Matteu 21:33–46

Lesson 197 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Okuta ti awọn ọmọle kọ silẹ li o di pataki igun ile. Lati ọdọ OLUWA li eyi: o ṣe iyanu li oju wa” (Orin Dafidi 118:22, 23).
Cross References

I Ọgbà Ajara

1. Baale ile kan gbin ọgbà ajara kan ti ó fi ṣe àgbàṣe fun awọn oluṣọgba, ó si lọ si ilu òkeere, Matteu 21:33; Isaiah 5:1-7; Orin Dafidi 80:8

2. O rán awọn ọmọ ọdọ rè̩ lati gba eso ọgba ajara naa, Matteu 21:34

3. Awọn oluṣọgba lu ọkan ninu awọn ọmọ ọdọ naa, wọn pa omiran, wọn sọ omiran lokuta pa, Matteu 21:35; Jeremiah 37:15; 38:6; 26:23

4. O rán awọn ọmọ ọdọ miiran, awọn oluṣọgba si ṣe bí i ti iṣaaju sí wọn, Matteu 21:36; 2 Kronika 36:15, 16; Nehemiah 9:26

5. Bori gbogbo rè̩, awọn oluṣọgba pa ọmọ rè̩, ki wọn le gba ìní rè̩, Matteu 21:37-39; Gẹnẹsisi 37:18-20; Johannu 11:53; Iṣe Awọn Aposteli 2:23

6. A o jẹ awọn oluṣọgba buburu naa ni ìyà, Matteu 21:40, 41; Iṣe Awọn Aposteli 13:46; 18:6; 28:28

II Okuta tí a Kọ Silè̩

1. Okuta ti a kọ silẹ di pataki igun ilé, Matteu 21:42; Orin Dafidi 118:22; Isaiah 28:16; Daniẹli 2:34; Iṣe Awọn Aposteli 4:11

2. Ẹnikẹni ti ó bá ṣubu lu Okuta yii yoo fọ, ṣugbọn ẹnikẹni ti ó bá ṣubu lù, yoo lọ lúúlú, Matteu 21:44; 1 Peteru 2:7, 8

3. Jesu mú idajọ wá sori awọn Ọmọ Israẹli, Matteu 21:43-46

Notes
ALAYE

Orilẹ-edè Ju ni òwe yii n bá wí, a si pa òwe naa lati fi hàn fun wọn pé Oluwa yàn wọn lati jé̩ eniyan ti Rè̩, ṣugbọn wọn ti já Ọlọrun tilẹ wọn si ti kọ awọn wolii Rè̩, nitori eyi a ó gba ọgba ajara naa lọwọ wọn a ó sì fi í fun awọn ẹlomiran.

Àṣàyàn Àjàrà

Wolii Isaiah ṣe apejuwe fun wa nipa ọgba ajara daradara eyi ti Oluwa gbìn, ati ilẹ ẹlé̩tù lójú níbi tí a ti n ṣe itọju rè̩ (Isaiah 5:1-7). A fi Kenaani, ilẹ ileri fun awọn Ọmọ Israẹli, a sì bukun ilẹ yii ní gbogbo ọna. Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe ilẹ naa n ṣàn fun wàrà ati oyin, eso ajara Eṣkolu si tobi lọpọlọpọ. Awọn ọgbà àjàrà miiran wà ti awọn Ọmọ Israẹli kò gbìn, awọn ọgbà ólífì ti n so èso wọn ati awọn ilú tí wọn kò kọ.

A ṣa okuta kuro ninu ilẹ naa. Eyi le yé wa pé ifẹ Oluwa ni lati lé awọn ara Kenaani jade - orilẹ èdè abọriṣa, ti kò ní Ọlọrun fi ṣe. A mú eyi ṣẹ, Ọlọrun ṣe ipa ti Rè̩, ó kù kí awọn Ọmọ Israẹli gbọran lati mú ki a ṣe aṣeparí ohun gbogbo.

