Matteu 21:12-32

Lesson 196 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ile adura li a ó ma pè ile mi” (Matteu 21:13).
Cross References

I Ọmọ Ọlọrun ninu Ile Ọlọrun

1. Jesu tún rí iwa ibajẹ ninu ile Ọlọrun, O lé awọn oluṣe buburu jade pẹlu ọwọ lile, Matteu 21:12, 13; Marku 11:15-17; Isaiah 56:7; Jeremiah 7:11

2. Lẹyin eyi, O ṣe iṣẹ miiran ti i ṣe ti Ọlọrun nibẹ. Matteu 21:14; Luku 19:47, 48; 20:1; 21:37

3. Inú bí awọn aṣaaju alaiṣootọ bí Jesu ti lo àṣẹ tí o tọ si I, wọn si dojú kọ Ọ ni gbangba, Matteu 21:15, 16; Marku 11:18; Luku 19:47, 48

4. Jesu fi Ọrọ Ọlọrun dá wọn lohùn, Matteu 21:16, 17; Orin Dafidi 8:2

II Ẹkọ lara Alaileso Igi Ọpọtọ

1. Nigbà ti ebi pa Jesu, Ó wá eso lori igi ọpọtọ ṣugbọn kò rí nnkan kan, Matteu 21:18, 19; Marku 11:13; Orin Dafidi 1:1-6

2. Igi alaileso naa jé̩ apẹẹrẹ Israẹli alaileso ati awọn alafẹnujé̩ ẹlẹsin pẹlu, Matteu 13:22; Johannu 15:1-9, 16; Galatia 5:22, 23

3. Idajọ naa wà fun aileso wọn, Matteu 21:19, 20; 3:10; Luku 19:20-26; Romu 11:29

4. A fi bi igbagbọ ti lagbara tó, bi ó ti niyelori tó ati bi ó ti jé̩ ọranyàn tó hàn, Matteu 21:21, 22; Romu 14:23; Habakkuku 2:4; Johannu 6:28, 29; Efesu 6:16; Heberu 11:1, 6; Jakọbu 1:5, 6

III Imoye ati Ọgbọn Jesu

1. A pe Kristi níjà nipa ti àṣẹ Rè̩, rírán-jade Rè̩ lati ọdọ Ọlọrun ati níti pé Ọlọrun ni Òun í ṣe, Matteu 21:23; Johannu 12:44-50; 13:20

2. Idahun Jesu tí o pa wọn lẹnu mọ ni o tilè̩ jé̩ ìfihàn aṣẹ Rè̩ Matteu 21:24, 25

3. Nigbà ti wọn kò le dahun bi ó ti tọ, ti wọn kò si gba Kristi gẹgẹ bi Messia sibẹ, wọn fi èké yẹ ibeere naa silè̩, Matteu 21:25-27; Luku 20:5-8

4. Èké ati aiṣòótọ jé̩ ki wọn padanu otitọ, Matteu 21:27; 13:4, 19; 2 Tẹssalonika 2:10-12

IV Baba ati Awọn Ọmọ Rè̩

1. Kíkọ ati ironupiwada ọmọ kin-in-ni dabi ẹlẹṣè̩ kan ti ó ronupiwada nikẹyin, Matteu 21:28, 29

2. Gbigbà ati ìṣọtè̩ ọmọ keji dabi àgàbàgebè kan, Matteu 21:30

3. Apejuwe yii wà fun Israẹli tí a ti ọwọ Ọlọrun yàn, ṣugbọn tí ó ṣe aigbọran sí Ọlọrun, Matteu 21:31, 32; Ẹksodu 19:5, 6, 8; Jeremiah 31:31, 32

Notes
ALAYE

Jesu, Ọmọ Ọlọrun

Akoko ti Jesu fi iṣẹgun wọ ilu Jerusalẹmu ti kọja, bakan naa si ni ọjọ ti ó ṣẹlẹ pẹlu. Awọn eniyan ti fi iyin fun Jesu, wọn si ti juba Rè̩ gẹgẹ bi Ọmọ Dafidi, Ẹni ti ó wá ní orukọ Oluwa. Wọn ti fi iyin fun Ọlọrun fun gbogbo iṣẹ iyanu Rè̩, wi pé, “Olubukun li Ọba ti o mbọ wá li orukọ Oluwa” (Luku 19:37, 38). Ni ọjọ keji ọsẹ, eyi ti ó ṣe déédé pẹlu ọjọ Ajé (Monday) ti wa, Jesu fi ilu Bẹtani silẹ, a si ri I ní Jerusalẹmu, nibẹ ni a fi yé wa pé Ó gbé lo ọjọ ti ó pọ julọ ninu ọsè̩ naa.

