1 Samuẹli 9:1-27; 10:1-27

Lesson 205 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dāmu awọn ọlọgbọn; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dāmu awọn ohun ti o li agbara” (1 Kọrinti 1:27).
Cross References

I Saulu Bẹ Samuẹli Wò

1. Saulu, ọmọ ọkunrin alagbara kan, jé̩ arẹwà ati ẹni ti o singbọnlẹ, 1 Samuẹli 9:1, 2

2. Baba rè̩ ran an lati lọ wá ẹran-ọsin ti o sọnu, 1 Samuẹli 9:3-5; Amosi 7:14, 15

3. A dari Saulu lati ọwọ Ọlọrun sọdọ Samuẹli, 1 Samuẹli 9:6-17

4. Samuẹli bu ọlá fun Saulu nibi àsè, 1 Samuẹli 9:18-27

5. Saulu fi iwa irè̩lè̩ hàn, 1 Samuẹli 9:21; 10:22; Owe 15:33; 22:4; Isaiah 57:15; Jakọbu 4:6

II Ifororoyan Saulu

1. Samuẹli fi òróró yan Saulu, o si fun un ni àmì mẹta, 1 Samuẹli 10:1-8

2. A gba ọkàn Saulu là, 1 Samuẹli 10:9-13

3. A yan Saulu lọba nipa didi ìbò, 1 Samuẹli 10:14-27

Notes
ALAYÉ

Saulu, Ogiripa

Nigbà ti Ọlọrun yan Saulu lati jọba lori Israẹli, O yan ọkunrin ti o singbọnlẹ. O jé̩ “arẹwa” eniyan, kò si si ẹni ti o ṣe arẹwà ju u lọ ninu gbogbo awọn Ọmọ Israẹli. O ga, ogiripa ni, boya o tilẹ gùn tó ẹsè̩ meje, lojú awọn Ọmọ Israẹli, irú ẹni ti o tọ lati ṣiwaju wọn lọ si ogun ni eyi. Baba rè̩, Kiṣi, jé̩ “ọkọnrin alagbara” – lai si aniani, ẹni ti o lọrọ ti o si ni okiki laaarin awọn eniyan ni.

A Dari Rè̩ si Samuẹli

O le dabi ẹni pé o jé̩ nnkan eeṣi fun Saulu lati wá sọdọ Samuẹli nigbà ti o n wá awọn nnkan ọsin baba rè̩ ti o sọnu. S̩ugbọn Ọlọrun sọ fun Samuẹli pe, “Niwoyi ọla emi o ran ọkọnrin kan lati ilẹ Bẹnjamini wá si ọ.” Ọlọrun wi pe, “Emi o ran …” Nigbà pupọ ni o n dabi ẹni pe awọn ẹlomiran ṣe eeṣi bá Ihinrere pade; ki i ṣe ọràn oribande rara - itọni Ọlọrun ni. Bi ebi otitọ bá n pa eniyan, Ọlọrun yoo mú oluwa rè̩ la ilẹ ati okun kọja, bi o ba gbà bẹẹ, ki ẹni naa le gbọ otitọ, ki o si le di ominira. Saulu wá gbogbo ilẹ Saliṣa, Salimu, Bẹnjamini ati Sufu titi o fi de ọdọ eniyan Ọlọrun - ṣugbọn Ọlọrun ni o mu u de ibè̩.

Ìwà Rere

Ọkan ninu awọn iwa rere ti Saulu ní ní ibẹrẹ ayé rè̩ ni ìwà ìrè̩lè̩. Nigbà ti Samuẹli wi pe oun ni ẹni ti Israẹli yoo yàn ni ọba, Saulu dahùn pe, “Ara Benjamini ki emi iṣe? kekere ninu ẹya Israẹli? idile mi kò si rẹhìn ninu gbogbo ẹya Benjamini? ẽsi ti ṣe ti iwọ sọrọ yi si mi?” Ìrè̩lè̩ yi ni o mu u ki o fi ara rè̩ pamọ saarin ohun èlò ni akoko ti o yẹ lati dá a lọlá laaarin awọn eniyan. Ọlọrun fé̩ ìrè̩lè̩, O si korira igberaga.

