Lesson 201 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Oluwa mbẹ ninu tẹmpili rè̩ mimọ; jẹ ki gbogbo aiye pa rọrọ niwaju rè̩” (Habakkuku 2:20).Cross References
I Idajọ lori Israẹli
1. Awọn Filistini pa ẹgbaaji (4000) ọkunrin nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli gbiyanju lati mu ajaga ẹrú kuro, 1 Samuẹli 4:1, 2; Joṣua 7:4, 5; Orin Dafidi 44:9, 10
2. Awọn àgbà Israẹli beere ìdí rè̩ ti a fi bori wọn, 1 Samuẹli 4:3; Joṣua 7:6-12
3. A gbé Apoti Majẹmu Ọlọrun wá si ibudo, 1 Samuẹli 4:4, 5
4. Awọn Filstini kó ogun wọn jọ, wọn si tún bori Israẹli, 1 Samuẹli 4:6-10
II Adanu Nlá Nlà tí ó Jé̩ ti Israẹli
1. Wọn gba Apoti Majẹmu Ọlọrun, wọn si pa awọn ọmọ Eli, 1 Samuẹli 4:11; Orin Dafidi 78:59-64
2. A mú iroyin buburu naa wá si S̩ilo, 1 Samuẹli 4:12, 13
3. Nigbà ti Eli gbọ pe wọn ti gba Apoti Majẹmu Ọlọrun, o ṣubu kuro lori ijoko rè̩, o si kú, 1 Samuẹli 4:14-18
III Aabo Ọlọrun lori Apoti-Ẹri naa ati Imupadabọ Rè̩
1. Oriṣa awọn Filistini ṣubu niwaju Apoti-Ẹri, 1 Samuẹli 5:1-5; Isaiah 19:1
2. Lẹyin ipọnju nlá oṣu meje, awọn Filistini pinnu lati dá Apoti-Ẹri pada si Israẹli, 1 Samuẹli 6:1-3
3. Awọn Filistini ṣe ohun kan lati mọ bi lati ọwọ Ọlọrun ni ipọnju naa ti de ba wọn, 1 Samuẹli 6:7-12
4. Awọn eniyan Israẹli fi tayọtayọ gba Apoti-Ẹri naa, 1 Samuẹli 6:13-15
5. Awọn ọkunrin Bẹtṣemesi wo inú Apoti-Ẹri naa, Oluwa si pa wọn run, 1 Samuẹli 6:19, 20; 2 Samuẹli 6:6, 7
Notes
ALAYÉIsinrú ati Eredi Rè̩
“Ọrọ Samuẹli si wá si gbogbo Israẹli.” Lai si aniani ọrọ yii jé̩ iṣipaya lati ọdọ Ọlọrun si Samuẹli, pe a o dá ile Eli lẹjọ nitori è̩ṣè̩ ati aiṣedeedee wà ninu rè̩ (1 Samuẹli 3:11-14). Hofni ati Finehasi, awọn ọmọ Eli, ti n ṣe iṣẹ alufaa ni ipo baba wọn, kò mọ Oluwa, wọn si sọ ara wọn di ẹni irira. Oluwa si wi pe Oun o gbe alufaa miiran dide (1 Samuẹli 2:35), ohun gbogbo si ṣẹlẹ lati mu iyipada yii ṣẹ kánkán.
Awọn Ọmọ Israẹli ti wà labẹ isinrú awọn Filistini fun ọjọ pipẹ. Lai si aniani ajaga isinrú naa wọ wọn lọrun nitori awọn Filistini paapaa gbà pe ijọba wọn lori awọn Ọmọ Israẹli jé̩ eyi ti o nira (1 Samuẹli 4:9). Nitori eyi, ogun awọn Ọmọ Israẹli gbiyanju lati le awọn Filistini kuro ni ilẹ wọn. Wọn tẹgun pẹlu ireti giga ṣugbọn lai pẹ awọn Ọmọ Israẹli sá niwaju awọn ọtá wọn. Wọn si fi iwọn ẹgbaaji (4000) ọkunrin silẹ ni papa ni okú. Ni ibudo awọn Ọmọ Israẹli ibeere yii si jade pe, “Nitori kini Oluwa ṣe le wa loni niwaju awọn Filistini?” Idi rè̩ ni pe: Oluwa ti fi awọn Ọmọ Israẹli silẹ nitori ti wọn ti dẹṣè̩ si I.
