Lesson 208 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Gbogbo ẹmi ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ki iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ pe o mbọ, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye” (1 Johannu 4:3).Cross References
I Kristi ti Wà Latetekọṣe
1. Jesu, ọkan naa pẹlu Ọlọrun ati ọkan ninu Mẹtalọkan, jé̩ Ọmọ ayeraye ti Ọlọrun, Johannu 1:1, 2, 15; 8:58; 17:5, 11, 21, 24; Isaiah 9:6; Ifihan 22:13; 1 Johannu 1:1, 2
2. Jesu, ninu iṣọkan pípé ni ìṣe ati ni èrò pẹlu Ọlọrun Baba ati Ẹmi Mimọ, dá gbogbo agbaye, Johannu 1:3, 10; Kolosse 1:15-17; Heberu 1:1-3; 1 Kọrinti 8:6; Efesu 3:9
3. Pataki jù lọ ninu iṣé̩ iranṣẹ Rè̩ ni lati mu ìyè ti kò nipẹkun wá fun arayé, Johannu 1:4, 5; 10:10; 11:25; 14:6; Romu 5:21; 2 Timoteu 1:10; 1 Johannu 1:6; 5:12
II Jesu Kristi, Imọlẹ Ayé
1 Johannu Baptisti ni a rán gẹgẹ bi aloore lati kede bíbọ Messia, Johannu 1:6-8, 15, 19-34; Isaiah 40:3; Malaki 3:1; Matteu 3:1-17; 11:10
2 Jesu ni imọlẹ ayé, Johannu 1:9; 8:12; Isaiah 9:2; 42:6; Matteu 4:16; Luku 1:79; Efesu 5:14; 1 Johannu 1:7; 2:8; Ifihan 21:23
3 Jesu wá lati gba ẹlẹṣè̩ là ṣugbọn a kọ Ọ lati ọdọ awọn Ju ati Keferi bẹẹ gẹgẹ, Johannu 1:10, 11; 12:48; Matteu 1:21-23; Orin Dafidi 2:2-4; Iṣe Awọn Aposteli 4:27
4 Anfaani ologo yii lati jé̩ ọmọ Ọlọrun ni a fi fun gbogbo awọn ti o gba Jesu gẹgẹ bi Kristi naa, Johannu 1:12, 13, 16, 17; Romu 8:14; Galatia 4:7; Filippi 2:15; 1 Johannu 3:1
5 Jesu ni Ọrọ Ọlọrun ti O di eniyan, Johannu 1:14, 18; 1 Timoteu 3:16; 1 Johannu 5:7; Ifihan 19:13
Notes
ALAYÉ“Ta ni Jesu i ṣe?”
Fun nnkan bi ẹgbaa (2000) ọdún sẹyin, ni ibeere kékeré ti a fi ṣí è̩kọ yii ti n jade lera lera. Jesu tikara Rè̩ fi ibeere yii siwaju awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pé: “Tali awọn enia nfi emi Ọmọ-enia ipe?” Ibeere yii ṣe pataki lọpọlọpọ lati ronu le lori nitori ipò ti a o wà titi ayeraye rọ mọ idahùn wa si ibeere yii.
Bibeli ti fihàn wa kedere pé, Jesu Kristi ki i ṣe wolii kan lasan, olukọ rere kan ṣá tabi ẹni kan ṣá ti a kàn fun ni è̩bùn agbara iṣẹ iyanu. Nigbà pupọ ni a ti sọ fun ni pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe ati pé lati ipilẹṣẹ ni O ti jé̩ Ọmọ Ọlọrun. Wíwà laayè Rè̩ kò ṣẹṣẹ bẹrẹ ni ọjọ ti a bi I ni Bẹtlẹhẹmu. O bẹrẹ igbesi-ayé Rè̩ gẹgẹ bi Ọmọ eniyan ni Bẹtlẹhẹmu, ṣugbọn O ti wà gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun lati “atetekọṣe.”
