Awọn Onidajọ 7:9-25; 8:1-35

Lesson 194 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awọn ẹlomiran gbẹkẹle kẹkẹ, awọn ẹlomiran le ẹṣin; ṣugbọn awa o ranti orukọ OLUWA Ọlọrun wa” (Orin Dafidi 20:7).
Notes

Ẹgbẹ Kekere

Fun ọdun meje ni awọn ara Midiani pọn awọn ọmọ Israẹli loju, wọn a maa jade ni ẹgbẹ nla lọ si ilẹ Kenaani lati pa a run. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli kigbe pe Oluwa lati gbà wọn, Ọlọrun gbé Gideoni dide, “ọkunrin alagbara.”

Awọn Midiani pọ bi eeṣú. “Awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ ainiye.” Awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Israẹli to ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) ki Ọlọrun to yọ awọn ti ẹrù n bà ati awọn ti kò mura tan kuro ninu wọn. Nigba ti Ọlọrun dán awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Gideoni wò, kiki ọọdunrun (300) ọkunrin ni o kù ninu ẹgbẹ ọmọ-ogun naa. Awọn ti o kù pada lọ sinu agọ wọn. Kiki awọn onigboya, awọn ti n ṣọna, ti wọn si gbọran, ni àye wà fun ninu ẹgbẹ ọmọ-ogun ti Ọlọrun lonii. Bi o tilẹ jẹ pe wọn kere niye, wọn jẹ aṣẹgun nipa igbagbọ ninu Oluwa.

A ti sọ fun Gideoni pe Ọlọrun yoo fi awọn Midiani lé e lọwọ. Nipasẹ awọn ọọdunrun (300) ọkunrin yii ni a o fọ awọn ọta tuutuu. Ọlọrun ki i fi iṣẹ ti kò ṣe e ṣe le ẹnikẹni lọwọ, nitori nigba ti O ba paṣẹ, Oun a maa fi agbara fun ni lati pa aṣẹ naa mọ. Ki i ṣe iṣẹ ti ko ṣe e ṣe ni Ọlọrun fi le Gideoni lọwọ. Bi a ba ro o gẹgẹ bi ọna ti wọn n gbà lati jagun ni igba ni, yoo dabi iwà ti kò mu ọgbọn lọwọ fun ọkunrin ti o ni ọọdunrun (300) ọkunrin pere lati dojukọ ẹgbẹ ogun nla bẹẹ; ṣugbọn Oluwa ni o rán Gideoni. Nipa igbagbọ ni o lọ ja ija naa.

Imulọkanle

Ọlọrun mọ pe awọn eniyan wọnyii ti tó fun Gideoni; o n fẹ imulọkanle lati ran igbagbọ rẹ lọwọ. Eyi ni Ọlọrun ṣe fun un. A sọ fun Gideoni pe ki o lọ si agọ awọn ọta ni alẹ ọjọ naa lati gbọ ohun ti wọn o maa sọ. Gideoni gbọran. O mu Pura iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ẹlẹri. Gideoni jẹ akọni ati onigboya ọkunrin; ju gbogbo rẹ lọ, o gbọran si aṣẹ Ọlọrun; igbagbọ rẹ wa ninu Oluwa. Dajudaju wọn rọra yọ lọ kẹlẹkẹlẹ ninu okunkun ki awọn iṣọ awọn ọta ma baa gbọ iro wọn. Bi wọn ti sunmọ tosi agọ awọn Midiani, wọn bẹrẹ si gbọ ohùn. Gideoni ati Pura duro lati gbọ, nitori Ọlọrun ti sọ pe wọn o gbọ ohun ti awọn ọta yoo maa sọ.

Gideoni gbọ ti ará Midiani kan n rọ ala kan ti o lá. O ti la àlá kan pe akara ọka barle kan ṣubu si ibudo wọn, o si wó agọ kan lulẹ. Gideoni ko tete yara kuro nibẹ. O dara ti Gideoni fara balẹ gbọ itumọ àlá naa, nitori eyi ni ọrọ imulọkanle ti Ọlọrun n fẹ ki ó gbọ. Awọn ẹlomiran a maa padanu ibukun ati imulọkanle ti wọn i ba ri gbà nitori wọn tete lọ – boya wọn tete kuro ni ipade isin tabi ibi adura nigba ti o kù diẹ fun wọn lati ri ibukun ti Ọlọrun n fẹ fun wọn gbà.

