1 Samuẹli 7:1–17

Lesson 202 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA li àbo mi; Ọlọrun mi si li apata àbo mi” (Orin Dafidi 94:22).
Notes

Òkùnkùn Nipa Ti Ẹmi ati Ìmọlè̩

Ni aarin ìgbà ti Apoti-ẹri Ọlọrun wà pẹlu awọn Filistini, ìlú kọọkan ti a gbe e lọ ni ìdájọ Ọlọrun ti wá si orí rè̩. Inú awọn Filistini dùn pé, o kuro laaarin wọn ati pé, awọn Ọmọ Israẹli si gba a pada si ilè̩ wọn.

Ninu Apoti-ẹri yii ni Ọrọ Ọlọrun wà, awọn Ofin wọnyii ni o wà fun awọn Ọmọ Israẹli gẹgẹ bí Bibeli ti jé̩ fun wa. A ti maa n gbọ pé, Bibeli ti wà ṣáájú ọlàjú; ibikibi ti awọn eniyan bá sì ti gbọran si àṣẹ Rè̩, Ọlọrun a maa bukùn wọn. Ki ni ṣe ti awọn Filistini kò gbadùn ìbùkún Ọlọrun nigbà tí Apoti-ẹri naa wà pẹlu wọn? Ìdí rè̩ ni pé, wọn kò gbọran si awọn àṣẹ naa, wọn kò si sin Ọlọrun. Keferi ti kò fé̩ mọ otitọ ni wọn; nitori naa, nigbà ti Ọrọ naa tọ wọn wá ti wọn si kọ Ọ, a dá wọn lẹbi fun ìwà buburu wọn.

Ni akoko yii, Ọrọ Ọlọrun a maa mú ìmọlè̩ wá fun gbogbo awọn tí ó bá gba A gbọ. S̩ugbọn nigbà ti awọn eniyan bá ní anfaani lati mọ otitọ tí ó wà ninu Bibeli, ti wọn si kọ lati gbé ìgbésí-ayé wọn bẹẹ gẹgẹ, ìmọlè̩ yii a maa di òkùnkùn fun wọn – si wo bi òkùnkùn naa ti n pọ tó! Wọn wà ni ipò ti o buru ju ti ẹni ti ko i ti gbọ nipa Jesu rí.

Apoti-ẹri naa wà lọdọ ẹbí Lefi kan ni Juda, wọn n ṣe ìtọjú rè̩ daradara. Ọlọrun si n bukún wọn. Ọdún diẹ lẹyin eyi ti Apoti-ẹri naa wà ni ilé Obedi-Edomu, Wolii naa sọ bayii nipa rè̩: “Apoti-ẹri OLUWA si gbé ni ilé Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: OLUWA si bukún Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rè̩” (2 Samuẹli 6:11).

Ìbùkún Idalẹbi È̩ṣè̩

Ìbùkún ọtọ kan wà ti awọn Ọmọ Israẹli rí gbà ni akoko tí Apoti-ẹri naa wà pẹlu wọn. Eyi ni ìbùkún idalẹbi fun è̩ṣè̩, ìmọ è̩bi fun ìwà aitọ tí wọn ti hù si Ọlọrun. “Gbogbo ile Israẹli si pohunrere ẹkún si OLUWA.”

O lè rò pé irú ipò ibanujẹ ọkàn bẹẹ ti idalẹbi fun è̩ṣè̩ maa n mú wá kò le jé̩ ibukún fun eniyan, ṣugbọn idalẹbi fun è̩ṣè̩ ni i maa mú awọn ẹlẹṣè̩ wá si ọdọ Ọlọrun. Nigbà ti idalẹbi fun è̩ṣè̩ bá wọ ọkàn, eniyan yoo ni irobinujẹ. Nigbà miiran, o lè ṣe alaifé̩ jẹun tabi ki o ma tilẹ fé̩ lati sùn. È̩rù lè maa ba a pé oun lè kú lojiji, tabi pé Jesu yoo dé, a o si fi oun silẹ lati la ipọnju nlá nì kọja. Ẹni ti Ọlọrun n bá sọrọ ni ọnà bayii lè fé̩ ni ìgbà miiran pé, ki Ọlọrun jọwọ oun jẹẹ fun ara oun. S̩ugbọn a gbọdọ maa dupẹ fun idalẹbi fun è̩ṣè̩!

Bi o bá jé̩ ẹlẹṣè̩, ro ohun ti yoo jé̩ abayọri si fun ọ bi Jesu kò bá tún mú idalẹbi fun è̩ṣè̩ wá sinu ọkàn rẹ mọ. Iwọ kò ni fé̩ lati ronupiwada ki a si gba ọ là mọ, iwọ yoo si ṣègbé titi lae. Kò si ninu agbara rẹ lati le tọ Jesu wá ni igbakuugba. O gbà pé ki Ẹmi Ọlọrun fa ọ wá sọdọ Rè̩. Jọwọ da A lohun nigbà ti O bá n pè ti O si n rọ ọ pẹlu ifẹ lati wá si ilé Baba nibi ti iwọ o wà lai lewu titi lae!

