1 Samuẹli 2:1-10; 3:1-21

Lesson 200 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA pe Samueli: on si dahun pe, Emi nĩ.” (1 Samuẹli 3:4).
Notes

Ìyìn fun Adura ti a Dahùn

Adura Hanna jé̩ orin idupé̩. Ọkàn rè̩ kún fun ọpẹ si Ọlọrun nitori pé O ti dáhùn adura rè̩. Nigbà kan, ṣiwaju akoko yii, o ti bá ọkọ rè̩ lọ sí S̩ilo “lati sìn ati lati ṣe irubọ si OLUWA awọn ọmọ-ogun.” Hanna ti n ṣafẹri ohun kan ti o ṣe iyebiye, ti o si ṣọwọn fun ọkàn rè̩ lati fi fun Oluwa. Kò ni ọmọ, ṣugbọn ó gbadura pé ki Ọlọrun fun oun ní ọmọkunrin kan. Oun naa ṣe ìlérí pé oun yoo ya ọmọ naa sọtọ fun Oluwa ati ìsìn Rè̩. Bi o ti n sọkún ti o si n fi ara rè̩ rubọ niwaju Oluwa, ó gbadura lati odò ọkàn rè̩ wá. “Kiki etè rè̩ li o nmì, ṣugbọn a kò gbọ ohùn rè̩.”

A Yà a Sọtọ fun Ọlọrun

Ni ìdáhùn si adura naa, Ọlọrun fun Hanna ni ọmọkunrin kan, ti ó pe orukọ rè̩ ni Samuẹli. Nigbà ti ó ṣi wà ni ọmọde, iya rè̩ mu un lọ si ilé Oluwa ni S̩ilo. Ki o baa le san è̩jé̩ rè̩, ó mú ọmọkunrin rè̩ - ọmọ rè̩ kanṣoṣo ni akoko naa – lati yà a sọtọ fun Ọlọrun. Eli ni o n ṣe akoso ilé Oluwa nigbà naa. Hanna fi Samuẹli silẹ lọdọ rè̩, ki ọmọ naa bá le kọ ọnà Oluwa, ki o si le maa ṣe iranṣẹ fun Un.

Ìyìn fún Olufunni

Orin Hanna jé̩ adura ọkàn rè̩ nigbà ti a ya Samuẹli sọtọ. O n yọ, inú rè̩ si dùn nitori ohun nlá ti Ọlọrun ti ṣe fun un. Bawo ni adura awọn miiran ti yàtọ tó, nigbà ti wọn maa n fẹ sọ fun Ọlọrun ohun nlá ti awọn n ṣe fun Un, ti wọn si n fi fun Un! Hanna kò tilẹ sọ nipa è̩bùn pataki ti orin kíkọ ti Ọlọrun fi fun un. Bẹẹ ni oun kò sọ asọtẹlẹ pé ọmọ oun yoo di eniyan nlá ti yoo si ṣe ohun rere. Hanna kò gbé Samuẹli, ẹni ti i ṣe è̩bùn ga, ṣugbọn Ọlọrun Olufunni ni è̩bùn ni ó gbé ga. O wí pé, “Emi yọ ni igbala rẹ … kò si ẹlomiran boyè̩ ni iwọ.”

Orin ìdúpé̩ Hanna fi ọnà pupọ jọ orin iṣẹgun Dafidi: “Emi o fẹ ọ, OLUWA, agbara mi. Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi. Emi o kepè OLUWA, ti o yẹ lati ma yin” (Orin Dafidi 18:1-3).

Hanna juba Ọlọrun fun iwa-mimọ Rè̩ ati fun ọgbọn Rè̩. Bi o ti n jẹri si agbara Ọlọrun ati ijolootọ Rè̩, o sọ nipa ìrírí rè̩. Awọn eniyan a maa saba fẹ lati gba ogo fun ara wọn, fun ohun rere ti o bá wà ninu igbesi-ayé wọn. S̩ugbọn Hanna mọ pé Ọlọrun ni O n funni ni agbara, ọrọ, ipò, ati gbogbo ibukún ninu igbesi-ayé wa. “OLUWA sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ: o rè̩ silẹ, o si gbe soke.”

