1 Samuẹli 13:5-14; 15:1-35

Lesson 207 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Oluwa ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gbà ohùn Oluwa gbọ? kiye si i, igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilè̩ si sàn jù ọra àgbo lọ” (1 Samuẹli 15:22).
Cross References

I Akoko Ipọnju

1. Awọn Filistini gbá ogun nlá nlà jọ ti Israẹli lati gbẹsan, 1 Samuẹli 13:3-5; Gẹnẹsisi 34:30; Ẹksodu 5:21

2. Israẹli wà lai ni ohun èlò ijagun, ipò rè̩ si buru jọjọ, 1 Samuẹli 13:6-8, 19-22; Ẹksodu 14:10-12

II Ìrúbọ Ti A Fi Ìkùgbù S̩e ati Ìbínú Ọlọrun Nitori Rè̩

1. Saulu fi ikanjú ati aini suuru duro de Samuẹli fun ọjọ meje, 1 Samuẹli 13:8; Romu 5:3, 4; Jakọbu 1:4

2. Saulu fi ìwà wèrè pàṣẹ lati rú ẹbọ sisun kan, 1 Samuẹli 13:9, 10; Numeri 16:1, 3, 40; 2 Kronika 26:16-20; Heberu 5:1

3. Samuẹli yọ sibẹ lakoko ti a dá, o si beere nipa ti àdáṣe Saulu, 1 Samuẹli 13:10-12; Gẹnẹsisi 3:13; 4:10; Joṣua 7:19

4. Saulu gbà fun Samuẹli pé oun ti ṣe lodi si è̩rí ọkàn oun, 1 Samuẹli 13:12; Orin Dafidi 50:16-21; Romu 1:32

5. Samuẹli sọ fun Saulu pé a ti gba ijọba naa kuro lọwọ rè̩, a si ti fi i fun ẹlomiran, 1 Samuẹli 13:13, 14; 2:30; 15:28; Orin Dafidi 78:70; Iṣe Awọn Aposteli 13:21-23

III Abayọrisi S̩iṣati ti Ọlọrun S̩á Saulu Tì

1. Oluwa pàṣẹ fun Saulu lati pa gbogbo ohun alaayè run ti i ṣe ti awọn Amaleki, oun kò si ṣe bẹẹ, 1 Samuẹli 15:1-9; Jeremiah 22:21; Titu 3:3

2. Ọlọrun fihàn fun Samuẹli pé Saulu kò pa àṣẹ Oun mọ, 1 Samuẹli 15:10-13; Iṣe Awọn Aposteli 5:3; 2 Samuẹli 12:7-9

3. Nigbà ti a beere nipa aigbọran rè̩, Saulu kò lati gba è̩bi rè̩, o wà lai ni ironupiwada sibẹ, 1 Samuẹli 15:14-21; Genesisi 3:12; 4:9; Johannu 8:44

4. Samuẹli sọ fun Saulu pé “igbọran sàn jù ẹbọ lọ” ati pe nitori oun ti kọ ọrọ Oluwa, a ti kọ oun paapaa, 1 Samuẹli 15:22-29; Romu 1:28; Jeremiah 6:30; Isaiah 1:22

5. Samuẹli pa Agagi, o si kuro lọdọ Saulu lai tun ri i mọ, 1 Samuẹli 15:30-35.

Notes
ALAYÉ

Ọkàn Ojo

Ọdún meji pere ni Saulu fi jọba nigbà ti Jonatani ọmọ rè̩ pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini kan, eyi si mú ki awọn Filistini gbá ara wọn jọ lati bá Israẹli jà. Bi o tilẹ jẹ pé awọn Ọmọ Israẹli kò ni ohun ìjà ju àáké ati ọkọ, sibẹ Saulu fun ipè, o si pe awọn Ọmọ Israẹli jọ si ogun naa. Ẹgbẹta (600) eniyan pere ni o wà pẹlu Saulu lati dojú kọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn Filistini.

