1 Samuẹli 2:1-10; 3:1-21.

Lesson 200 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI:“Nitori ti o fẹ ifẹ rè̩ si mi, nitorina li emi o ṣe gbà a: emi o gbé e leke, nitori ti o mọ orukọ mi” (Orin Dafidi 91:14).
Cross References

I Orin Ọpẹ

1. Adura Hanna jé̩ orin iyin ati ọpẹ si Ọlọrun, 1 Samuẹli 2:1-5; 1:6, 20; Orin Dafidi 113:9; Isaiah 54:1

2. Adura Hanna jé̩ asọtẹlẹ nipa ti aanu Ọlọrun ti o n bọ wá sori ayé, 1 Samuẹli 2:6-9; Orin Dafidi 75:4-7; 113:7, 8; Luku 1:52

3. Hanna sọtẹlẹ nipa bibọ Olugbala kan, 1 Samuẹli 2:10; Orin Dafidi 89:19-29; Luku 1:46-55, 67-75

II Ipè Ọlọrun

1. Kò si ifarahàn Ọlọrun ni ọjọ Eli alufaa, 1 Samuẹli 3:1; Amosi 8:11; Esekiẹli 7:26; Owe 29:18

2. Ojú Eli ṣookun to bẹẹ ti kò fi ri i pe iná Ọlọrun n kú lọ, 1 Samuẹli 3:2, 3; 4:15; Ẹksodu 27:20, 21; Lefitiku 24:2, 3; 2 Kronika 13:11

3. Gbigba è̩ṣè̩ layè mú ki ojú ẹmi Eli ṣe baibai lọpọlọpọ, 1 Samuẹli 3:2, 13; 2:12-17, 27-36; 1 Awọn Ọba 1:6; Lefitiku 10:1-3; Ẹksodu 19:22

4. Eli kò kọkọ mọ pé Oluwa n pe Samuẹli, 1 Samuẹli 3:4-9; Matteu 6:22, 23; 15:14; Jeremiah 5:21-24; Romu 2:1-4, 17-24

5. Nitori Samuẹli jé̩ ọdọ ati alailoye nipa ohun ti ẹmi, kò mọ pé Ọlọrun n pe oun, 1 Samuẹli 3:7; Iṣe Awọn Apọsteli 18:24-26; 19:23; Johannu 20:14; 21:4-7

6. Eli mọ nikẹyin pé, Ọlọrun ni O n pe Samuẹli, o si kọ ọ bí yoo ti fesi fun Ọlọrun, 1 Samuẹli 3:8-10; Orin Dafidi 85:8; Isaiah 6:8; Daniẹli 10:19; Iṣe Awọn Apọsteli 9:5, 6

III Wolii Ọlọrun

1. Ọlọrun sọ fun Samuẹli nipa idajọ ti yoo wá sori Eli ati ilé rè̩, 1 Samuẹli 3:11-14; Isaiah 29:13-16; Amosi 3:1-8; Habakkuku 1:5

2. Eli rọ Samuẹli lati jiṣẹ Ọlọrun fun oun, 1 Samuẹli 3:16; Orin Dafidi 141:5; Daniẹli 4:19

3. Ọlọrun wà pẹlu Samuẹli, Oluwa si fara hàn an lẹẹkan si i ní S̩ilo, 1 Samuẹli 3:19-21; 4:1; 9:6; Isaiah 44:26.

Notes
ALAYÉ

Orin Iyin

Ìtàn adura Hanna ati ifararubọ rè̩ si Ọlọrun pé ki O fun oun ní ọmọ jé̩ eyi ti o dara ti o si mú ni lọkàn. A fun Hanna ni ọmọkunrin kan ni idáhùn si adura rè̩ - ọmọ ti a ti yàn tẹlè̩ lati jé̩ ọkàn ninu awọn wolii giga ati ẹni ti igbesi ayé rè̩ yoo jé̩ è̩kọ ati iwuri fun gbogbo eniyan. Adura ọpẹ ati iyin rè̩ si Ọlọrun ti dùn tó lati jé̩ olubori irú ìtàn bayii! Lati yin Ọlọrun pẹlu orin ati adura fi ọkàn imoore hàn, ọkàn ti o kún fun ọpẹ nitori aanu ati ifẹ Ọlọrun.

Hanna kò fi ọwọ yẹpẹrẹ mú è̩bùn iyebiye ti o ri gbà lọwọ Ọlọrun. Bakan naa ni kò ṣalai di mimọ fun un pe kò ṣe e ṣe fun un lati bimọ rara, ayafi bi Ọlọrun ba fun un ni ifẹ ọkan rè̩; nitori “awọn ọmọ ni ini Oluwa” (Orin Dafidi 127:3). Sibẹ Hanna kò fi àkókáyà ọmọ rè̩ dipo ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rè̩. Kàkà ki o ṣe bẹẹ, ifẹ ati imoore rè̩ si Oluwa tubọ jinlẹ sii nitori iṣeun ifẹ nlá ati aanu Ọlọrun ni igbesi ayé rè̩. Hanna ni ìrírí ti o daju pé “Gbogbo è̩bun rere ati gbogbo è̩bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida” (Jakọbu 1:17).

