Lesson 195 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di igbala mi” (Ẹksodu 15:2).Notes
Awọn Ọmọ Israẹli a maa gbadun alaafia ati ọrọ niwọn igba ti wọn ba n sin Ọlọrun ni otitọ. Nigba ti wọn ba wà ni iha ti Oluwa, wọn a ni igboya, wọn a si ṣẹgun awọn orilẹ-ede miiran. Ọlọrun ti ṣeleri pe bi wọn ba gbọran si aṣẹ Oun, Oun yoo ṣe wọn ni ori ati awọn orilẹ-ede miiran ni irù. Nigba pupọ ni Israẹli fi n jẹ irù, ni itẹriba labẹ awọn orilẹ-ede abọriṣa ti ko fẹran Ọlọrun. Ipo wọn jẹ imuṣẹ idajọ Ọlọrun fun ẹṣẹ wọn.
Ibẹrẹ Idasilẹ
Samsoni jẹ ọkan ninu awọn onidajọ ti Ọlọrun gbe dide lati dá awọn Ọmọ Israẹli silẹ kuro ninu igbekun. Ọlọrun ti ṣeleri fun iya Samsoni pe ọmọ rẹ yoo bẹrẹ si i dá awọn Ọmọ Israẹli silẹ lọwọ awọn Filistini. Bi o ti n dagba, o n di alagbara si i, boya o tilẹ lagbara ju bi ẹnikẹni ti lagbara to ni ayé yii. Ẹmi Ọlọrun a maa bà lé e nigba miiran, nigba ti o bẹrẹ si i dagba, a si maa ṣe ohun ti ẹlomiran ko le ṣe.
Awọn Filistini jẹ ẹlẹṣẹ, Ọlọrun si ti pinnu lati mu idajọ wá si ori wọn. Wọn ti ni anfaani lati ronupiwada ṣugbọn wọn kọ lati yi pada si Ọlọrun. Nisisiyii, ijiya wọn bẹrẹ si i wá sori wọn lati ọwọ Samsoni.
Igbogun Ti Ẹṣẹ
Awọn ọmọ Ọlọrun lonii ni lati maa doju ija kọ ẹṣẹ nigba gbogbo. Ki i ṣe pe ki a kọjuja si ẹlẹṣẹ lati pa a run nitori ẹṣẹ rẹ, ṣugbọn a o maa doju ija kọ iwa aitọ nibikibi ti a ba gbe ri i. A o gbiyanju lati tọ ẹlẹṣẹ si ọdọ Jesu ki o ba le ronupiwada, ki o si ri igbala, ṣugbọn a ko le fara mọ ẹṣẹ rẹ tabi ki a lọwọ si i. A ni lati mú iduro wa lori otitọ ọrọ Ọlọrun ki a si kọju ija si ibi. “Ibẹru OLUWA ni ikorira ibi” (Owe 8:13).
Samsoni ni anfaani ni igba pupọ lati pa diẹ ninu awọn Filistini run; oun nikan ṣoṣo si pa ọpọlọpọ ninu awọn ọta. Awọn Filistini daamu nitori agbara Samsoni. Bawo ni wọn ṣe le mu un ni ẹrú? Bawo ni wọn ṣe le din agbara rẹ kù.
Awọn Filistini rán odindi ẹgbẹ ọmọ-ogun kan lati mu ọkunrin naa ti o ti mu iparun nlá nlà bayii wá si ori wọn. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ri ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun Filistini ti o pọ bẹẹ ti wọn n bọ wa, ẹru ba wọn. Dipo ti wọn i ba fi ran Samsoni lọwọ, wọn rán ẹgbẹẹdogun (3,000) awọn ọmọ-ogun Juda lati de e ki wọn si fi i le awọn Filistini lọwọ. Wọn wi fun Samsoni pe: “Iwọ kò mọ pe awọn Filistini li alaṣẹ lori wa? kili eyiti iwọ ṣe si wa yi?” Ki ni ṣe ti ohun ti Samsoni ṣe ni lati mu ibinu awọn ọta wá sori wọn, ti o fi gbogbo awọn Ọmọ Israẹli sinu ewu?
Igbọjẹgẹ
Eyi jẹ wiwo iṣoro pẹlu ọkan ojo. Ọlọrun ti gbe Samsoni dide lati bẹrẹ iṣẹ idasilẹ awọn Ọmọ Israẹli; bi awọn Ọmọ Israẹli ba si ti sowọ pọ pẹlu lati jà, boya wọn i ba ti tete ni iṣẹgun lori awọn Filistini. Dipo eyi, awọn Ọmọ Israẹli ni itẹlọrun lati maa gbé laaarin awọn ẹlẹṣẹ, ki wọn si wà labẹ igbekun wọn. Ẹru ba wọn lati mú iduro wọn fun ohun ti wọn mọ pe ó tọ.
