Matteu 22:1 – 14

Lesson 198 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ẹ lọ si ọna opópo, iyekiye ẹniti ẹ ba ri, ẹ pè wọn wá si ibi iyawo” (Matteu 22:9).
Cross References

I Àsè Igbeyawo ati awọn Alaimoore Eniyan

1. Ọba kan ṣe igbeyawo fun ọmọ rè̩, Matteu 22:1, 2; Luku 14:16; Ifihan 19:7-9

2. Awọn ọmọ-ọdọ lọ pe awọn ti a ti pè tẹlẹ si ibi igbeyawo, wọn kò si jé̩ ipe naa, Matteu 22:3; Marku 6:12; Luku 14:17-20

3. A rán awọn ọmọ-ọdọ miiran lọ, Matteu 22:4-6; Owe 9:2-6; Isaiah 25:6; Iṣe Awọn Aposteli 5:40; 1 Timoteu 6:10; Heberu 2:3

4. Ibinu ọba mu ki ó pa awọn apaniyan naa run, Matteu 22:7; Luku 14:24; 19:27; Daniẹli 9:26

II Àsè Igbeyawo ati Awọn tí ó Yé̩ Ìpè naa sí

Ọba naa pe gbogbo awọn ti a bá le rí, Matteu 22:8, 9; Luku 14:21; Iṣe Awọn Aposteli 13:46

1. Nikẹyin, ibi igbeyawo naa kún fun awọn tí a pè, Matteu 22:10; Luku 14:22, 23

III Alejo tí Kò Yẹ

1. A ri ẹni kan tí kò ní aṣọ iyawo, Matteu 22:11, 12; Ifihan 3:4; 16:15; Sefaniah 1:7, 8

2. A dì í, a sì gbé e sọ sinu òkùnkùn biribiri, Matteu 22:13; 8:12

3. “Ọpọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn”, Matteu 22:14; 20:16.

Notes
ALAYE

Eredi ti a fi pa owe yii ni lati kọ ni ní otitọ nipa Ijọba Ọrun, nipa fifi awọn ti a pè sibi àsè igbeyawo ṣe apẹẹrẹ, ati lati fi hàn bi ó ti jé̩ ohun danindanin tó lati ní aṣọ igbeyawo, eyi tí í ṣe imurasilẹ ti ó yẹ fun gbogbo ẹni tí yoo wá sí ibi àsè.

Àsè Igbeyawo

Ọlọrun n tọka, ninu òwe yii si àsè Ihinrere, eyi ti a n pe gbogbo eniyan sí. Awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ninu Majẹmu Laelae tí ó ṣapejuwe irẹpọ tímọtímọ tí ó wà laaarin Ọlọrun ati awọn ayanfẹ Rè̩ kò ṣàjèjì sí awọn awọn Ju nitori a n kọ wọn lẹkọọ yii nigbakuugba. Jesu wi pe, “Ijọba ọrun dabi ọba kan, ti o ṣe igbeyawo fun ọmọ rè̩”. A le ri otitọ ti a n kọ ní ìhín pé Ọlọrun ni ó rán awọn ọmọ ọdọ Rè̩ lati lọ í pe awọn tí a pè wá sí ibi igbeyawo. S̩ugbọn owe yii sọ fun ni pé wọn kọ lati wá. Bí a bá wo inu Iwe Mimọ a ó rí i bí a ti mú ọrọ yii ṣẹ nigba pupọ.

Awọn wolii wà lara awọn ọmọ ọdọ wọnni ti a kọ rán jade lati kéde Ihinrere ati lati pe awọn eniyan sibi àsè. Isaiah wi pe; “Ati ni oke nla yi li OLUWA awọn ọmọ ogun yio sè asè ohun abọpa fun gbogbo orilẹ-ède, asè ọti-waini lori gè̩dè̩gé̩dè̩, ti ohun abọpa ti o kún fun ọra, ti ọti-waini ti o tòro lori gè̩dè̩gé̩dẹ” (Isaiah 25:6). A sọ fun wa pé, “A ti wasu ihinrere fun wa gẹgẹ bi fun awọn na, ṣugbọn ọrọ ti nwọn gbọ kò ṣe wọn ni ire, nitoriti kò dàpọ mọ igbagbọ ninu awọn ti o gbọ ọ” (Heberu 4:2).