Nigbà pupọ ni Ọlọrun ṣe pataki fun awọn ẹlomiran nigbà ti wọn bá wà ninu wahala nlá tabi ibanujẹ tabi nigbà ti gbogbo nnkan ba ṣọwọ òdì si wọn. S̩ugbọn nigbà ti ipọnjú bá dopin, tabi ti wọn bá ri idahùn si è̩bè̩ wọn gbà lati ọdọ Ọlọrun, wọn a gbagbe Ọlọrun, wọn a si fi I si ipo ti o kere jù lọ ninu ifẹ wọn. Eyi kò ri bẹẹ pẹlu Hanna nitori o bú si orin ninu adura ọpẹ ati iyin si Ọlọrun lati inú ọkàn rè̩ wá.

Orin iyin rè̩ bè̩rè̩ pẹlu ọpẹ si Ọlọrun fun iṣeun ifẹ rè̩ si i. Orin yii si n ga siwaju to bẹẹ tí ó tàn dé ọdọ Jesu Kristi, Ẹni Ami Ororo Ọlọrun, ati Ọba wa ti n bọ wá.

Nipa ìmísí Ẹmi Mimọ, Hanna sọrọ nipa Jesu Kristi nipasẹ Ẹni ti a o ti bukun fun gbogbo orilẹ-ède agbayé; o sọ asọtẹlẹ nipa awọn ẹlẹṣè̩ ti a o gbé ga si ipò ọlá nipa aanu kan naa ti a ti fi hàn fun un. A o gbé talaka soke lati joko laaarin awọn ọmọ alade lati jogun ìté̩ ogo, ṣugbọn awọn ọtá Oluwa ni a o fọ tuutu, nigbà ti Jesu bá dé lati jọba gbogbo agbayé. Eyi ni orin iyin Hanna, ti i ṣe asọtẹlẹ ti o dara nipa Jesu Kristi Ẹni ti yoo jọba ni alaafia ati idajọ.

Ọpọlọpọ ibomiran ni o wà ninu Bibeli ti ìmísí wọn fara jọ eyi, ti wọn si tọka si Jesu Kristi. Orin Mose sọ nipa Kristi gẹgẹ bi “Apata”, gẹgẹ bẹẹ ni orin Hanna (1 Samuẹli 2:2). (Wo Deuteronomi 32:15, 18). Bakan naa ni Ẹmi Mimọ sọ lati ẹnu Maria, Iya Jesu, nipa lilo apejuwe kan naa gẹgẹ bi ti Hanna, pe, a o rẹ awọn agberaga silẹ, a o si gbé awọn talaka soke – eyi yoo ṣẹ nipa Ọmọ ti a o bi ni ọnà iyanu. (Wo Luku 1:52).

Alakẹbajẹ Obi

Gẹgẹ bi ileri ti Hanna ṣe fun Oluwa, ọmọ naa Samuẹli bẹrẹ iṣé̩ isin rè̩ si Ọlọrun ninu Agọ, labẹ akoso Eli, ti i ṣe olori alufaa. Ojuṣe olori alufaa ni lati maa boju to idagbasoke awọn eniyan Ọlọrun nipa ti ẹmi, ati lati ṣe akoso isin Ọlọrun bi o ti tọ. S̩ugbọn Eli kunà lọpọlọpọ lati ṣe ojuṣe rè̩!

Majẹmu Titun fi ipò ti awọn biṣọpu ni lati wà lelẹ: “Ẹniti o kawọ ile ara rè̩ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rè̩ tẹriba pẹlu iwa àgba gbogbo; (ṣugbọn bi enia kò ba mọ bi ā ti ṣe ikawọ ile ara rè̩, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?)” (1 Timoteu 3:4, 5).

“Awọn ọmọ Eli si jẹ ọmọ Beliali; nwọn kò mọ Oluwa” (1 Samuẹli 2:12). Wọn jé̩ ẹlẹṣè̩ gidigidi ati nitori ìwà ibajẹ wọn “enia korira ẹbọ Oluwa” (1 Samuẹli 2:17).

