Lesson 193 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara” (1 Kọrinti 1:27).Notes
Wọn Ṣetán lati Jà
Gideoni ti ṣẹ ogun rẹ kin-in-ni fun Oluwa. O ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, oye si ti yé awọn eniyan naa pe ibi kankan ki yoo de ba wọn fun titabuku si oriṣa awọn keferi naa. Awọn Ọmọ Israẹli ti mura tan bayii lati tẹle Gideoni lẹyin ati lati lọ bá awọn ará Midiani ati awọn ará Amaleki jagun gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olodumare.
Iran awọn Ọmọ Israẹli yii ko ti i lọ si ogun ri. Fun ọdun meje ni wọn ti n gbe inu ihò ati ọgbun, ti wọn n sá pamọ fun awọn ti wọn rúnlẹ wọ ilẹ wọn; agbara kaka ni wọn si fi n ri ounjẹ jẹ. Wọn o ha le lagbara tó lati jade lọ soju ija lati dojukọ awọn ti a ti kọ ni ogun?
Eniyan ti Pọ Jù
Nigba ti Gideoni ka awọn eniyan ti wọn ti jade tọ ọ wá lati jà, ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) ọmọ-ogun ni o ri. Boya o rò pe bi wọn ko ba tilẹ gbowọ ninu ogun jija, sibẹ wọn pọ to ni iye. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun un pe eniyan ti pọ ju. Gideoni kò gbiyanju lati ṣe alaye, ṣugbọn o gbọ ti Ọlọrun; bi Oluwa ba wi pe eniyan ti pọ ju, eniyan pọ ju naa ni.
O le ya ni lẹnu pe, ki ni ṣe ti Ọlọrun fi wi pe awọn ọmọ-ogun ti pọ ju. Dajudaju o sàn ki wọn pọ jù ju ki wọn má to lọ. Ibi wo ni o wa ninu ki wọn ba wọn lọ?, o kuku ṣe e ṣe ki wọn wulo. Ṣugbọn ogun ti Ọlọrun ni eyi, O si wi pe ọmọ-ogun ti pọ ju. Ti wi pe ẹrù n ba wọn le jẹ idi kan ti Ọlọrun kò fi fẹ wọn. Ọlọrun sọ fun Gideoni pe ki ó rán gbogbo awọn ojo pada. Boya aya Gideoni já nigba ti o ri i pe apá meji ninu mẹta awọn ọmọ-ogun rẹ pada sile nigba ti ogun ku ọla. Ṣugbọn igbẹkẹle rẹ wà ninu Ọlọrun.
Wọn Jẹ Alailagbara Lai Ni Ọlọrun
Ọlọrun ni yoo jà ninu ogun ti o doju kọ awọn ara Midiani. Bi o ba ṣe pe gbogbo ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) ọkunrin naa ni wọn lọ jagun, wọn le ti wi pe “A ni agbara. Lai si iranwọ Ọlọrun, awa le ṣẹ ogun yii.”
Nigba pupọ ni awọn Onigbagbọ ti wọn bẹrẹ si i sin nipa gbigbẹkẹ le E patapata maa n di ẹni ti o n gbẹkẹ le ara wọn ti wọn si n kuna lati mọ pe awọn kò le ṣe alaini iranwọ Jesu ninu ohun gbogbo ti awọn ba n ṣe, nigba gbogbo. Jesu wi pe: “Ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan” (Johannu 15:5). Niwọn igba ti Ẹmi ba n dari wa ninu iṣẹkiṣẹ ti o wù ki a ṣe fun Ọlọrun ni iṣẹ naa fidi mulẹ. Ẹ jẹ ki a kun fun ikiyesara lati beere pe ki O maa tọ gbogbo iṣisẹ wa, ki O si kọ wa ni ohun ti a o sọ, ki a ba le jẹ ibukun fun awọn ti a n fẹ ṣe iranwọ fun.
A sọ itan kan nipa oniwaasu kan ti o rò pe iwaasu oun kò jafafa to, o si gbadura gidigidi pe ki Ọlọrun le rán oun ni iṣẹ eyi ti yoo mu awọn eniyan lọkàn. Ọlọrun dahun adura rẹ, O si ti iṣẹ-iranṣẹ rẹ lẹyin. Ṣugbọn nigba ti o ṣe, a ko ri imisi Ẹmi-Mimọ ninu iwaasu rẹ to ti atẹyinwa mọ. A mọ ohun ti o fa a nigba ti o sọ pe “lakọkọ n ko lagbara, mo ni lati rọ mọ Oluwa gidigidi, ṣugbọn nisisiyii, mo ti le dá waasu daradara funra mi.” Iranṣẹ Ọlọrun tootọ ti o pa Ẹmi Ọlọrun mọ ninu ayé rẹ, kò jẹ fi igba kan rò pe oun le dá ṣe aṣeyọri.