Ọnà Òdì
Awọn àgbà Israẹli daba ọnà ti wọn yoo gbà yọ kuro ninu iṣubu wọn, o si dabi ẹni pe awọn eniyan fọwọ si imọran wọn. “Ẹ jẹ ki a mu apoti majẹmu Oluwa ti mbẹ ni S̩ilo sọdọ wa, pe, nigbati o ba de arin wa, ki o le gba wa kuro lọwọ awọn ọta wa.” Awọn eniyan mọ pe Oluwa kò jà fun wọn ati pe O ti fi àyè silẹ fun ọtà lati bori wọn. Sibẹ, wọn kò wa ojú rere Ọlọrun ni ọnà è̩tọ. O dabi ẹni pe, awọn àgbà Israẹli rò pe bi wọn ba le ni àmì Ọlọrun pẹlu wọn, dajudaju ojú Ọlọrun yoo wà pẹlu wọn; nigbà ti o jé̩ pé è̩ṣè̩ awọn alufaa ati ti awọn eniyan ti mú ki Ọlọrun ki o fà sẹyin kuro lọdọ wọn patapata. Nigbà ti Ọlọrun gbọ aiṣododo wọn, “o binu, o si korira Israẹli gidigidi. Bḝli o kọ agọ S̩ilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia” (Orin Dafidi 78:59, 60).
È̩ṣè̩ ni ohun kan ṣoṣo ti o lè mú ki Ọlọrun ki o yi ojú Rè̩ pada kuro lara awọn eniyan Rè̩. Bi a ba dẹṣè̩, ọnà kan ṣoṣo ti a le fi ri ojú rere Ọlọrun ni lati ronupiwada è̩ṣè̩ naa ki a si yipada sọdọ Ọlọrun ki a si wa aanu Rè̩. Eyi yii ni o yẹ ki awọn Ọmọ Israẹli ṣe nigbà ti awọn ọtá wọn bori wọn. Apẹẹrẹ wà ti wọn le tẹle nipa ohun ti Joṣua ṣe nigbà ti a ṣẹgun awọn Israẹli ni Ai. O dojú bolẹ niwaju Ọlọrun ni irẹlẹ ọkàn titi o fi ri ìdí ohun ti o fa iyọnu naa. Ni gẹrẹ ti wọn mú ohun iyasọtọ ati è̩ṣè̩ kuro ninu agọ, Ọlọrun fi iṣẹgun fun awọn eniyan Rè̩. Aanu Ọlọrun duro laelae lori awọn tí ó bá tọ Ọ wá pẹlu irobinujẹ ati ironupiwada, ṣugbọn Oun yoo dá awọn tí ó bá takú sinú è̩ṣè̩ wọn lẹjọ.
Agbara Kò Si ninu Àmì
Diẹ ni awọn Ọmọ Israẹli fi sàn ju awọn Keferi ti o yi wọn ká ni akoko yii. Wọn rò pe wọn le fi awọn ohun mimọ Ọlọrun tu Ọlọrun lojú lati dide fun iranlọwọ wọn gẹgẹ bi awọn Keferi ti n pe ọfọ ati ògèdè lati ké si awọn irunmọlẹ lati ràn wọn lọwọ. Gbigbe Apoti Majẹmu Ọlọrun wá sinu ibùdó nikan ki i ṣe è̩rí pe Oluwa yoo gbojú fo è̩ṣẹ awọn eniyan dá, ki O si ba Apoti-Ẹri wá. Ẹnikẹni ti o ba n lo awọn ohun mimọ Ọlọrun ati ti Ihinrere ni ilokulo n di è̩bi ti o pọ lọpọlọpọ ru ara rè̩.
