Lesson 204 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ iyìn, o yìn mi logo: ati ẹniti o ba mu ọna ọrọ rè̩ tọ li emi o fi igbala Ọlọrun hàn fun” (Orin Dafidi 50:23).Cross References
I Ọlá Nlá Ọlọrun
1. Ọlọrun kari gbogbo ayé, Orin Dafidi 50:1
2. Ofin Rè̩ n jade lọ lati Sioni, Orin Dafidi 50:2
3. Ajonirun iná ni Ọlọrun, Orin Dafidi 50:3
4. A pe awọn eniyan mimọ ni Ọrun ati ni ayé lati jẹri si Israẹli, Orin Dafidi 50:4-7
II Ọlọrun Bá Israẹli Wíjọ
1. Ẹbọ òde ara nikan kò tó, Orin Dafidi 50:8-13
2. Ọpé̩, è̩jé̩ ati adura atinuwa jé̩ dídùn inú Ọlọrun, Orin Dafidi 50:14, 15
III Ìdájọ lori Ìwà Buburu
1. Ọlọrun kọ ìwà agabagebe, Orin Dafidi 50:16, 17
2. Awọn agabagebe jẹbi olè jíjà, panṣaga ati ọrọ ibanijẹ, Orin Dafidi 50:18-20
3. Aimu idájọ ṣẹ kankan kò fi hàn pé Ọlọrun fé̩ ìwà buburu, Orin Dafidi 50:21, 22
IV Ìfé̩ Ọlọrun
1. Ìyìn gbé ogo Ọlọrun ga, Orin Dafidi 50:23
2. Ọrọ tabi ìrìn wa ni lati jé̩ pípé, Orin Dafidi 50:23.
Notes
ALAYÉỌlá Nlá Ọlọrun
“Ọlọrun Olodumare, ani OLUWA, li o ti sọrọ.” Ọlọrun Israẹli kò dabi awọn oriṣa orilẹ-ède ti o yí wọn ká. Oun ni Ọlọrun agbayé, Ẹlẹda ohun gbogbo. “Tali o ti wọn omi ni kòto-ọwọ rè̩, ti o si ti fi ika wọn ọrun, ti o si ti kó erùpẹ aiye jọ sinu òṣuwọn, ti o si fi ìwọn wọn awọn oke-nla, ati awọn oke kékèké ninu òṣuwọn?” “Gbe oju nyin soke sibi giga, ki ẹ si wò, tali o dá nkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npè gbogbo wọn li orukọ nipa titobi ipá rè̩, nitoripe on le ni ipá; kò si ọkan ti o kù … Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ, pe, Ọlọrun aiyeraiye, OLUWA, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, kì iṣārè̩, bḝni ārè̩ ki imu u? kò si awari oye rè̩” (Isaiah 40:12, 26, 28).
Ọlọrun gbogbo ayé, Oun naa ni Ọlọrun kan naa ti O ti yan Israẹli ti O si fi Sioni ṣe olori ibùgbé Rè̩. “Lati Sioni wá, pipé ẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ.” Awọn Ọmọ Israẹli ni a fi oju rere hàn fun ju gbogbo eniyan agbayé lọ, lati ni Ọlọrun alagbara gẹgẹ bi Ọlọrun wọn. A fi titobi Rè̩ hàn laaarin wọn nigbà ti O fun wọn ni ofin lori oke Sinai. “Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israẹli” (Ẹksodu 24:17). “Oke Sinai si jé̩ kiki ẽfi, nitoriti OLUWA sọkalẹ sori rè̩ ninu iná: ẽfi na si goke bi ẽfi ileru, gbogbo oke na si mìtiti” (Ẹksodu 19:18).
