Rutu 1:8, 14-22

Lesson 199 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, OLUWA; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ” (Orin Dafidi 86:9).
Notes

Ìyàn

Ni ọjọ pupọ sẹyin, ni akoko ti awọn onidajọ n ṣe akoso Israẹli, ìyàn kan dé si agbegbe kan ni ilè̩ Juda. Ohun-ọgbìn kò ṣe deede rárá, awọn eniyan kò si ni ounjẹ tó lati jẹ. Ọpọ ounjẹ wà ni ilè̩ miiran, nitori naa awọn miiran jade kuro ni ilẹ wọn, wọn si lọ si ibi ti wọn o gbé ri ọpọlọpọ ohun ti wọn n fẹ fun awọn ẹbí wọn.

Ọkan ninu awọn irú ẹbí bẹẹ ni ti Elimeleki ati Naomi, awọn ti wọn lọ pẹlu awọn ọmọkunrin meji lati maa gbé ni ilè̩ Moabu. S̩ugbọn ohun gbogbo kò lọ deede fun awọn ẹbí yii. Ni àkọkọ, baale ile naa kú; lai pẹ jọjọ lẹyin naa awọn ọmọkunrin mejeeji kú. Awọn ọmọkunrin wọnyii ti fẹ awọn ọmọbinrin Moabu; Naomi nikan ni o kù silẹ pẹlu awọn aya ọmọ rè̩ ni ilè̩ àjèjì yii, ki i ṣe ilè̩ Israẹli ti awọn eniyan rè̩ n gbé.

Ọkàn Rè̩ N Fà si Ilé

Inú Naomi bàjé̩ pupọ. Boya o rò pé gbogbo wahala wọnyii dé bá oun nitori oun ti fi ilè̩ Israẹli silẹ, ilè̩ ti Ọlọrun ti fi fun awọn eniyan Rè̩ ti O yàn, oun si ti lọ gbé laaarin awọn Keferi ara Moabu ti wọn n sin òrìṣà. Nisisiyii ti ọkọ rè̩ ati awọn ọmọ rè̩ ti ṣe aisi, kò tún si ẹni ti òye è̩sìn Ọlọrun rè̩ yé nibẹ mọ, o si dajú pé yoo mọ ipò àdáwà yii lara pupọ.

Òye ipo àdáwà ti Naomi wà yii lè yé wa. Boya awọn miiran laaarin wa ti gbé laaarin awọn ẹlẹṣè̩ fun ìgbà diẹ, eyi si ti mú ki ọkàn wa wúwo ninu wa nitori wọn kò fẹ lati sọrọ nipa Jesu. Laaarin àkokò yii, a lè pade ẹni kan ti o jé̩ Onigbagbọ loju ọnà - o tilẹ lè jé̩ ẹni ti a kò mọ tẹlẹ ri – o si dabi ẹni pé ọré̩ ti o ṣọwọn fun wa jù lọ ni a pade bayii. Irẹpọ awọn ọmọ Ọlọrun ṣe ọwọn pupọ fun Onigbagbọ, ju aṣepọ oun pẹlu awọn ẹbí rè̩ ti ki i ṣe Onigbagbọ lọ.

Onisaamu kọ akọsilẹ yii: “Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bè̩ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ rẹ mọ” (Orin Dafidi 119:63). Ọrọ Ọlọrun si paṣẹ fun wa pé, ki a má ṣe gbagbe ipejọpọ ara wa lati jọsin (Heberu 10:25).

Ìpinnu

Naomi pinnu pé, akoko tó fun oun lati pada sọdọ awọn eniyan ti rè̩. Boya Ọlọrun yoo bukun un sibẹ bi o ti n darugbo lọ yii ni ilẹ ibilẹ rè̩. Orpa ati Rutu, awọn iyawo awọn ọmọ rè̩ ba a de agbegbe ipinlẹ Moabu, nigbà ti o bẹrẹ ìrìn-àjò rè̩ pada si ilé. Wọn fẹran rè̩ pupọ, èrò pipinya pẹlu rè̩ si mú ki wọn sọkún. Wọn bẹ Naomi pé, ki o jé̩ ki awọn ba a pada si Bẹtlẹhẹmu-Juda.

Naomi n fẹ ki awọn ọmọbinrin wọnyii mọ ohun ti ìpinnu wọn yoo jasi fun wọn. Bi wọn bá pada si ilé awọn òbí wọn, dajudaju, wọn o tun fé̩ ọkọ, wọn o si tọ awọn ọmọ wọn gẹgẹ bi àṣà ilè̩ awọn ara Moabu, wọn o si maa sin òrìṣà ilè̩ naa. Bi wọn bá bá Naomi lọ, wọn yoo la iṣoro kọja, nitori Naomi jé̩ alaini, kò si ni ohun ti o lè fi fun wọn. Wọn o si wà laaarin awọn àjèjì eniyan ti àṣà wọn si yàtọ. Ju gbogbo rè̩ lọ, wọn o wà laaarin awọn eniyan ti wọn n sin Ọlọrun otitọ. Wọn n fẹ lati lọ sibẹ bi? Bi wọn bá lọ, o lè jé̩ pé wọn ki yoo tún pada si Moabu mọ.

