Lesson 197 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Kiyesi i, ki ẹ máṣe kọ ẹniti nkilọ” (Heberu 12:25).Notes
Ọgbà Àjàrà Kan
Bi Jesu ti n kọ ni ninu Tẹmpili ni akoko ti ikú Rè̩ n súnmọ tòsí, O wi pe, “Ẹ gbọ owe miran.” Eyi ti a n kọ lonii ni a n pè ni Owe awọn Oluṣọgba Buburu. Oluṣọgba dabi àgbè̩; oun ni ẹni ti o n ro ilẹ. Ninu owe yii, awọn oluṣọgba ni awọn ti o gba agbatọjú ọgbà-àjàrà lati ṣe ìtọjú rè̩.
Ẹni ti o ni ọgbà àjàrà naa ti ṣe aayan pupọ lati pese ọgbà naa silẹ ni ọnà ti o dara jù lọ. O daju pé baale tabi ẹni ti o ni ọgbà naa ti fara balẹ ṣiṣẹ lori ilẹ naa, o si ti wá awọn irugbin ti o dara jù lọ lati gbin sinu ọgbà naa.
Gbígbìn Nnkan
A maa n gbin èso sori awọn ilẹ miiran - apẹẹrẹ kan ni alikama. S̩ugbọn awọn eehu kékèké ni a maa n gbìn sinu ọgbà àjàrà. Kò si è̩rọ àgbè̩ ti a lè fi gbin awọn àjàrà kékèké wọnyii. Ọwọ ni a ni lati fi gbin ikọọkan. Boya o le maa fi ọkàn wo aworan ọkunrin yii gẹgẹ bi o ti n fi pẹlẹpẹlẹ gbin ikọọkan ninu awọn àjàrà yii. Awọn ti gbongbò wọn ba gùn ni a gbọdọ wa ihò ti o jìn tó lati gbin wọn si. Awọn miiran ti gbòngbò wọn si kúrú ni yoo gbin sinu ihò ti kò jìn tó bẹẹ. Olukuluku ọgbìn ni yoo rọra gbin, ti yoo si ṣe ìtọjú rè̩ lọnà ti o le jé̩ iranlọwọ fun un lati dàgbà daradara. Dajudaju ẹni ti o n gbin nnkan yii fi ìdí awọn àjàrà naa mulẹ ṣinṣin, o si mú wọn duro ṣánṣán, o si fun wọn ni àyè ti o tó lati dàgbà soke. Pẹlẹpẹlẹ ni o n ṣe ìtọjú wọn, nitori bi wọn ti jé̩ alailera ki wọn má ba bàjé̩.
Ìpinnu Kan
Lẹyin ti a gbìn wọn tán, awọn àjàrà naa n fẹ ki a maa bomi rin wọn, ki wọn maa ri ounjẹ jẹ. Baale naa ni ètò kan. Fun ìdí kan pataki ni o gbin awọn àjàrà naa. O ti sa gbogbo ipá rè̩ lati fun wọn ni ipilẹ daradara. Ìtọjú rè̩ kò mọ si gbígbìn nikan. Ẹni ti o ni ọgbà naa sọgbà yi i ká, lati daabo bo o. Nigbà miiran awọn ẹranko tabi awọn eniyan ti kò bikita, a tẹ ohun ọgbìn kékèké mọlẹ, tabi ki wọn ṣé̩ wọn, tabi ki wọn tu wọn kuro. Eyi ki yoo ṣẹlẹ si awọn àjàrà rè̩, nitori o ti sọgbà yi wọn ká.
Èso
Baale naa nireti lati ri èso lara àjàrà naa, nitori eyi O pese silẹ fun ikore pẹlu. O wa ibi ifunti, o si murasilẹ de ìgbà ti a o kó èso jọ, ti a o si fún àjàrà lati inú èso. O kọ ile-iṣọ kan, boya o ṣe eyi fun irọrun olutọju ọgbà naa, ki o ba le ti ibè̩ ri gbogbo ọgbà àjàrà naa nigbà ti o ba n ṣọ ọ.
Gbogbo nnkan wọnyii ni o ti ná ẹni ti o ni ọgbà àjàrà naa ni akoko, ìtọjú, ati owó. Nigbà ti o n lọ si ilu okere, oun kò fi ọgbà àjàrà rè̩ silẹ lai ni ìtọjú, tabi lai bikita fun un. O fi ọgbà àjàrà naa ṣe agbatọjú fun awọn oluṣọgba. A mọ daju pé è̩tọ ẹni ti o ni ọgbà àjàrà yii ni lati reti èso lati inú ọgbà àjàrà yii, gẹgẹ bi èrè lori rè̩, nitori naa ni akoko ikore o rán awọn iranṣẹ rè̩ lati lọ gba èso wá ninu ọgbà rè̩.