Ile Maria, Marta ati Lasaru wà ní Bẹtani. Ìgbà gbogbo ni Jesu sì n lọ sibẹ nitori irẹpọ ati ifẹ Onigbagbọ fara hàn ninu ile awọn ọmọ ẹyin tòótọ wọnyii. Bẹtani jé̩ ilu kekere kan lẹba Oke Olífì, ó jé̩ ibi ìdáké̩jé̩ nibi tí Jesu ti lè sinmi kí Ó sì yẹra kuro lọdọ awọn èrò tí ó wà ni ilu Jerusalẹmu.

Gé̩ré̩ tí Jesu bẹrẹ iṣé̩ iranṣẹ Rè̩, Ó lọ si Tẹmpili nibi ti Ó gbé lé awọn oni pàṣípàrọ owó ati awọn tí n ta maluu, agutan ati ẹyẹlé jade. Laisi aniani, awọn eniyan faramọ iwa ibajẹ yii ti o n lọ ninu ile Ọlọrun, boya awọn alaṣẹ awọn Júù pàápàá tí ó wà nigba nì ni wọn tilẹ dá a silẹ ní èrò ẹtan pé yoo jé̩ ohun ìrọrùn fun awọn tí wọn n ti òkèèrè wá lati jọsin ni Tẹmpili.

Ofin Mose ti fi ilana silẹ pe, gbogbo awọn ti wọn bá ti ọna jinjin wá lè yí ohun irubọ wọn pada si owó kí ó lè dín wahala wọn lati mu ohun tí wọn fé̩ fi rubọ gan-an wá sí Jerusalẹmu (Deuteronomi 14:24-26). Nigba ti wọn ba si de Jerusalẹmu, nigba naa ni ki wọn ki ó ra ohunkóhun tí wọn bá fé̩ fún irubọ wọn, Ọlọrun yoo si té̩wọ gbà á. Eyi kò fi hàn pé Ọlọrun fé̩ ki a sọ ile Òun di ile ọja títà. Tẹmpili Ọlọrun jé̩ ibi adura; ṣugbọn ojú kòkòrò ni ó mú kí awọn tí ó n ta ọjà wá sí agbègbè ibi tí ì bá jé̩ ibugbé Ọlọrun, ki wọn ki ó le jèrè lori awọn ẹran ati ẹyelé ti wọn n tà.

Ohun pataki ni pé ní ibẹrẹ iṣé̩ iranṣẹ Jesu ni ayé ati nigbà ti iṣé̩ iranṣẹ naa n parí lọ, Ó tako bíba ile Ọlọrun jé̩. Ó sọ ọrọ lile nigbà iṣaaju (Johannu 2:13-17), ṣugbọn ọrọ ti ikẹyin tún le ju ti iṣaaju lọ. Gbogbo iṣé̩ iranṣẹ Kristi fi ara tì sí eyi pé, Ọlọrun nikan - kì í ṣe iṣé̩ eniyan – ni a gbọdọ gbé ga; ati pe ile Ọlọrun gbọdọ jẹ ibi ọwọ, ati ibi adura nibi ti a ti le gbọ ododo Ọrọ Ọlọrun, kò si gbọdọ jé̩ “ihò olè” – ibugbe awọn eniyan buburu.