Eniyan le yẹra fun idaamu tabi inunibini igba diẹ nipa fifi ara mọ awọn ẹlẹṣẹ, ṣugbọn Ọlọrun n kiyesi i. Idajọ ti Oun yoo rán, ni ikẹyin, si ori awọn ti o gbọjẹgẹ pẹlu ẹṣẹ yoo wuwo pupọ lati fara dà ju ijiya diẹ ti ẹni naa ni lati fara da lati mu iduro rẹ fun otitọ.
Pari Ẹrẹkẹ
Awọn Ọmọ Israẹli doju kọ ẹni ti yoo gbà wọn silẹ, wọn fi okun titun de Samsoni, wọn si fi i le awọn Filistini lọwọ gẹgẹ bi ẹrú. Ṣugbọn Ọlọrun ti gbe Samsoni dide lati bẹrẹ idasilẹ Israẹli. O si fi agbara fun Samsoni lati já okun wọnni bi ẹni pe okun ọgbọ ti o ti jona ni wọn.
Samsoni mu ohun ti o kọkọ ri lati lò gẹgẹ bi ohun-ija lati bá awọn ara Filistini jà. Pari ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ ni. Pẹlu egungun yii nikan Samsoni pa ẹgbẹrun (1,000) ninu awọn Filistini. Ọlọrun bẹrẹ si gba Israẹli nipa agbara onigboya ọkunrin kan ṣoṣo. A ti maa n gbọ pe bi Ọlọrun bá wà ni iha wa, a ju ọpọlọpọ lọ bi o tilẹ ku awa nikan ṣoṣo.
Samsoni ti ni iṣẹgun nla. Orungbẹ n gbẹ ẹ nisisiyii. Ki ni yoo ṣẹlẹ si i bi ko ba ri omi mu? Njẹ iṣẹgun rẹ yoo ha já si asán, oungbẹ yoo ha pa a kú bi? Samsoni ke pe Ọlọrun fun iranwọ, iranlọwọ si de nipasẹ omi ninu pari ẹrẹkẹ naa. Samsoni mu omi o si tun ni agbara ọtun lati jagun si i.
Ida Ẹmi
A le fi pari ẹrẹkẹ yii wé Ọrọ Ọlọrun, ohun-ija Onigbagbọ ninu ikọjuja si ẹṣẹ. Paulu Aposteli kọ akọsilẹ bayii: “Ki ẹ ṣi mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmi, ti iṣe ọrọ Ọlọrun” (Efesu 6:17); ati: “Nitori ọrọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idak’ida oloju meji lọ” (Heberu 4:12). Ọlọrun n fẹ ki a lo ọrọ Rẹ lati fi kọjuja si ibi. Bi Satani bá dán wa wò lati ṣe ohun ti kò tọ, a le da a lohun pe, “ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe a ko gbọdọ ṣe bẹẹ; nitori naa emi ki yoo ṣe e.” Nigba ti eṣu dán Jesu wò, asà Rẹ ni “A ti kọwe rẹ.” Satani jẹ alailagbara niwaju aṣẹ Ọlọrun.
Ki i ṣe pe ohun ija nikan ni Ọrọ Ọlọrun jẹ fun wa, ṣugbọn a maa n ri agbara gbà lati inu ọrọ naa. Ni ọjọ kan nigba ti wolii Jeremiah rò pe o fẹrẹ jẹ pe oun nikan ni o kù ni gbogbo ayé ti o fẹran Ọlọrun ti o si gbọran si aṣẹ Rẹ, o ri apa kan Bibeli o si wi pe: “Nigbati a ri ọrọ rẹ, emi si jẹ wọn, ọrọ rẹ si jẹ inu didùn mi” (Jeremiah 15:16). Ki i ṣe takada ti a kọ ọrọ naa si ni o jẹ, ṣugbọn ohun ti o kà nibẹ ni o ranti ti o si pa a mọ bi iṣura sinu ọkàn rẹ, o fun un ni igboya ọtun lati maa lo ayé rẹ fun Ọlọrun.