O dara fun wa lati mọ pé a n sin Ọlọrun kan naa lonii. Ẹ jé̩ ki a ṣe àṣàrò nipa Rè̩ ki a si gbiyanju lati ri fìrí titobi Rè̩ ati agbara Rè̩. Èrò yii pé, Ẹni ti o fi ọrọ ẹnu Rè̩ dá ayé yoo feti si igbe wa yoo si dahùn è̩bè̩ wa, bi o ti wu ki o kéré tó, yẹ ki o mú wa kún fun ìrè̩lè̩ ati ifé̩ si I. O fi ìfé̩ nlá Rè̩ hàn ni ti pe O rán Ọmọ Rè̩ lati kú ki a le yọ wa kuro ninu ọnà è̩ṣè̩ wa. Njẹ a kò jẹ Ẹ ni igbese iyin ati idupẹ titi ayeraye?
Fífi Ẹbọ Dá Majẹmu
Onisaamu ṣe apejuwe bi Ọlọrun alagbara ti n pe awọn eniyan mimọ ni Ọrun ati ni ayé lati jẹri si idajọ òdodo Rè̩ lori Israẹli. “Kó awọn enia mimọ mi jọ pọ si ọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi da majẹmu.” Awọn eniyan mimọ Ọlọrun tootọ ni awọn ti o ti fi ẹbọ bá Ọlọrun dá majẹmu. Nigbà ti eniyan bá mọ riri iyè ainipẹkun, kò si iye ti o ga ju lati fi ra a. Ki ni ohun ti o ṣọwọn tó bẹẹ ti o le maa mú eniyan lọra, bi o bá jé̩ pé Ọlọrun n beere rè̩? Ọkẹ aimoye awọn ajẹriku ni kò ka ẹmí wọn si, ki wọn ba le jé̩ oloootọ si Kristi. È̩jè̩ wọn yoo ha jẹri gbe awọn ti o n kọ lati fi ara wọn fun Ọlorun ni ẹbọ aayè, mimọ, fun ìsìn Rè̩? Ọlọrun n fé̩ ki a le fi tifẹtifẹ kọ iya, baba, arabinrin tabi arakunrin, ki a sọ ẹmí wa paapaa nù, bi o bá gbà bẹẹ, ki awa ki o le jé̩ oloootọ ati olododo si Ẹni ti o pè wa. Jesu wi pé, “Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ mi lẹhin, ki o sẹ ara rè̩, ki o si gbé agbelebu rè̩, ki o si mā tọ mi lẹhin” (Matteu 16:24).
Ọkunrin kan tọ Jesu wá nigbà kan pẹlu awọn ọrọ wọnyii, “Oluwa, emi nfẹ lati mā tọ ọ lẹhin; ṣugbọn jẹki nkọ …” Jesu si dahùn pe, “Kò si ẹni, ti o fi ọwọ rè̩ le ohunelo itulẹ, ti o si wò ẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun” (Luku 9:62). Awọn miiran n fẹ sin Ọlọrun ti wọn bá lè kọ lọ ṣe awọn ohun wọnni ti ọkàn wọn n fé̩. Ọlọrun n pe gbogbo awọn ti o bá fé̩ sin In lati ba A fi ẹbọ dá majẹmu. Wọn ni lati pinnu lati fi awọn nnkan wọnni silẹ ti o ná wọn ni owó gẹgẹ bi Dafidi ìgbà nì ti ki yoo rú ẹbọ ti kò ni ná an ni owó si Oluwa.
È̩sùn tí A fi Kan Israẹli
Ọlọrun fi hàn gbangba fun Israẹli pe ki i ṣe pe Oun fé̩ ẹbọ wọn ni Oun ṣe n mú wọn wá si idajọ. “Bi ebi npa mi, Emi ki yio sọ fun ọ: nitori pe aiye ni ti emi, ati ẹkún inu rè̩.” Ọlọrun kò bá Israẹli wí nitori wọn kò sun ọrẹ ẹbọ sisun – eyi nì paapaa tó ohun tí ó lè mú ijiya wá. È̩sùn ti a fi wọn sùn ni pe wọn kò san è̩jé̩ wọn, wọn kò si ni ọkàn idupẹ si Ọlọrun.
