1 Samuẹli 4:1-18; 5:1-5; 6:1-3, 7-15, 19, 20

Lesson 201 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Tani yio le duro niwaju OLUWA Ọlọrun mimọ yi?” (1 Samuẹli 6:20).
Notes

Ogun pẹlu Awọn Filistini

Eli wà ni ipò alufaa titi di akoko ti Samuẹli fi dàgbà. Eli kò ṣe akitiyan lati kọ awọn eniyan nipa Ọlọrun; Ọrọ Oluwa si ṣọwọn, eyi yii ni pé, ìyàn Ọrọ naa mú. Eli fà sẹyin lati maa gba awọn Ọmọ Israẹli niyanju lati maa gbadura, ki wọn si wá Ọlọrun. Boya Eli n bá wọn wí, ṣugbọn kò fi dandan le e pé wọn ni lati gbọran si àṣẹ Ọlọrun.

A kò ka a pe awọn Ọmọ Israẹli beere amọran lọwọ Ọlọrun nigbà ti wọn lọ bá awọn Filistini jagun. A kò ri akọsilẹ pé wọn gbadura. Awọn Filistini lu awọn Ọmọ Israẹli bolè̩, ẹgbaaji (4,000) eniyan ninu wọn ni wọn sì pa.

È̩ṣè̩ ninu Àgọ

Ọpọlọpọ ọdún sẹyin ṣáájú ìgbà yií, Ọlọrun ti ṣe ìlérì yii fun awọn Ọmọ Israẹli, “Ọkọnrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin” (Joṣua 23:10). Awọn Ọmọ Israẹli kò gbọran si àṣẹ Ọlọrun, wọn kò si sin In, nitori naa ni kò ṣe jà fun wọn.

Awọn eniyan naa n da a sọ laaarin ara wọn, o si n yà wọn lẹnu ohun ti o fa a ti awọn Filistini fi ṣẹgun wọn bẹẹ. O jọ bi ẹni pé, wọn dá Ọlọrun lẹbi pé, O gba awọn Filistini layè lati bori ninu ogun naa, ṣugbọn awọn Ọmọ Israẹli kò gbaawẹ, wọn kò gbadura, bẹẹ ni wọn kò si bẹ Eli lati gbadura fun wọn.

Bi o tilẹ jé̩ pé Eli ti kùnà lati fi ọnà Oluwa kọ awọn Ọmọ Israẹli, o dajú pé awọn eniyan wà laaarin wọn ti wọn ti gbọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli ni ìgbà atijọ ni irú akoko bẹẹ. Ni ìgbà ayé Joṣua, a ṣẹgun wọn ni Ai, nitori è̩ṣè̩ wà laaarin wọn nigbà ti Akani mú ninu ohun iyasọtọ (Joṣua 7:1). Joṣua, aṣaájú wọn, fa aṣọ rè̩ ya, oun ati awọn àgbà awọn eniyan laaarin wọn si bu ekuru si ori wọn, gẹgẹ bi àmì ironupiwada niwaju Ọlọrun. Joṣua gbadura niwaju Apoti Majẹmu Oluwa titi di aṣaalé̩. Ọlọrun sọ fun Joṣua pé awọn eniyan naa ti dẹṣè̩, nitori eyi ni wọn kò ṣe lè duro niwaju awọn ọtá wọn. Ju bẹẹ lọ, Ọlọrun ni Oun ki yoo wà pẹlu awọn Ọmọ Israẹli mọ, afi bi a bá pa è̩ṣè̩ naa run, ti a si jẹ ẹni ti o jẹbi naa niyà (Joṣua 7:12). Awọn Ọmọ Israẹli wadii è̩ṣè̩ naa, wọn si hú u jade. Ohun iyasọtọ naa ni a fi iná sun lẹyin ibudo, a si jẹ ẹni ti o jè̩bi naa niyà. Nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli ti gbọran si aṣẹ Ọlọrun bayii, wọn tún pada lọ bá Ai jagun, Ọlọrun si fi iṣẹgun fun wọn.

Ìgbìmọ

Ní akoko yii, awọn Ọmọ Israẹli ṣe àpérò. Wọn hùwà wèrè ni gbigbiyanju lati wá ojurere Ọlọrun lai gbadura, ati lai ronupiwada. Awọn Ọmọ Israẹli pinnu lati gbé Apoti Majẹmu kuro ni S̩ilo. Apoti Majẹmu Oluwa jé̩ apẹẹrẹ Ẹmi Ọlọrun ati ifarahàn Rè̩ ni ibi Itẹ-Aanu.