Nasiri Kan
A ko le sọ bi iṣẹgun Samsoni i ba ti pọ to ju eyi ti o ni lọ, bi o ba ṣe pe nigba gbogbo ni o ti gbé igbesi-aye rẹ lati wu Ọlọrun. Iya rẹ ti yà á sọtọ fun iṣẹ-isin Ọlọrun, gẹgẹ bi Nasiri ki a tilẹ to bi i; bi o ba si ṣe pe o mu gbogbo ifararubọ wọnni ṣẹ ni, oun i ba le gbe igbesi-aye mimọ, ti o si wulo fun Ọlọrun ati eniyan. Ronu iru ibukun ti i ba jẹ ti rẹ bi o ba ṣe pe o pa agbara ti ẹmi ati ti ara ni mọ!
Awọn ọmọ ti wọn ni obi ti o jẹ ẹni iwa-¬bi¬-Ọlọrun ni ogún rere, wọn si ni iṣẹ nla lati ṣe. Bi awọn obi wa ba ti yà wá sọtọ fun Oluwa, eyi jẹ ibẹrẹ daradara si igbala ati igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun. Awọn ibukun wọnyii bẹrẹ lati igba ti a bi wa. Ṣugbọn bi a ba kọ lati rin ni ọna ti Ọlọrun là silẹ fun wa, a o jẹ iya ti o buru ju ti awọn ti kò tilẹ mọ Ihinrere ri. O daju pe Ọlọrun yoo rán idalẹbi fun ẹṣẹ sinu ọkàn awọn ọmọ ni idahun si adura awọn obi, ṣugbọn Ọlọrun kò le gba ẹnikẹni là bi ẹni naa kò ba fẹ. Olukuluku ni o gbọdọ ronupiwada fun ara rẹ; bi o ba si kọ lati ṣe bẹẹ, oun yoo ṣegbe titi ayeraye lẹyin gbogbo adura awọn obi rẹ.
Apa kan ninu ẹjẹ Nasiri ni pe wọn ni lati fi irun ori wọn silẹ ki o gùn, Ọlọrun si ti pa aṣẹ pataki kan nipa ti Samsoni, pe abẹ kò gbọdọ kan ori rẹ. Ki i ṣe gbogbo eniyan ti o ba da irun si, nipa ẹjẹ ni o n ni agbara bi ti Samsoni, ṣugbọn o dabi ẹni pe àsopọ kan wa laaarin agbara rẹ ati irun ori rẹ. Niwọn igba ti irun ori rẹ ba wa ni gígùn lai ge e, awọn Filistini kò ni agbara lati bori rẹ.
Biba Filistini Kan Ṣe Ọrẹ
Samsoni fi ara rẹ fun idoju kọ ọta nigba ti o tọ awọn Filistini lọ ti o si pade Delila. Nigba ti awọn Filistini gbọ pe o wà laaarin wọn, wọn fi owó bẹ Delila pe ki o fi i le awọn lọwọ. Nipa fifi ẹtàn ṣe bi ẹni pe o fẹran rẹ, o bẹ ẹ pe ki o sọ aṣiiri agbara rẹ fun oun. Samson wi pe bi a ba fi okun tutu meje de oun (okun ti o rọ bi ti wilo) oun yoo di alailagbara bi ọkunrin miiran. Lẹsẹ kan naa ni awọn ọta ti de lati fi okun tutu de e; ṣugbọn nigba ti Delila kigbe pe: “Awọn Filistini dé, Samsoni,” o dide o si já awọn ide naa bi ẹni pe a ti fi iná jó wọn, O si bọ lọwọ wọn.
Samsoni i ba ti dẹkun lilọ sọdọ Delila, paapaa ju lọ nigba ti o mọ pe o fẹ lati ṣe onikupani fun oun. Ṣugbọn o tun pada lọ; lẹẹkan si i o tun gbiyanju lati wadii aṣiiri agbara rẹ. Ni akoko yii, o sọ fun un pe, bi a ba fi okun tutu eyi ti a ko i ti i lo ri de oun, oun yoo di alailagbara. Nigba ti o sùn, awọn Filistini fi okun titun de e, ṣugbọn nigba ti o ji, o fà wọn já bi ẹni pe fọnran òwú lasan ni wọn. O dabi ẹni pe Samsoni ni inu-didun ninu fifi awọn Filistini ṣe ẹlẹya nipa itan ajeji ti o n sọ yii, ṣugbọn o n fi ewu dán ara rẹ wò ni, lai pẹ jọjọ yoo si bọ si ọwọ awọn ọta nipasẹ erekere yii.
Lati ọjọ de ọjọ ni Delila a maa bẹ ẹ pe ki o sọ aṣiiri agbara rẹ fun oun, nikẹyin o fi ẹkún bori rẹ. O sọ otitọ fun un pe oun wà labẹ ẹjẹ Nasiri, abẹ kò si ti i kan ori oun ri, ati pe bi a ba gé irun oun, oun yoo dabi ọkunrin miiran. Obinrin naa mu ki wọn ge irun rẹ, nigba ti awọn ọta si de, kò ni agbara mọ.
