Matteu 22:1-14

Lesson 198 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kiyesi i, mo duro li ẹnu ilẹkun, mo si nkànkun” (Ifihan 3:20).
Notes

Ipe si Ibi Igbeyawo

Ogunlọgọ ọkunrin, obinrin ati ọmọde ni wọn yi Jesu ká, ti wọn si n gbọ awọn ìtàn ti O n sọ. Wọn larinrin, a si sọ wọn ni ède ti o rọrun tó bẹẹ ti òye wọn lè fi yé awọn ọmọde. Siwaju si i, wọn kọ ni ni è̩kọ nipa Ijọba Ọrun. Ìtàn wọnyii ni a pè ni òwe.

Ni àkókò kan, Jesu sọ nipa ọba kan ti o lọrọ pupọ, ẹni ti ọmọkunrin rè̩ si n fé̩ gbéyàwó. Oun jé̩ ọba rere ti o fẹran awọn eniyan rè̩, o si fẹ ki gbogbo wọn wá lati gbadùn igbeyawo naa ati àsè nlá ti yoo tẹlẹ e.

Iwọ lè rò pé gbogbo eniyan ni yoo poungbẹ lati wá si ibi igbeyawo ọmọ-ọba ọkunrin ati ọmọ-ọba obinrin, ati lati ri bí inú aafin ti rí. Si ronu gbogbo ounjẹ àdídùn ti wọn i bá jẹ! Awọn ti n lọ si irú igbeyawo awọn ọlọlá bẹẹ lode òní lè ti maa fi owó pamọ fun ìgbà pípé̩, ki wọn ba lè wọ aṣọ ti o gbayì jù lọ ni ọjọ naa; wọn a si gbiyanju gidigidi lati mú è̩bùn igbeyawo ti o dara jù lọ ti o si wu ni jù lọ wá fún tọkọtaya ọjọ naa.

S̩ugbọn awọn eniyan ti Jesu sọ nipa rè̩ kò fé̩ lọ si ibi igbeyawo nlá yii. Ọba rán awọn ọmọ-ọdọ rè̩ lọ si ilé awọn ara ìlú naa lati mú ìwé ìpè lé wọn lọwọ - sibẹ awọn eniyan naa kò fi pè. Awọn kan lọ si oko wọn lati ṣiṣẹ, dípò ki wọn gba isinmi ti ọba ti fún wọn. Awọn miiran lọ si ọjà lati ra nnkan. Ọwọ olukuluku dí tó bẹẹ ti wọn kò fi rí àyè lati lọ si aafin ọba fun àpèjẹ nlá naa.

Ọba naa rò pé o ni lati jé̩ pé àṣìṣe kan wà nibi kan. Boya wọn kò mọ wákàtí àpèjẹ naa ni. Nitori bẹẹ, o tún rán awọn ọmọ-ọdọ rè̩ jade lati sọ fun wọn pé àsè naa ti ṣetán, a ti pa awọn maluu ati ẹran àbọpa, awọn ẹran ayangbẹ banti-banti si ti dé ori tábìlì. Sibẹ awọn eniyan naa kọ lati wá. Ninu wọn tilẹ pa awọn iranṣẹ ti o mú ihinrere naa wá fun wọn. Njé̩ kò ṣoro lati wòye bi eniyan ṣe lè hùwà bayii? Bi o bá jé̩ iwọ ni a pé si irú igbeyawo bayii, dajudaju iwọ yoo fẹ lati lọ; inú rẹ tilẹ lè dùn tó bẹẹ ti o kò ni lè sùn mọjú ọjọ naa.

Àsè Ọlọrun

A sọ pé òwe jé̩ ìtàn nipa nnkan ayé, eyi ti o ni itumọ nipa ohun ti Ọrun. Ẹ jé̩ ki a wo ẹni ti ọba ti o fẹ ṣe awọn eniyan rè̩ loore yii duro fun. Ẹni naa ni Ọlọrun Baba, ti O ni gbogbo agbara ni Ọrun ati ni ayé ni ikawọ, Ẹni ti awọn ẹran ti o wà ni ẹgbẹẹgbẹrun òkè si i ṣe ti Rè̩. Kìkì ire nikan ni O n fẹ ṣe fun awọn eniyan Rè̩, nitori O fẹran wọn pupọ.