Awọn Àsọté̩lè̩

Ki i ṣe ohun ti Ọlọrun ti ṣe kọja nikan ni Hanna sọ, ṣugbọn o sọ nipa ọjọ iwajú pẹlu. Ijolootọ Ọlọrun atẹyinwa fun un ni igbagbọ si i fun ìgbà ti n bọ. Nigbà ti o n fi ojú sọnà fun iṣẹgun nipa iranlọwọ Oluwa, Hanna sọ nipa gbogbo eniyan Ọlọrun. “Yio pa ẹsẹ awọn enia mimọ rè̩ mọ.” Awọn ọrọ iyanu wọnyii n fi igbagbọ ati igbẹkẹle ninu Ọlọrun hàn. Wọn tun jé̩ ìlérí fun awọn eniyan Rè̩, nitori Ọlọrun ni O mí si Hanna lati sọ wọn. Gbogbo nnkan ti awọn eniyan Ọlọrun ni i ṣe kò ju pe, ki wọn gbàgbọ, ki wọn gbọràn, ki wọn si gbẹkẹ wọn le E.

“Nipa agbara kò si ọkọnrin ti yoo bori.” Ọlọrun yoo pa awọn ti wọn gbẹkẹle E mọ, yoo si fun wọn ni iṣẹgun. Gideoni jé̩ apẹẹrẹ rere lati fihàn pé iṣẹgun kò duro lori agbara ogunlọgọ awọn eniyan. A ti kọ nipa Gideoni ati ẹgbé̩-ogun ọọdunrun (300) akikanju rè̩, ti wọn ṣẹgun, ti wọn si pa awọn ọmọ-ogun ara Midiani run, awọn ẹni ti ó pọ níye tó bẹẹ ti awọn ati ibakasiẹ wọn kò ni iye (Ẹkọ 194).

Awọn ọtá Oluwa ni awọn wọnni ti wọn lodi si I. Ọtá Rè̩ ni wọn. Hanna wí pé, a o fọ wọn “tutu”. Eyi ni ìrírí ti awọn Ọmọ Israẹli ní, ni akoko wọn, o si n ri bẹẹ lọ ni awọn ọjọ ti o tẹle asọtẹlẹ Hanna. Lati ìgbà yii lọ ni Ọlọrun ti n daabo bo awọn eniyan Rè̩, ti O si n yọ wọn nigbà ti awọn ọtá Rè̩ n ṣègbé. Bẹẹ ni yoo si maa ri titi a o fi pa ọtá ikẹhin run (1 Kọrinti 15:25, 26), ti Kristi yoo jọba lae ati laelae (Ifihan 11:15).

Adura alarinrin ti Hanna gbà yii ní è̩kọ pupọ ninu fun wa. A ba le kọ lati maa da iyin ati idupẹ pọ ninu adura wa! A ba le gbé Ọlọrun igbala wa ga, ki o sì yé wa pé, a o ni irú ayọ ti Hanna ní nigbà ti a bá fun Oluwa ní ohun naa ti a fẹran, ti o si ṣọwọn fun ọkàn wa, ati nigbà ti a bá san è̩jé̩ wa, ani awọn wọnni ti a jé̩ nigbà ti a wà ninu ìpọnjú (Orin Dafidi 66:13, 14)!

Samuẹli

Ki ni ṣẹlẹ si ọmọdekunrin Samuẹli ti Hanna “fi fun” Oluwa? Oun kò gbàgbé rè̩, bẹẹ ni kò wí pé ojuṣe oun nipa rè̩ ti pari. Ni ọdọọdún, a maa dá aṣọ ileke penpe, a si mu un lọ ba a nigbà ti o bá lọ si S̩ilo fun irubọ ọdọọdún. Lai ṣe aniani, nigbakuugba ti Hanna bá rí Samuẹli, a maa ranti bi Ọlọrun ti jolootọ pupọ tó lati dahùn adura rè̩.

Iṣé̩ Ìsìn fun Ọlọrun

Samuẹli n dàgbà si i. O ni ojurere lọdọ Ọlọrun ati eniyan. O fi ọkàn si iṣé̩, o si “nṣe iranṣẹ fun OLUWA niwaju Eli.” Awọn miiran lè rò pé kò si iṣé̩ ninu Ihinrere fun ọmọde. Iṣé̩ wà fun Samuẹli – o si jé̩ ọmọde. Boya ó n jiṣé̩ fun Eli, o si n ṣe iranwọ lati ri pé ilé Oluwa wà leto. Samuẹli kò fi ara wé apẹẹrẹ buburu awọn ọmọ Eli ti wọn jé̩ alaigbọran ati aṣe-tinu-ẹni. Samuẹli gbà lati dí àyè ti iya rè̩ fi i rubọ fun. O wí pé, “Emi fi i fun OLUWA; ni gbogbo ọjọ aiye rè̩.”