O ní àṣẹ lati sọ ọrọ yii. Oun ni Ọlọrun Ọmọ ti ó bá Ọlọrun Baba ati Ọlọrun Ẹmi Mimọ dọgba. Ó ti wà lati àtètèkọṣe! Niwọn igba ti Tẹmpili yii ti jẹ ile Ọlọrun, Jesu jé̩ Oluwa lori rè̩. Kò si ẹni ti ó ní ẹtọ lati takò Ó tabi jà Á níyàn, awọn ti ó bá sì n takò Ó kò gbà pé Ọlọrun ati Messia ni Jesu i ṣe, wọn si n sé̩ aṣẹ ati iṣẹ iranṣẹ Rè̩. Ní ṣiṣe eyi, awọn alaiṣootọ wọnyii n sé̩ Ọlọrun pàápàá ati gbogbo ọrọ awọn wolii Ọlọrun lati ibẹrẹ. Ohun ti wọn rí ninu iṣẹ iranṣẹ Rè̩, ninu ọrọ awọn wolii ti ó sọ nipa bibọ Rè̩ tabi Ẹmi Ọlọrun tí ó ṣiji bò Ó tó fún ẹri lati fi hàn wọn dáju-dáju pé Òun ni Ọmọ Ọlọrun. S̩ugbọn wọn sé̩ Ẹ. Ati nitori eyi, a le wi pe wọn di baba ati awọn ọmọ ẹyin kín-in-ni ti Aṣòdì-si-Kristi, ẹni ti yoo gba agbara nigba ipọnjú nlá (1 Johannu 2:18, 22; 4:2, 3).

Igi Ọpọtọ tí ó Yàgàn ati Alaileso Ọmọ-ẹyin

Bi wọn ti n lọ lati Bẹtani si Jerusalẹmu, ebi bẹrẹ si i pa Jesu. Eyi ki i ṣe ìgbà ọpọtọ ni tootọ; ṣugbọn nigbà ti Ó wà ni okeere O ri igi kan ti ó ti dé àyè ibi ti ó yẹ ki a ri eso ti ó pọn ká lori rè̩. S̩ugbọn nigba ti O wo orí rè̩ lati ri èso, kò rí ohunkohun. A sọ fun wa pe oriṣiriṣi igi ọpọtọ ni ó wà, ọkọọkan a si maa so eso nigba pupọ lọdun. Igi ọpọtọ yatọ si awọn igi miiran niti pé èso rè̩ ni ó kọ n yọ kí ó tó rúwé rárá. Nigbà ti ewé rè̩ ba gbòòrò tán ni èso rè̩ yoo pọn fun ikore. Nitori òkèèrè ni Kristi gbé rí igi yìí fi hàn wá pé, ewe awọn igi miiran kò tíì gbòòrò dé àyè wọn; ki i ṣe igba ti a n kórè èso ọpọtọ. S̩ugbọn nitori ewe igi yii ti gbòòrò dé àyè rè̩ a mọ pe ó wà lara awọn ti o n tètè mú eso jade, nitori naa Kristi ni ẹtọ lati reti eso lori igi yii.

Ọlọrun ki i beere ohun ti kò tọ. Ki I sì í reti ohun ti kò tọnà tabi ti kò ṣe é ṣe. Wọn a maa wi pé, “Ọlọrun yoo fún ni lagbara lati ṣe ohun ti Ó bá beere.” Kristi ko lọ si idi igi ọpọtọ yii kí Ó maa reti eso olífì, tabi ti ọpẹ tabi ti àjara. Eso ọpọtọ ni Ó n beere, Ó si ní ẹtọ lati ṣe bẹẹ nitori gbigbooro ewe igi yii fi hàn pé eso rè̩ ní lati pọn.

Ọlọrun kò fé̩ ki a ṣe afarawe ẹnikẹni. Ki Ọlọrun ki Ó tó té̩wọ gbà wá, Ó n fé̩ ki a duro ninu ipe kan naa ninu eyi ti a pe wa (1 Kọrinti 7:20), nitori “ailábámọ li è̩bun ati ipe Ọlọrun” (Romu 11:29). Ireti Ọlọrun ni pe ki olukuluku ki o so eso ti ara rè̩; ṣugbọn Ó n fé̩ kí a so eso. Ọlọrun yoo si beere ojuṣe yii lọwọ wa.