Bakan naa gẹgẹ ni Ọlọrun tun rán awọn iranṣẹ miiran si aye ẹṣẹ yii ki Oun ba le mu wọn wa sọdọ Oun tikara Rè̩. Ẹ ko ri bi ipe Ọlọrun yii ti kari gbogbo eniyan! Bi o bá jé̩ ipe si igbeyawo ọba ti aye yii ni, ẹnikẹni ki yoo kọ ọ, ṣugbọn wọn kọ eyi tí ó tóbi jù - ani ipe si àsè Ihinrere.

Wọn KọÌpè

A ka pe awọn ti a n pè si ibi àsè kò fi pe nnkan, wọn sì bá tiwọn lọ. Awọn miiran fẹ gbe igbesi aye idakẹjẹ ninu oko, wọn kò si fẹ ki a fi ohun nla naa yọ wọn lẹnu. Òwò awọn miiran dí wọn lọwọ, wọn kò ri àyè lati wá. Aniyan ayé dí ọpọlọpọ lọwọ lati jé̩ ipe naa, ainaani, ijafara ati aifi nnkan pè ni ó pilẹ kikọ ti awọn miiran kọ lati jé̩ ipe naa. Ẹwè̩, a tun rii pe awọn miiran ṣe atako, wọn tilẹ ṣe inunibini si awọn ọmọ ọdọ naa ti a rán lọ í pè wọn. Gbogbo awọn ti o kọ ipe ni ó ṣe àwáwí nitori àiwá wọn si ibi àsè igbeyawo. Gbogbo wọn ni ó n fé̩ ohun ayé yii ju awọn ibukun ti Ọrun.

Ibinu Ọba

A sọ fun ni ninu owe naa pe nigba ti ọba gbọ pe awọn ti a pè kọ lati wá, ó binu, ó si rán awọn ogun rè̩ lọ, o pa wọn run o si fi ina kun ilu wọn. Lẹyin ọdun diẹ ti Jesu ti pa owe yii, ọrọ yii ṣẹ si awọn Ju lara. Ni aadọrin ọdun lẹyin ti a bi Jesu. Titu pẹlu ogun awọn ara Romu pa Jerusalẹmu run patapata ati pupọ ninu awọn Ju. A pe wọn ṣugbọn wọn ko yẹ. Wọn ó ha ti yẹ niwọn igba ti wọn ti ṣe afojudi si Ọba Ọrun nipa ainaani ipe aanu ti Ó fi n pè wọn?

Nigba naa ni ọba paṣẹ fun awọn ọmọ ọdọ rè̩ lati jade lọ si òpópó ọna lati pe iye ẹni ti wọn bá le rí mú wá si ibi igbeyawo. Awọn ọmọ ọdọ naa si lọ, wọn si pe gbogbo ẹni ti wọn rí jọ. Wọn kò ṣe iyatọ laaarin awọn ẹni rere ati awọn ẹni buburu. Ibi Igbeyawo si kun fun awọn tí a pè. Ọlọrun paṣẹ ki awa naa ki ó ṣe bẹẹ gẹgẹ nitori Ó wi pé, “Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” (Marku 16:15). “Ati Ẹmi ati iyawo wipe, Mā bọ. Ati ẹniti o ngbọ ki o wipe, Mā bọ, Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi iye na lọfẹ” (Ifihan 22:17).

Aṣọ Iyawo

Laaarin awọn ara ila oorun, aṣọ igunwa funfun ni wọn n wọ ni igba ajọdun, wọn si gbà pe ẹnikẹni tí o ba wọ aṣọ miiran yatọ si eyi yẹ fun ijẹniya. Ẹni ti o ba si pe apejẹ ni o n pese aṣọ igunwa; a si n fi fun gbogbo ẹni ti a pe bi wọn ba tọ olori alase lọ lati beere.

Nigba ti ọba wọle lati wo awọn ti o wa jẹun, o ri ọkunrin kan nibẹ ti ko wọ aṣọ iyawo. Eyi kọ wa pe a ó yẹ olukuluku ẹni ti a pè wò. Ọba si wi pe, “Ọré̩, iwọ ti ṣe wọ ihin wá laini aṣọ iyawo?” Ọkunrin naa ko si le fọhun, nitori ọkàn rè̩ dá a lẹbi. Ko ri awawi kan ṣe nipa iwa afojudi ti o hù. A ti pese aṣọ silẹ ṣugbọn oun ko beere fun-un bẹẹ ni ko si gbé e wọ. Iwa afojudi ti kò lé̩gbé̩ ni ó hù.