Nitori naa, a mọ Oluwa wa Jesu Kristi gẹgẹ bi Ọlọrun Ọmọ. O wà pẹlu Ọlọrun Baba ati Ẹmi Mimọ ki a to dá ayé. Ọkan ninu Ọlọrun Mẹtalọkan ni Oun i ṣe. O dọgba, O si wà ni ìṣọkan pípé pẹlu Ọlọrun Baba ati Ọlọrun Ẹmi Mimọ. Gbogbo ìṣe ati ìwà Ọlọrun ti o wà ninu Ọlọrun Baba ati Ọlọrun Ẹmi Mimọ ni o wà ninu Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, ni ailoṣuwọn ati ni ẹkunrẹrẹ gẹgẹ bi a ti le ri i ninu Ọlọrun Baba ati Ẹmi Mimọ; nitori Bibeli sọ nipa Kristi pe, “ninu rè̩ ni gbogbo è̩kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara” (Kolosse 2:9).
Oriṣiriṣi àpèlé, orukọ ati apejuwe ti o jẹ mọ Kristi ni o wà ninu Ọrọ Ọlọrun. S̩ugbọn gbogbo iwọnyi ni o kùnà lati ṣapejuwe kíkún nipa titobi ati ìwà ayérayé “Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba: S̩ugbọn o bọ ogo rè̩ silẹ, o si mu awọ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia. Nigbati a si ti ri i ni iri enia, o rè̩ ara rè̩ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu.” Ẹmi Mimọ si tún sọ nipa Kristi bayii pe, “Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ: pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mā kunlẹ, …ati pe ki gbogbo ahọn ki o mā jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba” (Filippi 2:6-11).
Jesu ni Ọmọ Ọlọrun! Jesu ni Kristi - Ẹni àmì òróró, Messia! Jesu ni ireti olukuluku ẹni ti o n jijakadi lati di mimọ, lati jé̩ olododo ati lati jé̩ ẹni itẹwọgbà lọdọ Baba; nitori Oun ni Alagbawi, Arọpo ati Akọso ajinde wa ati Ọba wa ti n bọ wa!
“Ki Ni Mo Ni Fi Jesu S̩e?”
Ni akoko yii ninu ọdún, ọkàn wa kò le ṣai bojuwo ẹyin si akoko ti Kristi kọ wá si ayé yii, ni ìrè̩lè̩, sibẹ pẹlu ogo, ani ìgbà ti a bi I ni Bẹtlẹhẹmu ti a si tẹ Ẹ si ibujẹ ẹran, nitori àyè kò si fun Un ni ilé èrò. Ọpọ ninu awọn alafẹnujẹ ẹlẹsin Ọlọrun ni ọjọ wọnni, ni wọn mọ pé Kristi yoo wá ati bi yoo ṣe wá, ti wọn si ni ohun ti wọn yoo fi mọ pe bibọ Rè̩ súnmọ etile. S̩ugbọn ọgọọrọ ninu awọn wọnyii ni kò jẹwọ Jesu ni Kristi, wọn ko si gba A gẹgẹ bi Olugbala wọn.
A le fi ojú ẹmi wo ìba awọn eniyan diẹ ti o jẹwọ Rè̩ ti o si gba A ni ìgbà ìbí Rè̩. A ranti ìtàn awọn oluṣọ-agutan ti wọn gbọ orin awọn ogun ọrun ti o kede ìbí Kristi; ti wọn si lọ juba Olugbala arayé. Gbogbo wa ni o mọ ìtàn awọn amoye lati ìlà oorùn wá ati Simeoni ati Anna ti wọn n sin Ọlọrun ni Tẹmpili ati ọnà ti Ẹmi Mimọ fi tọ wọn ti O si ràn wọn lọwọ lati mọ ìwà Ọlọrun ninu Ọmọ kékeré naa, ẹni ti ẹgbẹẹgbẹrun eniyan lọkunrin lobinrin kunà lati ri laaarin gbogbo iṣẹ iranṣẹ Rè̩ laye. Awọn diẹ wọnyii ri àmì ti wọn fi mọ Ọmọ mimọ yii. Wọn kò wo O gẹgẹ bi ọmọ kan lasan. Wọn juba Rè̩ nitori wọn mọ Ọn ni Ọmọ Ọlọrun, Ireti arayé, Ẹni ti wọn ti n foju sọna fun.