A n pe ayé ti a wá lonii ni ayé ọlaju, ṣugbọn ogunlọgọ eniyan wà ti kò ti i bọ lọwọ ẹmi è̩tàn èké bawọnni. Ogunlọgọ eniyan ni o n fi Bibeli ṣe ajisa orire ninu ile wọn lọjọ òní. Wọn rò pe bi wọn ba le gbé Ọrọ Ọlọrun si tosi, wọn yoo lé ibi sẹyìn. Kò já mọ nnkan fun wọn, wọn i baa gbe Bibeli wọn si ilẹẹlẹ tabi ki ekuru bo o. Awọn miiran rò pe nipa wíwá si ile Ọlọrun lẹẹkan tabi lẹẹmeji lọdún, wọn yoo le tu Ọlọrun Ọrun lojú. Wọn a si lo iyoku ìgbà tí ó wà ninu ọdún gẹgẹ bi ọkàn buburu wọn ba ṣe dari wọn. Awọn miran si n lọ si ile Ọlọrun lati mú ki iṣẹ wọn fẹsẹ mulẹ ati ki iduro wọn paapaa le fẹsẹ mulẹ lọdọ awọn eniyan. Ọlọrun ki i fi ojú rere wo irú awọn ẹlẹsin bawọnni O n fé̩ awọn eniyan ti yoo sin Oun ni ẹmi ati otitọ.
È̩tọ ati Àìtọ
Nigbà ti wọn gbé Apoti Majẹmu Oluwa de ibùdó, gbogbo ogun Israẹli si hó gee, to bẹẹ ti ilẹ mi. Híhó yii lè jé̩ ti ojo tí ó fé̩ fi ọdájú apapandodo lé ìbè̩rù lọ; o yatọ si igbe iṣẹgun ti awọn ọmọ-ogun tí igbagbọ ati igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun kò yè̩. Eyi ki i ṣe ìgbà kin-in-ni ti wọn maa n gbé Apoti Majẹmu Oluwa lọ si ogun, ṣugbọn ki i ṣe lọnà ti awọn Ọmọ Israẹli n gbiyanju lati lo o ni akoko yii. Laaarin ogun Jẹriko, Apoti yii kan naa ni o ṣiwaju awọn ogun Israẹli nigbà ti wọn yi awọn ògiri ìlú naa ká ni ọjọ mẹfa; ati ni ọjọ keje oun naa ni o wà niwaju wọn nigbà ti wọn yi i ká ni ìgbà meje. Kò si sí híhó ninu ogun naa titi di ọjọ ikẹyìn ati ìyípo ìgbà ikẹyìn. Ati pẹlu, wọn ti fi tọwọtọwọ ṣe itọju Apoti-Ẹri naa fun iṣé̩ ti yoo ṣe; wọn si ti fi gbogbo aṣọ Agọ we e pọ to bẹẹ ti ẹni kan kò le ri ara rè̩. Olori alufaa nikan ni o ni è̩tọ lati wọ ibi ti Apoti Majẹmu mimọ wa, lẹẹkan lọdún – eyi si ni Ọjọ Etutu; ṣugbọn nihin gbogbo awọn ọmọ-ogun Israẹli ni o duro ti wọn n boju wo o. Eyi ti wọn i ba fi maa sọkun fun iyipada si buburu ni wọn fi n hó iho ayọ.
Duro S̩inṣin
Ẹni ti o ba fi ọwọ yẹpẹrẹ mú è̩bùn Ọlọrun yoo ri i pe lai pẹ a o gba a kuro lọwọ oun. Apoti-Ẹri Ọlọrun kò duro pé̩ pẹlu awọn ọmọ ogun Israẹli nitori wọn gbe e kuro ni àyè ti o yẹ ki o wà. Awọn Filistini gbọ igbe awọn Ọmọ Israẹli, wọn si kó ogun wọn jọ lati jà, wọn si ṣẹgun. Wọn gba Apoti-Ẹri Ọlọrun gẹgẹ bi ikogun, wọn si pa ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) eniyan laaarin awọn ọmọ ogun Israẹli. Hofni ati Finehasi, awọn ọmọ Eli, si kú gẹgẹ bi ọrọ ti wolii ti sọ. Awọn ọmọ ogun Israẹli fi itiju sá kuro ni ojú ogun, olukuluku n du ẹmi ara rè̩. Ọjọ ibanujẹ ni o jé̩ fun awọn eniyan ti wọn n pe ara wọn ni ọmọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn tikara wọn ni o jẹbi. Israẹli ti mọ ohun ti i ṣe èrè è̩ṣè̩ dajú. “Oluwa yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ wọn lọ li ọna kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọna meje” (Deuteronomi 28:25).
