Lesson 196 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ, ẹnyin o ri gbà” (Matteu 21:22).Notes
Ọjọ Kin-in-ni Ọsè̩
Ọsè̩ ikẹyin ki a to kan Kristi mọ agbelebu dé wayii. Kò ni pẹ ti Oun yoo pada lọ si Ọrun, ti yoo si fi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ lati maa waasu Ihinrere ti Ijọba Rè̩. Laaarin ọdún mẹta ati aabọ iṣẹ iranṣẹ Rè̩, O ti sọ ọpọlọpọ ọrọ fun wọn ti yoo mú wọn jé̩ ọmọ ibilẹ rere ni Ijọba Ọrun, ṣugbọn sibẹ O ṣi ni awọn è̩kọ diẹ si i lati kọ wọn.
Ọsè̩ yii bẹrẹ pẹlu wíwọ ti Oluwa wọ Jerusalẹmu pẹlu iṣẹgun. Igbe “Hosanna fun Ọmọ Dafidi,” ati “Olubukun li Ọba ti o mbọ wá li orukọ Oluwa: alafia li ọrun, ati ogo loke ọrun” (Luku 19:38), ni o gba igboro ilu naa kan. O dabi ẹni pe ọjọ naa dé wayii ti Jesu yoo kede ara Rè̩ ni Ọba awọn Ju. Dajudaju Oludande ti wọn ti n reti lati ìgbà pipẹ yoo gba agbara nisisiyii!
S̩ugbọn bẹẹ kọ! Awọn ọmọ-ogun Romu n ba ọnà wọn lọ bi ti atijọ. Awọn ijọba ayé yii wà sibẹ, nitori Ijọba ti Rè̩ ki i ṣe ti ayé yii. O wọ Jerusalẹmu gẹgẹ bi Wolii nì ti sọtẹlẹ, “o ni irè̩lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ.”
Akoko Ajọdún Irekọja
O jé̩ akoko ajọdún Irekọja, awọn Ju si ti wá lati awọn orilẹ-ède ti o yi wọn ká, lati ṣe irubọ wọn ni Tẹmpili ni Jerusalẹmu. Gbogbo opopo ọnà kún fun awọn olusin, awọn eniyan si n gboke-gbodo ninu awọn agbala ti o yi Tẹmpili ká, wọn n murasilẹ de ọjọ isinmi ọlọwọ ti o n bọ naa.
A Tabukù si Ile Ọlọrun
Ronu nnkan ti Jesu ri nigbà ti O wọ Tẹmpili, ile Baba Rè̩, ile adura! Dipò ki wọn maa gbadura, òwò ni awọn eniyan naa n ṣe, wọn n tà, wọn si n ra ẹran fun irubọ, wọn n paarọ owó ilu okeere si ti Jerusalẹmu. Awọn oniṣòwò naa si jé̩ alaiṣootọ to bẹẹ ti Jesu fi pe wọn ni olè. Wọn ja Ọlọrun ni olè ifé̩ inu ati ifọkansin, eyi ti wọn jẹ Ọlọrun ni igbese rè̩. Wọn ni inu dídùn ninu afarawe ati afẹfẹ-yè̩yè̩ ju ninu ijọsin tootọ.
Laaarin gbogbo rudurudu yii ni Jesu wọle. Eyi jé̩ ọsè̩ ti wọn yoo kàn Án mọ agbelebu, awọn olori awọn Ju tilẹ ti n gbero bi awọn ti ṣe le mu Un. S̩ugbọn bi O ti dá nikan wọ inu Tẹmpili, kò si eniyan kan ti o fọwọ kan An. O duro niwaju wọn, o si bá wọn wi gbangba fun ọjà tita wọn. Ohùn Rè̩ bo ariwo wọn mọlẹ pé, “A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà.”
Ó bi tabili awọn onipaṣipaarọ owó yii lulè̩, owó si fọnká kaakiri ori ilẹ! Oluwa Tẹmpili ni o wà nibẹ, awọn eniyan naa si jé̩ alailagbara niwaju Rè̩. Awọn ẹyẹle ti a ṣi silẹ ninu àgò wọn si fò salọ, awọn oniṣòwò kò si lè ṣe nnkan miiran ju pe ki wọn sare tẹle wọn lọ.
