Deuteronomi 23:21-23; Oniwasu 5:1-7; Awọn Onidajọ 11:11, 29-35

Lesson 209 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nigbati iwọ ba jẹ ẹjé̩ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a: nitori kò ni inu-didun si aṣiwère: san eyi ti iwọ jẹjé̩” (Oniwasu 5:4).
Cross References

I È̩kọ Nipa È̩jé̩

1. È̩ṣè̩ ni kikunà lati pa è̩jé̩ mọ, Deuteronomi 23:21, 23; Numeri 30:2; Jobu 22:27; Orin Dafidi 50:14, 15; 66:13, 14

2. Ki i ṣe è̩ṣè̩ bi a kò bá jé̩ è̩jé̩, Deuteronomi 23:22

3. S̩ọra lati jé̩ è̩jé̩ wèrè lai ronu jinlẹ, Oniwasu 5:1-7

II È̩jé̩ Jefta

1. Jefta mú ọrọ rè̩ tọ Oluwa lọ, Awọn Onidajọ 11:11

2. Ẹmi Oluwa ba le e, Awọn Onidajọ 11:29

3. Jefta jé̩ è̩jé̩, Awọn Onidajọ 11:30, 31

4. Oluwa fun un ni iṣẹgun lori awọn ọtá rè̩, Awọn Onidajọ 11:32, 33

5. Jefta pinnu lati pa è̩jé̩ rè̩ mọ, Awọn Onidajọ 11:34, 35

Notes
ALAYÉ

È̩jé̩ Atọkànwá

È̩jé̩ jé̩ akanṣe ileri ọwọ ti a ṣe fun Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, nigbà ti Hanna n beere ọmọ, o jé̩ è̩jé̩ pe, “Emi o fi i fun OLUWA ni gbogbo ọjọ aiye rè̩, abẹ ki yio si kàn a lori” (1 Samuẹli 1:11). Eyi jé̩ ileri akanṣe ti a ṣe fun Oluwa ki i ṣe ifararubọ lasan pe oun ṣetan lati yọọda Samuẹli fun Oluwa bi Ọlọrun ba ni i fi ṣe. Nigbà ti a bá fi ohun gbogbo rubọ fun Ọlọrun, a ni lati fi akoko, talẹnti, tabi iṣẹ ìsìn wa fun Un nigbà ti Oun bá nilò wọn. Nigbà ti a bá jé̩ è̩jé̩, a ni lati mú gbogbo è̩jé̩ naa ṣẹ. Awọn miiran ti jé̩ è̩jé̩ lati maa lo wakati kan loojọ ninu adura gbigba, lati maa jẹri ni akoko tabi ìgbà kan, lati ṣe tabi lati má ṣe awọn ohun kan. Ileri akanṣe ni eyi, è̩jé̩ si ni, ẹni ti o bá si jé̩ è̩jé̩ ni lati mu u ṣẹ. Ki a to jé̩ è̩jé̩, a ni lati ro ohun ti yoo gbà wá, ki a ba le mọ boya a o le mú è̩jé̩ naa ṣẹ. Ohun ti kò dara ni lati jé̩ è̩jé̩ ju bi ipá wa ti mọ tabi ju eyi ti a n reti lọwọ wa, nitori è̩ṣè̩ ni lati kùnà lati san è̩jé̩.

Ni ayé isisiyii, ọwọ yẹpẹrẹ ni awọn eniyan fi mú ileri. Nigbà ti o bá wọ ni ọpọlọpọ eniyan n mú ileri wọn ṣẹ. Ìgbà pupọ ni awọn oniṣowo n ṣe ileri, ati lẹyin ìgbà ti iṣẹ naa bá pari, wọn a yẹ àdéhùn wọn. Nigbà miiran ẹlomiran a yẹ ileri rè̩ ti oun bá ri i pe, oun yoo padanu owó lori iṣẹ naa. Awimayẹhùn ni Onigbagbọ tootọ i ṣe. Nigbà ti ó bá ti ṣe ileri, Ọlọrun n fẹ ki ó mú u ṣẹ, ileri naa i baa ṣe fun Ọlọrun tabi fun arakunrin rè̩. Paapaa julọ, bi ìdè ti kò le já ni ileri ti a ṣe fun Ọlọrun. “Nigbati iwọ ba jé̩jẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o máṣe fàsẹhin lati san a: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rè̩ nitõtọ lọwọ rẹ: yio si di è̩ṣẹ si ọ lọrùn” (Deuteronomi 23:21).