Nigbà naa ni ọba wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, “Ẹ di i tọwọ tẹsẹ, ẹ gbé e kuro, ki ẹ si sọ ọ sinu òkunkun lode; nibè̩ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.” Eyi ni ipin awọn ti o kuna lati wọ aṣọ iyawo.

Wo ibanujẹ nlá tí o de ba ọkunrin yii, lẹyìn ìgbà ti o ti ri imọlẹ didan ti àsè igbeyawo ti o si ti gbọ orin ayọ, ti o si ri awọn ọpọ èrò ti n yọ, ki a si wa gbé oun sọ sinu okunkun biribiri! Ọnà tabi àyè kò si mọ lati ronupiwada. O yẹ ki o ti lo anfaani ti a ti pese silẹ fun ire rè̩ nigbà ti àyè ṣi silẹ fun un.

Ọlọrun sọ bayii pe: “Ẹ jẹ ki a yọ, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rè̩ si ti mura tan. On ni a si fifun pe ki o wọ aṣọ ọgbọ wíwẹ ti o funfun gbõ: nitoripe aṣọ ọgbọ wíwẹ nì ni iṣe ododo awọn enia mimọ” (Ifihan 19:7, 8). A ri i nihin pe aṣọ igbeyawo tootọ ni i ṣe òdodo awọn eniyan mimọ. Ọlọrun tikara Rè̩ ni o pese aṣọ igbeyawo nipa iku Ọmọ Rè̩ lori agbelebu. Bawo ni o ti buru tó lati kọ aṣọ iyawo ti a nawọ rè̩ si wa! Ọfẹ ni, lai ni owó, a kò si diye le e. A tun ka ninu Bibeli pe: “Pa ẹnu rẹ mọ niwaju Oluwa ỌLỌRUN: nitoriti ọjọ OLUWA kù si dè̩dẹ: nitori OLUWA ti pesè ẹbọ kan silè̩, o si ti yà awọn alapèjẹ rè̩ si mimọ. Yio si ṣe li ọjọ ẹbọ OLUWA, ti emi o bè̩ awọn olori wò, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo iru awọn ti o wọ ajèji aṣọ” (Sefaniah 1:7, 8).

“Ọpọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn.” Ìpè yii wa fun gbogbo eniyan. A paṣẹ fun awọn ọmọ ọdọ nì lati lọ si òpópó ọnà lati pe gbogbo ẹni ti wọn ba ri, ati buburu ati rere, lati wá si ibi àsè igbeyawo. Gbogbo awọn ti o jé̩ ìpè naa ni a wọ ni aṣọ iyawo. Kikuna lati gba ohun ti Ọlọrun ti pesè silè̩ fun wa ni o n mu ẹkún ati ipayinkeke wa nikẹyin. Ọrọ Ọlọrun ṣe ìkìlọ ewu ti o rọ dè̩dè̩ lori awọn ti o ṣe ainaani igbala nlá yii. A yàn ọ nigbà ti iwọ ba jé̩ ìpè Kristi lati wá si ibi àsè iyawo. Iwọ ti jé̩ ìpe yii bi?

“Ohun gbogbo ṣe tan,’ wa sib’ase!

Wa, ’tori a ti té̩ tabili;

Ẹyin t’ebi n pa, t’aarẹ mu, ẹ wá,

Ẹ ó si jẹ ajẹyó.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ase igbeyawo wo ni owe yii duro fun?
  2. Awọn wo ni iranṣẹ ti a kọ ran jade?
  3. Ta ni o rán ipe yii jade? Njẹ awọn rere nikan ni a pè?
  4. Bawo ni awọn eniyan ṣe jé̩ ipe yii?
  5. Nigbà ti ọba naa wọle wá, ipo wo ni ó bá ọkunrin kan?
  6. Iru aṣọ igbeyawo wo ni ọba pese silẹ?
  7. Nitori ki ni a ṣe yàn awọn diẹ?