Rutu 1:8, 14-22.

Lesson 199 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi si ní awọn agutan miran, ti ki iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan” (Johannu 10:16).
Cross References

I Ipadabọ Naomi

1. Naomi rò lati pada wa si ilẹ Israẹli nigbà ti o gbọ pé Oluwa ti bẹ awọn eniyan Rè̩ wò lẹẹkan si i, Rutu 1:6; Orin Dafidi 111:5; Johannu 6:31-35; 1 Timoteu 6:8

2. Iyawo ọmọ Naomi mejeeji pinnu lati bá iya ọkọ wọn lọ, Rutu 1:7

3. Naomi dán ifẹ ọkàn awọn aya ọmọ rè̩ wò lati mọ ipinnu wọn nipa lilọ si ilẹ ajeji Rutu 1:8

II Iduroṣinṣin Ọkàn

1. Orpa fi ẹnu ko iya ọkọ rè̩ lẹnu o si pada si ilẹ Moabu, Rutu 1:14; Ẹksodu 18:27; Matteu 19:22; 2 Timoteu 4:10

2. Rutu rọ mọ Naomi bi o tilẹ jẹ pe Naomi rọ ọ ki o le pada, Rutu 1:15; Deuteronomi 4:4; Owe 18:24; Johannu 6:66-69

3. Idahun Rutu fi ifẹ otitọ ti ko lẹgbẹ ti o ni si Naomi ati si Ọlọrun rè̩ hàn, Rutu 1:16, 17; 2 Awọn Ọba 2:2-6; Iṣe Awọn Apọsteli 21:12-14

4. Nigbà ti Naomi ri i pe Rutu ti pinnu tán lọkàn rè̩ lati lọ, o dẹkun ọrọ iba a sọ, Rutu 1:18

III A Fi Ayọ Gbà Wọn ni Bẹtlẹhẹmu

1. Gbogbo ara ilu ni ẹnu yà nigbà ti awọn ero naa de, Rutu 1:19; Matteu 21:10, 11

2. Naomi royin gbogbo ohun ti o de bá a ni ilẹ Moabu, Rutu 1:20, 21; Orin Dafidi 119:67; Heberu 12:9-11

3. Naomi ati Rutu dé si Bẹtlẹhẹmu ni ibẹẹrẹ ikore ọka-barli, Rutu 1:22

Notes
ALAYÉ

“Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun ki iṣe ojusaju enia: ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bè̩ru rè̩, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:34, 35). Ọrọ wọnyi ni Peteru sọ fun ara ile Kọrneliu, ti iṣe Keferi; bẹẹ gẹgẹ ni a tun le sọ nipa Rutu, ara Moabu, ni iwọn ẹgbẹrun (1000) ọdun o le diẹ sẹyin, ki Peteru to sọ ọrọ yii. Ọlọrun ri ebi fun ohun ti ẹmi ni ookan aya Rutu ni ilẹ Moabu, ti o jinna rere si awọn eniyan Ọlọrun; ṣugbọn ọna kan ṣi silẹ nipasẹ eyi ti o le gbọ nipa Ọlọrun Israẹli, ki a si fi “onjẹ otitọ lati ọrun wá” (Johannu 6:32) bọ ọkàn rè̩. Nigbà ti Rutu gbọ nipa ọna lati sin Ọlọrun alaaye, o fi tọkàn tọkàn gba a o si kọ ọna ara rè̩ ati awọn eniyan rè̩ silẹ lati tẹle Ọlọrun otitọ. Nipa bayii, Rutu di apẹẹrẹ Iyawo Kristi lati inu iran Keferi.

Pipada si Ilẹ Israẹli

Ẹbí Elimeleki ṣí kuro ni ilẹ Israẹli nitori iyàn nlá ti o mu ni ilẹ naa. Wọn si wá si ilẹ Moabu lati ṣe atipo; ṣugbọn niwọn ọdun diẹ, Naomi, ẹni ti i ṣe iyawo Elimeleki ri i pe a fi oun nikan silẹ. Gẹrẹ lẹyin ikú ọkọ rè̩, awọn ọmọ Naomi mejeeji fé̩ awọn ọmọbinrin Moabu, ṣugbọn awọn ọmọkunrin wọnyii kò wà laaye fun ọjọ pupọ lẹyin ikú baba wọn. Ilu ti ẹbí Elimeleki ti rò pe yoo jé̩ ibi aabo fun wọn wá pada di iboji fun wọn lojiji.