“Di eyiti iwọ ni mu ṣinṣin, ki ẹnikẹni ki o máṣe gbà ade rè̩” (Ifihan 3:11). Ireti Ọlọrun ati ifẹ Rè̩ ni pe ki gbogbo eniyan ki o lo gbogbo ohun wọnni ti a fi si akoso wọn ni ọnà è̩tọ, bi bẹẹ kọ Ọlọrun yoo gba a. Jesu fi apẹẹrẹ yii hàn nipa òwe ọmọ ọdọ ti o gba talẹnti kan, ti o lọ fi owó oluwa rè̩ pamọ sinu ilẹ. Iranṣẹ naa mọ ohun ti o tọ lati ṣe pẹlu owo nì, ṣugbọn o kọ lati sa ipá rè̩. Nigbà ti oluwa ọmọ ọdọ naa dé lati àjò ti o si ri i pe kò naani talẹnti oun, ti kò si lo o, o paṣẹ pe, “Ẹ gbà talẹnti na li ọwọ rè̩” (Matteu 25:28). Ki i ṣe talẹnti nikan ni o sọnu, ṣugbọn o sọ gbogbo èrè ati ẹmi rè̩ nù pẹlu.
Ọrọ Ọlọrun ni o wà ninu Apoti Majẹmu. Nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli lo Apoti-Ẹri ni ilokulo, wọn sọ ọ nù. Ninu gbogbo iwe ti a n tè̩ jade ni gbogbo ayé lonii, Bibeli ni o n tà jù, ṣugbọn ẹ wo bi awọn eniyan ṣe n lọ Ọrọ Ọlọrun lọrùn ti wọn si n lo o ni ilokulo. Awọn eniyan ni lati ṣọra, nitori Ọrọ Ọlọrun sọ pe ọjọ naa n bọ nigbà ti a o gba Ọrọ naa kuro ninu ayé. “Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa Ọlọrun wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, ki iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ ọrọ Oluwa: nwọn o si ma rin kiri lati okun de okun, ati lati ariwa ani titi de gabasi, nwọn o sare siwá sẹhin lati wá ọrọ Oluwa, nwọn ki yio si ri” (Amosi 8:11, 12).
Ìròyìn Àjálù
Ìròyìn ìṣubú awọn Ọmọ Israẹli kò pẹ ki o to de S̩ilo. Eli jokoo lẹba ọnà, o n reti lati gbọ ìròyìn ogun nitori ọkàn rè̩ kò balẹ nitori Apoti Ọlọrun. O dabi ẹni pe iranṣẹ naa mọọmọ fẹ yọ kọja alufaa arugbo naa ki o ma ba sọ ìròyìn ibanujẹ ti o wà fun un. Nigbà ti ọkunrin naa de ilu lati ròyìn iṣubu è̩sín naa, gbogbo ilu fi igbe ta. Eli gbọ igbe yii o si beere ìdí rè̩. Nigbà naa ni iranṣẹ naa wá sọdọ Eli kankan, o si sọ ohun ti o ṣẹlẹ ni ọjọ naa fun un. Kukuru ni ìròyìn naa, ṣugbọn ọrọ kọọkan n fi kún ibanujẹ ẹni ti o n gbọ ọ, ibi n gori ibi. Eli le fara da ìròyìn naa ati ti ikú awọn ọmọ rè̩ mejeeji, ṣugbọn nigbà ti o fẹnu kan ìròyìn igbè̩yìn pé, “Nwọn si gbà apoti Ọlọrun;” nigbà naa ni agbara rè̩ yè̩, o ṣubu sẹyìn lori apoti, nitori o di arugbo tán, o si tóbi, ọrun rè̩ ṣé̩, o si kú.