Akoko Ipinnu

Nigbà ìpọnjú ni a n mọ oniwa rere eniyan; akoko yii si jẹ ìgbà iyiiriwo Saulu lọpọlọpọ. Gẹgẹ bi ọgagun, iba ọmọ ogun diẹ ni o wà pẹlu rè̩, oriṣiriṣi àjálù ni o si wà niwaju rè̩ ti o fihàn pe iparun le de lẹsẹkẹsẹ. Bi Saulu ti mọ pé o ṣe e ṣe fun awọn Filistini lati kọlu ogun Israẹli lẹsẹkẹsẹ, o ri i pé o yẹ ki oun mú ohun kan ṣe bi bẹẹ kọ, awọn ọtá yoo bori.

Lai si aniani, Saulu mọ dajú pé oun kò le ṣalai ni iranlọwọ Ọlọrun, ṣugbọn Samuẹli, Wolii Ọlọrun kò si nibẹ. S̩iwaju akoko yii, Samuẹli ti sọ fun Saulu ohun ti yoo ṣẹlẹ ni ọjọ yii, nitori naa ni o fi sọ fun un ki o duro ni ọjọ meje. Samuẹli si ti ṣeleri fun Saulu pé oun n bọ lati rú ọrẹ ẹbọ sisun lati bè̩bè̩ pé ki Oluwa ki o le ràn wọn lọwọ, a o si sọ fun Saulu nigbà naa ohun ti o yẹ ki o ṣe. S̩ugbọn Samuẹli kò ti i de! Ọjọ meje si ti pé, ṣugbọn Wolii naa kò ti i dé sibẹ.

Ìwà Ailọgbọn

Pẹlu gbogbo iwarapapà ati aifarabalẹ nitori Samuẹli kò dé ni akoko ti ó dá, Saulu tè̩ si ifẹ ọkàn ara rè̩ lati ṣètò bi yoo ti bọ kuro ninu iyọnu ti o de ba a. O pàṣẹ pé ki a mú ọrẹ ẹbọ sisun wá sọdọ rè̩, o si rú ẹbọ lati mú è̩bè̩ rè̩ tọ Ọlọrun lọ.

Saulu mọ agbara Ọlọrun dajú to bẹẹ ti kò fi fẹ lati lọ si ogun lai ni iranlọwọ Ọlọrun. Sibẹ ẹbọ ti Saulu kùgbù rú lai si Samuẹli, ẹni ti Ọlọrun yàn fun iṣé̩ Rè̩, jẹ iwara ti kò tọ, o si lewu lọpọlọpọ. O si jẹ ìwà afojudi si mimọ ati ọlá Ọlọrun, eyi ti Ọlọrun kò le gbojú fò dá.

Awọn ẹni ti a yàn nikan ni o ni è̩tọ lati rú ẹbọ sísun ati ọpé̩, ẹlomiran ti o bá si daṣa lati ṣe bẹẹ yoo jẹbi ikú, idajọ ti a si gbọdọ mú ṣẹ kankan. (Wo Numeri 18:7; Lefitiku 17:3-9). Majẹmu Titun sọ nipa ọrọ yii pé: “Nitori olukuluku olori alufa ti a yàn ninu awọn enia, li a fi jẹ fun awọn enia niti ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le mā mu è̩bun wá ati lati ṣe ẹbọ nitori è̩ṣẹ” (Heberu 5:1).

Awọn eniyan ti wà ṣiwaju ìgbà Saulu ti o ti gbiyanju lati fi èrú gba ipò alufaa, wọn si ṣe e si iparun ara wọn. Kora, Datani ati Abiramu jowú Mose, wọn si daṣà lati wadii àṣẹ ti Ọlọrun gbé le e lọwọ lati ṣe akoso ìsìn Ọlọrun. Ọlọrun jẹri Mose nipa mímú ki ilẹ la ẹnu ki o si gbé awọn ọdaràn wọnyii mì laayè. Iná si jade wá lati ọdọ Ọlọrun ti o run adọtalerugba (250) awọn ọmọ alade Israẹli ti o ní inú-didun si awọn oluṣe buburu naa. Bayii ni iṣe Saulu ti buru to. (Wo Numeri 16:1-50 tabi Ẹkọ 105).