Ohun Ti A S̩e si Awọn Ọmọ-ọdọ
Ki ni ohun ti a ṣe si awọn ọmọ-ọdọ naa? Njé̩ wọn ri eso ati owó gbà fun oluwa wọn? Rara o. Awọn oluṣọgba ti a fi ìtọjú ọgbà yii lé lọwọ lu ọkan ninu wọn, wọn sọ omiran ni okuta, wọn si pa ọkan ninu wọn. A tún rán awọn iranṣẹ miiran lati gba eyi ti o tọ si oluwa ọgbà naa, ṣugbọn gẹgẹ bi wọn ti ṣe si awọn ti iṣaaju ni wọn ṣe si wọn.
Oluwa ọgbà àjàrà naa kò ṣe aitọ rara. Oun ni o ni ọgbà àjàrà naa. A kò sọ fun wa pé o beere pé ki wọn san ohunkohun ki akoko ikore tó dé. Awọn ẹlomiran a maa beere pé ki a san owó ile tabi owó ọjà miiran, ni asan-silẹ. Awọn miiran lè beere fun owó nigbà ti èso kò i ti so. Awọn miiran a tilẹ fé̩ ki a kó èso naa wá fun wọn dipo rírán awọn iranṣẹ lati lọ gbà á wá. Kìkì ohun ti o tọ, ti o si tọnà ni oluwa ọgbà àjàrà naa beere. Awọn oluṣọgba naa ni o hùwà aitọ ati ìwà buburu.
Ọmọ Oluwa Ọgbà Àjàrà naa
Nigbà ti akoko tó, oluwa ọgbà àjàrà naa rán ọmọ rè̩ si ọgbà naa, nitori, o ni ireti pé, awọn oluṣọgba yoo bu ọlá fun ọmọ rè̩. Wọn kò ṣe bẹẹ. Nigbà ti wọn ri ọmọ rè̩ ti o n bọ, wọn dìtè̩ si i. Wọn wọ ọ jade kuro ninu ọgbà àjàrà naa bi ẹni pé ti wọn ni. Wọn pa a ki wọn ba le gba ogún ìbí ti o tọ sí i lọwọ rè̩. Wo irú ìwà buburu ti awọn eniyan wọnyii hù.
Ìjìyà
Òwe ti Jesu kọ ni nì yií. O wá beere lọwọ awọn ti o pé jọ si ọdọ Rè̩ ati awọn ti wọn n bi I lere, ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn oluṣọgba wọnyii nigbà ti ẹni ti o ni i ba dé. Awọn eniyan naa dahùn pé, yoo pa awọn oluṣọgba buburu wọnni run, yoo si fi ọgbà àjàrà rè̩ ṣe agbatọjú fun awọn oluṣọgbà miiran ti yoo maa fi èso fun un ni akoko.
Jesu ni ipinnu kan ni pipa òwe yii. Awọn olori alufaa ati awọn agbaagbà ti wọn n gbọ jé̩ awọn Ju ati ẹlẹsin pupọ. Wọn ti beere lọwọ Jesu pé, àṣẹ wo ni O ni ti O fi n kọ awọn eniyan bẹẹ. Ni òtítọ, wọn dabi awọn oluṣọgbà ti a tọka si ninu òwe yii.
Ọgbà Àjàrà Oluwa
Oluwa ni ẹni ti o ni ọgbà àjàrà yii duro fun. Ọlọrun ti gbin awọn eniyan Rè̩ gẹgẹ bi Ijọ kan ninu ayé yii. Oun ni o ni ín. O gba A ni ohun kan. Wolii Isaiah sọ fun ni nipa ọgbà àjàrà Oluwa ti a ṣe ohun gbogbo ti a ni lati ṣe sinu rè̩ (Isaiah 5:1, 2). Wolii Isaiah sọ fun ni pe awọn eniyan Ọlọrun ni “ọgbìn Oluwa” (Isaiah 61:3). Onisaamu kọ akọsilẹ nipa ọgbà àjàrà ti ọwọ Ọlọrun ti gbìn (Orin Dafidi 80:15). Jesu wi pé, “Igikigi ti Baba mi ti mbẹ li ọrun kò ba gbìn, a o fà a tú kuro” (Matteu 15:13).