Bi Gideoni ati Pura ti n tẹti silẹ lati gbọ, ara Midiani miiran sọ itumọ àlá ọmọ-ogun ẹlegbẹ rẹ fun un. O ni, “Eyiyi ki iṣe ohun miran bikoṣe idà Gideoni.” O si sọ siwaju si i pe Ọlọrun ti fi awọn Midiani le Gideoni lọwọ. Awọn ọta paapaa mọ pe Ọlọrun Israẹli yoo ṣẹgun wọn.

Wiwolẹ Sin

Nigba ti Gideoni gbọ ala yii, o wolẹ sin Ọlọrun. Ni ẹba ode agọ awọn ọta ni o wà, lori ilẹ awọn ọta, ṣugbọn o wolẹ sin Ọlọrun. Oun kò duro di igba ti o ba ṣẹṣẹ pada si agọ ti rẹ. Ẹ jẹ ki a tẹle apẹẹrẹ Gideoni lati maa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oore Rẹ si wa, lati maa yin In fun itọju Rẹ ti o nipọn lori wa ati imulọkanle ti O n fun wa. Ni ibikibi ti a ba wà, a le gbé ọkàn wa soke ni ọpẹ. ọpọlọpọ eniyan ni o ti ri i pe orukọ Jesu ninu adura wuyẹwuyẹ jẹ ohun ija ti o dara lati ṣẹgun ọta, ati aabo nigba ewu.

Ohun-Ija Ajeji

Eyi jẹ imulọkanle nlá nlà fun Gideoni. O pada tọ awọn eniyan rẹ lọ, o pín wọn si ẹgbẹ mẹta, o si fi ohun-ija ajeji lé wọn lọwọ. Gideoni fi ipe kan, iṣà kan ninu eyi ti atupa wà lé ọkọọkan ninu awọn ọọdunrun (300) ọkunrin ni lọwọ. Bayii ni awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Israẹli mura tan fun ogun. A paṣẹ fun wọn pe ki wọn ṣe gẹgẹ bi Gideoni ba ti ṣe – lati fun ipe nigba ti Gideoni ba fun ati lati hó nigba ti Gideoni ba hó.

Ohun-ija ti ẹmi ti o wà fun awọn eniyan Ọlọrun lonii ko dabi awọn ohun ija miiran. Paulu sọ nipa eyi ninu akọsilẹ rẹ (ll Kọrinti 10:4; Efesu 6:17; Heberu 4:12). Nigba ti ọmọdekunrin darandaran ni, ti a n pe ni Dafidi, lọ lati bá omiran ni ja ẹni ti o gbe gbogbo ihamọra wọ, ani Goliati, Dafidi ṣẹgun rẹ ni orukọ Oluwa. Dafidi wi pe: “Iwọ mu idà, ati ọkọ, ati awà tọ mi wá: ṣugbọn emi tọ ọ wá li orukọ OLUWA awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun ogun Israẹli ti iwọ ti gàn (l Samuẹli 17:45).

Kristi, Apẹẹrẹ Wa

Ọpọlọpọ awọn eniyan Ọlọrun ni o ni iriri pe wọn le jẹ aṣẹgun ninu gbogbo ija. Wọn a maa tẹle apẹẹrẹ aṣaaju wọn – Kristi. “Kristi ……jiya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ ipasẹ rẹ” (1 Peteru 2:21). Ni akoko idanwo, ki ni ohun ija ti Jesu lò? ọrọ Ọlọrun ni. O sọ fun Satani pe, “A ti kọwe rẹ pe” (Matteu 4:4, 7, 10). Awọn eniyan Ọlọrun a maa ṣẹgun ọta nipa ọrọ Oluwa, “ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ wa” (Heberu 12:2).

Awọn ọmọ-ogun Gideoni mu ki imọlẹ wọn tàn ninu okunkun. A sọ fun wa pe ki a jẹ ki imọlẹ wa ki o “mọlẹ tobẹẹ niwaju enia” (Matteu 5:16), ki a si maa tan “bi imọlẹ li aiye” (Filippi 2:15). Jijẹ ki imọlẹ tàn lati inu atupa wọn jẹ iranlọwọ fun awọn ọmọ-ogun Gideoni lati ni iṣẹgun ninu ogun naa.