Ni tootọ, Naomi ni itanṣan imọlẹ ninu ẹbí Elimeleki. Bi o tilẹ wà ni ilẹ ajeji sibẹ igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun duro ṣinṣin. Lai si aniani, o ti sọ agba-yanu ìtàn awọn Ọmọ Israẹli fun awọn aya ọmọ rè̩ ati iṣẹ iyanu ribiribi ti Ọlọrun ti ṣe nitori awọn eniyan Rè̩. A fi ipe Ẹmi Ọlọrun lọ ọkàn awọn obinrin mejeeji wọnyii; nigbà ti Naomi si pinnu lati pada si ilẹ rè̩, o dabi ẹni pe awọn obinrin yii ni ifẹ ati itara si ilẹ Israẹli ati lati sin Ọlọrun Israẹli ni idahun si ipe wọn.

Ni jijẹ ipe Ọlọrun si ọkàn rè̩, Rutu jẹ ọkan ninu awọn Keferi ti o kọkọ wá sọdọ Ọlọrun. Lonii, a paṣẹ fun gbogbo awọn ikọ Kristi lati lọ si gbogbo aye lati waasu Ihinrere ati lati jẹri si otitọ Ọrọ mimọ Ọlọrun. Kò si orilẹ-ède tabi è̩yà ti a tanu kuro lọdọ Ọlọrun; gbogbo eniyan le wá sọdọ Rè̩ nitori Jesu “ti wó ogiri ìkélé nì ti mbẹ lārin” ti o wà laaarin Ju ati Keferi (Efesu 2:11-22). Gbogbo eniyan alaaye, nibi gbogbo, ni a pè lati di Iyawo Kristi; ṣugbọn o ṣe ni laanu pe ki i ṣe ọpọ eniyan ni o ka ipe iyanu yii sí. A gba Rutu là nitori o fẹ lati kọ ohun gbogbo silẹ lati jere Kristi.

Ọnà Èrò Mimọ

Bi awọn obinrin wọnyii ti n lọ si ilu Naomi, Naomi bẹrẹ si ronu lori abayọrisi ipinnu awọn aya ọmọ rè̩. Ará ilẹ Moabu ni wọn; njé̩ awọn ara ilu rè̩ yoo fi tayọtayọ gbà wọn? Naomi kò ni ohun ti yoo fi bọ wọn; njẹ kò ni rọrun fun wọn lati ri ounjẹ ati aabo ni ilẹ wọn ati laaarin awọn eniyan wọn? Naomi fi ọrọ yii siwaju awọn aya ọmọ rè̩ lẹsọlẹsọ, o si rọ wọn lati pada si ilẹ wọn. Awọn mejeeji tún wi fun Naomi pe wọn yoo ba a lọ si ilẹ Israẹli, ṣugbọn Naomi tún tọka si awọn nnkan miiran yatọ si eyi ti o ti sọ fun wọn tẹlẹ. Orpa, iyawo Kiloni, pinnu lati pada si ilẹ rè̩ ati sọdọ awọn eniyan rè̩ nitori ilẹ Israẹli kò ni gbogbo nnkan ti o ti lero lati ri. S̩ugbọn Rutu ni ọkàn miiran, kò sí ohun ti o le mú ki o pada. Kò si wahala, irora tabi oofa ohun ayé ìgbà isisiyii ti o le fa iyawo Kristi lati pada sẹyin.

Ọkàn meloo ni o ti bẹrẹ ire ije ti igbagbọ ti o si ti fi itara iṣiwaju rin jinna lọna ilu Ọrun. Gẹgẹ bi irawọ ti n já ṣooro-ṣo ni oru dudu, wọn a sare tete, wọn a tan imọlẹ rokoṣo, wọn a si fi imọlẹ nlá si ipa ọna wọn; ṣugbọn lai pẹ jọjọ, wọn a paré̩. Irawọ ti n já ṣooro-ṣo yii ki i pẹ jo danu, awọn eniyan ti o ba si gbẹkẹle agbara ara wọn lai ṣe agbara ati ipá Ọlọrun yoo ri i lai pẹ pe “wọn ti jo tán” – lai si agbara tabi ifẹ lati tẹ siwaju si ọnà Ihinrere.

Bi Naomi ti tọka si awọn ohun iṣoro ti awọn aya ọmọ rè̩ le ba pade ni ilẹ Israẹli, bakan naa ni Jesu fẹ ki gbogbo awọn ọmọ ẹyin Rè̩ ro awọn nnkan wọnni ti wọn yoo ba pade ni ọna iwa mimọ kinnikinni, ki wọn si mura tẹlẹ lati pade awọn nnkan naa. Ogun agbọtẹlẹ ki i pa arọ.

