Lesson 206 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Oluwa sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ: o rè̩ silẹ, o si gbe soke” (1 Samuẹli 2:7).Cross References
I Fifi Ìdí Ijọba Saulu Mulè̩ ni Gilgali
1. Ki i ṣe gbogbo eniyan ni o gba Saulu lọba ni Mispe, 1 Samuẹli 10:26, 27
2. Iṣẹgun rè̩ akọkọ so Israẹli pọ ṣọkan labẹ rè̩, 1 Samuẹli 11:1-11
3. Ni akọkọ, Ọlọrun lè ti ọwọ rè̩ ṣiṣẹ, nitori o ni ẹmi rere ti o tayọ, 1 Samuẹli 11:11-13; 15:17
4. Iyara-ẹni-sọtọ ni ọtun ati yiyin Ọlọrun a maa fun ni layọ nigbà gbogbo, 1 Samuẹli 11:14, 15; Orin Dafidi 50:14, 15, 23
II Samuẹli Yọọda ki Israẹli Wadii Rè̩
1. Ọlọrun fun Israẹli lọba kan gẹgẹ bi ibeere wọn, 1 Samuẹli 12:1; 8:4-6, 19-22
2. Samuẹli fi awọn ọmọ rè̩ ti wọn kún fun è̩ṣè̩ lé Israẹli lọwọ fun idajọ, 1 Samuẹli 12:2
3. A pe Israẹli lati jẹri gbe Samuẹli bi o bá ti ṣe wọn ni ibi, 1 Samuẹli 12:3; 2 Timoteu 4:6-8
4. Israẹli jẹri si iṣé̩ rere Samuẹli, 1 Samuẹli 12:4, 5; 2 Kọrinti 4:1, 2; Titu 1:7-9
III Samuẹli Sun Awọn Ọmọ Israẹli Lẹsùn niwaju Oluwa
1. Samuẹli rán wọn leti pé igbega ti ọdọ Oluwa wá, 1 Samuẹli 12:6; Orin Dafidi 75:6, 7; Romu 13:1-7
2. Jijare ti Samuẹli jare fi hàn gbangba pé Israẹli ni o jẹbi, 1 Samuẹli 12:7
3. O rán wọn leti bi Ọlọrun ti ṣe gbà wọn latẹyinwá, 1 Samuẹli 12:8-11
4. Pẹlu gbogbo ifẹ Ọlọrun, Israẹli kọ Ọlọrun ni Ọba, wọn n fẹ ọba gẹgẹ bi ti awọn orilẹ-ède miiran, 1 Samuẹli 12:12, 13
IV Aanu ati Idajọ
1. A fi aanu lọ wọn bi wọn tilẹ ti kọ Ọlọrun, 1 Samuẹli 12:14; Isaiah 9:12, 17, 21; Orin Dafidi 103:17; Mika 7:18; Romu 10:21; 11:32-36; Titu 3:5
2. Ìjìyà wíwa ọrùn kì dajú, 1 Samuẹli 12:15; Romu 6:23
3. A rán àmì ibinú Ọlọrun si wọn, 1 Samueli 12:16-18
4. Ironupiwada Israẹli mú ki a ki wọn layà, ki a si gbà wọn niyanju lati sin Ọlọrun, 1 Samuẹli 12:19-25.
Notes
ALAYÉỌba Titun
Pẹlu ìrè̩lè̩ ọkàn si Ọlọrun ati si eniyan ni Saulu, tí í ṣe ọba titun ẹgbẹẹgbẹrun awọn Ọmọ Israẹli, mú ọnà ile pọn lẹyìn ti Wolii Samuẹli ti fi òróró yàn án ti wọn si ti pari gbogbo ètò ifijọba. Lai si aniani ẹnu ya Saulu bí gbogbo nnkan ti n lọ si nigbà ti a dá yàn án bi ọba laaarin ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọdọmọkunrin ti o dabi ẹni pé wọn jafafa jù ú lọ - nipa è̩bùn iṣakoso ati iṣelu – nitori idile Saulu jé̩ ọkan ninu awọn ti o kere jù ni Israẹli. Boya o n ronu igbesẹ ti oun yoo gbé lẹyìn ìgbà ti Ọlọrun ti yàn án, ti ogunlọgọ awọn Ọmọ Israẹli si ti gbà á gẹgẹ bi ọba wọn. A ni idaniloju pé o lọ si ile rè̩ lati duro de àṣẹ ati ilana Ọlọrun.