S̩íṣè̩ si È̩rí-Ọkàn

Kò pẹ ti Saulu rú ẹbọ sisun naa tán, Samuẹli dé, o si beere ìdí rè̩ ti Saulu fi ṣe bẹẹ. Idáhùn Saulu jé̩ ijẹwọ ọkàn ti o ni idalẹbi: “Emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na.”

Saulu kò ronupiwada ìwà ailọwọ yii, dajudaju oun ni o si ṣe ipilẹṣè̩ awọn aigbọran rè̩ iyoku si àṣẹ Ọlọrun. Nitori Saulu kò ronupiwada, Samuẹli wi fun un pé kò hùwà ọlọgbọn ati pé ijọba rè̩ ki yoo duro pé̩, Ọlọrun yoo si wá ẹlomiran ti yoo jẹ olori awọn eniyan Rè̩, ẹni bi ti inú Ọlọrun (1 Samuẹli 13:13, 14).

Irú ifẹ ọkàn ti Saulu le ni lati ẹyin wá, lati sin Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ dabi ẹni pe o ti fi i silẹ ni akoko ìṣòro yii. Èrò buburu bẹrẹ si wá si ọkàn rè̩, o si bẹrẹ si fara hàn bi onigberaga, oniwaduwadu ati alailọwọ. Igbẹyin buburu n duro de ẹnikẹni ti o ba jẹ ki irú èrò bayii wọ ọkàn rè̩ lati maa ṣakoso rè̩ ni igbesi-ayé rè̩. Saulu wá bẹrẹ si igbesi-ayé è̩ṣè̩ ati aigbọran paraku.

Itẹsiwaju Ninu Aigbọran

Ọrọ Ọlọrun tọ Saulu wá pé ki o lọ pa gbogbo ohun alaayè run ni ilu Amaleki, i baa ṣe eniyan tabi ẹranko – lai dá ohun kan si. Saulu kó ogun jọ, o si kọlu ilu Amaleki, o pa gbogbo eniyan inú rè̩, a fi ọba, o si pa gbogbo awọn ẹranko, a fi awọn ti o sanra ni o dá si laayè.

Oluwa si fi ìwà aigbọran Saulu hàn fun Samuẹli, O si wi fun un pé, “Emi kānu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọrọ mi ṣẹ” (1 Samuẹli 15:11). Nigbà ti Saulu si pade Samuẹli, o wi fun un pé oun ti mú ọrọ Oluwa ṣẹ.

Aigbọran Saulu keji yii jé̩ ohun amọọmọ ṣe, o si ṣe e lai bikita, boya o tọ tabi kò tọ. O rọrun fun Saulu lati di è̩bi lé awọn eniyan rè̩ nitori aiṣedeedee ara rè̩, gbogbo àwáwí ti o n ṣe fun aigbọran ti o ti ṣe ni o si fi n gbe ara rè̩.

Èsi Samuẹli si àwáwí Saulu jé̩ idahùn Ọlọrun si gbogbo aigbọran amọọmọ ṣe bẹẹ, “Iṣọtẹ dabi è̩ṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi iwa buburu ati ibọriṣa”. Ọlọrun tun sọ fun Saulu lati ẹnu Wolii Samuẹli pé, “Nitoripe iwọ kọ ọrọ Oluwa, on si kọ ọ li ọba” (1 Samuẹli 15:23).

Aigbọdọ Máṣe

Orikunkun Saulu lati gbọran si Ọlọrun lẹnu fi iṣẹ buburu ti è̩ṣè̩ n ṣe ninu ọkàn Saulu hàn. Ohun ti Saulu ṣe yii le dabi ẹni pé o kéré lojú ṣugbọn abayọrisi rè̩ tobi lọpọlọpọ. “Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipọ pẹlu” (Luku 16:10). Bẹẹ ni o ri pẹlu Saulu; oun kò mọ iyì igbọran ninu ohun kikinni, lai mọ pé ọpọ ohun kékèkè ni o n di ohun nlá.