Ododo patapata ni idajọ Ọlọrun. Ó n reti eso lọwọ wa gé̩gé̩ bi iwọn Ihinrere ti a ti gbà. Awọn ẹlomiran ní ẹbun ti ó pọ, nitori naa ohun tí ó pọ ni a n reti lọwọ wọn. Awọn miiran si ni anfaani ti o pọ ju ti ẹlẹgbẹ wọn lọ, nitori naa ni a o ṣe ka a si wọn lọrun bi wọn kò ba lo anfaani ologo ti Ọlọrun fi ta wọn lọrẹ. È̩bá ọna ni igi ọpọtọ yii wa nibi ti ì bá ti jé̩ ibukun fun ọpọlọpọ eniyan - ṣugbọn kò so eso! Ọpọlọpọ eniyan ni ó wà lonii ti wọn wà ni “ojútaye” nibi ti anfaani lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun ati lati so eso gbé wà fun wọn lọpọlọpọ ju ẹnikẹni lọ, ṣugbọn wọn kò ṣe bẹẹ. Awọn Ọmọ Israẹli jé̩ apẹẹrẹ irú wọnyi niwọn bi o ti jẹ ilana Ọlọrun pé ki wọn ki ó jé̩ iranṣẹ Majẹmu Ọlọrun, olupamọ Ọrọ Iye, ati ninu orilẹ-ede ẹni ti Messia yoo ti wá. S̩ugbọn a ti mọ pé wọn fà sẹyin kuro ninu Majẹmu ti wọn bá Ọlọrun dá, wọn kò si le so eso pupọ fun Ọlọrun gẹgẹ bi orilẹ-ede. Kàkà bẹẹ, ẹni kọọkan ṣa ni o mu anfaani Majẹmu mimọ wọnnì lò - Ju ati Keferi - awọn ẹni ti o ti fi tifẹtifẹ pa gbogbo ilana Majẹmu naa mọ, laaarin gbogbo igba ati akoko.

Bawo ni o ti dara to pe Ẹmi Ọlọrun ti fi ohun kan silè̩ fun wa ti a le tete ri gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọna pataki ti a fi le so eso – ohun naa ni adura ìṣìpè̩. Ọna ti a le gbà lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun pọ, ṣugbọn ọkan pataki ninu wọn ni adura gbigba. Kò si ohun tí a le ṣe ní aṣeyọri fun Ọlọrun lai si adura. Bé̩è̩ ni adura ninu ara rè̩ kò níláárí bí kò ṣe pe ó bá jé̩ gẹgẹ bi ifẹ ati ileri Ọlọrun. Bi iṣẹ isin kan ti wù kí ó níláárí tó, yoo jé̩ alailagbara afi bí ó ba lọ pẹlu igbagbọ lati mu ki ifẹ Ọlọrun di mímọ. Igbagbọ tootọ ni a fi n ri ibukun ti a n beere gbà. Oluwa lo iṣẹ iyanu yii lati bukun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ati lati sọ igbagbọ wọn – ati ti wa pẹlu di lile – ati pẹlu ki a le so eso si i lọpọlọpọ.

Ipenija tí ó Fa Ipenija

Awọn olori alufaa ati awọn agbaagba n wá ọna lati bi Jesu ṣubu. Aṣẹ tí Ó lò ní tẹmpili ni lílé awọn ti ó n ba ile Ọlọrun jé̩ jade, kikọ awọn eniyan ni Ọrọ Ọlọrun nibẹ ati ṣiṣe iṣẹ iyanu ti ó fi hàn gbangba pé Ọlọrun ati Messia ni Òun í ṣe, mú ki wọn takò Ó kikan-kikan. Ni ireti ati mu Jesu, wọn pè É níjà ní bibeere pé: “Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi?” Wọn n wá ipò lati ọdọ eniyan wá ṣugbọn kò si ipo kan ti ó dabi rẹ loju wọn. Lati ọdọ Ọlọrun wa ni a ti yan Jesu ti a si fi aṣẹ fun Un, ṣugbọn eyi kò jọ awọn àgàbàgebè ajọra-ẹni-lójú ati onigberaga wọnyii lójú.

Ẹni ti i ṣe Oluwa ile Ọlọrun pè wọn nija pẹlu ibeere ti wọn kò le fèsì. O yẹ ki wọn dahun. Wọn ni òye tó lati dahun pérépéré. S̩ugbọn bi wọn ba ṣe bẹẹ, aṣiiri àgàbàgebè wọn yoo tú, è̩ṣẹ wọn yoo si di mimọ.