Olukuluku eniyan ni a nawọ ìpè si fun àsè Ihinrere; kò si ẹni ti o yẹ ki o kùnà rè̩. S̩ugbọn awọn eniyan a maa ṣe àwáwí gẹgẹ bi wọn ti ṣe ninu òwe ti Jesu pa. Ọwọ wọn dí nitori wọn n ṣiṣẹ fun ara wọn - wọn n làkàkà lati ni ọrọ, tabi lati gbadùn afé̩ ayé - wọn kò ri àyè lati jé̩ ìpè Oluwa lati ni ìgbàlà.

Awọn Ju S̩áájú

Ìpè àkọkọ ti o jade, wà fun awọn Ju ni pàtàkì. Awọn ni àyànfé̩ eniyan Ọlọrun, O si fun wọn ni anfaani ipò kin-in-ni. S̩ugbọn nigbà pupọ ni wọn yipada kúrò lọdọ Ọlọrun ti wọn si sin òrìṣà dipo Rè̩. Wọn kò jé̩ feti si awọn wolii ti wọn mú ìpè Ọlọrun tọ wọn wá. Ọlọrun rán awọn wolii si awọn ìran miiran siwaju si i, O si wí pé: “Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọna buburu rè̩, … ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bḝni ẹnyin kò si gbọ temi” (Jeremiah 35:15). Ani, wọn tilẹ sọ okuta lu awọn wolii naa fun ìpè ifẹ ti wọn pè wọn.

Nigbà ti Jesu wà ni ayé, O tún fun awọn Ju ni anfaani miiran; O nawọ ìpè miiran si wọn. Lẹẹkan si i wọn kọ. O kilọ fun wọn pé wọn jé̩ alaiyẹ lati gbadùn anfaani awọn ibukun Rè̩, ati pé awọn ọmuti ati eniyan buburu i ba yọ lati wá si àsè naa.

Ìdájọ

Ọba inú ìtàn ti Jesu n sọ yii ní gbogbo agbara lori awọn ti o n jọba lé lori, inú si bi i pupọ si wọn, nitori gbogbo wọn ni wọn ti kọ lati wá, tó bẹẹ ti o fi rán awọn ẹgbé̩ ogun lati pa wọn run. O si sọ fun awọn iranṣẹ rè̩ lati jade lọ si ìgboro ìlú naa, ati si awọn òpópó ọnà, ki wọn si pe gbogbo awọn alejò wá si aafin rè̩. O wí pé awọn eniyan oun kò yẹ lati jokoo ni tabili oun, nitori naa oun o pé awọn eniyan ti yoo le mọ rírì iṣeun rè̩. Nigbà naa ni eniyan pupọ wá si aafin naa. Òmíràn jé̩ ẹni rere, awọn miiran si jé̩ eniyan buburu, ṣugbọn gbogbo wọn ni ọba té̩wọgbà.

Nigbà ti awọn Ju kan Jesu mọ agbelebu, a fun awọn Keferi ni ọtọtọ ojurere. Ọkẹ aimoye awọn Ju ni o jiya idajọ bi ti irú awọn ti a parún ninu ìtàn ti Oluwa sọ. Iye awọn Ju ti o kú ninu iparun Jerusalẹmu ni A.D. 70 (aadọrin ọdún lẹyin ti a bi Jesu) ju aadọta ọkẹ (1,000,000) lọ ọpọlọpọ ni wọn si tun n jiya si i titi di oni yii. Ninu Ogun Ajakaye Keji, awọn ti a pa ju ọọdunrun ọkẹ (6,000,000) lọ, ìdí rè̩ kò si ju pé wọn jé̩ Ju. Awọn Ju ti kọ ìpè Ọlọrun, wọn si pa awọn iranṣẹ ti o mú ìpè naa wá, leke gbogbo rè̩, wọn kan Jesu tikara Rè̩ mọ agbelebu.

