1 Samuẹli 7:1-17

Lesson 202 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “S̩ugbọn ẹ bè̩ru Oluwa, ki ẹ si fi gbogbo ọkàn nyin sin i lododo: njẹ, ẹ ronu ohun nlanla ti o ṣe fun nyin” (1 Samuẹli 12:24).
Cross References

I Apoti Majẹmu Ọlọrun ni Kirjatjearimu

1. Awọn ọkunrin Betṣemeṣi ti i ṣe ilu awọn alufaa, ṣe alaiyẹ fun itọju Apoti naa, 1 Samuẹli 6:19-21

2. Oluwa ti kọ Agọ S̩ilo silẹ, Orin Dafidi 78:60; Jeremiah 7:14

3. Awọn ọkunrin Kirjatjearimu fi tọwọtọwọ té̩wọ gba Apoti naa, 1 Samuẹli 7:1

II Ipe si Ironupiwada

1. Awọn ara ile Israẹli sọkun tọ Oluwa lọ, 1 Samuẹli 7:2, 3; Jeremiah 3:21, 22; Sekariah 12:10, 11; Matteu 5:4

2. Awọn Ọmọ Israẹli mú oriṣa wọn kuro, 1 Samuẹli 7:4; Hosea 14:8; Matteu 4:10

3. Samuẹli bè̩bè̩ fun awọn eniyan naa, awọn naa si so èso ti o yẹ fun ironupiwada, 1 Samuẹli 7:5, 6; Jobu 16:20; Matteu 3:7-9

III Iṣudẹdẹ Ogun

1. Awọn Filistini gbọ ti ipejọpọ ni Mispe, wọn dojú ìjà kọ Israẹli, 1 Samuẹli 7:7; 2 Awọn Ọba 6:15-17

2. Awọn Ọmọ Israẹli rọ Samuẹli lati gbadura fun igbala, 1 Samuẹli 7:8; Isaiah 37:4; Jakọbu 5:16

3. Samuẹli ru ẹbọ sisun, o si ke pe Ọlọrun fun iranlọwọ, 1 Samuẹli 7:9; 10:8; 16:2; Orin Dafidi 50:15

IV Iṣẹgun ti o Logo

1. Oluwa daamu awọn Filistini, a si pa wọn niwaju Israẹli, 1 Samuẹli 7:10, 11; Sekariah 4:6; 1 Kọrinti 10:13

2. Samuẹli gbé okuta kan ró fun iranti iṣẹgun naa, 1 Samuẹli 7:12; Joṣua 4:20-24

3. A tẹri awọn Filistini ba ni gbogbo ọjọ Samuẹli gẹgẹ bi onidajọ Israẹli, 1 Samuẹli 7:13-17.

Notes
ALAYÉ

Bi o tilẹ jé̩ pe awọn ara Betṣemeṣi jé̩ alufaa, Oluwa lu wọn pa nitori wọn bẹ inu Apoti-Ẹri wò. Awọn eniyan ti kò kú bẹrẹsi tara pe ki a le gbe Apoti-Ẹri naa lọ si ibomiran. Nigbà ti wọn ba lo Apoti-Ẹri, eyi ti i ṣe apẹẹrẹ ifarahàn Ọlọrun laaarin awọn ọmọ Rè̩, ni ọnà è̩tọ, yoo jé̩ ibukun fun awọn Ọmọ Israẹli; ṣugbọn bi wọn kò ba bu ọlá fun Un ti wọn si lo O ni ilokulo, Ọlọrun kò ni jafara lati fi ọlá Rè̩ hàn.