Ẹẹkan ṣoṣo ni a ti i gbé Apoti naa lọ si ogun rí. Ni ìgbà naa Oluwa pàṣẹ gẹgẹ bi awọn Ọmọ Israẹli yoo ti gba ìlú Jeriko. Bi awọn Ọmọ Israẹli ti n yí ìlú naa ká, ni wọn n gbé Apoti-ẹri naa lọ laaarin wọn. Ọlọrun ni O sọ fun wọn pé ki wọn gbé Apoti naa nigbà naa.

Ibi ti Ọlọrun Yàn

O sọ fun wọn pé, a ni lati gbé Apoti-ẹri naa kalè̩ si “Ibi Mimọ Julọ” (Ẹksodu 26:34), ninu Agọ, nibi ti wọn ti n sìn. Nibi ti Ọlọrun yàn (Deuteronomi 12:5), ni a pàṣẹ fun wọn lati maa jọsin nigbà ti wọn bá dé Ilẹ Kenaani. Ni S̩ilo ni a fi Àgọ naa lelẹ si (Joṣua 18:1), Ọlọrun kò si ti pàṣẹ pé ki a ṣi i kuro nibẹ. Yoo jé̩ ohun ti o lewu pupọ lati gbé Apoti-ẹri naa lai jé̩ pé Ọlọrun pàṣẹ bẹẹ, ṣugbọn awọn ọmọ Eli, Hofni ati Finehasi, awọn alufaa, gbé Apoti-ẹri naa lọ.

Kò yé wọn pé bi wọn tilẹ ni Apoti naa pẹlu wọn, Ẹmi Ọlọrun ti fi wọn silẹ, nitori è̩sè̩ wọn. Awọn Ọmọ Israẹli ni igbẹkẹle ninu Apoti naa, dipo ki wọn gbẹkẹle Oluwa tí Apoti-ẹri naa duro fun. Ọlọrun ni wọn i bá maa wò, nitori agbara Rè̩ ni yoo fọn awọn ọtá ká. Awọn eniyan wà ni akoko isisiyii ti wọn ni itẹlọrun ninu ìlànà ìsìn, ṣugbọn ti wọn n sé̩ agbara ti o wà ninu rè̩. Ifarahàn òde ara lasan ni wọn fi iyè si ju lati ni ọkàn mimọ lọ.

Apoti-Ẹri Naa ati awọn Ọtá

Nigbà ti wọn gbé Apoti naa dé ibudo, awọn Ọmọ Israẹli hó ìhó nlá nlà bi ẹni pé iṣẹgun ti jé̩ ti wọn. Awọn ọtá gbọ ihó nlá naa, wọn si ri Apoti naa. Awọn Filisitini mọ pé Apoti-ẹri naa jé̩ àmì ifarahàn Oluwa. Hihó awọn Ọmọ Israẹli ati ifarahàn Apoti-ẹri naa mú ìbè̩rù wọ inú ọkàn awọn Filistini. Nitori wọn jé̩ orilẹ-ède abọriṣa, wọn rò pé Apoti-ẹri naa gan an ni Ọlọrun tikara Rè̩. Wọn ranti awọn iṣẹ-iyanu ti Ọlọrun ti ṣe ni ìgbà irinkiri awọn Ọmọ Israẹli ninu aginju, nigbà ti Apoti-ẹri naa wà pẹlu wọn. Awọn ọtá mọ pé a kò i ti ṣe bayii gbé Apoti-ẹri wá si ojú ogun lati bá wọn jà rí. Awọn Filistini kò tuuba, ṣugbọn wọn mú ara wọn ni ọkàn le lati jé̩ alagbara, ki wọn ṣe bi ọkunrin, ki wọn si jà.

Iṣubu ati Ikú

S̩oki ni akọsilẹ nipa ogun naa jé̩. A ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli; ninu ipayà nlá ni olukuluku si sá pada sinu àgọ rè̩. Awọn ọmọ-ogun ẹlẹsè̩ ti a pa ninu awọn Ọmọ Israẹli si jé̩ ẹgbaa mẹẹdogun (30,000), pẹlu Hofni ati Finehasi, awọn ọmọ Eli. Awọn Filistini gba Apoti Oluwa. Awọn Ọmọ Israẹli ti ni ìgboyà ati ifọkanbalẹ, ṣugbọn è̩ṣè̩ wà ninu wọn pẹlu. Wọn ti fi igbagbọ wọn sinu Apoti-ẹri dipo Oluwa tikara Rè̩. Eniyan lè ni ìgboyà, kí ó si fi gbogbo ọkàn di ohun ti o gbagbọ mú; ṣugbọn ó ni lati dari igbagbọ ati igbẹkẹle rè̩ sí ojú ọnà ti o tọ, eyi yii ni pé ninu Ọlọrun otitọ ati alaayè.

