1 Samuẹli 8:1-22

Lesson 203 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ki ẹ má si da ara nyin pọ mọ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé” (Romu 12:2).
Cross References

I A Yí Idajọ Po

1. Ni ìgbà ogbó rè̩, Samuẹli yan awọn ọmọ rè̩ bi onidajọ lorí Israẹli, 1 Samuẹli 8:1, 2; 2 Kronika 19:5-7

2. Awọn ọmọ Samuẹli kò rìn ni ibẹru Oluwa, 1 Samuẹli 8:3; Deuteronomi 16:19; Isaiah 33:14-16; 1 Timoteu 6:10

3. Awọn àgbà Israẹli fi otitọ yii ṣe ìbòjú lati beere fun ọba kan, 1 Samuẹli 8:4, 5; Deuteronomi 17:14, 15; Iṣe Awọn Apọsteli 13:20, 21

II Adura Samuẹli ati Idahun Ọlọrun

1. Samuẹli kò ni èsì fun irú ibeere awọn àgbà Israẹli ti kò tọnà, nitori eyi ó wá imọran Ọlọrun, 1 Samuẹli 8:6; Ẹksodu 32:30-33; Esra 9:3-5; Luku 6:12

2. A da a lohun pe awọn eniyan naa ti kọ Ọlọrun silẹ, 1 Samuẹli 8:7, 8; Ẹksodu 16:8; Luku 10:16

3. A pàṣẹ fun Samuẹli lati fi ibeere Israẹli fun un, ṣugbọn ki o kilọ fun wọn nipa abayọri si rè̩, 1 Samuẹli 8:9; Esekiẹli 45:9; 46:18

III Iwa Ọba Ayé yii

1. Ọba Ọrun n fi aanu ṣe akoso; ṣugbọn ọba ayé yii n fi ọwọ lile ṣe akoso, 1 Samuẹli 8:10-18; 1 Awọn Ọba 9:22; 12:4, 12-14; 21:7, 15

2. Awọn eniyan naa kọ lati feti si Samuẹli, wọn n fé̩ ọba sibẹ, 1 Samuẹli 8:19, 20; Orin Dafidi 81:11, 12; Jeremiah 44:16; Esekiẹli 33:31

3. Oluwa gbà lati fi ibeere awọn eniyan naa fun wọn, 1 Samuẹli 8:21, 22; Hosea 13:9-11

Notes
ALAYÉ

Awọn Onidajọ

Bi ọjọ Samuẹli ti n kù fẹẹfẹẹ, o ni lati maa rò pé ta ni yoo jẹ onidajọ Israẹli lẹyin oun. Samuẹli mọ ìtàn awọn Ọmọ Israẹli pé nigbà pupọ ni ìrè̩wè̩sì nipa ti ẹmi maa n bá wọn nigbà ti oloootọ onidajọ ti o wà lori wọn bá kú. Nigbà pupọ ni awọn Ọmọ Israẹli n ṣubu sinu ibọriṣa titi ìyọnu ati ìsìnrú yoo fi dé bá wọn; nigbà naa ni wọn o ké pe Ọlọrun fun igbala, Ọlọrun a si gbé onidajọ titun ati olugbala dide fun wọn. Samuẹli kò si fé̩ ki eyi ki o ṣẹlẹ nigbà ti oun bá kú, nitori naa ni o ṣe yan awọn ọmọ rè̩ gẹgẹ bi onidajọ nigbà ti o wà laaye sibẹ.

Lai si aniani, Samuẹli ti kọ awọn ọmọ rè̩ gidigidi ni Ofin Ọlọrun, o si lero pe wọn yoo ṣe òdodo si awọn eniyan. Wọn kò ni ṣe alai ti gbọ ìtàn ìparun awọn ọmọ Eli lẹnu baba wọn, nitori wọn kunà lati rìn ni ọnà Oluwa. O dajú pe ọkàn Samuẹli balẹ pe awọn ọmọ rè̩ yoo ṣe ohun ti o tọ ti o si yẹ. A kò sọ fun ni bi akoko ti awọn ọmọ Samuẹli fi jẹ onidajọ ni Beerṣeba ti pé̩ tó; ṣugbọn kò pẹ ti o ti hàn gbangba pé wọn kò rin ninu ọnà baba, ẹni iwa-bi-Ọlọrun. Wọn ti yipada lati maa tọ èrèkérè lẹyin lati gba àbè̩té̩lè̩, wọn si n yí idajọ pò.

