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn baba wọn nigba ti o gbà wọn kuro ni oko ẹru Egipti; ati bi o ti lé awọn ọta wọn kuro ni iwaju wọn nigba ti wọn de ilẹ Kenaani. Idi rẹ ti ohun gbogbo yi pada ni pe Israẹli ti ṣe aigbọran si Ọlọrun, wọn si ti sin awọn oriṣa.
Wọn ṣe ohun ti o tọ ni kike pe Oluwa. Ọlọrun ti ṣeleri pe Oun yoo dariji wọn bi wọn ba ronupiwada; O si mú ileri Rẹ ṣẹ. Lẹsẹ kan naa ti wọn bá ti yi pada si I, Oun naa a si bẹrẹ si ràn wọn lọwọ.
A fi Gideoni Hàn
Ọdọmọkunrin kan wà ni Israeli, lati inu ẹya Manasse, ẹni ti o n pakà ni ibi ifunti. Ibi ajeji ni eyi lati maa pakà, ṣugbọn o ṣe eyi lati fi ara pamọ fun awọn ara Midiani ti n fẹ lati pa ọkà rẹ run, boya o n rò pe wọn ki yoo wo apá ibẹ.
Kò si ohun titayọ kan lara Gideoni. Ẹbi rẹ ko ṣe ohun kan ti o tayọ, wọn kò si ni owó pupọ. Ṣugbọn Ọlọrun wo inu ọkàn Gideoni O si ri i pe yoo gbọran si aṣẹ Oun bi o ba mọ ohun ti o yẹ lati ṣe. Nitori naa O rán angẹli lati jiṣẹ fun un pe a yan Gideoni lati ṣe aṣaaju ni Israẹli.
Ibẹwo Angẹli Kan
Angẹli naa dabi eniyan nigba ti o wá jokoo lẹba igi oaku nitosi ibi ti Gideoni ti n paka. Nigba ti o sọrọ, o wi fun Gideoni pe, “OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara.” O le ṣoro fun Gideoni lati mọ itumọ eyi. O mọ pe Ọlọrun ti ṣe iṣẹ-iyanu fun awọn baba nla oun ni Egipti ati ninu aginju. Dajudaju, bi Ọlọrun ba wà pẹlu rẹ, oun ki ba ti fi ara pamọ ni ibi ifunti lati maa pa iwọnba ọkà diẹ ti o n pa pẹlu ironu. Njẹ inu iho ni wọn o maa gbe bi Ọlọrun ba wà pẹlu wọn? Ki ni ohun ti Gideoni si ti ṣe ti angẹli naa fi n pè é ni ọkunrin alagbara?
Agbara ti o wà ninu Gideoni ni pe oun yoo gbọran si aṣẹ Ọlọrun. Oun ki yoo bẹrù awọn eniyan ti o yi i ká ṣugbọn yoo ṣe ifẹ Oluwa. Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe: “Ki iṣe gbogbo ẹniti npè mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọle ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun” (Matteu 7:21). Igbọran ni Ọlọrun n wò.
Ọlọrun le lo Gideoni nitori yoo tẹti silẹ nigba ti Ọlọrun ba n sọrọ. Paulu Aposteli kọwe bayii si awọn ará Kọrinti: “Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọn …… ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ” (l Kọrinti 1:27-29). Ọlọrun a maa lo awọn ohun alailera ki gbogbo eniyan ba le mọ pe Ọlọrun ni O ṣe iṣẹ naa. Bi o ba jẹ olori ogun olokiki, tabi oṣelu onimọ giga ni O yàn, awọn eniyan le ro pe nipa agbara rẹ ni o fi ṣẹgun.
Ẹbọ Ohun Jijẹ
O ṣe Gideoni ni kayefi bi ohun ti angẹli naa, ẹni ti o rò pe eniyan kan lasan ni, sọ ṣe le jẹ otitọ, nitori naa o beere fun ami idaniloju. Gideoni ni ki ó duro sibẹ labẹ igi oaku naa titi oun yoo fi gbé ounjẹ wá fun un. Angẹli naa ṣeleri lati duro.
Gideoni pese ọmọ ewurẹ kan, ati akara alaiwu diẹ. O fi ẹran naa sinu agbọn, omi rẹ ni o si fi sinu ikoko, o si gbe e wá fun angẹli naa pẹlu akara alaiwu. Ṣugbọn angẹli naa kò jẹ ẹ. Ohun ti o sọ le ṣe ajeji gidigidi fun Gideoni, ṣugbọn Gideoni gbọran.
Angẹli naa sọ pe ki Gideoni gbe ẹran naa ati akara naa sori okuta kan ki o si da omi ẹran naa silẹ. Gideoni i ba ka eleyi si ofo nla; talaka ni wọn jẹ, bi angẹli naa ko ba fẹ lati jẹ ounjẹ ti o pese fun un, awọn ẹbi rẹ le jẹ ẹ. Ṣugbọn Gideoni gbọran lai beere ohunkohun; nigba ti o si to ounjẹ naa si ori okuta naa, angẹli naa fi ọpa rẹ kàn án, ina si ti inu okuta naa jade o si jó o.