Ìgbà pupọ ni irú eyi pẹlu n ṣẹlẹ lọjọ oni, ni ọnà kan. Ọpọ ni o n wá si Tẹmpili Rè̩ lati fi ara hàn lasan, lati sin ni ètè nikan, ti a kò si ri wọn ninu ẹgbé̩ awọn ọmọ-ẹyin ti o tẹle E lọ si ibi agbelebu! Ọpọ ni o si tun n tẹle E lasan ti kò rìn ni ipasẹ Rè̩! Ọpọ ni o si kùnà lati ri I gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun, nitori olukọni lasan, wolii ati ẹni rere kan ṣá ni wọn gba A si. S̩ugbọn sibẹ, “awọn oluṣọ-agutan,” “awọn amoye,” ati awọn iranṣẹ oloootọ ti a fi Ẹmi Ọlọrun tọ, wà sibẹ ti wọn ri I gẹgẹ bi Oun ti ri - Ọmọ Ọlọrun, Olugbala arayé.
“Ki ni Jesu S̩e?”
Ẹmi Mimọ, lati ẹnu Johannu Aposteli, sọ fun wa pe Jesu tọ awọn ti Rè̩ wá, ṣugbọn wọn kò gba A. Jesu wá lati gbà wa kuro lọwọ è̩ṣè̩. O wá lati wosan ati lati jí òkú dide. O wá san gbese irapada wa ati lati ṣi ọnà silẹ fun wa lati bá Ọlọrun làjà. O wá kọ wa lati wà laayè ati lati túmọ Ofin Ọlọrun fun wa ni kíkún. Gbogbo awọn ti o gba A ni O fi agbara fun lati di Ọmọ Ọlọrun ati ajumọ-jogun ibukun ayerayé pẹlu Rè̩.
Kristi wá lati fun ni ni imọlẹ. A n pe E ni “imọlẹ aiye”. Imọlẹ ti O mú wá n fun ni ni ìyè ainipẹkun ati alaafia pipe pẹlu Ọlọrun. Kò fi ohun lile kan silẹ lati ṣe ju pe ki a gba A gẹgẹ bi Olugbala, Oluwa, ati Ọba nipa igbagbọ bi ọmọ kékeré, ati didi awọn ileri Ọlọrun mú. Olukuluku eniyan ti o wà ni orilẹ ati ède kọọkan, i baa ṣe funfun tabi dudu, ọlọrọ tabi talaka, ni gbogbo ìgbà, ni o ni è̩tọ si Imọlẹ yii ati anfaani rè̩. Aanu ati òdodo Ọlọrun ti la ọnà Igbala silẹ to bẹẹ ti ẹni kọọkan le ri imọlẹ ni iwọn ti o to fun igbala rè̩, bi oun ba le gba igbala naa, ki o si rin ni Imọlẹ ti o ṣi paya fun un. S̩ugbọn nisisiyii, gẹgẹ bi akoko ti o gbé àwọ awa eniyan wọ, Jesu wá ṣugbọn wọn kò gba A, O n sọrọ, ṣugbọn wọn kò gbọ ti Rè̩; O n bẹbẹ, ṣugbọn wọn kò da A lohun; O n pè, ìgbà gbogbo ni wọn si n kọ Ọ.
“Eredi wíwá Rè̩?”