Ọba Kan

O dabi ẹni pe eyi ni awọn agbaagba Israẹli fi ké̩wọ lati ṣètò ayipada ninu ijọba ilu wọn. Wọn fi ohun meji siwaju Samuẹli lati yè̩ wo: pe o n di arugbo, awọn ọmọ rè̩ kò si rin ni ọnà rè̩. Wọn kò ri aleebu ninu igbesi-ayé Samuẹli. Iwa rè̩ dara lọpọlọpọ, o si jé̩ apẹẹrẹ tí inú Israẹli i ba dùn lati tẹle. Bi o tilẹ jẹ arúgbó, o ti dàgbà ninu iṣé̩ isin si Ọlọrun ati si eniyan; bí ọjọ ori rè̩ kò tilẹ fun un ni anfaani lati tún ṣe ibẹwo gbogbo ibi iṣé̩ isin rè̩ gẹgẹ bi oun ti n ṣe tẹlẹ, sibẹ ọjọ orí yii yoo fun ni ìrírí ati ọgbọn ti wọn kò le ri nibikibi ni gbogbo Israẹli. Samuẹli jé̩ ẹni ọgọta ọdún ni akoko yii - ọjọ orí yii kò ti i to eyi tí ó le di i lọwọ ki o ma le wúlò.

Awọn àgbà Israẹli wá pẹlu ibeere pé ki Samuẹli yan ọba fun wọn. Kò dajú pé è̩sùn ti wọn fi awọn ọmọ Samuẹli sùn pe wọn n gba àbè̩té̩lè̩, ti wọn si n yí idajọ po, jé̩ danindanin ni ọkàn wọn. Bi o bá jé̩ pé è̩sùn yii ni olori è̩dùn wọn, o daniloju pe Samuẹli yoo din àṣẹ awọn ọmọ rè̩ kù. Awọn agbaagba mu è̩sùn yii wá nitori ìdí kan – eyi nì ni lati beere fun ọba. Wolii arugbo nì, ti o ni idapọ pẹlu Ọlọrun Ọrun, ti ogunlọgọ awọn enia n bu ọlá fun ni Israẹli, kò té̩ awọn agbaagba eniyan lọrun mọ. Wọn n fé̩ ọba. Wọn kò darukọ ọba olododo ti yoo jọba lori wọn daradara ju awọn ọmọ Samuẹli lọ; ṣugbọn wọn wi pe, “Fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ède.” Ni ireti pé wọn n ṣe ayipada si rere, Israẹli gbé ohun rere sọnù, wọn si fi buburu dipo rè̩. Ni gbogbo ìgbà ni ọmọ eniyan yoo maa ṣe eyi, bí a bá fi wọn silẹ pẹlu èrò ọkàn wọn, tí wọn si n tẹle ọnà ara wọn. “OLUWA! emi mọ pe, ọna enia kò si ni ipa ara rè̩: kò si ni ipá enia ti nrin, lati tọ iṣisẹ rè̩” (Jeremiah 10:23). Yatọ si eyi, “A ṣe ilana ẹsẹ enia lati ọwọ Ọlọrun wá: o si ṣe inu didùn si ọnà rè̩” (Orin Dafidi 37:23).