Ẹbọ Wa si Ọlọrun
Lonii, Ọlọrun kò fé̩ awọn ohun ìní wa; Oun kò si fé̩ ọrọ wa; Oun kò fé̩ maluu wa tabi ohunkohun ti o jé̩ ohun ìní wa ti o n ṣegbe. S̩ugbọn awa ni a kò lè wà lai si Ọlọrun! Ọlọrun fun wa ni agbara lati kó awọn ohun alumọni ayé yii jọ; nitori naa lọdọ Rè̩ ni a ti ri gbogbo ohun ti a ni gbà, i baa ṣe ibukun ti Ẹmi tabi ti ara. Bí Oun bá n fẹ maluu, O le sọkalẹ ki O si mú wọn lati ẹgbẹrun òkè.
Iwọ ha wi pé, “Njẹ bi Ọlọrun kò ba fẹ ohun ìní mi, akoko mi, talẹnti mi, ki ni mo ha n fi fun Un si? Ki ni ṣe ti mo ni lati fi ara mi rubọ fun Un?” Ti Rè̩ ni ohun gbogbo i ṣe. Bi a bá ni talẹnti, agbara tabi ipá, lati ọdọ Ọlọrun ni gbogbo wọn ti wá. “Gbogbo è̩bun rere ati gbogbo è̩bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá” (Jakọbu 1:17). Iriju lasan ni a jé̩ lori gbogbo ìní ati è̩bùn ti Ọlọrun fi fun wa; kò ha yẹ ki a ni ọkàn imoore to bẹẹ ti a o fi dá awọn è̩bùn wọnni pada fun Un nipa lilo wọn fun iṣé̩ Rè̩? Dajudaju a kò fé̩ gbọ ibawi nì pe, “Ẹ gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode.”
Olukuluku wa ni yoo jihin fun Ọlọrun ni ọjọ kan nipa bi a ti lo awọn ohun wọnni ti Ọlọrun fi si itọju wa. Ihinrere n tè̩ siwaju lonii. Njé̩ iwọ jé̩ alabapin ninu iṣẹ naa? Njé̩ iwọ n ṣe iranlọwọ lati mú ẹrù naa fúyé̩ fun awọn ti o wà loju ogun? Njé̩ iwọ n fi awọn è̩bùn, talẹnti ati awọn ohun wọnni ti Ọlọrun fi fun ọ si arọwọto fun Ọlọrun lati lò? Bi o kò tilẹ ṣe bẹẹ, Ihinrere yoo maa tẹ siwaju; ṣugbọn boya ọkàn kan ti o wà lọwọ ọtún rẹ ati ekeji lọwọ òsì rẹ, ki yoo gbọ ihin igbala nitori iwọ kùnà lati sa ipá ti rẹ. Oṣiṣẹ ṣọwọn lonii ju ti atẹyinwa lọ; ikore oko pọn, Oluwa si n beere pe, “Tali emi o rán?” Njé̩ iwọ wà lara awọn ti o n wi pé, “Jẹ ki nkọ …?” (ṣe eyi tabi eyi nì). Iṣẹ Oluwa kò gbọdọ duro! O ni lati jé̩ ohun ekinni ninu igbesi-ayé rẹ. Ipè ikẹyin fun awọn alagbaṣe n kọja lọ. Jé̩ ipè naa lonii.
Olugbala
“Ki o si kepè mi li ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo.” Nigbà pupọ ni o ṣe pe aiṣedeedee eniyan ni o n fà á sinu iyọnu. Bi eyi ba ri bẹẹ, Ọlọrun ti ṣeleri pe bi a bá lè ké pe Oun ni ọjọ ìpọnjú, Oun yoo gbà wa. Ọkàn wa ni lati kún fun ọpé̩ si irú Ọlọrun bayii.