Fifi Ara fun Idanwo
Ẹnikẹni ti o ba n fi ara fun idanwo yẹ ki o mọ daju pe idanwo yoo bori oun naa nikẹyin. Ọrọ Ọlọrun kilọ fun wa pe: “Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin” (Jakọbu 4:7). Samsoni fi ara fun idanwo dipo ti oun i ba fi yẹra fun un, awọn Filistini si mu un, wọn si fi i si abẹ isinru iṣẹ lile ninu ile tubu. Wọn yọ ojú rẹ kuro, o si jokoo ninu okunkun.
A le ri ibanujẹ nla ti o de ba apẹyinda nitori o yi pada kuro lẹyin Ọlọrun. Ẹni ti o ba n ṣe ohun ti o wu Oluwa yoo ṣẹgun ọta; ṣugbọn bi o ba yi pada kuro lẹyin Olugbala, Satani ni oluwa rẹ, yoo si mu ki o ṣiṣẹ lile fun ere ikú ayeraye. Apẹyinda sọ imọlẹ ologo ti Ihinrere nù, o si jokoo ninu okunkun ẹṣẹ, ninu ifọju si awọn ohun rere ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn ti o fẹ Ẹ.
Ironupiwada
Samsoni ni akoko lati rò nipa Ọlọrun nigba ti o wà ni ipò ẹrú ninu ile tubu. O dabi ọmọ oninakuna ẹni ti “oju rẹ walẹ” ninu agbo ẹlẹdẹ ni ilẹ ajeji lẹyin ti o ti ná gbogbo owó rẹ tan ninu ẹṣẹ. Samsoni wa ri i pe ẹṣẹ rẹ ni o mu wahala yii wá si ori oun, o si yipada si Ọlọrun.
Irun Samsoni bẹrẹ si i hù, agbara lati ọdọ Ọlọrun wá si n dé fun un bi irun naa ti n hù. Ni ọjọ kan ti awọn Filistini n yin ọlọrun eke, wọn wi pe on ni o fi Samsoni le wọn lọwọ, wọn mu Samsoni wá si iwaju wọn lati fi ṣe ẹlẹya. Ọpọlọpọ eniyan ni o ti pe jọ si gbọngan nla naa nibi ti wọn n fẹ ṣe ajọyọ naa, ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni o si wà lori orule ile naa. Laaarin ipejọpọ awọn abọriṣa wọnyii Samsoni gbe ọkàn rẹ soke si Ọlọrun Israẹli, o si gbadura pe: “Oluwa ỌLỌRUN, emi bẹ ọ, ranti mi, ki o si jọọ fun mi li agbara lẹẹkanṣoṣo yi.” Ọlọrun gbọ adura rẹ, O si san fun un gẹgẹ bi igbagbọ rẹ. Ninu Heberu ori kọkanla, a kà pe nipa igbagbọ ni a sọ Samsoni “di alagbara ninu ailera.”
Pipada Jẹ Ipe Ọlọrun
Samsoni beere pe ki a mu oun wá si itosi awọn ọwọn ti o wà ni agbedemeji ile naa, bi ẹni pe o n fẹ lati fi ara ti wọn lati sinmi. Ṣugbọn Ọlọrun ti fi iṣẹ pipa awọn Filistini run le e lọwọ; ni wakati ikẹyin aye rẹ, Samsoni tungba ẹrù iṣẹ naa rù. O ke pe Ọlọrun fun agbara, pẹlu imikanlẹ nla o fa ile nla naa lulẹ lori ogunlọgọ awọn eniyan ti wọn wà nibẹ. Ẹgbẹẹgbẹrun ni o kú. Samsoni kú pẹlu wọn, ṣugbọn ni ikú rẹ o pa ju iye awọn eniyan ti o pa ni igba ayé rẹ lọ, a si gbẹsan Israẹli lara awọn ọta wọn.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ohun ti o jẹ ajeji nipa Samsoni?
- Ki ni ṣe ti a fi jẹ onidajọ?
- Bawo ni Samsoni ti ṣe iṣẹ naa?
- Bawo ni a ṣe mọ pe awọn Ọmọ Israẹli kò ti Samsoni lẹyin?
- Ki in mu ki Samsoni sọ agbara rẹ nù?
- Ki ni awọn Filistini ṣe si Samsoni nigba ti wọn mu un?
- Ṣe apejuwe ọjọ ikẹyin ayé Samsoni.
- Ki ni ṣe ti Samsoni tun ni agbara lẹẹkan si i?