Àṣìyàn

Samuẹli le ri ìṣìnà ninu ibeere awọn eniyan wọnyii bí ó tilè̩ jé̩ pé oun le ṣai ri bi ìṣìnà naa ti pọ tó kí ó tó tọ Ọlọrun lọ ninu adura. Ifẹ lati ni ọba fi hàn pe wọn fẹ ṣá akoso Ọlọrun lori wọn tì, labẹ eyi ti wọn ti wà rí. Samuẹli rò pe awọn eniyan wọnyii n kọ oun, pe idajọ oun ti sú wọn; ṣugbọn Oluwa fi hàn an pé Oun ni awọn eniyan naa kọ. Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli fi n ronú lati gba ara wọn kuro labẹ akoso Ọlọrun? Nitori wọn kò fé̩ gbà lati wà labẹ Ọba ti wọn kò ri, bí ó tilè̩ jé̩ pé O ti fi ara Rè̩ hàn nipa wọn nigbà pupọ, gẹgẹ bi alagbara. Awọn Ọmọ Israẹli n fé̩ lati fi ijọba ọba ayé, ẹni ti wọn le ri, dipo Ijọba Ọlọrun - paṣiparọ ti o buru ju lọ. Wọn n fé̩ ọba lati maa jade niwaju wọn, ki o maa jagun fun wọn. I ha ṣe pé wọn ti gbagbé ìgbà pupọ ti Oluwa ti jà fun wọn ati awọn baba wọn, ti o si jé̩ pé ohun ti wọn ni lati ṣe ni pé ki wọn “duro jẹ, ki nwọn si ri igbala OLUWA”?

Irú ìṣoro kan naa, lati maa gbé igbesi-ayé igbagbọ ati ifọkantan Ọlọrun lọjọọjọ, ni o n dojú kọ awọn Onigbagbọ lode oni. Ọpọlọpọ eniyan ni wọn maa n ni ifọkanbalẹ niwọn ìgbà ti wọn bá fi iṣura ayé yii yí ara wọn ká, ṣugbọn awọn ìlérí Ọlọrun ti o ṣọwọn ni kò níyì lojú wọn. Lati ni ọpọlọpọ owó ní ìpamọ ní ibi ifowopamọsi ayé yii, eyi tí o n wà fun ìgbà diẹ, kún wọn lojú ju ati ní ìwé owó tí ó ṣe pé igbagbọ nikan ni a fi n gba a. Wọn n ṣogo ninu ọgbọn ati ìjáfáfá wọn nigbà tí o yẹ ki ojú ki o tì wọn fun aini igbẹkẹle ninu Ọlọrun. “Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipara ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale. S̩ugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipara ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale” (Matteu 6:19, 20).

Ọpọ Eniyan tabi Diẹ

Ìdí miiran ti awọn Ọmọ Israẹli ṣe n fé̩ ki ọba ayé ki o jọba lori wọn ni pe ki wọn le rí bi awọn orilẹ-ède ti o yí wọn ká. Onidajọ ati wolii ti yoo maa kiri lati ilu dé ilu pẹlu aṣọ irẹlẹ kò ni iyì tó awọn ọba onigberaga orilẹ-ède ti o yí wọn ká ti o n wọ aṣọ igunwa alarabara; nitori naa, awọn Ọmọ Israẹli pinnu pé wọn kò le fara da a mọ lati nikan wà lai ni ọba. Nigbà miiran, o le jẹ ohun iṣoro fun awọn diẹ ti o di otitọ mú lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ wọn si Ọlọrun, nigbà ti ohun gbogbo n dán fun awọn ọpọ eniyan ti o wà ni ayika wọn ti ọnà wọn kò ṣe deede pẹlu Ọlọrun; ṣugbọn Onigbagbọ ni lati maa wo èrè ti o wà niwaju.

Iduro Onigbagbọ jé̩ eyi ti kò fara mọ ọnà ati awọn àṣà ayé yii. Ifẹ Kristi ti o wà ninu eniyan a maa mú ki èrò ati ifẹ ọkàn rè̩ yi pada to bẹẹ, ti oluwa rè̩ yoo fi yàtọ si ti atijọ patapata; nitori “o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun” (2 Kọrinti 5:17). Lati pa ara rè̩ mọ ninu ifẹ Ọlọrun, a pàṣẹ fun Onigbagbọ pé, “Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rè̩” (1 Johannu 2:15).

Ọpọlọpọ eniyan ni o n kọsẹ nipa ọràn yiya ara ẹni kuro ninu ayé. Yoo jé̩ ìdùnnú wọn lati gba Jesu sinu ọkàn wọn bi wọn bá lè maa bá ìwà wọle wọde wọn isisiyii lọ ki wọn si maa gba iyin awọn ọré̩ ayé, ṣugbọn wọn kò le fara da è̩gàn ati eebú ti awọn ẹlẹṣè̩ fi n yọ ṣuti si igbesi-ayé irẹlẹ awọn Onigbagbọ. Gẹgẹ bí awọn àgbà Israẹli, wọn fé̩ bá ayé dọgba. S̩ugbọn ranti, Ọlọrun kò ni inú didùn si ọnà ayé. O n wá awọn eniyan kan ti o n fé̩ lati ya ara wọn kuro ninu ayé.