Wọn Gba A Tọwọ Tẹsẹ ni Kirjatjearimu

Bi awọn ara Betṣemeṣi ti n yọ pe a gbe Apoti Ọlọrun kuro lọdọ wọn, ni awọn ara Kirjatjearimu n yọ bẹẹ gẹgẹ lati gba a sọdọ wọn. Awọn eniyan wọnyii ki i ṣe alufaa tabi ọmọ Lefi, gẹgẹ bi akọsilẹ ti fi hàn; sibẹ wọn fi tọwọtọwọ ṣe itọju Apoti-Ẹri naa, Ọlọrun si bu ọlá fun wọn nitori iṣe wọn. A gbé Apoti-Ẹri naa si ile Abinadabu, ẹni ti o ṣe e ṣe ki o jé̩ olufọkansin, ti ilẹ rè̩ si le jé̩ eyi ti o dara jù laaarin gbogbo ìlú. Awọn eniyan naa si ya Eleasari ọmọ rè̩ si mimọ lati maa tọjú Apoti-Ẹri Ọlọrun. O dabi ẹni pe ifẹ Ọlọrun ni lati gbà fun ọkunrin yii lati ṣe itọjú iṣura mimọ ti o ṣe iyebiye yii, bi o tilẹ jé̩ pe oun ki i ṣe ẹni pataki laaarin Israẹli. O sàn fun Ọlọrun lati lo ẹnikẹni ti o ya ayé rè̩ sọtọ fun isin Ọlọrun ju alufaa tabi Lefi ti o n dẹṣè̩ tabi ti o dara pọ mọ ayé.

Nigbà ti Jesu wà ni ayé, O ri i pe awọn ti n pe ara wọn ni alakoso isin ti wọn si n gboke gbodo ninu Tẹmpili, kò yẹ fun iṣẹ Ijọba Rè̩. Jesu pe awọn oṣiṣẹ Rè̩ ti o yẹ, awọn ọmọ-ẹyin ati awọn Apọsteli lati aarin awọn eniyan ti o rẹlẹ: “Ẹ sa wo ipè nyin, ará, bi o ti ṣepe ki iṣe ọpọ awọn ọlọgbọn enia nipa ti ara, ki iṣe ọpọ awọn alagbara, ki iṣe ọpọ awọn ọlọlá li a pè” (1 Kọrinti 1:26). Eyi jé̩ẹ otitọ lọna pataki yii pe, awọn ọlọgbọn, awọn alagbara ati awọn ọlọlá ki yoo rẹ ara wọn silẹ lati jé̩ ipe Kristi ati ti Ọrun.

Yíyípadà si Ọlọrun

Apoti-Ẹri Ọlọrun wà ni ile Abinadabu fun ogun (20) ọdún ki o to di pe awọn Ọmọ Israẹli ṣe nnkan kan nipa rè̩. Eyi fi hàn wa gẹgẹ bi è̩ṣè̩ ìgbà nì ti pọ to ati bi ibọriṣa ti gbilẹ to laaarin awọn eniyan. Bi o bá ṣe pe awọn eniyan n sin Ọlọrun gẹgẹ bi wọn ti ṣe ni lati sin In, ki yoo pẹ ti wọn yoo fi mọ pe Apoti-Ẹri Ọlọrun kò si lọdọ wọn. Ni Ọjọ Etutu, olori alufaa i ba ti wọ Ibi Mimọ Julọ nibi ti Ọlọrun n fé̩ ki a gbé Apoti naa si, ki o ba le ṣe etutu fun awọn eniyan. Fun odidi ogun ọdún, kò dajú pe Ọjọ Etutu wà. È̩ṣè̩ didá ti gbà wọn lọkàn to bẹẹ ti wọn kò bikita nipa Agọ tabi isin Ọlọrun.

A kò gbọ pupọ nipa wolii Samuẹli ni akoko yii, ṣugbọn a gbà pe o n ṣaapọn ni ibi iṣẹ ti Ọlọrun fi le e lọwọ lati maa yí awọn eniyan lọkàn pada si Ọlọrun otitọ. Iwaasu naa gba ogun ọdún ṣugbọn lojiji itara kan dide laaarin awọn eniyan. Ki i ṣe awọn eniyan diẹ, ṣugbọn gbogbo ile Israẹli bẹrẹsi pohun réré ẹkun si Oluwa. A le wi pe eyi jé̩ ọkan ninu awọn isọji ti o ga julọ lati ibẹrẹ ọjọ.