Eli, baba alakẹbajẹ, ṣe ikilọ fun awọn ọmọ rè̩ nigbà kan nipa è̩ṣè̩ iwa-ibajẹ ti wọn n dá, kò si ṣe ohunkohun ju bayii lọ. Aijẹ wọn niyà ju pe ki o fi ẹnu lasan ba wọn wí ni o jé̩ è̩ṣẹ si ọkàn ara rè̩ ati si ọkàn awọn ọmọ rè̩. Ọpọlọpọ ibi ti o wọ ayé nipa awọn obi ti kò bikita nipa awọn ọmọ wọn ti wọn si kọ lati jẹ wọn niya kò ṣe e diwọn rara. Gbigba è̩ṣẹ layè jé̩ iná ti yoo jó gbogbo egungun eniyan, yoo si dari gbogbo awọn ti n dẹṣẹ sinu adagun iná ainipẹkun.

Bí è̩ṣè̩ Eli ti pọ tó ni gbigba iwa ìkà awọn ọmọ rè̩ layè ninu ile ara rè̩, ó ṣe ibi ti o buru ju eyi lọpọlọpọ nitori ti o gba awọn ọmọ rè̩ layè lati mú abuku bá ile Ọlọrun. Iranṣẹ ni awọn ọmọ naa jé̩ ninu iṣẹ isin Agọ, ati ninu iṣẹ yii wọn di ohun ikọsẹ si gbogbo awọn ẹni ti o n fé̩ lati sin Ọlọrun.

Isin Ọlọrun beere ọwọ mimọ. A si n reti ohun ti o pọ lọwọ awọn ẹni ti n ṣiṣẹ iranṣẹ. Iyẹra kuro ninu è̩ṣè̩ ati ìwà aimọ jé̩ ohun pataki kan ti o mú Ihinrere Jesu Kristi ta gbogbo ẹsin ati igbekalẹ ọgbọn orí eniyan yọ. Sibẹ, Eli ẹni ti i ṣe alakoso ati alabojuto ọran igbagbọ, kò naani ohun ti i ṣe ti Ọlọrun nipa iwa mimọ to bẹẹ ti kò fi mura giri lati fi opin si è̩ṣè̩ didá ninu ile ara rè̩ tabi ile Ọlọrun.

Idajọ Ọlọrun

A kò gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mú ọrọ Ọlọrun, ṣugbọn Eli ṣe afojudi si iwa mimọ Ọlọrun; ojú Ọlọrun si kan si i. (Wo Deuteronomi 29:19, 20). “Egbé ni fun awọn oluṣọ agutan Israẹli ti mbọ ara wọn” (Esekieli 34:2) ni ọrọ Oluwa si Esekieli. Awọn ọrọ yii ba Eli mu rẹgi. Kò ni pẹ ti a o mu Eli kuro; a o si pa ìran rè̩ run. Idile rè̩ ki yoo ni ipa ninu iṣẹ iṣẹ isin Ọlọrun mọ. Eyi ni è̩san fun Eli ni gbigba è̩ṣè̩ layè.

È̩ṣè̩ Eli fọ ọ lojú to bẹẹ ti kò fi le ri ohunkohun lọnà ti o tọ gan an. O jé̩ ọkan ninu awọn ẹni ti Jesu sọ nipa rè̩ pe wọn le ri ẹrun igi ti o wà lojú awọn arakunrin wọn, ṣugbọn wọn kò le ri iti igi ti o wà loju awọn tikara wọn (Luku 6:39-42). È̩ṣè̩ Eli pọ to bẹẹ ti o fi n sun iya Samuẹli lẹsùn imutipara ninu ile Ọlọrun nigbà ti o ṣe pe n ṣe ni obinrin yii n fi tè̩dùntè̩dùn gbadura si Ọlọrun. Pẹlupẹlu awọn ọmọ Eli n ba isin Ọlọrun jẹ nipa aile ko iwa buburu wọn ni ijanu.

Imọlẹ Baibai

Ojú Eli ti bẹrẹ si ṣe baibai to bẹẹ ti kò fi mọ pe itanna Ọlọrun ti fé̩ kú nitori aisi itọjú. Atupa ile Ọlorun ti o n kú lọ yii jé̩ apẹẹrẹ isin Ọlọrun. O duro fun Ọrọ Ọlọrun, ti Ẹmi Mimọ n tan imọlẹ si. O si ti bẹrẹ si i kú nisisiyii. Iwe Mimọ sọ nipa akoko yii ninu ìtàn orilẹ-ède Israẹli pe “Ọrọ Oluwa si ṣọwọn lọjọ wọnni; ifihàn kò pọ” (1 Samuẹli 3:1). Itumọ eyi ni pe otitọ Ọrọ Ọlọrun ti kuro ninu ọkàn awọn eniyan, wọn kò si fayè gba Ọlọrun lati fi ara hàn fun awọn eniyan nitori è̩ṣè̩ wọn. Ni wakati yii gan an ni Ọlọrun ba Samuẹli sọrọ laaarin òru.