Idahun Ọlọrun

Samuẹli kò ni èsì ti i ba fi fun awọn Ọmọ Israẹli nigbà ti wọn kọ wá fi ibeere wọn siwaju rè̩. Bi o bá jé̩ pe o dù wọn ni èsì wọn lai bá Ọlọrun sọrọ, awọn eniyan naa le sọ dajudaju pé, Samuẹli n lo ipò giga. Bi o ba si jé̩ pe o fi ibeere wọn fun wọn lai mọ inú Ọlọrun ni, Samuẹli i ba jẹ alaiṣootọ ati alajọpin ninu iṣé̩ wọn. Samuẹli mọ inu ìhámọ ti oun wà, nitori naa o tọ Ọlọrun lọ ninu adura lati ri ojutu iṣoro ti o wà niwaju rè̩. Kò pẹ ti èsì fi de. Àbá ti wọn n dá lati ni ọba ayé kò té̩ Ọlọrun lọrun, ṣugbọn O sọ fun Samuẹli pe ki o gbọ ohùn wọn, “ṣugbọn lẹhin igbati iwọ ba ti jẹri si wọn tan, nigbana ni ki iwọ ki o si fi iwà ọba ti yio jẹ lori wọn hàn wọn.”

Samuẹli si fi ìwà ọba ti yoo jẹ lori awọn Ọmọ Israẹli hàn wọn. Dipo Ọba Ọrun ti a kò ri Ẹni ti o n fi è̩bùn rere ati è̩bùn pípé fun ni, awọn eniyan naa n wá ọba ti yoo maa gba gbogbo è̩bùn lai fun wọn ni ohun kan. Samuẹli fi apẹẹrẹ awọn ọba buburu ti o n jẹ ni awọn ilu ila oorun ni ayika Palẹstini lakoko igbà naa hàn wọn. Awọn Ọmọ Israẹli ni lati maa reti ọba ti yoo fi awọn ọmọkunrin wọn ṣe oluṣọ ara rè̩, awọn ọmọ ogun ati oṣiṣẹ rè̩, wọn ni lati ni ireti pe ọba naa yoo mu awọn ọmọbinrin wọn lati ṣe alásè ati ẹni ti yoo maa din àkàrà fun itọju ọpọlọpọ awọn alejo rè̩. Ọba naa yoo gba ilẹ wọn ti o lọra julọ fun awọn iranṣẹ rè̩, yoo si gba idamẹwa èrè wọn fun ara rè̩. Ju eyi lọ, Oluwa wi pe nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli ba ri ìṣìnà ohun ti wọn yàn, ti wọn ba si ke pe Oun, Oun ki yoo gbọ igbe wọn. Pẹlu ìbáwí irú eyi lati ọdọ Ọlọrun, a rò pe o yẹ ki awọn Ọmọ Israẹli ki o wi lẹsẹkẹsẹ pe, “A ti yọwọ yọsẹ wa o.”

Bíbá Ọlọrun Jà

A ri apẹẹrẹ bí gbogbo eniyan ti ri nihin: wọn ni ifẹ ti o yàtọ si ifẹ Oluwa. Wọn takú sinu ifẹ ara wọn, pẹlu ojú lila silẹ si abayọrisi rè̩, titi Oluwa fi fohùn si ibeere wọn, ti O si fi ayé silẹ fun wọn lati ni ohun ti wọn n fé̩. Nitori Ọlọrun yọọda ohunkohun ki i ṣe idaniloju pé ifẹ Rè̩ ni. Ohun kan le lodi patapata si ifẹ Ọlọrun, ṣugbọn bi O bá ri eniyan kan tabi ju bẹẹ ti wọn bá fi ọkan si ohun naa, Oun yoo fi àyè silẹ fun wọn lati tẹ siwaju, gẹgẹ bi O ti ṣe ni ti Wolii Balaamu. Balaamu fi ọkàn si i lati gba èrè nì; Oluwa si fi àyè silẹ fun un nigbooṣe ki o lọ sọdọ ọba Moabu; ṣugbọn Balaamu kò gba èrè naa.