Nisisiyii Samuẹli jade kankan, o si wi fun awọn eniyan ohun ti o yẹ ki wọn ṣe bi wọn ba n fé̩ ki Ọlọrun Ọrun ki o tẹwọ gbà wọn. Wọn ni lati pa gbogbo ọlọrun ajeji ti awọn Keferi run, wọn si ni lati kọ wọn silẹ; ọkàn awọn eniyan si ni lati mura tán lati sin Oluwa nikan. Awọn eniyan si feti si ikilọ Samuẹli nitori wọn ṣe gẹgẹ bi Samuẹli ti palaṣẹ, wọn si sin Oluwa nikan ṣoṣo.

Israẹli ni Mispe

Nigbà ti Samuẹli ri i pe awọn eniyan naa n fé̩ pada si ọdọ Ọlọrun, o pe apejọ gbogbo awọn eniyan Israẹli si ọdọ ara rè̩ ni Mispe. Ipejọpọ awọn Onigbagbọ niye lori ju bi a ti le fẹnu sọ lọ. Awọn ti o mọọmọ yẹra kuro ninu idapọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun yoo sọ ohun gbogbo ribiribi nù. “Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere: ki a má mā kọ ipejọpọ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mā gbà ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile” (Heberu 10:24, 25). Èrè ikiya wà ninu apẹẹrẹ rere, agbara si wà ninu iṣọkan. Iṣoro pupọ ni o wà lọnà ẹni ti o ba fé̩ lati maa dá nikan rìn lọ si Ọrun, ṣugbọn ajumọrin awọn ẹgbẹ Onigbagbọ a maa jé̩ anfaani ti a kò le fẹnu sọ bi o ti niye lori tó.

Samuẹli jé̩ wolii Ọlọrun tootọ, ẹni ti o n kede ilana Ọlọrun. Ni akoko yii, Samuẹli wà ni ipo alagbawi bakan naa, nitori wọn ti kọ iṣẹ alufaa ati ilana irubọ silẹ fun ìgbà diẹ. Wolii naa si gbadura fun awọn eniyan; awọn eniyan naa mọ riri ipo è̩ṣè̩ ti wọn wà, wọn si ṣe ohun ti o tọ lati tún ọnà wọn ṣe. Wọn pọn omi, wọn si tu u silẹ niwaju Oluwa, wọn gbaawẹ ni ọjọ naa, wọn si wi pe, “Awa ti dẹṣẹ si Oluwa.” Alufaa Ọlọrun kan ti sọ ọnà ti a fi le ri igbala lọnà kukuru bayii pe, “Wá, képè É, si Jé̩wọ.” Ohun ti awọn Ọmọ Israẹli ṣe ni eyi. Ọlọrun gba è̩bè̩ awọn eniyan naa, gẹgẹ bi a ti le ri i nipa ohun ti o ṣẹlẹ lai pẹ.

Ironupiwada Tootọ

Pipọn omi ati titu u silẹ niwaju Oluwa fi hàn bi ironupiwada ati irẹ-ara-ẹni silẹ awọn Ọmọ Israẹli ti pọ tó. O lè jé̩ pe wọn gba ara wọn gẹgẹ bi “omi ti a tú silẹ ti a kò si le ṣajọ mọ” (2 Samuẹli 14:14) afi bi Oluwa bá lè ràn wọn lọwọ. Títú omi silẹ lè jé̩ apẹẹrẹ adura ti o n ti inú ọkàn wá ti wọn tú silẹ niwaju Ọlọrun wọn. Hanna fi itara gbadura lati inú ọkàn rè̩ wa si Oluwa; ètè rè̩ nikan ni o n mì, ṣugbọn a kò gbọ ohùn rè̩. Sibẹ ni ṣiṣe àlàyé fun Eli, o wi pe, ọkàn oun ni oun “ntú jade” niwaju Oluwa (1 Samuẹli 1:15).