Àjàrà
Oluwa ti “gbin” olukuluku Onigbagbọ. O yan wọn jade lati jé̩ Ijọ Rè̩ ati ọgbà-àjàrà Rè̩, nitori wọn jé̩ ipe Rè̩. Ọlọrun a maa fun olukuluku ni ìtọjú ati imulọkànle ti o tọ fun un. Ọlọrun ti pese ounjẹ ati ohun mímu ti ẹmi fun awọn eniyan Rè̩. Jesu wi pe, “Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ ki yio gbẹ ẹ mọ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rè̩, ti yio ma sun si iye ainipẹkun” (Johannu 4:14). Jesu wi pe: “Baba mi li o fi onjẹ otitọ nì fun nyin lati ọrun wá. Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi iye fun araiye” (Johannu 6:32, 33).
Ọlọrun a maa daabo bo awọn eniyan Rè̩. “Angẹli Oluwa yi awọn ti o bè̩ru rè̩ ká, o si gbà wọn” (Orin Dafidi 34:7). Ọlọrun ti ṣe gbogbo ìpèsè wọnyii silẹ fun awọn eniyan Rè̩. “Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro” (Johannu 15:16). “Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro” (Johannu 15:2).
Awọn Oluṣọgbà
Ọlọrun fi ofin fun awọn Ju. O bá Abrahamu dá majẹmu (Ẹkọ 8 ati 157). Lẹyin naa lori Oke Sinai, Ọlọrun bá awọn Ju dá majẹmu gẹgẹ bi orilẹ-ède. (Ẹkọ 69 ati 158). Iṣakoso awọn eniyan Ọlọrun ni a fi lé ọwọ awọn aṣaaju wọn. Iṣẹ wọn ni lati maa ṣe ìtọjú awọn eniyan Ọlọrun (awọn ti i ṣe ọgbà-àjàrà Rè̩), ki a bá le ri èso kó jọ fun Oluwa.
Awọn Iranṣẹ
Ni akoko ti o tọ, Ọlọrun fé̩ èso; O si rán awọn iranṣẹ Rè̩, awọn wolii, lati rán awọn eniyan naa leti iṣẹ wọn si Oluwa, ati lati ṣe iranlọwọ fun ikore awọn ọkàn. Awọn iranṣẹ naa - awọn wolii ìgbà Majẹmu Laelae – a maa tọ awọn eniyan sọnà, wọn a si maa bá wọn wí. Ọlọrun kò beere ohun ti kò ṣe e ṣe lọwọ wọn. O fẹ ki awọn eniyan naa kiyesi awọn Ofin wọnni, ki wọn si pa wọn mọ.
Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si awọn oloootọ iranṣẹ Ọlọrun wọnyii, awọn wolii? A lu Jeremiah (Jeremiah 37:15). O sọ asọtẹlẹ ti o bá awọn eniyan wí nitori wọn kọ lati gbọran si àṣẹ Oluwa. A sọ Sekariah, ọmọ Jehoiada alufaa, ni okuta pa nigbà ti o rán awọn eniyan naa leti pé wọn ti kọ Ọlọrun silẹ, wọn kò le ṣe rere (2 Kronika 24:20-22). “Nwọn fi awọn onṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, wọn si kẹgan ọrọ rè̩, nwọn si fi awọn woli rè̩ ṣẹsin” (2 Kronika 36:16).
Ninu Majẹmu Titun, a kà nipa Johannu Baptisti, ẹni ti Ọlọrun rán. Oun paapaa jé̩ ajẹrikú. A bé̩ ẹ lori nigbà ti o waasu ti o takò è̩ṣè̩. (Matteu 14:10).
Ọmọ Naa
Ni akoko ti o tọ, Ọlọrun rán Ọmọ bíbí Rè̩ kan ṣoṣo (Johannu 3:16). Awọn eniyan Rè̩, awọn Ju, korira Rè̩ (Johannu 15:24, 25). Wọn kọ Kristi gẹgẹ bi wọn ti kọ lati gbọ ti awọn wolii. Wọn bẹrẹ si gbìmọ si I, wọn si dìtè̩, eyi ti o yọrí si kíkan Kristi mọ agbelebu (Matteu 26:47-49; Marku 15:9-15; Matteu 27:35).