Ọkunrin kan laaarin awọn ọmọ-ogun Isarẹli, ẹni ti o rí ohun gbogbo ti o ṣẹlẹ, sáré lọ si S̩ilo lati lọ royin iṣubu wọn. Eli wà lẹba ọnà, o n reti lati gbọ ìròyìn nipa ogun. È̩rù n ba a gidigidi fun aabo lori Apoti Oluwa. Kò ni ìgboyà tó lati kọ fun awọn eniyan naa ki o si pa Apoti naa mọ si S̩ilo, ṣugbọn ninu ọkàn rè̩, o mọ pé wọn ti dẹṣè̩.

O dabi ẹni pé ìròyìn naa ati ikú awọn ọmọ rè̩ kò daamu Eli nigbà ti o gbọ, bi ẹni pé ó ti n reti ìmúṣẹ asọtẹlẹ Ọlọrun lori wọn ni akoko yii. S̩ugbọn nigbà ti Eli gbọ pé a gba Apoti naa lọ, o ṣubu sẹyin lori ijoko rè̩ lẹba bode, ọrùn rè̩ si ṣé̩. Bayii ni Eli kú lai sọ ọrọ kan mọ, ẹni ọdún mejidinlọgọrun (98) ni i ṣe, o si ṣe onidajọ Israẹli fun ogoji ọdún.

A Gba Apoti naa Lọ

Ìdájọ nlá wá sori awọn ọmọ Eli gẹgẹ bi Ọlọrun ti wí: “Ni ọjọ kanna li awọn mejeji yio kú” (1 Samuẹli 2:34). Hofni ati Finehasi ti fi ipò iṣé̩ wọn silẹ, wọn si ti fa ara wọn kuro labẹ aabo Ọlọrun. Ki i ṣe ìdí iṣé̩ wọn ni wọn wà ni ojú-ogun. Wọn rí ìṣìnà ati ìkùnà wọn nigbà ti o ti pé̩ jù fun wọn; ṣugbọn a lè kẹkọọ lara ohun ti o ṣẹlẹ si wọn.

Etí awọn Ọmọ Israẹli hó nitootọ (1 Samuẹli 3:11), gẹgẹ bi Ọlọrun ti wí, nigbà ti wọn gbọ ìròyìn ogun naa. Ìṣubú naa jé̩ àdánù nlá. Pipadanu ti Israẹli padanu Apoti naa kò mú ọlá wá fun Ọlọrun. O mú àdánù wá fun Israẹli ati ìtìjú fun S̩ilo, nitori ìlú yii ki yoo tún jé̩ ibujoko Apoti Oluwa mọ.

Àpótí naa ati Òrìṣà kan

Ní gbogbo akoko yii, inú awọn Filistini dùn, ọkàn wọn si n ṣogo ninu iṣẹgun wọn yii. Wọn kò pa Apoti naa lara ṣugbọn, wọn gbe e lọ si ilé òrìṣà wọn, si ilé Dagoni, ni Aṣdodu, ọkàn ninu awọn ìlú wọn. A kò sin Ọlọrun rara, bi a ko bá sin Oun nikan ṣoṣo. Apoti naa bori Dagoni ninu tẹmpili ti rè̩. A ki yoo sin Ọlọrun pẹlu ọlọrun miiran, ṣugbọn a o gbe E ga ju gbogbo wọn lọ. Òrìṣà naa ṣubu dojú bolè̩ ni ipò ọtá ti a ṣẹgun rè̩, niwaju Apoti Oluwa. Awọn alufaa Dagoni yara lati gbé òrìṣà naa pada si ipò rè̩. Ni òwúrọ ọjọ keji, ki i ṣe pé Dagoni ṣubu lulè̩ nikan, ṣugbọn o ti gé si ọtọọtọ. Orí ati awọn ọwọ rè̩ ti gé kuro tó bẹẹ ti ó jé̩ kùkùté Dagoni nikan ni o kù. A lè rò pé awọn Filistini yoo mọ pé a n fi Dagoni hàn gẹgẹ bi òrìṣà lasan ni, pé kò ni agbara, pé kò yẹ ni ohun ti a lè gbadura sí, kò si yẹ ni ohun ti a lè bu ọlá fun; ṣugbọn awọn Filistini kò gbà pé Oluwa Ọlọrun Israẹli nikan ṣoṣo ni Ọlọrun otitọ. Ọkàn wọn séle sinu iboriṣa wọn.