È̩kọ yii jé̩ eyi ti o fi ironupiwada tootọ hàn. Igbesẹ kin-in-ni ti ẹlẹṣè̩ ni lati gbé ni pe ọkàn rè̩ ni lati jí giri si eyi pe oun n fẹ ohun kan ti o ju ohun ti oun ni lọ. “Gbogbo ile Israẹli si pohunrere ẹkun si OLUWA.” Igbesẹ keji ni ki ẹlẹṣẹ kọ ọnà rè̩ silẹ, ki o si pinnu lati sin Oluwa. “Awọn ọmọ Israẹli si mu Baalimu ati Aṣtarotu kuro, nwọn si sin OLUWA nikan.” Adura si Ọlọrun ati ijẹwọ è̩ṣè̩ ni o si maa n tẹle e. Samuẹli wi pe, “Emi o si bẹbẹ si OLUWA fun yin.” Awọn Ọmọ Israẹli si wi pe, “Awa ti dẹṣẹ si Oluwa.” Lai si aniani awọn eniyan yii ati Samuẹli jumọ dohùn pọ ni adura.

Idojukọ

Gẹrẹ ti eniyan ba ti yipada kuro ninu è̩ṣè̩ ti o si pinnu lati sin Ọlọrun ati lati lọ si Ọrun, eṣu yoo yọjú lati di i lọwọ ninu irin àjò rè̩. Eyi ṣẹlẹ si awọn Ọmọ Israẹli nigbà ti wọn pada si igbagbọ awọn baba wọn. Fun iwọn ogun ọdún awọn Filistini kò gbé ogun wá si ilẹ Israẹli, ṣugbọn gẹrẹ ti awọn eniyan kó ara wọn jọ si Mispe fun adura, eyi rú ọtá soke o si gbogun ti Israẹli.

Jé̩ ki ẹni ti o pinnu lati sin Ọlọrun mọ pé oun ni ọtá ti è̩mí lati bá jà. Eṣu a maa sun Onigbagbọ ni è̩sùn èké niwaju Ọlọrun: ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn awọn ọmọ Rè̩, iṣẹgun si dajú nipa È̩jè̩ Ọdọ-agutan. “Nitori a ti lé olufisùn awọn arakọnrin wa jade, ti o n fi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru. Nwọn si ṣẹgun rè̩ nitori è̩jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọrọ ẹrí wọn” (Ifihan 12:10, 11). Jesu ṣẹgun eṣu ati idanwo nipa lilo ọrọ Ọlọrun, awa naa si le ṣe bẹẹ gẹgẹ. “Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi OLUWA yio gbe ọpágun soke si i” (Isaiah 59:19).

Adura Gbà

Nisisiyii awọn Ọmọ Israẹli ti di alagbara ninu ẹmi, wọn si le doju kọ ọtá wọn lai bẹru. Bi o tilẹ jé̩ pé awọn Ọmọ Israẹli wá si Mispe lati gbadura, boya wọn tilẹ fi ohun ìjà wọn silẹ nile, sibẹ wọn le doju kọ ọtá wọn. Wọn le ba Ọlọrun sọrọ, kò si ohun ija kan ti o lagbara ju adura. Bi a ba gbadura ni ọnà è̩tọ yoo mi ọwọ agbara Ọlọrun. Awọn Ọmọ Israẹli gbadura, wọn si bẹ Samuẹli pe, “Máṣe dakẹ ati ma ke pe OLUWA Ọlọrun wa fun wa, yio si gbà wa lọwọ awọn Filistini.”

Samuẹli le ri i lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bi akoko naa ti ṣoro tó. O ṣe e ṣe ki o ri ibẹru ni ọkàn awọn eniyan naa, ṣugbọn o tún lè ri igbagbọ ati ifẹ awọn eniyan naa lati gbẹkẹle Ọlọrun ti wọn ṣẹṣẹ bá dá majẹmu. Samuẹli mọ pe o yẹ lati ṣe irubọ si Ọlọrun, nitori naa, o mu ọdọ-agutan kan o si fi ru ẹbọ sisun. Ọlọrun yé̩ irubọ naa sí. Ọlọrun a maa yé̩ ironubinujẹ ati ifọkantan Ọlọrun sí nibikibi ti O ba ti ri i.