Saulu kere lojú ara rè̩. O ri i pe ọgbọn oun kò tó fun awọn ètò ti o wà niwaju rè̩ ati aṣiwaju ti a yàn án lati ṣe. Ọlọrun le lo irú awọn eniyan ti o ni ọkàn ati ẹmi bẹẹ. Ọlọrun ki i lo awọn tí o tó tán lojú ara wọn, awọn aṣetinu-ẹni. A ki i si fi òróró yan awọn irú eniyan bẹẹ. Irú ẹni ti o ba rẹ ara rè̩ silẹ fun Ọlọrun ati Ẹmi Mimọ, ti o si lè jọwọ gbogbo ìfé̩, ìlànà, ìtara, ilọsiwaju ati gbogbo ìní rè̩ fun Ọlọrun ati Ẹmi Mimọ, ni o le ri ifororoyan Ọlọrun gbà, eyi ti o ṣe pataki fun idagbasoke ti ẹmi.
Ìṣọkan Jé̩ Ìwà ti o S̩e Danindanin
Awọn eniyan oloootọ diẹ feti si ipe Ọlọrun, wọn si tẹle Saulu lọ si ilu rè̩. S̩ugbọn awọn kan ṣọtẹ si ọba titun yii. Awọn wọnyii ni ọmọ Beliali, ẹlẹṣè̩ ati eniyan lasan; wọn kò mọ, bẹẹ ni wọn kò tilẹ bikita lati mọ ifẹ Ọlọrun ninu ọran yii tabi ninu ohun miiran pẹlu. Wọn le ṣai pọ niye, ṣugbọn ifarahàn awọn diẹ wọnyii fi hàn pé gbogbo Israẹli kò si ninu iṣọkan.
Ni ibi meji tabi ju bẹẹ lọ ni a ti sọ fun wa ninu Iwe Mimọ pé, “iwukara diẹ ni imu gbogbo iyẹfun di wiwu” (1 Kọrinti 5:6; Galatia 5:9). Eyi ti a pè ni “è̩ṣẹ kekere” yoo yà wá kuro lọdọ Ọlọrun. “Kọlọkọlọ kékeké” le ba ọgbà àjàrà eleso daradara jé̩, bi a ba gbà á layè. Ibajẹ diẹ ti a kò mú kuro lara èso didun le sọ gbogbo èso naa di ibajẹ ati ohun alaini laari ni iwọn wakati diẹ.
S̩ugbọn Saulu paapaa fara balẹ ni akoko yii, ki o má ba ṣiwaju Ọlọrun, nipa iṣe rè̩ si awọn eniyan wọnyii ti wọn kọ Ọlọrun ati oun paapaa. O dakẹ jẹẹ. Otitọ ni pé Ọlọrun yoo bá awọn oluṣe buburu wí bi awa bá sa ipá wa lati ṣi ọnà ti Oun fi yoo ṣe e silẹ lai si iranlọwọ è̩dá. Ọlọrun fé̩ awọn eniyan Rè̩, yoo si sa gbogbo ipá Rè̩ lati pese wọn silẹ fun Ọrun ti O ti pese silẹ fun wọn. Bakan naa ni Ọlọrun yoo gbeja awọn eniyan Rè̩ bi o tilẹ dabi ẹni pe gbogbo ogun ọrun apaadi dide si wọn lati sùn wọn lè̩sùn èké. O sọ ninu Ọrọ Rè̩ pé, nigbà ti a ba n ṣe rere, ti a si jẹ wá niya nitori bẹẹ, bi a ba fi suuru gba a, eyi jẹ itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun (1 Peteru 2:19, 20).
Wọn sun Jesu ni è̩sùn èké, wọn ṣọtẹ si I, wọn si kọ Ọ; ṣugbọn O fi suuru gbà á. Ọlọrun paṣẹ fun wa lati rin ni ipasẹ Oluwa ati Olugbala wa; eyi ni a si ni lati ṣe ti a ba fé̩ jé̩ alabapin ogo Rè̩ (1 Peteru 2:21-23; 2 Timoteu 2:11, 12). Ọlọrun yoo mú gbogbo ohun ti yoo di wa lọwọ fun isin Rè̩ kuro bi a bá gba fun Un lati ṣe bẹẹ. Bí a bá takú si ọnà wa, tí a sì jé̩ ki ẹmi iṣọtẹ si Ọlọrun gba ọkàn wa, a o ri i pe a ti sé ilẹkun mọ ara wa, a ki i si ṣe ti Rè̩ mọ.