Nigbà ti Orpa gbọ nipa irú igbesi-ayé miiran ti o ni lati lọ gbé ni ilẹ Juda, o pinnu lati pada sọdọ awọn eniyan rè̩ ati sọdọ awọn òrìṣà rè̩: bẹẹ ni a kò tún gbọ nipa rè̩ mọ. S̩ugbọn ẹmi ti o yatọ wà ninu Rutu.

Ìrètí Ayérayé

Rutu ti rí ohun kan ninu ìgbésí-ayé Naomi ti o ti mú un lọkàn. Ó lè wò rékọjá gbogbo ìṣòro ayé yii, rékọjá awọn eniyan wọnni ati iṣe wọn ti yoo jé̩ àjèjì si i. O rí Naomi gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, ti o ni ìrètí ìyè ainipẹkun. O dajú pe irú igbagbọ ti o wà ninu Abrahamu ni o wà ninu ọkàn rè̩, ẹni ti o mọ pé atipo ni oun ni ayé yii, ti o n gbé inú agọ, ṣugbọn o n wo ìlú ayérayé kan “ti o ni ipilè̩; eyiti Ọlọrun tè̩do ti o si kọ” (Heberu 11:10). Ohun ti o ṣe pataki jù lọ fun un ní ìgbésí-ayé rè̩ ni ìrètí lati lọ si ìlú Ọlọrun, Jerusalẹmu Titun.

Lati Ilè̩ Gbogbo

Awọn Ọmọ Israẹli, awọn ọmọ Abrahamu, jé̩ awọn eniyan ti Ọlọrun yàn. O ti fun wọn ni ọtọtọ ibukun, O si ti fi ìtọjú ati iṣé̩ ti ìsìn òtítọ lé wọn lọwọ. Eyi yii ki i ṣe pé kiki awon Ọmọ Israẹli nikan ni a lè gbàlà. A mí si Onisaamu lati kọ akọsilẹ yii: “Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa” (Orin Dafidi 86:9).

Rutu jé̩ ará ilè̩ Moabu, ki i ṣe Ọmọ Israẹli; ṣugbọn nigbà ti oungbẹ n gbẹ é̩ fun è̩sìn tootọ, ti o si n fé̩ lati sin Ọlọrun kan ṣoṣo ti i ṣe Ọlọrun tootọ, O bojuwo o, O si gba a gẹgẹ bi ọmọ Rè̩. Adura ti Rutu gbà nigbà ti o n fé̩ bá iya ọkọ rè̩ lọ ni yii: “Máṣe rọ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibi ti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ, li emi o wọ: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi.”

Ninu awọn ọrọ wọnyii, Rutu kọ ìgbésí-ayé rè̩ àtijọ silẹ ati ohun gbogbo ti o ti mọ. Ìgbésí-ayé titun ni eyi ti o wà ni iwaju rè̩ yii, ọjọ iwaju ti kò mọ bi yoo ti rí, ṣugbọn o ni igbagbọ ninu Ọlọrun ti Naomi n sìn pé yoo ṣe ìtọjú oun. O ṣe ohun ti olukuluku ẹlẹṣè̩ ti o ronupiwada ni lati ṣe, ki o tó lè rí igbala. Eniyan ni lati kọ awọn è̩ṣè̩ rè̩ silè̩, ki o kọ wọn silẹ titi laelae, ki o si yipada si Ọlọrun pẹlu ìlérí lati gbé ìgbésí-ayé rè̩ fun Ọlọrun gẹgẹ bi Ọrọ Rè̩ ti pàṣẹ. O ni lati fi awọn ìlépa ti o lodi si ifẹ Ọlọrun silẹ. Ẹnikẹni ti o bá bè̩rè̩ si i rin bayii lè ni idaniloju pé Ọlọrun yoo fi ọwọ ifẹ Rè̩ ṣe ìtọjú rè̩.

Awọn Aṣẹgun Kíkún

Nigbà ti Jesu bá pada wá si ayé yii lati wá mú Iyawo Rè̩ lọ, Oun yoo gba awọn ti o ti kọ gbogbo ohun ayé yii silẹ lati tẹle E. Gbogbo ifẹ inú Iyawo ni lati wu Ọkọ rè̩. Awọn ti yoo jé̩ Iyawo Kristi ni awọn ti wọn n fi tọkàntọkàn yọọda ohunkohun ti Ọlọrun n fẹ lọwọ wọn fun Un; wọn a maa gbàgbe ilé baba wọn, awọn eniyan wọn, lati lọ ṣiṣẹ ninu ọgbà ìkórè Oluwa.