Ilé Ìyìn
Tẹmpili naa ti parọrọ tó nigbà ti awọn ọlọjà alariwo ti lọ, pẹlu awọn alaròyé onibara wọn. Igbe “mu-u-u” awọn maluu dakẹ, “mẹ-ẹ-ẹ” awọn agutan si dẹkun.
Igbe ki ni a wa n gbọ? Awọn ọmọde n kọ, “Hosanna fun Ọmọ Dafidi.” Wọn n yin Jesu, Ẹni ti o wá lati gba awọn ti o ti nù là, lati di ọgbé̩ awọn onirobinujẹ, lati fi alaafia fun ọkàn ti o daamu. Ogo Ọlọrun ti sọkalẹ sinu ile Rè̩, Ọmọ Rè̩ ọwọn n wo awọn amukun ti wọn wá sọdọ Rè̩ sàn, O si n la ojú awọn afọju. Ohun ti Ọlọrun n fẹ ninu Tẹmpili Rè̩ ni yii. Ile ijọsin ni o jé̩, ile adura si ni.
O yẹ ki a kiyesara lati bu ọlá fun ile Ọlọrun! A ni lati ranti nigbà ti a bá wọ ile-isin wá, pé, niwaju Ọlọrun ni a wà, a si wá lati juba Rè̩. O n fẹ ki awọn ọmọde maa kọrin ìyìn Rè̩ gẹgẹ bi wọn ti ṣe nigbà nì ninu Tẹmpili ni Jerusalẹmu.
A Pe awọn Ọmọde
Ni akoko ti wa, a ri pé ọpọlọpọ awọn obi ni wọn ti kọ ìsìn Ọlọrun silẹ, ti wọn ki i lọ si ile Ọlọrun. Nigbà pupọ, awọn ọmọde a maa fi ọkàn wọn fun Ọlọrun ṣaaju baba ati iya wọn. Oluwa n wá awọn ti yoo jé̩ ọmọ ibilẹ Ijọba Rè̩, bi awọn agbalagba bá tilẹ kọ lati wá sọdọ Rè̩, Oun yoo pe awọn ọdọ lati sin In. Pupọ ninu wọn ni yoo gba èrè ainipẹkun ni Ọrun nitori wọn fẹran Jesu. Ni ti awọn ọmọde, O sọ pe, “Ẹ má si da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitoriti irú wọn ni ijọba ọrun” (Matteu 19:14).
Jesu fi ọmọde kan ṣe apẹẹrẹ ọmọ ibilẹ Ijọba Rè̩: “Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun. Nitorina ẹnikẹni ti o ba rè̩ ara rè̩ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio papọju ni ijọba ọrun. Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi” (Matteu 18:3-5).
Mose ti kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli lé̩sọlé̩sọ nipa kikọ awọn ọmọ wọn ni aṣẹ Ọlọrun: “Ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọrọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigba ti iwọ ba nrin li ọna, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide” (Deuteronomi 6:7). Oun kò rò pé o ti yá jù lati kọ awọn ọmọde nipa Oluwa nigbà ti wọn ṣi kere.
Nigbà ti awọn ọmọde bá gbọ ipè Ọlọrun, kò si ẹni ti o yẹ ki o wi pé wọn kere jù. O tete maa n yé awọn ọmọde bi a ṣe lè di atunbi ju awọn àgbà lọ. Ìrọrùn Ihinrere a maa fa ni mọra, ọmọde a si gbagbọ pe Jesu dariji oun nigbà ti agbalagba ba ṣi n gbiyanju lati fi ọgbọn gbé e yè̩wò.
Bi o ba ri i pe Oluwa n pe ọ, fi gbogbo ifẹ ati ijolootọ ti o wà lọkàn rẹ da A lohun. S̩e ileri igbesi-ayé rẹ fun Un nisisiyii ati titi lae. O fẹran rẹ, O si n fẹ ki ìyìn ti inú ọkàn rẹ ati ètè rẹ jade wá. “Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun” (1 Johannu 3:1).