“Ibukún ni fun ẹniti o gbọ temi, ti o nṣọ ẹnu-ọna mi lojojumọ, ti o si nduro ti opó ẹnu-ilẹkun mi” (Owe 8:34). Iṣẹ Samuẹli ni eyi ninu Agọ. Ojoojumọ ni Samuẹli n sin Ọlọrun ninu ile Rè̩ pẹlu ọkàn ti o ṣipaya ati etí tité̩ si ohun ti i ṣe ti Ẹmi. Nigbà ti Ọlọrun ba a sọrọ ni ọganjọ òru, Samuẹli dahun lẹsẹkẹsẹ.

Nitori ti kò mọ pe Ọlọrun ni o n ba oun sọrọ, Samuẹli tọ Eli lọ. O dabi ẹni pe Eli kò mọ ohùn Ọlọrun mọ nitori o rán Samuẹli pada ki o lọ sùn. Nigbà mẹta ni Ọlọrun pe Samuẹli, nigbà mẹta naa ni Eli rán an pada ki o lọ dubulẹ. Nigbà kẹta ni Eli to mọ pe Ọlọrun ni o n pe Samuẹli, o si wi fun un pe, ki o dahùn ti o ba tún pe, nitori Oluwa ni. Ọlọrun tún pe Samuẹli, o si da A lohun pẹlu awọn ọrọ iyebiye wọnni pe, “Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ.” Bayii ni Ọlọrun pe Samuẹli si iṣẹ isin ati ikọ fun Ọlọrun. Ọmọde kekere ni, ṣugbọn o ni etí lati gbọ ati ọkàn lati ṣe ohun ti Oluwa palaṣẹ.

Iṣẹ Iriju Tootọ

“Pẹlupẹlu a mbere lọwọ iriju pe ki oluwarè̩ na ki o jẹ olõtọ” (1 Kọrinti 4:2). Jé̩ ki gbogbo awọn ti o n di arugbo ninu iṣé̩ ati isin Ọlọrun ki o fi itara di ipa ati ojuṣe wọn mú ninu rè̩. Nitori ara wa ti di arugbo kò fi hàn pe iṣé̩ wa si Ọlọrun kò tún bá ìgbà mu, kò si wulò mọ. Ọrọ Ọlọrun wi pe, “S̩ugbọn ipa-ọna awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan” (Owe 4:18). Ati pẹlu, “Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọna ododo” (Owe 16:31).

Igbagbọ pipé ati igbẹkẹle ninu Ọlọrun ti a ti fi ọpọlọpọ ọdún kò jọ nipa ijolootọ ninu iṣé̩ isin Ọlọrun jé̩ ayọrisi rere ti o yẹ ki olukuluku ọdọmọde le fé̩ ki wọn si làkàkà lati ni.

Ifihàn

Jé̩ ki gbogbo awọn ọdọmọde ki o kẹkọọ lara Samuẹli. Yoo ti dara tó bí gbogbo wọn ba le jé̩ ipe Ọlọrun lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bi Samuẹli ti jẹ ẹ, pẹlu ifararubọ bakan naa ati itara ninu idahun wọn! O jé̩ ẹni ti Ọlọrun lò lọpọlọpọ, Ọrọ Ọlọrun si sọ nipa rè̩ pé, “Gbogbo Israẹli lati Dani titi o fi de Beerṣeba mọ pe a ti fi Samuẹli kalẹ ni woli fun Oluwa.” Oluwa “kò si jẹ ki ọkan ninu ọrọ rè̩ wọnni bọ silẹ” (1 Samuẹli 3:19, 20).

Igbesi ayé Samuẹli wulò, o si ni ni èrè lọnà gbogbo. O jé̩ igbesi ayé ti o dara nitori o gbọran si Ọlọrun lẹnu lati ìgbà èwe rè̩, o si n ṣe akiyesi ohun gbogbo ti o n gbọ. Dajudaju otitọ ni Ọrọ Ọlọrun ti o wi pe, “Ọmọ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ. Nitori ọjọ gigùn ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ. Máṣe jẹ ki ānu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walā aiya rẹ: Bẹni iwọ o ri ojurere, ati ọna rere loju Ọlọrun ati enia” (Owe 3:1-4).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Hanna fi gbadura?
  2. Ọnà wo ni o fi sọrọ nipa Jesu Kristi?
  3. Ki ni itumọ ọrọ yii “ifihan kò pọ”?
  4. Ki ni ṣe ti Oluwa fi kọ Eli?
  5. Apẹẹrẹ ki ni atupa Ọlọrun jé̩?
  6. Nitori ki ni o fi yẹ ki eniyan jẹ oloootọ iriju?
  7. Ki ni anfaani sisin Ọlọrun lati ìgbà èwe?