Nigbà ti ẹlẹṣè̩ bá n wá igbala, yoo ṣe ileri fun Ọlọrun lati fi ayé rè̩ sin Ọlọrun. Eniyan le ṣai gbọ ipinnu yii, ṣugbọn ipinnu ni sibẹ Ọlọrun si n fé̩ ki o mú u ṣẹ. Nigbà pupọ a maa mú atunṣe lọwọ. Ọlọrun yoo gba ọrọ ẹni ti o bá ṣeleri lati mú gbogbo ohun ti o wọ bọ si títọ ni iṣe rè̩ si awọn eniyan ẹlẹgbé̩ rè̩. Nigbà miiran, ẹlomiran a ri igbala, ṣugbọn nitori aile mú ileri rè̩ ṣẹ, nigbà ti ọràn ti o ba ni lati jẹwọ rè̩ bá le, oun a si sọ ayọ iṣẹgun rè̩ nù. O ti ṣe ileri fun Ọlọrun, kò si fẹ mu u ṣẹ. Nigbà ti Ọlọrun bá fi ohun ti yoo gbà wá hàn fun wa, a ni lati san an - kò si ọnà ẹburu.

Ìgbà pupọ ni Onigbagbọ n jé̩ è̩jé̩ nigbà ipọnju tabi iyiiriwo. Wọn a jé̩ è̩jé̩ nigbà ti wọn ni ifẹ gbigbona lati tubọ ni agbara Ọlọrun ni igbesi ayé wọn. Nigbà ti a bá jé̩ è̩jé̩ ni akoko bayii, ohun danindanin ni a ni lati mu u ṣẹ lọna kan naa ti a gbọdọ gbà mú ifararubọ ti Ọlọrun beere lọwọ wa ṣẹ.

“S̩ugbọn bi iwọ ba fàsẹhin lati jé̩jẹ, ki yio di è̩ṣẹ si ọ lọrùn. Ohun ti o ba ti ète rẹ jade, ni ki iwọ ki o pamọ, ki o si ṣe; gẹgẹ bi iwọ ti jé̩jẹ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ani ọrẹ ifé̩-atinuwa, ti iwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ileri” (Deuteronomi 23:22, 23). Bi a bá ba Ọlọrun jè̩jẹ ọrẹ ifé̩-atinuwá, a ni lati san an. Ki tun ṣe tiwa mọ lati yàn lati san an tabi lati má san an, ṣugbọn ohun aigbọdọ má ṣe ni si Oluwa. Ni ọnà keji, bi a kò ba jé̩jẹ lati fi ọrẹ atinuwa fun Oluwa, a kò dẹṣè̩. “O san ki iwọ ki o má jẹ ẹjé̩, jù ki iwọ ki o jẹ ẹjé̩, ki o má san a” (Oniwasu 5:5).

Ìlérí ti a S̩e pẹlu Ikanju

A kilọ fun wa pe ki a má ṣe kanju tabi fi iwara sọrọ. “Nipa ọpọlọpọ ọrọ li āmọ ohùn aṣiwère.” Ọlọrun ràn wa lọwọ ki a má ṣe jé̩ è̩jé̩ aṣiwèrè ki a le maa ronu si ọrọ wa ki a si le sọ ọ pẹlu ọgbọn. “Nigbati iwọ ba jẹ ẹjé̩ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a: nitori kò ni inu-didun si aṣiwère: san eyi ti iwọ jẹjé̩.” Ọlọrun kò ni inu-didun si aṣiwèrè. O n fé̩ ki a san è̩jé̩, a baa fi wèrè sọ ọ tabi pẹlu ọgbọn.