Njẹ iwọ ri ohun ti angeli naa ṣe si ounjẹ ti a gbe wa fun un? O sọ ọ di ẹbọ si Ọlọrun. Bi ẹẹfin ti n rú soke lati inu ẹbọ naa, angẹli Oluwa naa si lọ. Angẹli naa ti dá majẹmu kan pẹlu Gideoni. O ti ṣe ileri pe Ọlọrun yoo wà pẹlu Gideoni nigba ti o bá lọ bá Midiani jà. Ẹbọ yii si jẹ edidi lori ileri naa.
Ẹrù wa ba Gideoni. O ti ri angẹli. Nigba ti o ba to akoko fun eniyan lati kú, awọn ẹlomiran a maa ri angẹli nigba miiran. Nitori naa Gideoni ro pe oun yoo kú. Ṣugbọn o gbọ ohùn Ọlọrun ti o sọ fun un pe: “Alafia fun ọ: má ṣe bẹru, iwọ ki yio kú.” A si tu Gideoni ninu, o si mọ pe Ọlọrun ni o pe oun lati ṣiṣẹ fun Un. O mọ pẹpẹ kan fun iranti pe angẹli Ọlọrun ba a sọrọ nibẹ, o si pe e ni Jehofaṣalomu, itumọ eyi ti i ṣe: Oluwa ni alaafia.
A pa Awọn Oriṣa Run
A ti pe Gideoni lati gba Israẹli silẹ ṣugbọn iṣẹ ti o ṣoro ni o wà niwaju rẹ. Ohun kin-in-ni ni lati rọ awọn Ọmọ Israẹli ti o yi i ká lati kọ oriṣa wọn silẹ ki wọn si sin Ọlọrun. Ọlọrun kò jẹ ki o fi akoko ṣofo rara. Ni oru ọjọ naa gan an ni Oluwa fara hàn an ti O si sọ fun un pe ki o wó pẹpẹ Baali lulẹ ki o si bẹ igi igbo oriṣa naa lulẹ. Lẹyin eyi, ki o mọ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ki o si mu ọkan ninu akọ-maluu daradara ti baba rẹ, boya ti a ti n tọju lati fi rubọ si oriṣa tẹlẹ, ki o si fi i rubọ.
Bibọ oriṣa jẹ ohun ti awọn abọriṣa kà si ohun pataki ju lọ. Gideoni yoo ha dan an wo lati pa awọn ọlọrun eke run ati ibi ti a ti n sin ẹsìn eke yii? Njẹ yoo maa bẹru bi, pe boya awọn oriṣa naa yoo ṣe oun ni ibi tabi ki wọn mú egun wa si ori oun? Awọn eniyan ti o n sin oriṣa wọnyii gbagbọ pe wọn ni agbara.
Ọpọlọpọ eniyan ni Afirika ati India lonii ni o gbagbọ pe awọn ọlọrun eke, awọn àjẹ ati awọn oloogun le gegun fun wọn. Awọn miiran ninu wọn ni agbara lati ṣe bẹẹ ni tootọ nipa agbara eṣu. Ṣugbọn Jesu le pa agbara naa run. Nigbakugba ti ẹnikẹni ba yi pada si Jesu ti o si gba A gbọ, eṣu tabi awọn alufaa rẹ kò ni agbara mọ lori ẹni naa.
Igbagbọ Gideoni
Ọlọrun ti pe Gideoni, o si gba ohùn Ọlọrun gbọ, kò si bẹru lati gbẹkẹle E. Ni alẹ ọjọ keji, o mu mẹwaa ninu awọn iranṣẹ rẹ, wọn fi igboya wo pẹpẹ Baali lulẹ wọn si ge igbo rẹ lulẹ. Lẹyin eyi wọn mọ pẹpẹ titun fun Ọlọrun, wọn si fi akọ-maluu naa rubọ lori rẹ.
Nigba ti awọn eniyan ilu naa jí ni owurọ ti wọn si ri abuku ti a ṣe si oriṣa wọn, wọn kún fun ibinu nla wọn si n fẹ lati pa ẹni ti o ṣe e. Ṣugbọn baba Gideoni gbè é nija, o si ba awọn eniyan ilu naa sọrọ. Bi oriṣa wọn ba jẹ alagbara nlá nlá bẹẹ, on ki yoo ha ti fi iya jẹ Gideoni fun ṣiṣe abuku si pẹpẹ rẹ? Bi Baali kò ba le ran ara rẹ lọwọ nigba ti a wó ere oriṣa rẹ lulẹ, bawo ni o ṣe le ran ẹlomiran lọwọ?