Afarawe Iwa-Bi-Ọlọrun
Fun awọn ti o ṣe pe ètò ìsìn lasan ni wọn kan n tẹle – ti wọn kan n fi ẹnu lasan sọ nipa majẹmu Ọlọrun ti wọn si n waasu ofin Rè̩ - Ọlọrun fi è̩ṣẹ ti wọn n dá hàn gedegbe. Wọn n bá olè dimọ pọ, boya wọn tilẹ n ra ọjà ti ó jí. Wọn jẹbi panṣaga, è̩ṣẹ ti awọn ẹlẹsin miiran tilẹ fara mọ lode oni. Nitori eyi ni wọn ṣe bé̩ Johannu Baptisti lori nitori o sọ gbangba fun Hẹrodu pe kò tọ fun un lati fé̩ iyawo arakunrin rè̩. Wọn si tún jẹbi sisọ ọrọ buburu ati èkè. Wọn n ṣaata arakunrin wọn. Gbogbo eyi ni wọn n ṣe, wọn lero pe wọn le ri “oju rere” Ọlọrun nipa mímú ẹbọ wá lai si ironupiwada atọkanwa.
Fifa Idajọ Sẹyin
“Nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pāpa lati huwa ibi” (Oniwasu 8:11). “Nkan wọnyi ni iwọ ṣe, emi si dakẹ” (Orin Dafidi 50:21). Oluwa ninu aanu Rè̩, fun ọmọ eniyan ni anfaani lati wá si ironupiwada; ṣugbọn bi o bá kọ lati ronupiwada, idajọ dájú. Israẹli lero pé Ọlọrun jé̩ alakẹbajé̩ bi ti wọn. Wọn rò pé a kò ri è̩ṣè̩ wọn ati pé Ọlọrun ki yoo jé̩ eniyan buburu niyà. Ọlọrun sọ fun Israẹli pe ìdájọ yoo wá, wọn yoo si ri i. “A kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7). Ọlọrun rán ìkìlọ líle si awọn Ọmọ Israẹli nitori ọnà ajambaku ti wọn gbà n sìn, ati igbesi-ayé ibajé̩ ti wọn n gbé. “Njẹ rò eyi, ẹnyin ti o gbagbe Ọlọrun, ki emi ki o má ba fà nyin ya pẹrẹ-pẹrẹ, ti kò si olugbala.” Pẹlu gbogbo ìkìlọ líle yii, ọnà aanu ṣi silẹ: “Ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ iyìn, o yìn mi logo: ati ẹniti o ba mu ọna ọrọ rè̩ tọ li emi o fi igbala Ọlọrun hàn fun.”
Igbesi-Ayé Ailẹṣè̩
Ọlọrun ní inú dídùn si aanu, O sì fé̩ iyìn, ṣugbọn kò si ohun ti o lè dipo rinrin deedee. Kò si ohun ti a lè fi dipo igbesi-ayé ti kò ni è̩ṣè̩. Kò si ẹni ti o lè rú ẹbọ ọpé̩ si Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni ti a ti wè̩ ninu È̩jè̩ Ọdọ-Agutan, ti igbesi-ayé rè̩ si jé̩ ailẹgan. Jẹ ki ẹni irapada Oluwa ki o fi iyìn fun Un; ki o si dupé̩ fun igbala nlá Rè̩.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni itumọ dídá majẹmu pẹlu ẹbọ?
- Wá awọn ẹsẹ Iwe Mimọ ti o ṣapejuwe titobi Ọlọrun.
- Ki ni pataki è̩sùn ti a fi Israẹli sùn?
- Ki ni awọn ileri ti o wà ni orí ìwè yii?
- Ki ni awọn ileri wọnyii rọ mọ?
- Ki ni itumọ “ọrọ” ni ẹsẹ kẹtalelogun?
- Èwo ninu ofin mẹwaa ni Ọlọrun sọ pe eniyan buburu ti rú?
- Ki ni Ọlọrun fé̩ ki Israẹli ki o ṣe?