Melomelo ni igba ti ihó iṣẹgun lẹnu awọn ti a rà pada ti fọ ogun ọta tuutuu. Odi Jẹriko wó lulẹ nipa igbagbọ nigba ti awọn Ọmọ Israẹli gbọran si aṣẹ Ọlọrun ti wọn si hó (Joṣua 6:20).

Titẹle Aṣaaju Wọn

Awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Israẹli ọọdunrun (300) yii ni igbagbọ ati igbẹkẹle ninu aṣaaju wọn. Awọn ọkunrin naa ṣe gẹgẹ bi Gideoni ti paṣẹ fun wọn lati ṣe. Awọn ẹgbẹ mẹtẹẹta naa yi ibudo awọn ọta ká. Ni gẹrẹ ti wọn paarọ iṣọ, Gideoni fun wọn ni ami. A fun ọọdunrun (300) ipe naa, a fọ ọọdunrun (300) iṣà naa mọlẹ, imọlẹ ọọdunrun (300) atupa si tàn yi awọn ọta ká; iró ihó kan si dún jade bayii pe, “Idà OLUWA ati ti Gideoni.” Idà Oluwa ni ọwọ Gideoni ni o mu iṣẹgun naa wá.

Ẹru nlá nlà de ba ọkàn awọn ọta. Ariwo, iná ati ihó naa ninu idakẹrọrọ oru mú idaamu bá awọn ọta, to bẹẹ ti wọn fi sá. Ninu ibẹru wọn, ẹni kin-in-ni ṣubu nipa idà ẹni keji. Awọn ẹgbẹ mẹta ọmọ-ogun Gideoni si duro “olukuluku ni ipò rẹ yi ibudó na ká.” Wọn ko sure lọ sinu ogun naa bi ẹni pe wọn n warapapa lati jà tabi lati kó ikogun. Wọn duro de aṣẹ lati ọdọ Gideoni. Eyi yoo jẹ ẹkọ daradara kan lati kọ lara awọn ọmọ-ogun Gideoni -- ki olukuluku ki o duro ni ipò ti rẹ. Njẹ Ọlọrun le gbẹkẹle wa lati duro ni ipò wa, ki a maa reti aṣẹ Rẹ?

Iṣẹgun Patapata Ni A N Fẹ

Gideoni kò ni itẹlọrun pẹlu lilé awọn Midiani kuro ni ilẹ Kenaani nikan. Ọlọrun ti sọ fun un pe a ti fi ogun Midiani le e lọwọ. Bi o tilẹ jẹ pe ọkẹ mẹfa (120,000) ni a ti pa ninu awọn ọta naa, ẹẹdẹgbaajọ (15,000) ni o salọ pẹlu Seba ati Salmunna, awọn ọba Midiani. Gideoni n fẹ ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣeleri. O fẹ lati ṣe iṣẹ naa bi o ti tọ -- ki i ṣe lati mu apá kan ninu aṣẹ Ọlọrun ṣẹ.

Efraimu

Awọn ọkunrin Israẹli pé jọ wọn si lepa awọn Midiani. Gideoni ranṣẹ si awọn ọkunrin Efraimu, awọn ti o mú meji ninu awọn ọmọ-alade Midiani. Awọn ọkunrin Efraimu bá Gideoni sọ. Wọn bi leere idi rẹ ti o fi ṣe bẹẹ si wọn, ti kò fi pe wọn ṣaaju akoko yii nigba ti o n lọ ba awọn ara Midiani jà. Inu bi wọn boya wọn tilẹ n jowu pẹlu. Gideoni ṣe iyọnu si wọn o si wi pe, “Kini mo ha ṣe nisisiyi ti a le fiwe ti nyin?” Nitori inu tutu ati ẹmi irẹlẹ Gideoni awọn ọkunrin Efraimu kò tun binu mọ, inu wọn si tutu. Ni iru ipo bayii, Gideoni fihàn pe “Idahùn pẹlẹ yi ibinu pada” (Owe 15:1).