Awọn Ọlọrun Ti Kò Lagbara
Eyi mu wá ranti awọn ọlọrun ti awọn ará Egipti n sìn nigba ti awọn Ọmọ Israẹli wà ni igbekun. Nigba ti Ọlọrun mú ajakalẹ arun wá sori Egipti, kò si ọkan ninu gbogbo awọn ọlọrun wọnni ti o dide lati gbeja ara rẹ. Awọn ará Egipti a maa sin Odo Nile, ṣugbọn Ọlọrun sọ omi naa di ẹjẹ to bẹẹ ti o fi di oorun buburu si wọn. Wọn a maa sin ọpọlọ, Ọlọrun si rán ọpọlọpọ ọpọlọ si wọn to bẹẹ ti wọn fi wà ninu akara ti wọn n pò, ninu aarò wọn, lori ibusun wọn, ati nibikibi ti awọn ara Egipti ba lọ, titi wọn fi korira wọn gidigidi. Wọn a maa bọ maluu, Ọlọrun si rán arun saarin awọn ẹran-ọsin wọn to bẹẹ ti ọpọlọpọ ninu wọn fi kú. Ki ni ire ti awọn ọlọrun wọnyii le ṣe, awọn ti kò le ran ara wọn lọwọ ti wọn kò si le ran ẹnikẹni lọwọ pẹlu?
O dabi ẹni pé ọrọ Joaṣi tẹ awọn eniyan ilu naa lọrun, wọn ko si ṣe ibi kan si Gideoni. Iṣiṣẹ kin-in-ni ninu ija Gideoni yọri si iṣẹgun. Awọn eniyan ti rẹ ti wà ni iha ti rẹ.
Irun Agutan Gideoni
Awọn ará Midiani ati awọn ara Amaleki tun kó ara wọn jọ lati wa ba Israẹli jà. Ẹmi Ọlọrun bà lé Gideoni lati ko ogun Israẹli jọ, Gideoni si fun ipe fun ogun. A ranṣẹ jakejado ẹya Aṣeri, Sebuluni ati Naftali, wọn jẹ ipe naa wọn si mura lati lọ si ogun.
Ohun gbogbo ti n lọ deede fun Gideoni titi o fi di akoko yii, ṣugbọn o n fẹ lati ni idaniloju pe oun n ṣe ohun ti Ọlọrun n fẹ ki ohun ṣe. O mọ pe ti Ọlọrun ni ogun naa, ti rẹ si ni lati tẹle aṣẹ. Gideoni beere fun ami idaniloju miiran lati fi mọ pe oun ni yoo jẹ aṣaaju fun Israẹli. Yoo fi irun agutan le ilẹ; bi o ba kún fun omi iri, ṣugbọn ki iri má ṣe sẹ si ilẹ ni ayika rẹ, oun yoo mọ pe Ọlọrun ti dá oun lohun, O si ti yan oun ni aṣaaju fun Israẹli. Dajudaju, nigba ti ilẹ mọ, irun agutan naa kún fun iri, ilẹ si gbẹ.
Gideoni beere fun ami idaniloju kan sii. Yoo tun tẹ irun agutan naa silẹ ni alẹ ọjọ kan sii, ni akoko yii, o ni lati wà ni gbigbẹ, ki ilẹ ayika rẹ si tutu fun iri. Ọlọrun tun dáhùn lẹẹkan sii gẹgẹ bi ó ti beere. Irun agutan naa wà ni gbigbẹ patapata ṣugbọn ilẹ ayika rẹ si tutu fun iri.
Gideoni ni itẹlọrun wayii. O mọ pe ifẹ Ọlọrun fun oun ni lati lọ ṣẹgun awọn ará Midiani ati awọn ará Amaleki ti wọn n yọ awọn eniyan Ọlọrun lẹnu, o si mọ pe Ọlọrun yoo ran oun lọwọ lati ni iṣẹgun.
Questions
AWỌN IBEERE- Iru ipo wo ni awọn Ọmọ Israẹli wà ni akoko yii?
- Ki ni Gideoni n ṣe nigba ti angẹli ni wá bẹ ẹ wò?
- Ki ni ọrọ ti angẹli naa sọ?
- Ki ni ṣe ti Gideoni fi lọra lati gba ọrọ naa gbọ
- Bawo ni angẹli naa ti fihan pe ohun ti oun sọ jẹ otitọ?
- Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si ẹran, akara, ati omi ẹran ti Gideoni gbe fun angẹli naa?
- Ki ni ohun kin-in-ni ti Gideoni ati awọn eniyan rẹ ṣe gẹgẹ bi aṣe Ọlọrun?
- Ki ni ohun ti awọn eniyan ilu naa rò nipa rẹ?
- Bawo ni Gideoni ṣe bọ lọwọ iku fun ohun ti o ṣe si Baali?
- Sọ itan irun agutan Gideoni