Nigbà aisan tabi ipọnju, o di ọranyan fun wa lati yẹ ọkàn wa wò ati lati tun è̩jé̩ wa ati ifararubọ wa ṣe. A lè fi àyè silẹ ki a dán wa wò, ki ifararubọ wa ba le jinlẹ. Ọlọrun n pè wá si ifararubọ ti o jinlẹ ni irú ìgbà bẹẹ, ṣugbọn nigba ti a bá ti ṣẹgun tán, a ni lati ṣe bi ti Dafidi ni ìgbà laelae ti o wi pe, “Emi o san ẹjé̩ mi fun ọ, ti ète mi ti jé̩, ti ẹnu mi si ti sọ nigbati mo wà ninu ipọnju” (Orin Dafidi 66:13, 14).

È̩bè̩ Jẹfta

Jẹfta jé̩ ẹni kan ti o ni ìwúwo pupọ ninu ọkàn rè̩. A yàn án lati kó awọn eniyan Gileadi lọ soju ìjà lati bá awọn Ammoni jà. O mọ pé yoo gba agbara ti o pọ ju ti rè̩ lati ṣe alakoso awọn eniyan wọnyii ti wọn ti le e jade nigbà kan rí, ati lati ṣẹgun awọn Ammoni. “Jefta si sọ gbogbo ọrọ rè̩ niwaju OLUWA ni Mispa” (Awọn Onidajọ 11:11). O kó wahala rè̩ tọ Oluwa lọ ninu adura.

“Nigbana li ẹmi OLUWA bà lé Jefta, on si kọja Gileadi ati Manasse, o si kọja Mispa ti Gileadi o si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni” (Awọn Onidajọ 11:29). Dajudaju, o n gbá ọmọ ogun rè̩ jọ bi o ti n kọja lọ ni agbegbe wọnyii. Ohun iyanu ni ọnà ti Ẹmi Oluwa gba n bà lé awọn ọkunrin alagbara ìgbà nì lati pese wọn silẹ fun ogun jija. Lai si Ẹmi Ọlọrun, wọn ki i fé̩ lọ si ojú ìjà. O dabi apẹẹrẹ gbigba Ẹmi Mimọ, ìyàtọ ti o wà ni pé, ni ìgbà ti wa Ẹmi Ọlọrun wá lati bá wa gbé titi laelae ni. Nigbà nì, a n fi wọ ni fun iṣẹ pataki kan. Bakan naa ni o ri fun Samsoni. Ẹmi Oluwa n bà lé awọn onidajọ lati fun wọn ni ọgbọn lati ṣakoso awọn Ọmọ Israẹli.

Ìgbà Iṣoro

Nigbà ti Jefta ri i pé, oun kò le ṣai lọ si ogun, o bá Oluwa dá majẹmu. Awọn Ọmọ Israẹli wà ni ipaya, ewu si dojú kọ orilẹ-ède wọn. A pe e si ipò giga, o si n fé̩ lati ṣẹgun lọnakọna.

Nigbà ti eniyan ba mọ aini rè̩ ti o si n fé̩ iranlọwọ Ọlọrun ni gbogbo ohun ti o bá n ṣe, aini naa yoo bori ohun gbogbo ni ọkàn rè̩. Bi itara yii bá jẹ ti atọkanwá, yoo wa ilẹ jìn ni ifararubọ ati ileri rè̩ si Oluwa. Irú ipò ti Jefta wà ni eyi. O jé̩ ìgbà iṣoro. A ha lè diwọn ibi ti a lè dé pẹlu Ọlọrun nigbà ti a bá n wá ìrírí lọdọ Rè̩ - fun apẹẹrẹ, fifi Agbara Ẹmi Mimọ wọni? Gbogbo aala ati idiwọ ni a n mú kuro. A ni lati dé ibi ti a o ti lè wi pé, “Emi yoo san ohunkohun ti o bá gbà mi; emi yoo là á já, bi o ti wù ki o rí.” O ṣe danindanin lati dé gongo yii bi a bá fé̩ ri Ẹmi Mimọ gbà. O gbà pé ki a ni ifararubọ ti o jinlẹ. Jefta dé irú àyè yii gan an nigbà ti o jé̩ è̩jé̩ pataki yii fun Oluwa.