Idanwo Keji
Ọlọrun sọ fun Gideoni pe awọn ẹgbaa marun un (10,000) ọmọ ogun ti o kù naa pọju sibẹ, nitori naa O fun wọn ni idanwo keji. Gideoni kó awọn ọmọ-ogun naa lọ si odò ki wọn ba le mu omi. Bawo ni wọn ṣe mu omi? Ẹgbaa marun un din ọọdunrun (9,700) ninu wọn wolẹ lori eekun wọn, wọn si da oju bo omi. Wọn kò kiyesi awọn ọtá. Ṣugbọn ọọdunrun (300) ọmọ-ogun wà nibẹ ti wọn ṣe giri. Njẹ o ti i ṣe akiyesi ajá ri bi o ti n la omi? O maa n dabi ẹni pe bi o ti n mu omi naa, o n ṣọ nnkan kan. Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rẹ maa kiyesara -- ki wọn maa ṣọra fun ọta. O le jẹ pe awọn ọọdunrun (300) ọkunrin naa fi ọwọ wọn bu omi naa ti wọn si mu un lai kunlẹ ati lai pa oju wọn dé. Wọnyii ni Ọlọrun fẹ lò ninu ijakadi wọn akọkọ pẹlu awọn ará Midiani.
Awọn Ohun-Ija Ọlọrun
Ẹgbẹ yii ni lati kere ni iye pupọ lẹgbẹ ogunlọgọ awọn ará Midiani ti wọn wà ni afonifoji ni isalẹ. Dajudaju awọn ara Midiani ro pe kò ni ju ere ọmọde lasan lati doju awọn ọmọ-ogun Gideoni kekere bolẹ (Ihamọra wọn kò ju ipe lọ, ati iṣa ati fitila).
Bẹẹni, gbogbo ohun-ija ti awọn ọkunrin Gideoni mú lọwọ wọn kò ju ipe, iṣa ati fitila: awọn wọnyii ki i ṣe ohun-ija ti eniyan saba maa n fi ṣe aṣeyọri ninu ogun jija. Ṣugbọn ihamọra Ọlọrun ni wọn jẹ. Ohunkohun ti Ọlọrun ba lò lati mu ifẹ Rẹ ṣẹ ko ni ṣai dara dandan ju ohun ti eniyan le ro pe ohun n fẹ lọ. Ko si idà tabi ọkọ laaarin awọn Ọmọ Israẹli. Wọn jẹ eniyan ti a ti tẹri wọn ba, o si rọrun pupọ ju lati jẹ gaba lori orilẹ-ede ti ko ni ohun ijagun. Nitori naa nigba ti Israẹli jade lọ si ogun kò tilẹ si nnkan kan rara ti wọn ni ti wọn i ba fi sọ lọjọ iwaju pe, “Nipa ipa ati agbara wa ni a fi ṣẹgun awọn ọta.”
Iyawo Kristi
Ẹ jẹ ki a fi ẹgbẹ ogun Gideoni wé Ijọ Kristi. Ni ọjọ kan lai pẹ, Jesu yoo tun pada wa lati mu iyawo Rẹ lọ si Ase-alẹ Igbeyawo. Ẹmi Mimọ wà ni aye bayii, O n pese awọn eniyan Rẹ silẹ, O n yiiri wọn wò lati le fi iduro wọn niwaju Rẹ hàn. Odiwọn ti a ni lati de ni a fihàn fun wa ninu Ọrọ Ọlọrun. Lẹyin ti a ba ti ri igbala, isọdimimọ ati ifiwọni Ẹmi Mimọ, iṣẹ kù sibẹ ti a ni lati ṣe. A kọ wa pe: “Ẹ fi iwarere kún igbagbọ, ati imọ kún iwa rere; ati airekọja kún imọ: ati sũru kún airekọja; ati iwa-bi-Ọlọrun kú sũru; ati ifẹ ọmọnikeji kún iwa-bi-Ọlọrun, ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji” (2 Peteru 1:5-7).
Gbogbo ọmọ-ogun Gideoni jẹ Ọmọ Israẹli, ọmọ Ọlọrun. Eniyan pupọ lonii ni wọn n wi pe ọmọ Ọlọrun ni awọn jẹ ati pe awọn gba Jesu gbọ. Ṣugbọn Ọlọrun n rán idanwo jade lati fihàn awọn ẹni ti i ṣe onigbagbọ tootọ ti o n pese ara wọn silẹ lati pade Jesu, Ọkọ-Iyawo, nigba ti O ba de. Awọn ojo ati alaigbagbọ yoo ri i pe awọn ki i ṣe ọmọ Ọlọrun rara, wọn o si ni ipa ti wọn ninu adagun iná. Wọn le wi pe awọn gbagbọ, ṣugbọn wọn ni lati fihàn nipa ṣiṣe ohun ti Jesu palaṣẹ. O wi pe “Bi ẹnikẹni ba fẹràn mi, yio pa ọrọ mi mọ: Baba mi yio si fẹran rẹ, awa o si tọ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ” (Johannu 14:23).