È̩kọ ìmọ ìjìnlè̩ àsìkò yii fihàn pé ọpọ aimoye awọn nnkan kékèké ni o n papọ ti o si n di nnkan nlá. Awọn ọjọgbọn tun sọ bayii pé, awọn nnkan kékèké ti o so pọ mọ ara wọn, ti olukuluku si ni ipa ti rè̩ ni ayika ti rè̩ ni o para pọ di ayé wa yii. Bi iṣẹ ọwọ Ọlọrun nlá nlà yii bá n gbọran si ilana Ẹlẹda, dajudaju eniyan ti a dá ni aworan Ọlọrun ni lati tẹriba fun ifẹ Ọlọrun bi wọn ba n fẹ ri ojú rere Rè̩.

Laaarin awọn ọmọ ogun ni ilẹ Amẹrika, ofin kan wà pé wọn ni lati kọ lati gbọran ki o to di pe wọn di ẹni ti n pàṣẹ. Eyi jé̩ ọnà miiran lati sọ ohun ti Samuẹli sọ fun Saulu pé, “Igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilè̩ si sàn jù ọra àgbo lọ” (1 Samuẹli 15:22).

Àyè kò si ni ijọba Ọlọrun fun awọn ọlọtè̩. Saulu fi ara rè̩ hàn gẹgẹ bi ọlọtè̩, abayọrisi rè̩ ni pé Samueli fa aṣọ ileke rè̩ ya ni apẹẹrẹ bi Ọlọrun yoo ṣe fa ijọba Israẹli ya mọ ọn lọwọ. Ọlọrun si fi ijọba naa fun Dafidi, ẹni bi ti inú Ọlọrun. Dafidi bu ọlá fun ofin ati àṣẹ Ọlọrun, o si pa wọn mọ bi o tilẹ gbà á ni ifararubọ ti o ga pupọ.

Ọpọlọpọ eniyan ni o kùnà lati wọ Ijọba Ọlọrun nitori orikunkun igbakuugba si Ọrọ Ọlọrun ninu ohun ti wọn ro pé kò já mọ nnkan. Ọlọrun ki i sọrọ lasan. Ohun ti O ba sọ niye lori pupọ nitori Oun ni Ọlọrun Olodumare, kò si si ẹlomiran. Nitori naa, fun eniyan lati maa foju tinrin apá kan ohun ti Ọlọrun sọ tabi ti O fihàn jé̩ titabuku si gbogbo ohun ti Ọlọrun ti sọ tabi ti O ṣe.

Ayé yii kún fún oriṣiriṣi è̩sìn, ọgbọn ayé ati ilana ti ọmọ eniyan gbekalẹ, wọn si n lo apá kan Bibeli lati fidi igbekalẹ wọn mulẹ bi otitọ. Wọn a ṣá apá kan iyoku ọrọ Ọlọrun tì, bi ohun ti kò nilaari tabi ti kò wulo fun ìgbà isisiyii. Nipa awọn eniyan bẹẹ ni Ọlọrun sọ pé, “Bi ẹnikẹni ba fi kún wọn, Ọlọrun yio fi kún awọn iyọnu ti a kọ sinu iwe yi fun u. Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọrọ iwe isọtẹlẹ yi, Ọlọrun yio si mu ipa tirè̩ kuro ninu iwe iye, ati kuro ninu ilu mimọ nì, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu iwe yi” (Ifihan 22:18, 19). (Tun wo Deuteronomi 4:1, 2).

Saulu yọ kuro ninu Ọrọ Oluwa, Ọlọrun si yọ orukọ rè̩ kuro ninu Iwe Iye, O si fi ijọba naa fun ẹlomiran. Aileronupiwada Saulu mú ọjọ ikore wá - ikore ibanujẹ - ati, ni opin rè̩, ikú lati ọwọ oun funra rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lọnà wo ni Saulu gbà kọ ṣe aigbọran si àṣẹ Ọlọrun?
  2. Ta ni yẹ ki o rubọ sísun si Oluwa?
  3. Ki ni è̩ṣè̩ aigbọran keji ti Saulu ṣè̩?
  4. Bawo ni Samuẹli ṣe mọ nipa aigbọran yii?
  5. Ki ni awọn àwáwí Saulu fun aigbọran rè̩?
  6. Ki ni Ọlọrun sọ nipa eyi?
  7. Ki ni yoo ṣẹlẹ si gbogbo awọn ti o bá ṣe aigbọran si Ọlọrun?