Ikú tabi Iyè

Awọn ọrọ ti o dá Orpa pada sọdọ awọn eniyan rè̩ ati oriṣa rè̩ jẹ agbara fun Rutu lati ṣe ipinnu lati lọ si ilẹ Israẹli, ati lati sin Ọlọrun otitọ, nipa Ẹni ti o ti kọ nipa ọrọ ati iṣe iya ọkọ rè̩. Awọn ọrọ ti o jẹ “ikú si ikú” fun Orpa, jẹ “iyè si inu iyè” fun Rutu, ẹni ti kò jẹ ki ohun ayé yii ṣọwọn fun oun; ṣugbọn ti o fi tayọtayọ kọ gbogbo rè̩ silẹ lati jere ifẹ Ọlọrun Israẹli. O ni anfaani ọpọlọpọ ni aye yii ati ni opin ayé rè̩, o tun ri iyè ainipẹkun ni Ebute rere nì. Iran tootọ ti Ilu Mimọ nì ati èrè ti i ṣe ti Iyawo Kristi mú ki o rọrun fun Onigbagbọ lati wi pẹlu Paulu pe, ohun ayé isisiyii jẹ “alailera ati alagbe”.

Orpa kò kuna ninu ifẹ ati ìrònú fun iya ọkọ rè̩. O gbé ohùn rè̩ sókè o si sọkún bi èrò ati fi iya ọkọ rè̩ silẹ ti wọ inu rè̩: o si fi ẹnu ko iya ọkọ rè̩ lẹnu pẹlu ifẹ; sibẹ eyi kò mú ki o ka Ihinrere otitọ yii sí ju awọn ọnà ẹtàn awọn ara Moabu, ibatan rè̩, ati awọn ọré̩ rè̩ ati oriṣa ilẹ rè̩ lọ. Gbogbo èrò rè̩ ko tayọ ohun igbà isisiyii, kò ro ìgbè̩yìn wò rárá.

“Nitori ero ti ara ikú; ṣugbọn ero ti Ẹmi ni iye ati alafia” (Romu 8:6). Iyawo Kristi ni lati ni inu Kristi (1 Kọrinti 2:16; 1 Peteru 4:1). Jesu kò ni irẹpọ pẹlu ayé, O si n pe Iyawo Rè̩ lati ya ara rè̩ kuro ninu ayé. Kíkọ ẹgbé̩ ayé, adùn ati itara fun ohun ayé le ṣoro loju awọn ẹlomiran, nitori eṣu ti fọ wọn loju pẹlu ẹtàn ati imulẹmofo rè̩. Eṣu kò le fun ni ni ohun ti o daju; ikú ni èrè è̩ṣè̩.

Jijẹwọ Otitọ

Ijẹwọ ifẹ ati otitọ Rutu si Naomi ati Ọlọrun rè̩ ti dara to! O ṣe e ṣe ki o jẹ pe iwa rere Naomi ni o rú ifẹ iṣaaju yii soke ninu Rutu, ṣugbọn nigbẹyin Rutu paapaa di alabapin ninu ododo Ọlọrun ti Naomi n sin. Ifẹ si Ọlọrun naa ga to bẹẹ gẹẹ ti ọkàn rè̩ fi korira lati pada si Moabu ati sọdọ awọn oriṣa rè̩ bi o tilẹ jẹ pe Naomi fi eyi lọ ọ. Lẹsẹkẹsẹ ni Rutu bori idanwo yii, bi a ba tilẹ pe e ni idanwo. O dana sun afara ikẹyin tí ó lè mu un pada si ilẹ rè̩, nipa bayii o sọ ọgbun ti o ya a nipa kuro ninu ifẹ ati irẹpọ atijọ di gbigbooro. Oun kò lérò lati pada si ọnà rè̩ atijọ mọ, o tilẹ korira ki a tún fi lọ ọ. Ipinnu lile Rutu dabi igbà ti a fi ikere ti ilẹkun mọ olè sode.

Rutu, ti i ṣe apẹẹrẹ Iyawo Kristi lati inú ìran Keferi feti si itọni Ẹmi Ọlọrun. “Nitori iye awọn ti a nṣe amọna fun lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun” (Romu 8:14). Iyawo Kristi lonii n feti si gbogbo ohun ti Ẹmi Ọlọrun n ba wọn sọ, wọn si n gbe aṣọ ọgbọ wiwẹ ti o funfun gboo nì wọ, “nitoripe aṣọ ọgbọ wíwẹ nì ni iṣe ododo awọn enia mimọ” (Ifihan 19:8).