Àpótí naa laaarin Ọtà

Fun oṣù meje ni iyọnu ajakalẹ-arun fi bá awọn Filistini, nitori Apoti Oluwa, sibẹ wọn kò fẹ lati da a pada. Wọn bè̩rè̩ si i gbé Apoti naa lọ lati ìlú kan sí omiran, ibikibi ti o bá sì dé “ìparun ikú” yoo wà nibẹ. Awọn ti kò kú ni àrùn buburu kọlu.

Nigbà ti awọn Filistini ri i pé kò si alaafia tabi aabo fun wọn niwọn ìgbà ti Apoti naa bá wà lọdọ wọn, wọn pejọ pọ lati ro ohun ti wọn o ṣe si I. Ìbè̩rù ati irora mú wọn dá Apoti-ẹri naa pada. Wọn kan kè̩ké̩ titun, eyi ti maluu n fà, a si dá Apoti-ẹri naa pada fun awọn Ọmọ Israẹli. Awọn Filistini kò gba ohun irapada tabi owókowó fun un. Inú wọn dùn pé Apoti naa lọ kuro lọdọ wọn, wọn si fi iṣura lelẹ fun irubọ, ki ọwọ Ọlọrun bá le ṣi kuro lara wọn.

Aibọwọ

Awọn Ọmọ Israẹli kò tilè̩ gbiyanju lati gba Apoti naa tabi san irapada fun un, tabi ki wọn tilẹ beere nipa rè̩. Nitootọ ni wọn fi ayọ gba a pada; wọn si gbé Apoti-ẹri naa lé orí okuta nlá kan ni oko Joṣua, ara Bẹtṣemeṣi. Nibẹ ni wọn fi Apoti-ẹri naa si lai bò ati ni ọnà ti gbogbo eniyan lè maa yẹ ẹ wò. Bi o tilẹ jé̩ pé ó lodi si ohun ti a fi lelẹ ninu Ofin, awọn Ọmọ Israẹli la igi kè̩ké̩ naa, wọn si fi awọn maluu nì rú ẹbọ sisun. Eyi yii ki i ṣe ẹbọ sisun ti o tọnà, bẹẹ ni ki i ṣe ẹbọ ti awọn alufaa rú ninu Àgọ. Awọn ọkunrin Bẹtṣemeṣi yọ lati rí Apoti naa - ṣugbọn wọn kò ni è̩tọ lati wo inú rè̩. Awọn alufaa paapaa kò ni è̩tọ lati wo inú Apoti-ẹri Majẹmu yii. Nitori eyi ọwọ Ọlọrun wà lara wọn, a si pa ọpọlọpọ ninu wọn. Aibọwọ ati aibu-ọlá fun Apoti-ẹri naa jé̩ è̩ṣè̩ si Ọlọrun. Awọn Ọmọ Israẹli kọ è̩kọ pé, eniyan ni lati ṣọra bi o ti n ṣe si awọn ohun mimọ ti Ọlọrun, awọn ohun iyasọtọ ti i ṣe ti ilé Oluwa, ati ipò mimọ, ati pé, eniyan kò gbọdọ rò pé oun lè sọrọ tabi hùwà gẹgẹ bi oun bá ti fé̩, nitori ti Ọlọrun ni lati gbe ni ga. “Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke” (Orin Dafidi 75:6, 7).

Awọn ọkunrin Bẹtṣemeṣi mọ agbara ati ìwà-mimọ Ọlọrun. Wọn kigbe pé, “Tani yio le duro niwaju Oluwa Ọlọrun mimọ yi?” Ka Orin Dafidi 1 ati Orin Dafidi 15 fun idáhùn si eyi.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti wọn gbé Apoti naa lọ si ojú-ogun?
  2. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli kùnà lati ṣe ki wọn tó lọ si ogun?
  3. Ki ni abayọrisi ogun naa?
  4. Ki ni ṣẹlẹ si Eli ati awọn ọmọ rè̩?
  5. Ki ni ṣẹlẹ si Apoti Oluwa?
  6. Ki ni ṣẹlẹ si òrìṣà nì?
  7. Ki ni ṣe ti awọn Filistini dá Apoti naa pada?
  8. Ki ni ṣe ti Ọlọrun pa awọn ọkunrin Bẹtṣemeṣi?