Nigbà ti awọn olori alufaa ati awọn Farisi gbọ awọn òwe ti Jesu pa yii, wọn mọ pé awọn ni O n bá wí. Jesu fihàn pé, wọn ti kọ Oun silẹ gẹgẹ bi awọn oluṣọgba ti kọ ọmọ ẹni ti o ni ọgbà nì silẹ. O tilẹ burú lati kọ Jesu, Ọmọ Ọlọrun ju lati kọ ọmọ ọlọgbà nì silẹ. Kikọ Jesu jé̩ kíkọ ìyè ainipẹkun. Jesu wi pe: “Ẹnyin kò ti kà a ninu iwemimọ pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ silẹ, on na li o si di pàtaki igun ile.” Bi o tilẹ jé̩ pé awọn Ju kọ Kristi silẹ, ètò Ọlọrun sibẹ ni pé gbogbo ilé ti ẹmi ni a gbọdọ kọ, ki a si fi ìdí rè̩ kalẹ lori Kristi ati awọn è̩kọ Rè̩, gẹgẹ bí ìpìlè̩ tootọ. Kristi ni pataki okuta igun ilé (Iṣe Awọn Aposteli 4:11; Efesu 2:20; 1 Peteru 2:6).
Awọn Keferi
Awọn olori alufaa ati awọn Farisi dá awọn oluṣọgbà wọnni lẹbi. Ọrọ awọn tikara wọn ni o dá wọn lẹjọ. A fi ọgbà àjàrà naa fun ẹlomiran. A gba Ijọba Ọlọrun kuro lọwọ awọn Ju, a si fi fun awọn Keferi. Paulu ati Barnaba sọ nipa eyi nigbà ti wọn wí pé, “Ẹnyin li o tọ ki a kọ sọ ọrọ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ si kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi” (Iṣe Awọn Aposteli 13:46).
Ọlọrun ti fi “iṣẹ agbatọju” ninu ọgbà-àjàrà Rè̩ fun wa, awa Keferi (gẹgẹ bi ẹni ti n sanwo lori ohun ti ó yá, ki i ṣe gẹgẹ bi ẹni ti a fi tọrẹ fun), O si n reti lati ri èso rere ninu igbesi-ayé wa. Bi Kristi bá wá wo èso ninu igbesi-ayé rẹ lonii, ki ni yoo bá nibẹ? Yoo ha jé̩ èso oróro ìgbé̩, kékeré, kíkan, ti kò nilaari rara - èso ti ara? Tabi Kristi yoo ha ri èso ti Ẹmi – eyi ti o ṣe itẹwọgbà, ti o wulò, ti ibukun Oluwa wà lori rẹ? (Ka Galatia 5:19-23; Efesu 5:3-9). Awọn eniyan Ọlọrun a maa gbé igbesi-ayé aileeri, mímọ, ti o si kún fun iṣẹ fun Un. “Eso wọn li ẹnyin o fi mọ wọn” (Matteu 7:16).
Boya gbogbo eniyan ni yoo dá awọn oluṣọgbà wọnni lẹbi fun irú ìwà ti wọn hù si ọmọ ọlọgbà naa, ati awọn iranṣẹ rè̩. Dajudaju gbogbo eniyan yoo dá awọn Ju lẹbi fun kíkọ Kristi ati kikan An mọ agbelebu. È̩tọ ni lati dá wọn lẹbi fun ìwà buburu bẹẹ. S̩ugbọn ẹ jé̩ ki a yẹ ara wa wò, awa Keferi. Ọpọlọpọ awọn Keferi paapaa ni o ṣe alaibikita fun Kristi, wọn kọ Ọ silẹ, wọn si n ké̩gàn Rè̩ ati awọn eniyan Rè̩. Akoko n bọ ti ìlè̩kùn igbala yoo ti fun awọn Keferi. Ki yoo tún si anfaani lati ri idariji gbà fun wọn mọ. Akoko awọn Keferi yoo kún (Luku 21:24). Ẹ jé̩ ki olukuluku yẹ ara rè̩ wò. Njé̩ aibikita fun Kristi, kikọ Ọ silẹ, ati titi I jade ha wà ninu igbesi-ayé rẹ? Tabi o ti pese àyè silẹ fun Un, o si ti ṣilẹkun ọkàn rẹ silẹ fun Un lati wọle?
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Jesu fi kọ ni ni òwe yii?
- Ta ni ẹni ti i ṣe oluwa ọgbà-àjàrà naa?
- Ki ni ohun ti o ṣe ninu rè̩?
- Ki ni ṣe ti a hùwà buburu si awọn iranṣẹ rè̩?
- Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si ọmọ rè̩?
- Ki ni ṣe ti a fi ọgbà-àjàrà naa ṣe agbatọjú fun awọn ẹlomiran?
- Ki ni ohun ti òwe yii fihàn fun awọn Ju?
- Ki ni è̩kọ ti a ri kọ ninu òwe yii?