Ọkàn fun Ọlọrun

Nigbà ti Naomi ri i pe Rutu ti “pinnu rè̩ tán” lati lọ, nigbà naa ni o dẹkun ọrọ i ba a sọ. Boya irú ipinnu yii ni Naomi n wá lati ibẹrẹ, ṣugbọn o n fé̩ ki Rutu ṣiro ohun ti yoo gbà á, ki o si fi ifẹ inú ara rè̩ wa a. Naomi mọ pe iṣé̩ iranṣẹ Israẹli ni lati waasu majẹmu wọn pẹlu Ọlọrun fun awọn orilẹ-ède ti o yi wọn ká ati lati jèrè ọkàn nipa mimú wọn wá si orilẹ-ède ati ogun awọn Ọmọ Israẹli. Ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ki awọn idile Israẹli ki o tú kaakiri laaarin awọn Keferi gẹgẹ bi Elimeleki ti ṣe; ṣugbọn ifẹ Ọlọrun ni pe ki awọn Ọmọ Israẹli ni irẹpọ didùn pẹlu Ọlọrun wọn to bẹẹ ti yoo fa awọn eniyan ayé iyoku si ilẹ Israẹli ati si majẹmu kan naa pẹlu Ọlọrun, irú eyi ti awọn Ọmọ Israẹli n jẹ igbádùn rè̩. Jijere Rutu, Keferi, jé̩ ohun ti o tọnà, o si fi ifẹ Ọlọrun hàn lati gba “ẹnikẹni” ti o ba tọ Ọ wa lati igbà nì.

Jijere ọkàn fun Ihinrere kò i ti yi pada kuro lọnà ti Ọlọrun là fun Israẹli. Ki i ṣe ifẹ Rè̩ fun Onigbagbọ lati dara pọ mọ ayé ki o ba le gba diẹ là; O fẹ ki awọn eniyan ti Rè̩ ki o ya ara wọn kuro ninu ayé ki wọn si maa gbé igbesi ayé ti o jé̩ apẹẹrẹ to bẹẹ ti gbogbo awọn ẹni ti o wà ni ayika wọn yoo fi mọ pe Olugbala kan wà lọrun, Ẹni ti n fi agbara fun ni lati gbé igbesi-ayé Onigbagbọ.

Ọkàn ti o Jí Giri

Tifẹ-tifẹ ni awọn Ọmọ Israẹli fi gba Rutu si ẹbí Juda. Rutu di iyawo Boasi, o si wà ninu ìran Jesu Kristi Oluwa wa (Matteu 1:5). O sa gbogbo ipá rè̩ lati jé̩ ipe Ọlọrun ti a fi siwaju rè̩. Ẹmi Ọlọrun wọ inú ọkàn Rutu, o si fun un lagbara lati so èso igbesi ayé aṣẹgun, eyi ti o ṣe danindanin ni igbesi ayé Iyawo Kristi, eyi ti i ṣe: “ifẹ, ayọ, alafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ, ìwa tutù, ikora-ẹni-nijanu” (Galatia 5:22, 23).

Iyipada yii kò dé si Rutu nipa ori-ba-n-de. A sọ Rutu jí si anfaani ati sin Ọlọrun Israẹli, o si pinnu, bi o tilẹ jé̩ pé a rọ ọ lati ṣe yatọ, o tẹlé irawọ ti o n tọ ọ sọnà si orisun Imọlẹ. A le sọ nipa Rutu ati Keferi miiran tí ó jé̩ ipe lati di iyawo Kristi pé, “Nitori bi a ti ke iwọ kuro lara igi oróro igbé̩ nipa ẹda, ti a si lọ iwọ sinu igi oróro rere lodi si ti ẹda” (Romu 11:24). Igi oróro rere ni Jesu Kristi Oluwa wa. “Kristi ni i ṣe ori ijọ enia rè̩: on si ni Olugbala ara … Bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rè̩ fun u; ki on ki o le sọ ọ di mimọ lẹhin ti a ti fi ọrọ wẹ ẹ mọ ninu agbada omi. Ki on le mu u wá sọdọ ara rè̩ bi ijọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ ati alaini àbuku” (Efesu 5:23, 25-27).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti ẹbí Elimeleki fi lọ si ilẹ Moabu?
  2. Sọ gbogbo nnkan ti o ṣẹlẹ si ẹbí yii ni ilẹ Moabu.
  3. Nigbà wo ni Naomi pinnu lati pada si ilẹ Israẹli?
  4. Ta ni fé̩ bá Naomi lọ si ilẹ Israẹli?
  5. Njé̩ Naomi gbà wọn niyanju tabi o dayà fò wọn lati bá a lọ?
  6. Ki ni èsì Rutu si ọrọ Naomi?
  7. Irú iyẹsi wo ni Naomi ati Rutu rí gbà ni Bẹtlẹhẹmu?
  8. Nitori ki ni Rutu ṣe jé̩ apẹẹrẹ rere ti Iyawo Kristi lati inú ìran Keferi?
  9. Awọn eniyan wo ni a n pè lonii lati jé̩ Iyawo Kristi?