Ẹlẹri Ọlọrun
Ọlọrun kò i ti fi ara Rè̩ silẹ lai si ẹlẹri. Nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli kọ lati yin Ọlọrun nipa igbesi ayé ti wọn n gbé, Ọlọrun gba iyin ni ihà miiran. Awọn Filistini n fi Ọlọrun Israẹli pe ọkan ninu awọn oriṣa, ṣugbọn lai pẹ, wọn rii pe Oun ni Ọlọrun alagbara ni gbogbo àgbàyé. Wọn gbé Apoti Ọlọrun ti wọn gbà si ẹbá oriṣa Dagoni ni tẹmpili rè̩. Nigbà ti ilẹ mọ, awọn Filistini rii pe Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju Apoti Oluwa. Ni èrò pe eeṣì ni eyi ṣe, awọn Filistini tún gbé Dagoni duro si ipo rè̩; ṣugbọn nigbà ti wọn wadii ni ọjọ keji wọn rii pe Dagoni tún ṣubu lẹẹkeji. Nigbà yii, kukute rè̩ nikan ni o wà nilẹ; ati ọwọ ati ori rè̩ ti gé kuro.
Ọwọ Oluwa si wuwo si ara awọn Filistini. Ibikibi ti wọn ba gbé Apoti Ọlọrun lọ ni ajakalẹ arùn ti n ba wọn jà titi wọn yoo fi kigbe fun idande. Lẹyìn ijiyà oṣù meje ni awọn eniyan ranṣẹ si awọn alufaa ati awọn alasọtẹlẹ lati beere ohun ti wọn yoo ṣe lati rán Apoti Ọlọrun pada si ipò rè̩. Wọn damọran ọnà kan, wọn si gbidanwo lati wo boya lati ọwọ Oluwa ni ipọnju naa ti wá. “Nitorina ẹ ṣe kẹkẹ titun kan nisisiyi, ki ẹ si mu abo malu meji ti o nfi ọmu fun ọmọ, eyi ti kò ti igbà ajaga si ọrùn ri, ki ẹ si so o mọ kẹké̩ na, ki ẹnyin ki o si mu ọmọ wọn kuro lọdọ wọn wá ile. Ki ẹnyin ki o si gbe apoti Oluwa nì ka ori kẹké̩ na, ki ẹnyin ki o si fi ohun elo wura wọnni ti ẹnyin dá fun u nitori ẹbọ ọrẹ irekọja, ninu apoti kan li apakan rè̩; ki ẹnyin rán a, yio si lọ. Ki ẹ si kiyesi i, bi o ba lọ si ọna agbegbe tirè̩ si Betṣemeṣi, a jẹ pe on na li o ṣe wa ni buburu yi: ṣugbọn bi ko ṣe bḝ, nigbana li awa o to mọ pe, ki iṣe ọwọ rè̩ li o lù wa, ṣugbọn ẽṣi li o ṣe si wa” (1 Samuẹli 6:7-9).
Awọn abo maluu si lọ taara si ọnà Betṣemeṣi, wọn si n ké bi wọn ti n lọ ni ọnà; wọn kò si yà si ọtún tabi si osì. Bayii ni Ọlọrun Israẹli fi ara Rè̩ hàn fun awọn Filistini ni ọnà ti kò ni iyemeji ninu rara. Bakan naa ni Ọlọrun yoo fi ara Rè̩ hàn fun gbogbo eniyan bi wọn ba le fun Un ni àyè ni otitọ.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti a fi pa awọn Ọmọ Israẹli niwaju awọn Filistini?
- Njé̩ o yẹ ki wọn gbé Apoti Oluwa wá si ojú ogun?
- Ki ni ṣẹlẹ nigbà ti wọn jagun nigbà keji?
- Ki ni awọn Filistini ṣe pẹlu Apoti Oluwa?
- Ki ni yí awọn Filistini ni ọkàn pada lati rán Apoti-Ẹri naa pada si ilẹ Israẹli?
- Bawo ni wọn ṣe rán Apoti Ọlọrun naa pada?
- Ki ni awọn Filistini ṣe lati fi mọ boya Ọlọrun ni tabi Oun kọ ni o mú ijiya wá ba wọn?
- Njé̩ inú awọn Ọmọ Israẹli dùn lati gba Apoti-Ẹri wọn pada?
- Ki ni ṣe ti Oluwa fi rii pe o yẹ lati pa diẹ ninu awọn eniyan Betṣemeṣi?