Awọn ẹlomiran wà boya ti wọn ti tẹle Oluwa tọkantọkan fun igba diẹ, ṣugbọn nitori Jesu kò tete de gẹgẹ bi wọn ti ro pe yoo ṣe, wọn wá di alaikiyesara, wọn kò si wo ọna fun Un mọ rárá. Wọn le gbe igbesi-aye rere ki wọn si maa wi pe awọn n reti Jesu. Ṣugbọn, ki a sọ tootọ, njẹ wọn n reti Rẹ bi? Nigba ti wọn ba lọ dubulẹ loru, njẹ wọn maa n ronu pe Jesu le de ki ilẹ to mọ? Ero yii logo to fun awọn ti o wa ni imurasilẹ!
Eniyan meloo ni wọn ti di alafara ti wọn si ti ṣe nnkan kekere kan ti wọn ko ni fẹ maa ṣe nigba ti Jesu ba de? Tabi wọn i ba kuku fẹ ki Jesu má ti i wá fun igba diẹ titi wọn yoo fi ṣe aṣeyọri kan ninu aye yii, tabi titi wọn yoo fi gbadun afẹ aye fun igba diẹ si i? Ki ni ero wọn akọkọ ni owurọ? Ṣe wọn ṣe ipinnu ti ara wọn ni, tabi wọn n wi pe “Jesu ṣe lonii ni?”
Ipoungbẹ fun Bibọ Jesu
Njẹ iwọ n fẹ ki Jesu de lonii? Bi o ba ti mura tan lati pade Rẹ, iwọ n fẹ. Jesu kọ awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lati maa gbadura pe, “Ki ijọba rẹ de.” Oluwa fẹ ki awọn eniyan Rẹ ni ifẹ gbigbona lati ri I to bẹẹ ti wọn o fi kigbe si I pe, “Maa bọ Jesu Oluwa, yara tete dé.” Bayii ni Iyawo ti n ṣe. O n reti lati gbọ ọrọ wọnyii: Ẹ je ki a yọ, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rẹ si ti mura tan” (Ifihan 19:7).
Ọlọrun jẹ ki Johannu lori oke Erekusu Patmo ri iran Jerusalẹmu Titun ati ogo ti o wà lẹyin ayé yii. Ero nipa ogo yii ti o le jẹ ti gbogbo wa yẹ ki o fi ipinnu sinu ọkàn olukuluku lati mura silẹ lati pade Jesu, ohunkohun ti o wù ki o gbà wá.
Jesu ti ṣeleri pe, awọn eniyan Rẹ yoo dabi Rẹ. “Nigbati a bá fihan, a ó dabi rẹ; nitori awa o ri i ani bi on ti ri” (1 Johannu 3:2). Iru ara ologo ti Jesu ní lẹyin ti O jinde kuro ninu okú ni Iyawo Kristi yoo ni, wọn o si ṣe akoso, wọn o si jọba pẹlu Rẹ lae ati laelae.
Awọn ti wọn jẹ ara Ijọ Kristi ti wọn n wọna fun Jesu, ti wọn n fi ọkàn si gbogbo nnkan ti O ni ki wọn ṣe, ti wọn si n rin ninu imolẹ ti O rán, ni yoo jẹ Iyawo naa. Wọn yoo dabi ọọdunrun (300) ọmọ-ogun Gideoni nipasẹ ẹni ti Ọlọrun ṣẹgun fun Israẹli. Wọn yoo kere niye si ọgọọrọ eniyan ti wọn n pe ara wọn ni Onigbagbọ ṣugbọn ti wọn ki i ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ. Iyawo naa ni a o yàn nitori o ti jẹ oloootọ, o si ti mu gbogbo nnkan ti Ọlọrun beere ṣẹ. Olukuluku eniyan ni o ni anfaani lati pẹlu awọn oloootọ.
Questions
AWỌN IBEERE- Ọkunrin meloo ni Gideoni rí nigba ti ó pe awọn Ọmọ Israẹli si ihamọra?
- Ki ni Ọlọrun sọ nipa iye wọn?
- Idanwo wo ni a kọ ṣe fun wọn lati mọ bi wọn bá jẹ ọmọ-ogun rere?
- Ewo ni idanwo keji?
- Ọmọ-ogun meloo ni o pada nigba ekinni ati ekeji? Eniyan meloo ni ó kù?
- Irú ohun-ijà wo ni ẹgbẹ-ogun Gideoni ní?
- Awọn wo ni yoo ṣe Iyawo Kristi?