Ìṣọkan jé̩ ohun danindanin ninu ohunkohun ti a n ṣe fun ọlá ati ogo Ọlọrun. Mimọ ni Ọlọrun. Ọkan naa ni Baba, Ọmọ ati Ẹmi. O ti pàṣẹ pé a ni lati jé̩ mimọ ki a si wà ni iṣọkan, eyi ti kò ṣe e ṣe bi kò ṣe nipa È̩jè̩ Ọdọ-agutan ti n sọ ni di mimọ (Matteu 5:48; Lefitiku 20:7; Heberu 2:11; 12:14). Imisi ara ni o n dá iyapa silẹ laaarin awọn eniyan Ọlọrun; awọn tí ó bá si n ṣe e tabi ti wọn fi àyè gbà á kò rin gẹgẹ bí Ọlọrun ti n fé̩ ki wọn rìn, ṣugbọn wọn n rìn gẹgẹ bí ti ayé (1 Kọrinti 1:10; 3:3; 11:17, 18). Awọn ipinya bi “kọlọkọlọ kékeké” ki i pẹ di iṣé̩ ti ara ti n pa ọkàn run: iyapa tabi ìjà, ìṣọtè̩ tabi ọrọ ọtè̩; adamọ tabi è̩kọ èké; ati ìjà (Galatia 5:19-21). Aisi irẹpọ yoo mú ki ohunkohun ti a n ṣe fun ogo Ọlọrun ki o kùnà, i baa ṣe ti ẹmi tabi ti ara. A ni lati wà ni irẹpọ ni àyà ati ọkàn tí a bá fé̩ ṣe aṣeyọri.
Ọgbọn tí Ọlọrun Fun Samueli
Igbala ọkàn ati anfaani awọn Ọmọ Israẹli nikan ni ohun ti o jé̩ ifẹ ọkàn Samueli, eniyan Ọlọrun. O ti jé̩ onidajọ lori wọn fun ọpọlọpọ ọdún, o si ti sin Ọlọrun ati eniyan pẹlu ni otitọ ọkàn, ni gbogbo igbesi-ayé rè̩. Titi di akoko yii, o ti pe apejọ orilẹ-ède naa fun adura ati ironupiwada, nitori iwa buburu ati ìsìn ibọriṣa wọn. O dabi ẹni pe eyi ni ohun ti o leke ọkàn rè̩ ni igbesi-ayé rè̩ - pé ki a le gba Israẹli là. Awọn ẹni ìwà-bi-Ọlọrun miiran ti ni irú ipinnu bẹẹ nipa awọn ẹlẹṣè̩ ti o wà ni gbogbo agbaye. Irú itara bẹẹ kò ni ṣalai wà ni ọkàn olukuluku ọkunrin tabi obinrin ti a ba tunbi nitootọ. Gbogbo wa ni ikọ fun Kristi. Gbogbo wa ni ìwé Rè̩ ti a n kà. Gbogbo wa si ni imọlẹ ninu ayé okunkun yii.
Nitori naa, Samueli lo gbogbo anfaani àyè rè̩ lakoko yii, nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli n bẹrẹ igbesi-ayé titun gẹgẹ bi orilẹ-ède, lati mú wọn wá sọdọ Ọlọrun. Iwe Mimọ si sọ bi ó ti ṣe aṣeyọri tó. Adura olododo maa n ṣiṣẹ lọpọlọpọ. Adura è̩bè̩ awọn ti o n ri i bi awọn ẹlẹṣè̩ ayé yii ti n lọ si ọrun apaadi ti mú igbala ba awọn ẹlẹṣè̩ ti o ju ọkan lọ, bi o tilẹ jé̩ pé ẹni ti o n bẹbẹ yii kò mọ ẹni ti oun n gbadura fún. Samueli jé̩ oloootọ ninu iṣẹ iranṣẹ rè̩ fun Israẹli.
Samueli fi ara rè̩ si ipò ti o lagbara nipa ṣiṣi ọkàn rè̩ paya fun awọn eniyan rè̩, ti o si fun wọn ni anfaani lati sùn ún lè̩sùn bi aiṣedeedee kan ba wà lọwọ oun tabi ki wọn sọ fun un bi akoko kan ba wà ti oun ré̩ wọn jẹ rí. Wọn jẹri pe ó jé̩ oloootọ.