Ronú ìbùkún ti o n tẹle idalẹbi fun è̩ṣè̩, nigbà ti ẹlẹṣè̩ bá jé̩ ìpè naa, ti ó ronupiwada è̩ṣè̩ rè̩, ti a si da a silè̩. Ẹrù naa yoo bọ. Ohun gbogbo yoo di ọtun fun un. O ti di è̩dá titun ninu Kristi Jesu. Irunu, ìwà abuku, ọrọ ìbínú ti o ti maa n sọ, ki yoo tún sí mọ. Dipo awọn wọnyii ni orin ayọ, ẹmi iṣoore fun awọn ẹlomiran, iranlọwọ fun awọn ti o n fé̩ iranlọwọ; ati ju gbogbo eyi lọ, ìrètí ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu. Gbogbo eyi wà bẹẹ, nitori Ọlọrun mú idalẹbi wá sinu ọkàn ẹlẹṣè̩ naa, ki o ba le kaanu fun è̩ṣè̩ rè̩, ki o si wá idariji.

Ironupiwada awọn Ọmọ Israẹli

Idalẹbi fun è̩ṣè̩ mú ki awọn Ọmọ Israẹli pohunrere ẹkún niwaju Oluwa. O mú ki wọn mọ pé, wọn ti rú ofin Rè̩, wọn si kaanu pupọ fun è̩ṣè̩ wọn. Ki ni ohun ti wọn lè ṣe nisisiyii?

Samuẹli ni onidajọ wọn, Wolii Ọlọrun tootọ si ni, o si le sọ ohun ti awọn eniyan naa yoo ṣe fun wọn. Bi wọn yoo bá ronupiwada, Ọlọrun yoo dariji wọn, yoo si fun wọn ni ayọ. Wọn ni lati pa è̩ṣè̩ ati òrìṣà tí ó wà laaarin wọn run.

Ìròbìnújé̩ awọn Ọmọ Israẹli pọ tó bẹẹ ti wọn fi mura tán lati fi tayọtayọ ṣe ohunkohun ti Ọlọrun n fé̩ ki wọn ṣe. Wọn yàn ni ọjọ naa lati fara mọ Oluwa titi. A maa n gbọ ti awọn ọmọde maa n pari è̩rí wọn bayii, “Mo n fé̩ lati rin ọnà naa jalè̩.” Ohun ti Ọlọrun n fé̩ ki a ṣe gan an ni eyi – “lati rin ọnà naa jalè̩.”

Nigbà ti ẹlẹṣè̩ bá ronupiwada ni tootọ, yoo ṣeleri lati fi ayé rè̩ fun Ọlọrun, lati ṣe ohunkohun ti Ọlọrun bá beere. Ó ṣetán lati fi awọn ohun wọnni ti Ọlọrun kò fé̩ silè̩, bí awọn ohun ìgbádùn ayé, irọ, ati ìjà. Boya oun kò tilẹ darukọ ikọọkan ninu wọn pé oun yoo fi wọn silè̩ - kò lè ronú kan gbogbo wọn patapata nigbà ti ó bá n gbadura - ṣugbọn nigbà ti ó bá ṣeleri pé, oun fi ayé oun fun Ọlọrun, o ti kó akojá ohun gbogbo ninu ileri yii.

Awọn Ọmọ Israẹli pa awọn òrìṣà wọn run. Eyi jé̩ ìṣísè̩ ti o n fihàn pé wọn ronupiwada. Nigbà naa ni Samuẹli pè wọn si Mispe fun ipade adura. Samuẹli jé̩ iranṣẹ oloootọ, ati ẹni ti ó n lọ lati ìlú dé ìlú lati kọ awọn eniyan lati sin Ọlọrun; gẹgẹ bi oloootọ ojiṣẹ Ọlọrun, o n fé̩ lati gbadura fun awọn eniyan ti wọn bá n fé̩ igbala.

Isọji ni Mispe

Wo irú isọji nlá nlà ti yoo bé̩ silẹ ni Mispe, nigbà ti gbogbo agbajọ awọn Ọmọ Israẹli yipada si Ọlọrun! Wo o bi inú Samuẹli yoo ti dùn tó bi o ti n gbọ ti awọn eniyan naa n gbadura fun idariji! Ìrísí ẹlẹṣè̩ kan ti a ṣè̩ṣè̩ rà pada a maa mú ayọ nlá bá ọkàn olukuluku Onigbagbọ, ayọ si n bẹ ni Ọrun lori ọkàn ti o n ṣègbé kan ti ó pada bọ. Wo irú ayọ nlá ti yoo wà laaarin awọn angẹli ninu ogo ni Ọrun nigbà ti wọn n gbọ ìyìn awọn ọpọlọpọ ẹlẹṣè̩ ti a dariji yii! Ìyìn a maa kún inu ọkàn ti a rapada sọdọ Ọlọrun. Agbara Satani ti o fọ, ifẹ Ọlọrun a si maa ṣakoso ọkàn wọn. S̩ugbọn Satani ki yoo ṣiwọ ninu ìjà naa.