Aṣọ Igbeyawo

Ọrọ pọ si i ninu ìtàn ti Jesu sọ. Gbogbo awọn èrò pupọ ti o wá ni ọba naa ti tẹwọgbà; ṣugbọn nigbà ti o yẹ awọn àlejò rè̩ wò, o ri i pé ọkunrin kan ti jé̩ alaibikita nipa ìwọṣọ rè̩. Kò wọ aṣọ iyawo ti ọba ti pèsè silẹ, ìrísí rè̩ kò si bá ibi ti o wà mu rárá. Ọkunrin yii kò ṣe ọmọluwabi tó lati yé̩ àṣà aafin naa si.

Oninuure ni ọba naa, o si pe àlejò naa ni “Ọré̩,” o si beere èrèdí rè̩ ti kò fi wọ aṣọ iyawo. Boya bi o bá jé̩ pé ọkunrin yii ni àlàyé rere kan ni, ọba i bá fun un ni àyè lati lọ wọṣọ. S̩ugbọn ọkunrin naa kò ni àlàyé. Aibikitia ọkunrin yii ni o fa a, kò si ri nnkan kan wí. O ti kùnà lati gbọran si àṣẹ ọba, nitori bẹẹ o ni lati jìyà fun un. Ọba pé awọn iranṣẹ rè̩ lati gbe e jade ki wọn si sọ ọ sinu ọgbun okunkun nibi ti ẹkún ati ipayinkeke gbé wà.

Ìpè Ihinrere n jade lọ bayii. Gbogbo wa ni a pè; gbogbo wa ni anfaani wà fun lati gbadùn awọn ibukun ti Ijọba Ọrun. S̩ugbọn a ni lati mura silẹ de e. Ọlọrun n pese “aṣọ iyawo” fun ẹni kọọkan wa – “aṣọ ododo,” “aṣọ ọgbọ” ti awọn eniyan mimọ. Awọn wọnyii jé̩ ọrọ ti a fi n ṣapejuwe ipò Onigbagbọ otitọ nipa ti ẹmi. Lakọkọ a gbọdọ dari è̩ṣè̩ rè̩ ji i. Lẹyin naa a ni lati wẹ ẹ mọ, ki a sọ ọ di mimọ, ki a fi awọn oore-ọfẹ Onigbagbọ ṣe e lọṣọ. Lẹyin naa ni o ṣetan lati ni ifiwọni Ẹmi Mimọ, ki o si ri agbara gbà lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun. Nigbà ti o bá lo awọn ohun ti Ọlọrun ti fi fun un, lati fi ṣiṣẹ fun Jesu, o wọ aṣọ iyawo, o si ṣetan lati lọ si Àsè-Alé̩ Igbeyawo ti Ọmọ Ọlọrun, eyi ti awa pẹlu ti gbọ nipa rè̩. “Ẹniti o ba ṣẹgun, on na li a o fi aṣọ funfun wọ; emi ki yio pa orukọ rè̩ ré̩ kuro ninu iwe ìye, ṣugbọn emi o jẹwọ rè̩ niwaju Baba mi, ati niwaju awọn angẹli rè̩” (Ifihan 3:5).

A ti pesè ohun gbogbo silẹ fun wa, a kò si ni ri àwáwí wí ti a kò bá ṣetan nigbà ti Jesu bá pè wa. Kò yẹ ki a jé̩ ki ohunkohun dí wa lọwọ lati ṣe imurasilẹ ti yoo ṣi Ilẹkun Aafin silẹ fun wa, nigbà ti a bá kede Àsè-Alé̩ Igbeyawo Ọdọ-Agutan. Èrò ti o yẹ ki o maa leke ọkàn wa lojoojumọ ni eyi, “Bi ipè bá dún lonii, mo ṣetan lati lọ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Awọn wo ni a kọ fi ìwé ìpè si àsè igbeyawo naa ṣọwọ si?
  2. Ki ni ṣe ti wọn kò fi yẹ?
  3. Awọn wo ni a pè nikẹyin?
  4. Fi awọn eniyan inú ìtàn naa wé awọn orilẹ-ède agbayé.
  5. Kin ni a ni lati ṣe lati wà ni imurasilẹ fun Igbeyawo naa?
  6. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti wọn bá n fẹ ṣe àwáwí?
  7. Nigbà wo ni a le maa reti ìpè fun Igbeyawo naa?