Fifi ọdọ-agutan ru ẹbọ sisun ni o pari ironupiwada awọn eniyan naa. “Laisi itajẹsilẹ kò si idariji” (Heberu 9:22). “Nigbati emi ba ri è̩jẹ na, emi o ré nyin kọja” (Eksodu 12:13). Oluwa ri è̩jè̩ naa, O si tẹwọ gba adura awọn Ọmọ Israẹli ati ti Samuẹli. Oluwa sán aará nlá sori awọn Filistini, O si daamu wọn, O si pa wọn niwaju Israẹli. Oluwa fi iṣẹgun fun Israẹli lori awọn Filistini, wọn si le wọn jade nigbà naa to bẹẹ ti wọn kò le wá si ilẹ Israẹli ni gbogbo ọjọ Samuẹli.

“Ebeneseri”

Wọn si gbé ọwọn kan kalẹ bi ohun iranti iṣẹgun nlá ti Ọlọrun fi fun wọn. Ebeneseri, eyi ti i ṣe orukọ okuta iranti yii, ni itumọ ti o ṣe pataki: “Titi de ihin li Oluwa ràn wa lọwọ.” A kò gbé okuta yii kalẹ fun iyin eniyan, nitori iṣẹgun naa ko ti ipa eniyan wá. Orukọ kan ṣoṣo ni wọn gbé ga – eyi ni orukọ Ọlọrun Israẹli. Okuta iranlọwọ ni eyi. O kó gbogbo ibukun ti o ti kọja pọ ati ẹkún ati ibanujẹ ti o ti mú awọn Ọmọ Israẹli pada si ọdọ Ọlọrun ati ayọ on iṣẹgun ti wọn ṣẹṣẹ ní. O dabi ẹni pe o kún fun igbagbọ fun ọjọ iwajú. Pe Ọlọrun ràn wa lọwọ “titi de ihin” jé̩ è̩rí pe a le gbẹkẹle E siwaju si i fun iranlọwọ, bi a ba le gbagbọ, ti igbẹkẹle wa ninu Rè̩ kò si yè̩.

Igbekalẹ irú ọwọn yii lọkàn Onigbagbọ jé̩ ibukún nlá nlà. Iriri kọọkan lati ọdọ Ọlọrun wá jé̩ “okuta iranlọwọ.” A le gbé okuta ibùsọ kọọkan kalẹ bí a bá ti n ri ibukún gbà lati Ọrun; nigbà naa bi ìjì ipọnju tilẹ n jà, oluwa rè̩ le tọka si akoko ati okuta wọnni ki o si wi pe, “Titi de ihin li Oluwa ṣe iranwọ.” Awọn okuta iranlọwọ wọnyii kò gbọdọ ṣọwọn ni igbesi-ayé Onigbagbọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nitori ki ni a ṣe gbé Apoti-Ẹri Ọlọrun kuro ni Betṣemeṣi?
  2. Bawo ni o ti pẹ to ki awọn Ọmọ Israẹli tó pada sọdọ Ọlọrun?
  3. Ki ni è̩ri kin-in-ni ti a ri nipa ipadabọ wọn?
  4. Bawo ni Samuẹli ṣe gba awọn Ọmọ Israẹli ni iyanju ni akoko ironupiwada wọn?
  5. Njé̩ awọn Ọmọ Israẹli ṣe ohun ti Samuẹli palaṣẹ fun wọn?
  6. Ki ni ṣe ti awọn Filistini fi wá si ilẹ Israẹli ni akoko yii?
  7. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe nipa igbogunti yii?
  8. Ta ni ṣẹgun?
  9. Sọ itumọ “Ebeneseri”.