Ọlọrun gbin aṣayan ajara si ilẹ yii, ẹbí awọn eniyan tí ó bè̩rù Ọlọrun. Oju baale ẹbí yii riran tayọ awọn ilu ati ọrọ aye yii, ó n retí ilu ti ó ní ìpìlè̩, tí a ti ọwọ Ọlọrun kọ (Heberu 11:10). Ẹni tí Ọlọrun yàn yii ni Abrahamu, ọkunrin Onigbagbọ nì tí ó gba Ọlọrun gbọ tí ó sì gbọran sí I lẹnu; irú Ọmọ Abrahamu ni Ọlọrun gbìn sinu ọgba ajara yii. Igi daradara ni Abrahamu í ṣe! Ki ni à bá tún ṣe sí ọgba ajara Ọlọrun?

Ìlú Òkèèrè

Nihin, a fi Oluwa wé baale ile kan tí ó n re ilú òkèèrè. Ó fi ọgba ajara lé awọn oluṣọgba lọwọ. Ó n reti pé kí awọn wọnyii wẹ àṣàyàn ajara tí ó gbìn, kí wọn bomi rin-ín, kí wọn ṣe itọju rè̩. Ni akoko eso Ó n reti lati rí eso ká. Ó wò, si kiyesí i, eso kikan ni ó mú wá. Awọn oluṣọgba yii ti kùna patapata. Ajara pataki yii ti di aláìníláárí.

Oluwa ọgbà àjàrà ti ṣe ipa ti Rè̩, Ó mú suuru fun wọn, Ó rán awọn wolii si wọn lati kọ wọn bí a ti í ṣe itọju ọgba ajara Rè̩. “Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn” (Jeremiah 35:15). O sọ fun wọn pe wọn ti ṣe iwọsi sí awọn tí a rán si wọn lati gba ìbísí oko rè̩ wá.Wọn sọ okuta lu awọn miiran, wọn lu awọn miiran, wọn si pa awọn miiran. “Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati inà, ati ju bḝ lọ ti ìde ati ti tubu: A sọ wọn li okuta, a fi ayùn ré̩ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rin kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro;” (Heberu 11:36, 37).

Rírán Ọmọ

Nikẹyin gbogbo wọn, oluwa ọgba ajara naa rán ọmọ rè̩ sí wọn, wi pe “Nwọn o ṣe ojusaju fun ọmọ mi.” S̩ugbọn bi ọdun ti n gori ọdun ni orilẹ-ede naa n burú sii. Kò si ilera ninu rè̩, bikoṣe ọgbé̩, ipalara, ati egbò ti n rà. Awọn oluṣọgba wi pé, “Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si kó ogún rè̩.” Ni akoko yii gan-an ti Jesu n pa owe yii, awọn olori alufaa ati awọn Farisi n gbimọ lati pa “Ọmọ” ki wọn si wọ Ọ jade kuro ninu ọgbà àjàrà naa.

Ibeere tí ó Já Gaara

Nigbà ti Jesu ti pa òwe yii tan, Ó beere ibeere kan lọwọ awọn ti o n gbọ ọrọ Rè̩ bayii pe, “Nigbati oluwa ọgbà ajara ba de, kini yio ṣe si awọn oluṣọgba wọnni?” Wọn fesi daradara. “Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa òṣi, yio si fi ọgbà ajara rè̩ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran.” Lai pẹ, a ri i tí a ké awọn Júù a sì yan orilẹ-ede Keferi dipo wọn (Romu 11).

A fi Ọgba Ajara fun Awọn Ẹlomiran

Lati igba Abrahamu titi di igba Kristi ni Oluwa ti n mú sùúrù fun awọn Ọmọ Israẹli. Oriṣiriṣi ọna ni Ó lò lati pa wọn mọ gẹgẹ bí awọn eniyan ìní Rè̩. Lọna keji, Ó bù síi fun wọn, Ó bukun wọn tilé tọnà, Ó si sọ wọn di orilẹ-edè nlá. Ọkàn wọn gbéga, wọn si ṣọtẹ. Nigbà naa ni Ó rè̩ wọn silẹ, Ó si rán wọn lọ sí igbekun. Nikẹyin gbogbo rè̩, Ó rán Ọmọ Rè̩ - Ọmọ Rè̩ ayanfẹ julọ.

S̩ugbọn ọkàn wọn kún fun ibi sibẹ. Wọn kọ Ọ, wọn kàn-Án mọ agbelebu, wọn si kigbe soke pe, “Ki ẹjẹ rè̩ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa.” Gé̩ré̩ ti wọn sọ awọn ọrọ wọnnì, a gba ọgbà ajara naa lọwọ wọn, a si fi í fun awọn Keferi.