Ọlọrun n sọrọ nipa Iyawo Ọdọ-Agutan nigbà ti O wi pé “Dẹti silẹ, ọmọbirin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ! Bḝli Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sin i” (Orin Dafidi 45:10, 11).

P

aulu Apọsteli jé̩ ki a mọ diẹ ninu ohun ti ifararubọ yii jé̩, nigbà ti o wi pé: “Nitorina mo fi iyọnu Ọlọrun bè̩ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ āye, mimọ, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isin nyin ti o tọna” (Romu 12:1). Paulu fihàn pé, o ṣe e ṣe. O wi pé: “Mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ imọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbé̩, ki emi ki o le jère Kristi” (Filippi 3:8). Kò si ohun miiran ni ayé yii ti o já mọ nnkan kan fun un jù pé ki o wu Jesu, ki o si wà ni imurasilẹ lati dé ibi ajinde kin-in-ni.

Pipada Sẹhin

Orpa jé̩ aworan awọn eniyan ti wọn ri ẹwà Ihinrere, ti wọn si bè̩rè̩ lati tẹle Jesu. S̩ugbọn nigbà ti ọnà naa ṣoro, ti wọn si ri i pe agbelebu wà fun wọn lati rù, wọn pada si ìgbésí-ayé wọn àtijọ. Wọn kò le wò rekọja awọn idanwo lati ri èrè ti Jesu n fihàn awọn ti o bá ṣẹgun.

Jesu wí fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pé: “Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye (Johannu 16:33). Nigbà ti Jesu bá si dé sinu ọkàn wa, a maa n ni agbara lati ṣẹgun. “Ẹnyin ọmọ mi, ti Ọlọrun li ẹnyin, ẹnyin si ti ṣẹgun wọn: nitori ẹniti mbẹ ninu nyin tobi jù ẹniti mbẹ ninu aiye lọ” (1 Johannu 4:4).

Èrè

Ìṣísè̩ nlá ni Rutu gbé nigbà ti o kọ ilé ati awọn eniyan rè̩ silẹ lati maa bá awọn Ọmọ Israẹli gbé, ati lati maa sin Ọlọrun wọn. O fi gbogbo rè̩ silẹ lati tẹle Oluwa. Jesu ṣeleri pé: “Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakọnrin, tabi arabirin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọrọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun” (Matteu 19:29).

Ọlọrun bè̩rè̩ si pèsè fun Rutu nipa fifun oun ati Naomi ni ounjẹ ni gẹrẹ ti wọn pada dé ilé. Kò pé̩ pupọ ki Rutu tó fé̩ Boasi, ọkunrin ọlọrọ kan ni Juda, eyi ti o si sọ ọ di ẹni kan ni ìdílé ọba, ninu eyi ti a ti bi Jesu. Rahabu, obinrin miiran ti o jé̩ Keferi ti ati kọ è̩kọ nipa rè̩ ni iya Boasi, Rutu ati Boasi si ni iya ati baba ti ó bi baba Dafidi àgbà.

Anfaani kan naa ni a gbé ka iwaju Rutu ati Orpa. Awọn mejeeji ni o lè wá lati sin Ọlọrun otitọ. Orpa pada sọdọ awọn òrìṣà rè̩, a kò si tún gbọ ohunkohun nipa rè̩ mọ. Rutu sọ fun Naomi pé, “Awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi.” Kiyesi ọlá ti o bọ si! A fi orukọ rè̩ pe ìwé kan ninu Bibeli; oun ti i ṣe obinrin Keferi gba ipò ọlá nlá ti o tayọ, eyi ti olukuluku obinrin ni Israẹli n fé̩, eyi yii ni lati jé̩ ọkan ninu ìdílé ti a ti bí Messia Israẹli.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Elimeleki ati ẹbí rè̩ fi Juda sílè̩?
  2. Bawo ni wọn ṣe fi ìdí ara wọn kalè̩ ni ìlú ti wọn lọ?
  3. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si Elimeleki ati awọn ọmọkunrin rè̩ mejeeji?
  4. Ki ni Naomi pinnu lati ṣe?
  5. S̩e apejuwe pipinya Naomi ati awọn iyawo awọn ọmọ rè̩.
  6. Bawo ni Naomi ṣe mọ pé Ọlọrun yoo tẹwọgba Rutu?
  7. S̩e àlàyé ohun ti ìpinnu Rutu jé̩ fun un?