Ìdí rè̩ ti awọn olori ninu Tẹmpili kò fi gbadùn orin awọn ọmọde naa ni pe awọn alaṣẹ naa n jowú ọlá ti a fi fun Jesu. O sọ fun awọn alufaa naa pe niwọn bi wọn ti kùnà lati yin Oun logo, ki wọn si ri i pe Oun ni Messia naa, Baba ti lo ẹnu awọn ọmọde lati kọrin ìyìn Rè̩.
Bẹẹ ni awọn olori ẹsin wọnyii kò tún fẹ gbọ idupẹ awọn eniyan ti a wò aisan wọn sàn ti a si mú bọ si ipò ilera. Awọn ti a ba pe ni iranṣẹ Ọlọrun ti o si yẹ ki wọn ran awọn eniyan lọwọ, kúkú yàn lati fé̩ gbọ ariyanjiyan awọn onipaṣiparọ owó ati ti awọn oniṣòwò agutan.
Alaileso Igi Ọpọtọ
Lowurọ ọjọ keji, nigbà ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ n pada si Jerusalẹmu lati Bẹtani, nibi ti wọn ti wà mọjú, ebi n pa A; nigbà ti O si ri igi ọpọtọ kan, O n wa eso lori rè̩ lati jẹ. S̩ugbọn kiki ewé lasan ni o ni. Eyi dun Un, O si wi fun igi naa pe, “Ki eso ki o má so lori rẹ lati oni lọ titi lailai,” igi naa si gbẹ.
Nigbà ti a ba di ọmọ Ọlọrun, a jé̩ ọgbin Rè̩, igi Rè̩. Lẹyin ìgbà diẹ yoo wá wo bi a ba n so eso. Awọn eniyan miiran le wi pe iṣẹ rere ni eso yii, ṣugbọn Paulu sọ fun ni pe iwọnyi ni awọn eso ti Ẹmi: “Ifẹ, ayọ, alafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ, ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu” (Galatia 5:22). Dajudaju, bi a bá ni eso igbagbọ ati ifẹ yii, a o ṣe ọpọlọpọ iṣẹ rere lati fihàn pe a ni in. Jakọbu Apọsteli kọ pe: “Ọgbọn ti o ti oke wá, a kọ mọ, a si ni alafia, a ni ipamọra, kì si iṣoro lati bè̩, a kún fun ānu ati fun eso rere, li aisi ègbè, ati laisi agabagebe” (Jakọbu 3:17). Eyi ni Jesu n reti lati ri lori awọn “igi” Rè̩.
Wiwẹ Igi Mọ
Bi Jesu bá dé ọdọ ọkan ninu awọn “igi ọpọtọ” Rè̩, ti O bá si ri èso diẹ, bi igbagbọ, ifẹ ati alaafia, ṣugbọn ti ìwà tútù ati ikora-ẹni-nijanu rè̩ kéré, yoo wi pé igi naa yẹ fun wíwè̩ mọ ati atunṣe. Yoo fun un ni anfaani lati so èso si i. “Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro: gbogbo ẹká ti o ba si so eso, on a wè̩ ẹ mọ, ki o le so eso si i” (Johannu 15:2). Nigbà ti Oluwa ba “n wẹ” awọn ọmọ Rè̩ mọ, a maa n ni irora; ṣugbọn ayọ ti awọn ti o ni itẹsiwaju nipa rè̩ ti ma n pọ to lọjọ iwaju! “Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin, a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ nipa rè̩, ani eso ododo” (Heberu 12:11).
Bi “igi” naa ba kọ sibẹ lati so eso, a o ké e lulẹ. Jesu pa owe kan lati fi eyi hàn: “Ọkọnrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rè̩; o si de, o nwá eso lori rè̩, kò si ri nkan. O si wi fun oluṣọgba rè̩ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu?” S̩ugbọn oluṣogba naa dahun pe, “Oluwa, jọwọ rè̩ li ọdún kan yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rè̩ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i: bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi kò ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ke e lulè̩” (Luku 13:6-9).
Ronu nipa aanu Ọlọrun lati fun wa ni anfaani miiran lẹyin ti Oun kò ri èso, tabi ti O ri iba diẹ kinun! Eyi yẹ ki o fun wa ni iṣiri lati fi ayé wa rubọ siwaju ati siwaju fun Ọlọrun ki èso rere ba le dagba ninu wa, ki a si le wu Olugbala.