Ọba onigberaga kan fọnnu nigbà kan pé, “Koṣepe eyi ni Babeli nla, ti emi ti fi lile agbara mi kọ ni ile ijọba, ati fun ogo ọlanla mi?” (Danieli 4:30). Nigbà ti ọrọ wọnyii wà ni ẹnu rè̩ sibẹ, Ọlọrun rè̩ é̩ silẹ, O si gba ijọba rè̩ kuro lọwọ rè̩; ki i ṣe ijọba rè̩ nikan, ati òye rè̩ pẹlu. O yẹ ki eniyan ki o mọ pe kò si ohun kan ti oun ni ti ki i ṣe pé Ọlọrun ni o fun oun tabi ti o fi àyè silẹ fun oun lati ni i. Bi o ba ni ọrọ, “Ki iwọ ki o ranti OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe, on li o fun ọ li agbara lati lí ọrọ” (Deuteronomi 8:18). “Gbogbo è̩bun rere ati gbogbo è̩bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá” (Jakọbu 1:17).

Ìrè̩lè̩

Idahùn Saulu ni eyi: “Ara Benjamini ki emi iṣe? kekere ninu ẹya Israẹli? idile mi kò si rẹhin …?” Nigbà ti Ọlọrun pe Gideoni, idahùn rè̩ ni pe, Yẽ oluwa mi, ọna wo li emi o fi gbà Israẹli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jé̩ ẹni ikẹhin ni ile baba mi” (Awọn Onidajọ 6:15). Ọlọrun yan awọn onirẹlẹ ki Oun ki o le fi titobi agbara Rè̩ hàn.

Nigbà ti Oluwa sọ fun Mose pé Oun yoo ran an lọ si ọdọ Farao, Mose dahùn pé, “Tali emi, ti emi o fi tọ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israẹli jade lati Egipti wá?” (Ẹksodu 3:11). “Tali emi?” Ta ni ẹnikẹni ninu wa jé̩ ti Ọlọrun fi ni lati fi agbara nlá Rè̩ hàn fun wa? Ìdí rè̩ ni pe: “Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dāmu awọn ọlọgbọn; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dāmu awọn ohun ti o li agbara; ati awọn ohun aiye ti kò niyin, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan: ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rè̩.” Paulu, Apọsteli giga si awọn Keferi pe, “Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Apọsteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè ni Apọsteli” (1 Kọrinti 15:9). Awọn eniyan pataki lọwọ Ọlọrun ni awọn onirẹlẹ. Laaarin awọn ẹlẹṣè̩ paapaa, wọn a maa wi pe, “Awọn eniyan pataki gidi ki i gberaga.”

Ọgbọn

Ọgbọn ti Saulu ní fara hàn nigbà ti awọn ọmọ Beliali fi è̩gàn wi pe, “Ọkọnrin yi yio ti ṣe gbà wa?” Saulu si dakẹ. Sọlomọni wi pe, “Ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọn,” ati “Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rè̩ mọ, o pa ọkàn rè̩ mọ kuro ninu iyọnu” (Owe 10:19; 21:23). Jakọbu kọ wa pe asan ni igbagbọ wa bi a kò ba kó ahọn wa ni ijanu. O ya Pilatu lẹnu nigbà ti Olugbala wa dakẹ nigbà ti wọn n kẹgan Rè̩. A ha mọ ọ ni ọlọgbọn nipa kíkó ahọn rẹ nijanu?

Èrè Kíkún

Nigbà ti iranṣẹ Saulu damọran pé ki wọn lọ sọdọ eniyan Ọlọrun lati beere ọnà, Saulu dahùn pé, “Bi awa ba lọ, kili awa o mu lọ fun ọkọnrin na, nitoripe akara tan ni apò wa, ko si si ọrẹ ti a o mu tọ ẹni Ọlọrun na: kili awa ni?” Iranṣẹ naa dahun pe, “Mo ni idamẹrin ṣekeli fadaka lọwọ, eyi li emi o fun ẹni Ọlọrun na, ki o le fi ọna wa hàn wa.” “Kili awa ni?” Saulu wá sọdọ eniyan Ọlọrun pẹlu ikoko ofifo ti o si gbẹ, lati beere ọnà. O wá si ibi orisun tootọ. Eniyan Ọlọrun fi ọnà hàn an. O wá ni òfo, o si pada lọ pẹlu adé. O wá gẹgẹ bi daran-daran; o si pada lọ bi ọba. Bẹẹ ni, o si tún ju ọba lọ! O wá bi ẹlẹṣè̩, o si pada lọ bi ọmọ Ọlọrun.