O hàn si gbogbo eniyan pé, Ọlọrun kò wà pẹlu Israẹli nigbà naa gẹgẹ bi ti atẹyinwa. Apoti ẹri kò si ninu Agọ mọ. Shekina (ti i ṣe ogo Ọlọrun) kò si ni Ibi Mimọ Julọ mọ. S̩ugbọn ẹni kan wà laaarin wọn, boya ko ti i kú ni akoko yii, ẹni ti orukọ rè̩ n jé̩ Ikabodu; a sọ ọ ni orukọ yii nitori ogo Ọlọrun ti lọ kuro ni Israẹli ni igbà ìbí rè̩. Ki ni de? Ki ni ṣe ti Ọlọrun kò fi si nibẹ mọ? È̩bi aṣiwaju wọn ni bi? Èsì Israẹli si ibeere Samueli fi è̩bi fun ẹni ti è̩bi i ṣe ti rè̩. Samueli kò jẹbi ohunkohun. O ti fi tọkàn tọkàn sin Ọlọrun, kò si fi èrú tabi anfaani ipò rè̩ gba ohunkohun lọwọ wọn, tabi ki o fi aiṣododo gba ohun kan. O ti ṣe idajọ ododo, o si ti lakaka lati mú orilẹ-ède naa súnmọ Ọlọrun. Ti wọn ni è̩bi naa.
Ijẹwọ awọn Ọmọ Israẹli pé, olododo ni Samueli i ṣe, jé̩ ipilẹ pataki lori eyi ti Samueli gbé bẹrẹ è̩sùn ti o sùn wọn; o bẹrẹ si fihàn wọn bi Ọlọrun ti pese lọnà iyanu fun wọn lati ẹyìn wá; bi O ti gbà wọn lọwọ awọn ara Egipti, awọn ara Kenaani, Midiani, Amori ati Filistini. Laaarin akoko yii Ọlọrun ni Ọba wọn. Samueli si tè̩ siwaju lati fihàn awọn Ọmọ Israẹli bi aṣiṣe wọn ti pọ tó ni kikọ Ọlọrun gẹgẹ bi Ọba wọn ti wọn si beere ọba ti o dabi ti awọn orilẹ-ède ti o yi wọn ká. Kò si ọnà mọ lati yi ohun ti wọn ti fi ìwà wèrè ṣe pada, tabi lati ṣe atunṣe ohun ti wọn ti fi ifẹ inú wọn yàn. Wọn ti ṣe ipinnu; a si ti fi ororo yan ọba wọn. Wọn ti yan ọba, nitori naa wọn ni lati jiya fun aṣiṣe wọn.
Sibẹ aanu wà fun wọn! Kò yani lẹnu ti Dafidi fi n kọwe nigbakuugba nipa aanu Ọlọrun – aanu Ọlọrun ti o wà titi! Bi wọn ba bè̩rù Oluwa ti wọn si sin In, bi wọn ba feti si ohun Rè̩ ti wọn si pa àṣẹ Rè̩ mọ, Oluwa yoo wà pẹlu wọn sibẹ. Bi wọn tilẹ kọ Ọ bi Ọba wọn, Oun yoo si wà sibẹ lati bukun fun wọn. Ọdọ Ọlọrun nikan ni a ti le ri irú aanu ati ifẹ bẹẹ. S̩ugbọn a paṣẹ fun awọn ọmọ Ọlọrun lati fẹ aanu, a si sọ fun wọn pé a o bukun fun alaanu, yoo si ri aanu gbà.
Samuẹli si ke pe Ọlọrun lati rán àmì ti a le foju ri lati ti è̩sùn ati è̩bè̩ rè̩ lẹhin. Akoko ìkórè ni, ti i ṣe ìgbà ọgbẹlè̩ ninu ọdún. Oluwa rán òjò ati ààrá lati fihàn fun awọn eniyan naa pé otitọ ni ọrọ Samueli, ati pé awọn ni o jè̩bi. Lẹsẹkẹsẹ ni awọn eniyan mọ ọn lara. Wọn si bẹ eniyan Ọlọrun yii lati gbadura fun wọn, lati fihàn pe wọn ronupiwada tọkàntọkàn, nitori Samueli sọrọ ìkìyà ati ìṣírí fun wọn lẹsẹkẹsẹ, ati pẹlu, o kilọ fun wọn pé ki wọn ki o má ṣe ṣọtẹ tabi kọ Ọlọrun silẹ mọ ni ọjọ iwajú.