Ohun pupọ wà ninu Eto Igbala ti kò le yé eniyan ẹlẹran ara nitori ohun ti Ẹmi, Ẹmi nikan ni o n túmọ rè̩. “Ki ni ṣe ti Jesu fi wá?” jẹ ibeere ti a lè fesi nipa ṣiṣe àṣàrò lori ifẹ ailẹgbẹ, aanu, iṣeun, ati ipamọra Ọlọrun Olodumare. S̩ugbọn kò di ìgbà ti òye ìdáhùn yii bá yé wa perepere ki a to le ri igbala. Ohun ti a ni i ṣe ni ki a gbagbọ tọkàn tọkàn pé, O wá, O si san gbèsè igbala wa.
Awọn ti kò gba A gbọ, ti wọn wi pe kò wá ninu ara, awọn ti o tẹmbẹlu iṣẹ iyanu Rè̩ tabi ti wọn ṣiyemeji è̩kọ Rè̩, wà ninu awọn eniyan ti eṣu, ẹni ti a n pè ni Aṣodisi-Kristi yoo maa ṣe oluwa wọn ni ìgbà Ìpọnjú Nlá. Kò si idaduro gedegbe. A kò le dá duro gedegbe, nitori a ni lati gba Kristi gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala wa, ki a si maa rin ninu imọlẹ Rè̩, ki a si gba è̩bùn ìyè ainipẹkun Rè̩ tabi ki a kọ Ọ, ki a si wa ṣọtè̩ gbangba si I.
Awọn ti o gba A ni O fun ni iyè ainipẹkun, ati agbara lati di ọmọ Ọlọrun, ati ipá lati jé̩ alagbaṣe ninu ọgbà àjàrà Rè̩ ni inú ayé yii. Awọn ti o kọ Ọ kò ni ọnà miiran jù pe, ki wọn lo ayerayé pẹlu awọn miiran ti o kọ Kristi - awọn ẹlẹgbin, opurọ, apaniyan ati olè - ati pẹlu eṣu ati awọn angẹli rè̩.
Eto naa ti ga to! Wo bi o ti pé tó ni gbogbo iṣakoso rè̩! Wo bi anfaani rè̩ ti wà fun gbogbo eniyan! O wà lati atetekọṣe titi de opin, o si wà fun ẹni ti o ga ju lọ titi de awọn ti o rẹlẹ ju lọ ninu awọn eniyan, ati fun awọn oniwa rere ati awọn ọbayejẹ ju lọ. Eyi ṣe e ṣe nitori Jesu wá ni ìwà ìrè̩lè̩ si ayé lati gbé, lati jìyà, lati kú ati lati jinde kuro ninu òkú, ki Oun le goke re Ọrun! “Ọpé̩ ni fun Ọlọrun nitori alailesọ è̩bun rè̩” – Kristi naa - Ọrọ Ọlọrun ti o di Eniyan!
Questions
AWỌN IBEERE- Ipa igbesi-ayé Kristi wo ni o bẹrẹ nigbà ti a bi I?
- Njẹ Kristi wà ṣiwaju ìbí Rè̩ ni Bẹtlẹhẹmu? Sọ awọn ẹsẹ Bibeli ti o fi ìdí ìdáhùn rẹ mulè̩.
- Sọ awọn orukọ ti o tọka si Kristi ninu Bibeli.
- Ẹnikan ṣoṣo ha ni Mẹtalọkan tabi ju bẹẹ lọ?
- Ki ni iṣẹ pataki ti Jesu wá ṣe layé?
- Ta ni ẹni ti o wá tun ọnà Oluwa ṣe?
- Eeṣe ti a fi n pe Jesu ni “ imọlẹ aiye”?
- Irú anfaani ologo wo ni a fun gbogbo awọn ti o gba Kristi?
- Ọdọ awọn wo ni Kristi wá? njẹ wọn gba A?
- Ki ni awọn ohun iṣoro ti a fi sọnà awọn ti a n pè lati gba igbala Ọlọrun?