Oun Funra Rè̩ Gba Ìpè

Yíyà tí iya rè̩ ya a sọtọ, kò tó. Ọlọrun pe Samuẹli funra rè̩ gẹgẹ bi ẹnikan pẹlu. Ọmọ ti o ṣe orí ire jù lọ ni ẹni ti awọn òbí rè̩ yà sọtọ fun Oluwa. Boya awọn òbí ti rẹ ti fi iwọ naa “fun” Oluwa, ṣugbọn Ọlọrun n fé̩ ki iwọ funra rẹ fi ayé rẹ rubọ fun Un ati fun iṣé̩-ìsìn Rè̩. Ọlọrun n fé̩ ki o jé̩ ìpè ti Oun fi n pè ọ gan an. Ọlọrun n fé̩ awọn òṣìṣé̩ ti yoo yọọda ara wọn - awọn ti yoo fi tinutinu dí àyè ti O fi fun wọn.

Jíjé̩ Ìpè Ọlọrun

Ọnà àrà patapata ni Ọlọrun gbà fi ara Rè̩ hàn fun Samuẹli. Ni alé̩ ọjọ kan, lẹyin ti Eli ti wọ ibùsùn rè̩ lọ, ti Samuẹli si dubulẹ lati sùn, Samuẹli gbọ bi a ti n pe orukọ rè̩. Samuẹli rò pé Eli ni o n fé̩ rí oun, ó sì saré lọ si yàrá Eli, gẹgẹ bi ọmọ rere. S̩ugbọn Eli wi pé oun kò pe e, ó sọ fun un pé ki ó pada lọ sùn. Eyi ṣẹlẹ ni ìgbà mẹta, titi ó fi wá yé Eli pé Oluwa ni O n pe Samuẹli. Eli sọ fun Samuẹli lati dahùn nigbà ti ohùn Ọlọrun bá pè e.

Lẹẹkan si i, Samuẹli dubulẹ, boya o n wòye bi Ọlọrun yoo tún pè e, nitori ti kò dahùn nigbà ti Ọlọrun ti kọ pe e. Samuẹli mura lati tẹti silẹ gbọ ohùn Ọlọrun. O jé̩ anfaani ati ojuṣe ribiribi fun Samuẹli lati mọ ifẹ Ọlọrun. Oluwa dé, O duro, O sì pè, “Samuẹli, Samuẹli.” Oun si dahùn pé, “Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ.”

Ìpè Ọlọrun

Ìpè Ọlọrun si ọ le ma ri bi ìpè Rè̩ si Samuẹli gan an. Ọlọrun le pè ọ ni orukọ, bi O ti pe Samuẹli, ṣugbọn O lè má ṣe bẹẹ. Nigbà miiran, Ọlọrun maa n sọrọ ni ohùn ti a lè gbọ. S̩ugbọn nigbà pupọ ju bẹẹ lọ, O maa n bá ọkàn sọrọ. O maa n fihàn ni pé è̩ṣè̩ wà ninu ọkàn ati igbesi-ayé ẹni. Ọlọrun maa n fihàn eniyan pé o yẹ ki o ní Olugbala kan. O ṣe e ṣe ki o ti ní ifẹ kan ninu ọkàn rẹ lati gbadura, ki o si bẹ Ọlọrun pé, ki O fi è̩ṣè̩ rẹ jì ọ. Boya o ti n poungbẹ lati di Onigbagbọ, o si n fẹ ri pe ọnà rẹ tọ pẹlu Ọlọrun. Ìpè Ọlọrun ni eyi si ọ. Boya kò ye ọ bẹẹ tẹlẹ. Lati isisiyii lọ, iwọ o mọ pé Ọlọrun n fẹ ki o dahùn gẹgẹ bi Samuẹli ti ṣe – “Ma wi; nitori ti iranṣẹ rẹ ngbọ.” Lẹyin ti eniyan bá tilẹ ti rí igbala, Ọlọrun lè pe e lati ṣe iṣé̩ kan pàtó, lati ṣe ohun kan gunmọ fun Un. Ọlọrun jé̩ ki ifẹ rẹ si Oluwa ati fun iṣé̩ Rè̩ rú ọkàn rẹ soke lati da A lohùn pé, “Emi nĩ.”

Iṣé̩ Ti A rán Samuẹli

Ọlọrun ni iṣé̩ lati rán Samuẹli. Ki i ṣe nipa Samuẹli funra rè̩. Ọlọrun kò wí pé, Oun o sọ Samuẹli di eniyan nlá tabi pe Samuẹli yoo ṣe ọpọlọpọ ohun nlá. Iṣé̩ ti Ọlọrun kọ rán Samuẹli kuru; ó ba ni ninu jé̩; fun ẹlomiran si ni. Iṣé̩ naa jé̩ nipa ilé Eli.