Idajọ

Gideoni lepa iyoku awọn Midiani rekọja odo Jordani. Aarẹ mu awọn eniyan rẹ, ebi si n pa wọn. Wọn beere fun iṣu-akara lọwọ awọn ọkunrin Sukkotu ati Pẹnuẹli, awọn mejeeji lati inu ẹyà Gadi (awọn Ọmọ Israẹli). Iru iṣẹ-alejo bayii tọ si ẹnikẹni ti o n rin irin-ajo, paapaa ju lọ aṣayan ẹgbẹ ọmọ-ogun Oluwa. Ṣugbọn ẹnikẹni kò fi nnkan kan fun awọn ọmọ-ogun Gideoni, Gideoni si jẹ ki o di mimọ fun wọn pe a o jẹ wọn ni iyà, fun iwa imọ-ti-ara-ẹni-nikan yii. Lẹyin eyi, Ọlọrun gba Gideoni laye lati kọ wọn lẹkọọ pe wọn kò gbọdọ ṣe idena fun awọn ọmọ-ogun Oluwa. Iya wọn jẹ eyi ti o wuwo ni tootọ ṣugbọn o tọ bẹẹ, nitori wọn kò fiyesi ikilọ naa. Gideoni kò pada si ile titi o fi pa awọn ọtá run ti wọn kò fi le pọn awọn Ọmọ Israẹli loju mọ.

Ọlọrun, Alakoso Wọn

Nigba ti Gideoni ati awọn ọmọ-ogun rẹ pada si Kenaani, awọn Ọmọ Israẹli ati ile rẹ n fẹ ki o ṣe alakoso lori wọn nitori o ti gbà wọn lọwọ awọn Midiani. Ni ọna ti ẹmi, awọn ti Kristi ti gbà silẹ lọwọ Satani fẹ ki Oluwa ki o jẹ Aṣaaju ati Alakoso igbesi-aye wọn. Oluwa ni o fi Gideoni ṣe olori wọn, o si di ipò yii mu titi di ọjọ ikú rẹ. O sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe: “OLUWA ni yio ma ṣe alaṣẹ nyin.” Boya o rò gẹgẹ bi Paulu ẹni ti o wi fun awọn ara Kọrinti pe ki wọn maa ṣe afarawe oun gẹgẹ bi oun ti n ṣe afarawe Kristi (l Kọrinti 11:1).

Iku Gideoni

Awọn Ọmọ Israẹli wà ni alaafia fun ogoji ọdun ni igba aye Gideoni. Ni otitọ ni o ṣe aṣiṣe; o kuna lati beere lọwọ Ọlọrun. Dajudaju oun n fẹ lati ṣe ohun iranti kan fun ikogun ti wọn kó. O gba oruka-eti ti wọn ti ri kó lọwọ awọn ọta o si fi ṣe efodu kan. Efodu yii, ti i ṣe apa kan ninu aṣọ ti alufaa n wọ, di ohun ti awọn eniyan n sìn bi oriṣa, o si di idẹkun fun Gideoni. Wò o bi o ti ṣe ohun pataki fun eniyan lati gbé igbesi-aye rẹ pẹlu iṣọra ati adura pupọ ki aṣiṣe kan ma baa di apẹẹrẹ ti ko dara ti awọn ẹlomiran le tẹle!

Lẹyin ikú Gideoni awọn Ọmọ Israẹli kọ Ọlọrun otitọ ati alaaye silẹ. Wọn sọ oriṣa di ọlọrun wọn. Wọn gbagbe Ọlọrun naa ti O ti gbà wọn silẹ ni iha gbogbo lọwọ awọn ọta. Bẹẹ ni wọn kò si fi inu rere hàn fun awọn ara ile Gideoni lati fi imoore hàn fun ohun ti o ṣe fun wọn. Nigba pupọ ni eyi maa n ri bẹẹ, bi eniyan ba gbagbe Ọlọrun, a maa gbagbe awọn ti o ba jẹ ọrẹ rẹ pẹlu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Gideoni ṣe di olori awọn Ọmọ Israẹli?
  2. Ki ni ṣe ti ẹgbẹ ọmọ-ogun rẹ kere to bẹẹ?
  3. Ki ni ala ara Midiani naa? ki si ni itumọ rẹ?
  4. Ohun ija wo ni awọn ọmọ-ogun Gideoni lò?
  5. Ki ni ṣe ti Gideoni ati awọn ọmọ-ogun rẹ fi ṣe aṣeyọri?
  6. Bawo ni a ṣe le jẹ ki “imọlẹ” wa ki o tàn?
  7. Ki ni ṣe ti a ni lati jẹ ki “imọlẹ” wa ki o tan?
  8. Ki ni ṣe ti awọn eniyan naa hó pe: “Idà OLUWA ati ti Gideoni”?
  9. Ki ni ṣe ti Gideoni lepa ti o si pa awọn ọta naa run patapata?