Ohun ti Ọlọrun n Beere
Ninu awọn àṣàyàn è̩kọ yii, a le ri iwa-bi-Ọlọrun ti a gbọdọ ní ki a to le wulo fun Ọlọrun fun ọlá ati ogo Rè̩. “A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti OLUWA bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ānu, ati ki o rìn ni irè̩lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ” (Mika 6:8). Saulu ní awọn ìwà rere yii nigbà kan ní igbesi-ayé rè̩. Samuẹli, eniyan Ọlọrun, ní wọn ní gbogbo ọjọ ayé rè̩. Awọn Ọmọ Israẹli jẹ igbadùn wọn nigbà pupọ, ṣugbọn fun ìgbà ti o pọ ju ninu ìtàn wọn ni wọn kò dé ojú àmì tí Ọlọrun fé̩ ki wọn dé.
Ninu awọn ẹsẹ ti o pari è̩kọ wa, a ka awọn ohun wọnni lẹsẹlẹsẹ, ti a n beere ati ilana nipa ti ẹsin Ọlọrun, eyi ti Samuẹli fun awọn eniyan naa. Lẹyin eyi, o ṣeleri lati jẹ oloootọ si Ọlọrun nitori wọn, ni gbigbadura fun wọn ati ni kikọ wọn “li ọna rere ati titọ”; o fun wọn ni ìṣírí mẹta: Ekinni, bi wọn ba fẹ wu Ọlọrun ki wọn si ri ibukun Rè̩ gbà, wọn ni lati “bè̩rù Oluwa, ki wọn si sin i li òdodo” pẹlu gbogbo ọkàn wọn. Ekeji ni pé, wọn ni lati “ronu ohun nlanla” ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn ati fun awọn baba nlá wọn, ni fi fun wọn ni ibukun nlá ti Majẹmu Ainipẹkun, eyi ti o fi ireti ailopin ti igbala ati Ilẹ Ileri ati awọn ibukun rè̩ fun wọn. Ẹkẹta, a kilọ fun wọn pé bi wọn kò bá tẹle Ọlọrun, wọn yoo ṣegbe, awọn ati ọba wọn.
Ninu awọn ẹsẹ ìwè diẹ yii, a ri akọsilẹ ni ṣoki ti o kọ ni nipa ohun ti Ihinrere n beere lọwọ wa ati irú ihà ti a ni lati kọ si è̩kọ ati ìpè rè̩. A ni lati sin Oluwa ni ẹmi ati otitọ (Johannu 4:24). A ni lati jé̩ oloootọ ni ìyìn wa fun ire tí ó mú bá wa lara ati lẹmi (Orin Dafidi 103:2; Galatia 6:14). A si kilọ fun wa pé bi a kò ba naani ìsìn Ọlọrun, a o jìyà fun ijafara ati ìwà aiṣedeedee wa (Heberu 2:1-4).
Questions
AWỌN IBEERE- Njẹ gbogbo Israẹli ni o gba Saulu bi ọba nigbà ti a fi òróró yàn án?
- Bawo ni iṣọkan ti ṣe pataki to ninu iṣẹ ìsìn wa si Ọlọrun, ati ninu ìsìn Rè̩?
- S̩e àṣàrò lori awọn ẹsẹ ọrọ Ọlọrun wọnyii: Amosi 3:3; 1 Kọrinti 14:32, 33, 40; Efesu 4:3, 13
- Ki ni Ọlọrun n ṣe fun wa nigbà ti a bá fi ara wa rubọ lọtun, ti a si rú ẹbọ ọpé̩ si I?
- Ki ni ohun ibi ti o wà ninu ibeere awọn Ọmọ Israẹli fun ọba?
- Njẹ Samueli jẹbi ohun kan tabi ki o ṣe ainaani iṣẹ rè̩ si awọn Ọmọ Israẹli?
- Wá inú Bibeli fun awọn ẹsẹ ọrọ Ọlọrun lori àánú.
- Njẹ Israẹli ronupiwada è̩ṣè̩ wọn?
- Irú ìhà wo ni Samueli kọ si wọn nigbẹyin gẹgẹ bi a ti fihàn ninu è̩kọ wa yii?
- Bawo ni Ọlọrun ṣe fihàn pé Oun fara mọ è̩sùn ti Samueli fi awọn Ọmọ Israẹli sùn?