Iṣé̩ Nipa Igbagbọ
Ẹnu ya awọn ọmọ-ẹyin lati ri pé igi ọpọtọ naa tètè gbẹ bẹẹ. Wọn ti ri ti Jesu ṣiṣẹ iyanu, wọn si ti gbọ nigbà ti O paṣẹ ti ìgbì lile dakẹ jé̩. S̩ugbọn ẹnu tún yà wọn si i nipa agbara Rè̩ lori awọn ohun ti a dá.
Jesu gbiyanju lati mú ki o yé awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe igbagbọ ninu Ọlọrun ni o ṣiṣẹ naa. O wi fun wọn pé bi wọn bá gba Ọlọrun gbọ, awọn naa le ṣe ohun ti Oun ti ṣe. Ohunkohun ti wọn bá beere lọwọ Baba ni orukọ Rè̩, wọn o ri i gba, bi wọn bá gbagbọ. S̩ugbọn “li aisi igbagbọ ko ṣe iṣe lati wù u” (Heberu 11:6). Nipa igbagbọ nikan ni ohun gbogbo ti a bá ṣe fun Ọlọrun lè ti fi ìdí mulẹ. Niwọn ìgbà ti o jé̩ pé, bi a bá ti ni igbagbọ tó ni Ọlọrun lè ṣiṣẹ, iṣẹ meloo ni O lè tipasẹ mi ṣe? tabi meloo ni O le tipasẹ rẹ ṣe?
Gbígbé Inú Rè̩
Jesu kò wi pé Oun o dahùn adura lati mú ifẹkufẹ ti ara wa ṣẹ. O wi pe: “Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọrọ mi ba si ngbé inu yin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fé̩, a o si ṣe e fun nyin” (Johannu 15:7). Nigbà ti a bá n gbé inú Rè̩ a o beere nnkan gẹgẹ bi Ọrọ Rè̩, a o si ni igbagbọ pe Oun yoo ṣe e. “Bi ọkàn wa kò ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun. Ati ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rè̩, nitoriti awa npa ofin rè̩ mọ, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rè̩” (1 Johannu 3:21, 22).
Igbagbọ jé̩ ọkan ninu awọn èso ti Ẹmi, a si gbọdọ ni in bi a bá n fẹ ki inú Oluwa dùn si “igi ọpọtọ” Rè̩. Bi a ti n ṣe àṣàrò ninu Ọrọ Rè̩ ni igbagbọ wa yoo maa dàgbà. “Nipa gbigbọ ni igbagbọ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọrọ Ọlọrun” (Romu 10:17). Nigbà ti a bá si lo igbagbọ ti Ọlọrun fi fun wa, yoo dàgbà, a o si gba A gbọ lori ọrọ ti o wúwo jù bẹẹ lọ.
Ni ọsè̩ ikẹyin yii Kristi gbadura fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩, pé, ki igbagbọ wọn má ṣe yè̩. Adura yii kàn wa lonii. Ki Ọlọrun jé̩ ki a maa gbé ninu Ọrọ Rè̩ ki igbagbọ wa le maa dàgbà, ki a si lè ni agbara lati ṣe iṣẹ ti O palaṣẹ fun wa lati ṣe!
Questions
AWỌN IBEERE- Orukọ wo ni a n pe ọsè̩ ti o kẹyin ṣaaju kikan Jesu mọ agbelebu?
- Ki ni ṣẹlẹ ni ọjọ kin-in-ni ọsè̩ naa?
- Nigbà ti Jesu dé Tẹmpili, ki ni O ri?
- Ki ni awọn alufaa n gbero lati ṣe si Jesu?
- Bawo ni Jesu ṣe fihàn pe è̩rù wọn kò ba Oun?
- Ki ni ṣẹlẹ ninu Tẹmpili lẹyin ti a lé gbogbo awọn ẹlẹṣè̩ jade?
- Sọ diẹ nipa bi Jesu ti fẹran awọn ọmọde tó.
- Bawo ni a ṣe lè ṣiṣẹ fun Oluwa?