Bí eniyan bá n bá Ọlọrun du ohunkohun titi Ọlọrun fi fi àyè silẹ fun ohun naa, a ki gbadùn ohun naa nigbà ti a ba ri i gbà. “O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn” (Orin Dafidi 106:15). Ọlọrun fi ọba fun awọn Ọmọ Israẹli ṣugbọn ìran ti o beere fun un kò pé̩ layé lati jẹ igbadùn ọba naa. Saulu ni ọba kin-in-ni ni Israẹli, ti ijọba ogoji ọdún rè̩ kún fun aisinmi, ìjà, ariwo ati ogun. Ìgbà ti Dafidi jọba ni Israẹli tó gbadùn ọba wọn.

Ọlọrun Alaṣẹ

“Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ” (Orin Dafidi 76:10). Eyi jé̩ apẹẹrẹ bi Ọlọrun alaṣẹ ṣe n mú iṣé̩ eniyan, ti o tilẹ lodi si ifẹ Rè̩ lò gẹgẹ bi ohun èlò fun iṣé̩ Rè̩. Ọlọrun kò i ṣetán lati fi ọba ayé jẹ fun Israẹli ni akoko yii, sibẹ Ọlọrun mọ pé Dafidi yoo jẹ ọba ati ni ìran alade Dafidi, Jesu Kristi Oluwa wa yoo jẹ Olugbala arayé. Bí Israẹli bá ti duro de akoko Ọlọrun, wọn i ba ti ri ifẹ ọkàn wọn gbà lai fa ibinu Ọlọrun.

Eyi yii ni èrèdí rè̩ ti awọn ti o wà nigbà Jesu fi ranṣẹ si Ọmọ Ọlọrun pé, “Awa kò fé̩ ki ọkọnrin yi jọba lori wa” (Luku 19:14). Àtakò ti awọn Ju ati Romu ni si Jesu ni o rán Jesu lọ sori agbelebu; ṣugbọn lẹẹkan si i ibinu eniyan yin Ọlọrun, nitori ni ọjọ naa ni “isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalẹmu, fun è̩ṣẹ ati fun ìwa aimọ” (Sekariah 13:1). A kaanu pupọ fun awọn ti o n ṣiṣẹ Ọlọrun lọnà bayii! Wọn ṣègbé ninu è̩ṣè̩ wọn; ìṣe wọn si jẹ è̩ṣè̩ bí o tilè̩ jé̩ pé o wu Ọlọrun lati lo ìṣe wọn ni imuṣẹ ọrọ Rè̩. Yoo ti dara tó lati fi Ọlọrun si ipò kin-in-ni ninu ọkàn wa, ki iṣé̩ wa ki o le yin In logo.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Samuẹli fi awọn ọmọ rè̩ jẹ onidajọ ni Israẹli?
  2. Ki ni è̩sùn ti awọn Ọmọ Israẹli mú wá siwaju Samuẹli nipa awọn ọmọ rè̩?
  3. Sọ pupọ ninu awọn ìdí ti awọn àgbà Israẹli fi n wá ọba.
  4. Ki ni ìhà ti Samuẹli kọ si ibeere yii? Ki ni ihà ti Ọlọrun kọ si i?
  5. Ki ni Ọlọrun pàṣẹ fun Samuẹli lati ṣe?
  6. Njé̩ awọn Ọmọ Israẹli gba ohùn Ọlọrun gbọ nigbà ti Samuẹli mú ọrọ Rè̩ tọ wọn wá?
  7. Ki ni ṣe ti o fi lewu fun eniyan lati fi ara mọ ọnà ara rè̩ bi o tilẹ lodi si ifẹ Ọlọrun?
  8. Njé̩ awọn àgbà Israẹli gbadùn ọba wọn nigbà ti a fi i fun wọn?
  9. Ọba wo ni awọn Onigbagbọ n reti lati ri ni ọjọ kan lai pé̩?