Nipa Jesu ni iwaasu Johannu. Gbogbo ohun ti ó ṣẹlẹ ninu iṣẹ iranṣẹ rè̩ n tọka si Ọdọ-Agutan Ọlọrun. Bi wọn ba gba ẹri Johannu wọn ni lati gba Jesu gbọ. S̩ugbọn nigba ti a ri Jesu bọmi ni Ọlọrun Baba sọrọ pato lati Ọrun wá pé, “Eyi ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi” (Matteu 3:17). Nibẹ ni Ẹmi Mimọ sọkalẹ, O si bà lé Ọmọ Eniyan, mimọ ati alailabawọn gẹgẹ bi ẹlẹri si aṣẹ Rè̩. Idahun si ibeere wọn wà ninu ibeere ti Jesu fi siwaju wọn. Oun kò gba aṣẹ lati ọdọ eniyan; lati ọdọ Ọlọrun ni aṣẹ Rè̩ ti wá, ó si tayọ gbogbo aṣẹ ti eniyan.

Awọn Alai-fẹ-kan an-ṣe-Ọmọ

Laaarin ọsẹ kan naa ni Jesu n kọ ni ní Tẹmpili, O si sọ fun awọn ti wọn pejọ ti I nipa ọkunrin kan ti ó ní ọmọ meji ti ó pè lati lọ ṣiṣẹ ninu ọgbàa ajara. Bi a bá gba apẹẹrẹ Bibeli ti ó n fi ọgbà ajara wé oko ikore Ọlọrun, a ó rí otitọ pataki nihin.

Ọkan ninu awọn ọmọkunrin wọnyii dabi ẹlẹṣẹ ti ó n mọọmọ dẹṣẹ, tí Ẹmi Ọlọrun si kéde Ijọba Ọlọrun fún ti ó dahun pé oun ki yoo lọ, ṣugbọn nigbooṣe ti ó ronupiwada, ó lọ ṣiṣẹ fun Baba rè̩. Eyi ekeji si dabi orilẹ-ede Júù tí wọn wí pé awọn yoo lọ, ṣugbọn ti wọn kò ṣe bẹẹ. Eyi ti ó lọ ni ó ṣe ifẹ Baba rè̩.

O ṣe é ṣe lati wí pé Wolíì ni Kristi, ki a má sì gba ẹkọ Rè̩. O ṣe é ṣe lati pe É ni Ọba, ki a má si jé̩ oloootọ si I. Eniyan le gbà Á ni alaṣẹ, kí ó má sì sìn-Ín bí ó ti tọ. O tilẹ ṣe é ṣe lati gbà pé Oun ni Ọmọ Ọlọrun, ki a má si sin I. Ó ṣe ni láàánú pé awọn miiran wà, tí wọn gbagbọ pé Oun nikan ni Olugbala, ti wọn kò si jé̩ gbà Á gẹgẹ bi Olugbala wọn. Ẹni ti o ṣe ifẹ Baba naa ni ẹni ti o dahun ìpè Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ohun pataki ti ó ṣẹlẹ ṣiwaju ẹkọ wa yii?
  2. Ki ni ohun ti ó ṣẹlẹ ni Tẹmpili ti ó fi hàn pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun?
  3. Ki ni awọn ọmọ kekere ṣe ni Tẹmpili?
  4. Nibo ni Jesu ti lo àkókò idáké̩jé̩ Rè̩ laaarin ọsẹ ti ó kẹyin yii?
  5. Sọ itan igi ọpọtọ alaileso.
  6. Ẹkọ nla wo ni Jesu n kọ wa ninu ohun ti ó ṣẹlẹ yii?
  7. Sọ ìlérí nlá ti a kọ sinu Matteu 21:22.
  8. Ki ni ṣe ti awọn olori alufáà ati awọn àgbàagbà fi tako àṣẹ Jesu?
  9. Ki ni èsi Jesu?
  10. Fi ìtàn ọkunrin nì ati awọn ọmọ rè̩ meji wé ilana Majẹmu Ọlọrun.