Eyi jé̩ ohun iyanu lọpọlọpọ! A wá sọdọ Oluwa pẹlu irobinujẹ ati ni ọwọ òfo; a si pada pẹlu ayọ kíkún. A wolẹ niwaju Rè̩ gẹgẹ bi ẹlẹṣè̩ ti a dá lẹbi ikú; ṣugbọn a lọ pẹlu idalare ati idariji kíkún. Awa, ẹni ti o ti jé̩ ẹrú Satani ni a sọ di ọmọ Ọlọrun ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi. “Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun” (1 Johannu 3:1).

È̩dá Titun

Lai si aniani, Saulu ni ìrírí igbala ti o dajú. Samuẹli wi fun un pe, “Ẹmi Oluwa yio si bà le ọ, iwọ yio si ma ba wọn sọtẹlẹ, iwọ o si di ẹlomiran.” A sọ fun wa pé, “Bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun” (2 Kọrinti 5:17), eyi ni ọnà miiran ti a fi n wi pe eniyan yí pada. Ohun kan naa ni Jesu n sọ nigbà ti O wi pe, “A kò le ṣe alaitún nyin bi.”

Nigbà ti a bá ri igbala, ki i ṣe pe a dari è̩ṣè̩ wa ji wa nikan, ṣugbọn a yí wa pada. Iṣé̩ iyanu ṣe ninu wa, eyi ti o yi wa pada lati ọmọ ayé yii ti a si di ọmọ Ọlọrun. “Ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun.” Awa ti a ti kú ninu aiṣedeedee ati è̩ṣè̩, ni a sọ di aayè lati maa rìn ni ọtun ìwà. Ọlọrun fun Saulu ni “ọkàn miran”, bẹẹ ni “Ẹmi Ọlọrun si bà le e, o si sọtẹlẹ.” Ẹ wo irú iyipada yii ni igbesi-ayé Saulu! Dajudaju kò si ẹni ti o le ṣiyemeji irapada Saulu. Gbogbo awọn ti o ti mọ ọn tẹlẹ ri, beere pẹlu iyanu pe, “Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?” Iyalẹnu awọn eniyan naa pọ tó bẹẹ ti o fi di owe laaarin awọn eniyan pé, “Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?”

Ibẹrẹ Rere – Opin Buburu

Ẹ wo irú iṣisẹ rere ti ẹni ti Ọlọrun ti yàn lati jọba lori Israẹli kọ gbé! S̩ugbọn o jé̩ ohun ti o ba ni ninu jé̩ pé kò duro pé̩ ni ọnà ti Ọlọrun fi ẹsẹ rè̩ lé. O jé̩ ikilọ fun gbogbo eniyan lonii pé ohun ti o rọrun ni lati ni “iriri atunbi” ki a si di ọmọ Ọlọrun, ki a si tún fà sẹyin ki a si di ẹni ègbé. Nigbà kan Saulu mọ irẹpọ ati ojú rere Ọlọrun ṣugbọn nigbẹyin Ẹmi Ọlọrun fi i silẹ “Oluwa kò da a lohùn” (1 Samueli 28:6).

Iboji ẹni ti o pa ara rẹ ati ọrun apaadi ti i ṣe ti eṣu ni ipin ẹni ti awọn eniyan sọ nipa rè̩ rí, pé, “Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?” Jesu wi pe, “Ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na ni a ó gbalà? (Matteu 10:22). O ṣanfaani fun ẹni ti o ti bè̩rè̩ ni ọnà naa “ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni iwọ ti rò pé Saulu ti ga tó?
  2. Lati inú è̩yà wo ni Israẹli ni ó ti jade?
  3. Bawo ni a ṣe mọ pe wíwá Saulu si ọdọ Samuẹli kò ṣẹlẹ bẹẹ lasan?
  4. Irú ìwà rere wo ni Saulu fi hàn?
  5. Bawo ni a ṣe mọ pe Saulu di atunbi?
  6. Fi ìdí ọrọ yii mulẹ lati inú Bibeli pé ohun ti o ṣe e ṣe ni pe ki eniyan ri igbala tán, ki o tún fà sẹyin, ki o si di ẹni ègbé laelae.
  7. Awọn ileri wo ni Ọlọrun ṣe fun awọn onirẹlẹ?
  8. Ọnà wo ni Saulu fi hùwà ọlọgbọn?
  9. Ki ni idamẹrin ṣekeli kan ni owó wa?
  10. Ki ni awọn àmì ti Samuẹli fi fun Saulu lati fi hàn pe Ọlọrun wà pẹlu rè̩?