Kí ó tó tó akoko yi, Ọlọrun ti kilọ fun Eli pé, kò jé̩ oloootọ gẹgẹ bi alufaa, ati pé o ka awọn ọmọ rè̩ si ju bi o ti ka Ọlọrun si lọ. Eli mọ pé awọn ọmọ oun jé̩ eniyan buburu. A ti sọ fun un pé awọn ọmọ rè̩ mejeeji yoo kú ni ọjọ kan naa, ati pé Ọlọrun yoo gbé alufaa oloootọ dide. Eli ati awọn ọmọ rè̩ kò gbadura pé, ki Ọlọrun dari ji wọn. Kaka bẹẹ, wọn n bá iṣé̩ wọn atẹyinwá lọ, lai naani ikilọ Ọlọrun.

Ni akoko yii, Eli rẹ ara rè̩ silẹ lati bi Samuẹli, ẹni ti i ṣe ọmọde ati iranṣẹ rè̩, nipa iṣé̩ ti Ọlọrun rán. Eli kò jowú bẹẹ ni kò ni ẹmi ikannu nitori Ọlọrun ti bá Samuẹli sọrọ dipo oun. Eli huwà otitọ bi o tilẹ jé̩ pé ó yọri si ìtìjú fun un. Samuẹli jé̩ gbogbo iṣé̩ naa fun Eli. Kò fi ohun kan pamọ. Kò ni inú dídùn lati jé̩ iṣé̩ ti o buru fun Eli, ṣugbọn Samuẹli jé̩ oloootọ, o si gbọran si Ọlọrun.

Kò si Ironupiwada

Ọrọ ti Ọlọrun sọ ni kukuru ni pé, Oun kò ni dari è̩ṣè̩ awọn ọmọ Eli jì. Ìdájọ yii le, sibẹ ó tọ, nitori eniyan kò le maa huwà ibi ki o si reti pé nnkan yoo lọ deedee fun oun. Wọn ti ṣai kiyesi ìkìlọ Ọlọrun, ati ìbáwí Eli (1 Samuẹli 2:24, 25). Wọn sọ irubọ Oluwa di ìríra (1 Samuẹli 2:15-17). Wọn jé̩ ọmọlẹyin Satani, wọn kò si mọ Ọlọrun (1 Samuẹli 2:12). Wọn n dẹṣè̩ si i titi Ọlọrun kò fi fun wọn ni àyè mọ lati ronupiwada (Gẹnẹsisi 6:3; Owe 29:1). Eli jìyà ìtìjú ati òṣì nitori ó kùnà lati ṣe ojuṣe rè̩. O bá awọn ọmọ rè̩ wí, ṣugbọn kò fi ìyà jẹ wọn nigbà ti o mọ nipa è̩ṣè̩ wọn ti o si jé̩ pé iṣesi wọn ninu ile Oluwa wà labẹ akoso rè̩.

Ọlá fun Samuẹli

Ọlọrun mú iṣé̩ ti Samuẹli jé̩ fun Eli ṣẹ. Eyi mú ọlá wá fun Samuẹli, ó si fi ìdí rè̩ mulẹ niwaju gbogbo Israẹli pé yoo jé̩ wolii Oluwa. Ọlọrun wà pẹlu Samuẹli. Ifarahàn Oluwa mú ki ọgbọn ati oore-ọfẹ pọ sii fun Samuẹli gẹgẹ bi ifarahàn Oluwa yoo ti mú ki ọgbọn ati oore-ọfẹ pọ sii fun wa lonii.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti adura Hanna kún fun ìyìn ati ọpé̩?
  2. Ki ni ṣe ti “o fi” Samuẹli fun Oluwa?
  3. Ki ni ṣe ti o fi ṣe danindanin fun Hanna lati ya Samuẹli sọtọ fun Oluwa?
  4. Irú eniyan wo ni Eli?
  5. Ki ni ṣe ti Samuẹli kò dá Oluwa lohùn lakọkọ?
  6. Ki ni Samuẹli ti dahùn nigbà ti o mọ pé Ọlọrun ni O n pe oun?
  7. Ti ta ni iṣé̩ ti Ọlọrun rán Samuẹli?
  8. Ki ni ṣe ti Ọlọrun kò dariji awọn ọmọ Eli?