Gẹgẹ bi Ọlọrun ti n bá orilẹ-ede lò, bẹẹ gẹgẹ ni Óun bá ẹni kọọkan lò. Iwọ ha dabi awọn oluṣọgba buburu wọnnì bí? Iwọ ha n wi pe, “Emi kò fẹ ki Jesu jọba ninu ọkàn mi?” Ẹmi Ọlọrun kì yoo fi igba gbogbo bá eniyan jà. Jesu n rọ olukuluku eniyan; ṣugbọn bi iwọ bá kọ Ọ patapata, nigba ti Oluwa ọgba ajara naa bá dé, ki ni yoo ṣẹlẹ si ọ? Ẹnu awọn Farisi paapaa ni wọn fi ṣe idajọ ara wọn nigba ti wọn wi pe, “Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa oṣi, yio si fi ọgbà ajara rè̩ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran.” Wọn kò lero rárá pe Ihinrere n kọja lọ lati ọdọ awọn Ju si ọdọ awọn keferi. “Paulu on Barnaba si sọ laibẹru pe, Ẹnyin li o tọ ki a kọ sọ ọrọ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ sì kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun; wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi” (Iṣe Awọn Aposteli 13:46).

Okuta tí a Kọ Silè̩

A sọ fun ni pé nigba ti a n gbé̩ awọn okuta lati ori oke wá lati fi kọ Tẹmpili, wọn kó awọn okuta wọnyii wá sí ibi tí Tẹmpili wà. Ọga awọn ọmọlé wo awọn okuta naa yika ó sì kọ ọkan ninu rè̩ nitori ó wi pé kò si àyè fún un. S̩ugbọn nigba ti ó bè̩rè̩ si kọ ile nla yii, o ri i pé okuta ti òun ti kọ ni okuta pataki igun ilé. Boya otitọ ni eyi ṣẹlẹ tabi bẹẹ kọ, a kò mọ, ṣugbọn a mọ pé otitọ ni nipa ti ẹmi. “Okuta ti awọn ọmọle kọ silè̩, on na li o si di pataki igun ile: eyi ni iṣẹ Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa” (Matteu 21:42).

Jesu ni okuta pataki Igun-ile. Oun ni ipilẹ ti gbogbo ile Ihinrere duro le lori. Ọlọrun kò le kọ ile yii lori eniyan. Bí Ó bá ṣe bẹẹ, ì bá ti wó. Nitori naa, Ó rán Ọmọ Rè̩ nikan ṣoṣo si aye yii lati jiya ki Ó sì kú fún irapada gbogbo agbaye.

Lọ Lúúlú

Bi a ba ṣubu lu okuta yii a ó fọ. Ẹmi Oluwa yoo fọ ẹmi agidi ati ọtè̩ wa, yoo si fun wa ni ọkàn ironu. Ọlọrun wi pe, “Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin” (Esekiẹli 36:26).

Iyatọ pupọ wa laaarin ṣiṣubu lu Okuta naa kí ó sì fọ wa, ati ki Okuta naa kí ó ṣubu lù wá kí ó sì lọ wá lúúlú. Orilẹ-ède Ju kò fé̩ ṣubu lu Okuta naa. S̩ugbọn lai pẹ ó ṣubu lù wọn a si lọ wọn lúúlú, a si tú wọn káàkiri orilẹ-ede gbogbo. A le yàn lonii lati ṣubu lu Okuta naa tabi ki a jé̩ kí ó ṣubu lù wá.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Orilẹ-èdè wo ni owe yii n bá wí?
  2. Awọn wo ni oluṣọgba? Ki ni wọn ṣe si awọn iranṣẹ Oluwa?
  3. Ki ni ṣe ti awọn oluṣọgba naa kò bọwọ fun Ọmọ?
  4. Ki ni abayọrisi owe yii lara awọn olori alufaa ati Farisi?
  5. Awọn wo ni wọn gba ọgba ajara nigba ti a gbà á lọwọ awọn Ju?
  6. Ta ni Okuta ti awọn ọmọle kọ silẹ?
  7. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti wọn bá ṣubu lu Okuta naa?
  8. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti Okuta naa ba ṣubu lù?