Ìdánwò Gidi

Ọlọrun yé̩ è̩jé̩ Jefta si, O si fun un ni iṣẹgun. Ìgbà naa ni ìdánwò gidi ṣè̩ṣè̩ wá dé. Bakan naa ni o maa n ri fun wa nigbakuugba: nigbà ti a bá fi ara wa rubọ, ti a si ni iṣẹgun, nigbà naa ni Ọlọrun yoo fi ìka Rè̩ lé ayé wa. Oun yoo si wi pé, “Iwọ ṣe ileri yii; tinutinu ha ni bi?” Nigbà miiran, awọn eniyan yoo bẹrẹ si lọ kókó yii. Nigbà miiran wọn a bẹrẹ si fà sẹyin ni ifararubọ wọn. S̩ugbọn eyi kò ri bẹẹ pẹlu Jẹfta. Awọn ọrọ rè̩ ni pé, “Emi ti yà ẹnu mi si Oluwa, emi kò si le pada.” Ọrọ wọnyii fi ìwà ati eniyan nlá ti Jẹfta jé̩ hàn. Awọn eniyan nlá miiran ti gba okiki ni ojú ìjà, ṣugbọn Jẹfta nihin jé̩ eniyan ti Ọlọrun lè lò ti O si lè gbẹkẹle. “Emi ti yà ẹnu mi si Oluwa, emi ko si le pada.”

Kò Sí Ipadasẹhìn

Wo irú ìpinnu ti o wà ninu ọrọ yii! Ipadasẹyìn! Rara o! “Emi ki yoo bojuwo è̩yìn.” Ìwà ọmọ ogun tootọ ni yii. Ọlọrun ri ohun kan ninu ọkunrin ologun yii, eyi ti Ọrun jẹri si. Ki i ṣe ojú ìjà nikan ni awọn eniyan ti n fi ìwà akọni hàn. Akoko ọrọ ati ọlá jé̩ ìgbà ti irú iduro wa i maa fara hàn gan an.

Jesu n wá awọn eniyan ti yoo ṣe ìpinnu lati jé̩ oloootọ dé opin, nigbà ti O wi pé, “Ko si ẹni, ti o fi ọwọ rè̩ le ohunelo itulẹ, ti o si wò ẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun” (Luku 9:62). Iwọ ha yẹ fun Ijọba naa bi! Iwọ ha ti san è̩jé̩ rẹ bi? tabi iwọ n wo è̩yìn? Eliṣa ni ipinnu lati bá Elijah rìn gbogbo ọnà naa já. Nigbà ti a rọ ọ pé, “duro nihin”, o wi pé, “Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi ki o fi ọ silẹ” (2 Awọn Ọba 2:2). Eliṣa ri agbada Elijah gbà. Agbara naa jé̩ ti rè̩! Ki ni ilepa rẹ? Njé̩ ipinnu rẹ lagbara bẹẹ bi?

Pẹlu gbogbo ọkàn ni Rutu, ara Moabu, fi bẹbẹ nigbà ti o wi pé, “Máṣe rọ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ, li emi o wọ; awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi: ibiti iwọ ba kú li emi o kú si, nibè̩ li a o si sin mi: ki OLUWA ki o ṣe bḝ si mi, ati jù bḝ lọ pẹlu, bi ohun kan bikoṣe ikú ba yà iwọ ati emi” (Rutu 1:16, 17). Ìpinnu rẹ duro bi? Njé̩ iwọ pẹlu awọn wọnyii ati gẹgẹ bi Jẹfta lè wi pé, “Emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada?”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni è̩jé̩?
  2. Ki ni n mú ki eniyan jé̩ è̩jé̩?
  3. Ta ni a fi ẹni ti kò lè san è̩jé̩ rè̩ wé?
  4. Ki ni a n pe ni è̩jé̩ aṣiwèrè?
  5. Nipa ta ni a kà ninu Majẹmu Titun ti o jé̩ è̩jé̩?
  6. Ki ni ìhà ti Jẹfta kọ si sisan è̩jé̩ rè̩?
  7. Irú ọnà wo ni a fi darukọ Jẹfta ninu Majẹmu Titun?
  8. Ọnà wo ni Ọlọrun ṣe yé̩ è̩jé̩ Jẹfta sí?