Iyiriwo

Laaarin gbogbo ayọ yii ni Mispe ni igbe idagiri kan ta. Awọn Filistini dé lati bá wọn jà. Satani dé lati gbiyanju lati ba ibukún isọji nlá nlà yii jé̩. S̩ugbọn nisisiyii, awọn Ọmọ Israẹli wà ninu ojurere Ọlọrun, Oun yoo si ja ogun wọn fun wọn. Ni àkọkọ, awọn Ọmọ Israẹli dabi ẹni ti o ṣè̩ṣè̩ ri igbala, ti kò ti i mọ bi Ọlọrun ti le ṣe fun wọn tó nigbà ti a bá n dán wọn wò. È̩rù ba wọn, wọn si bẹ Samuẹli pé ki o gbadura pupọ fun wọn. Samuẹli ṣe bẹẹ, wo irú idáhùn iyanu ti o ri gbà! Oluwa sán ààrá ti o lagbara pupọ tó bẹẹ ti jìnnì-jìnnì mú awọn Filistini, ti wọn si daamu, ó si rọrun fun awọn Ọmọ Israẹli lati lé wọn lọ.

Ohun ti n mú ayọ kún ọkàn ni lati ri bi Ọlọrun ti n jà fun wa. Ẹni ti o ṣè̩ṣè̩ rí igbala lè ṣe alaiti ri ọwọ Ọlọrun ninu ìgbésí-ayé rè̩ lọnà bayii rí, ayọ nlá a si gba ọkàn rè̩ kan pẹlu agbara titun ti ó wà ninu ìgbésí-ayé rè̩ yii.

Iṣẹgun Patapata

Awọn Ọmọ Israẹli lé awọn Filistini sá, wọn si lepa wọn titi dé Betkari. Wo irú iṣẹgun ologo bayii! Israẹli kò i ti ri iṣẹgun tí ó pọ tó bayii lati ìgbà ọjọ Joṣua ati Gideoni. Ìgbà miiran wà ti wọn ti ṣẹgun awọn ẹgbé̩ ogun Filistini kekere, ṣugbọn eyi yii a maa ṣẹlẹ lẹyin ìgbà ti wọn bá ti kó awọn Ọmọ Israẹli lẹrù lọ pupọ. Nigbà naa awọn Ọmọ Israẹli ti ni itẹlọrun pẹlu iṣẹgun laabọ.

S̩ugbọn Israẹli ti ni iṣẹgun patapata nisisiyii. Wọn ti lé awọn Filistini pada si ilè̩ wọn. Yoo ya awọn ẹbí awọn Filistini lẹnu nigbà ti wọn ri awọn ọmọ-ogun wọn ti wọn pada ninu ìbè̩rù, ti wọn n sá eré àsálà fun ẹmi wọn lai si ọkà ati ẹran ati agutan ti wọn maa n mú pada bọ walé nigbà ti wọn bá lọ kó awọn Ọmọ Israẹli lẹrù nigbà àtíjọ.

Ẹmi Ogun

Ìyàtọ nlá ni o wà ni àgọ awọn Ọmọ Israẹli. Ẹmi lati jagun ti wọ inú ọkàn wọn. Agbara wọn ti ọdọ Oluwa wá nipasẹ ibaré̩ titun ti wọn ṣè̩ṣè̩ ni pẹlu Rè̩, wọn si tè̩ siwaju lati maa lu awọn ọtá wọn bolè̩, titi ilè̩ wọn fi di ominira. A ti gbé wọn ró nipa adura, wọn si ti di alagbara lati dojuja kọ è̩ṣè̩.

Iṣẹgun kan ki i ṣe òpin ìjà naa. Ìgbésí-ayé Onigbagbọ jé̩ ìgbésí-ayé ogun jijà lati ìgbà dé ìgbà, ṣugbọn, “awa jù ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa” (Romu 8:37). Ni ojoojumọ ni a gbọdọ maa beere fun agbara ọtun lọdọ Oluwa. Irẹpọ bayii pẹlu Ọlọrun ni ó maa n mú ìgboyà wá lati dojuja kọ awọn agbara ibi, a o si ni ìtara ọtun lati lọ ni orukọ Oluwa si iṣẹgun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni Apoti-ẹri Ọlọrun wà ni akoko è̩kọ yii?
  2. Nigbà wo ni Apoti-ẹri naa mú ibukún wá? nigbà wo ni o si mú ìdájọ wá?
  3. Ki ni idalẹbi ọkàn?
  4. Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli n pohunrere ẹkún?
  5. Ki Samuẹli sọ pé ki wọn ṣe?
  6. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe, ki wọn tó lọ fun ipade adura ni Mispe?
  7. Ki ni ṣẹlẹ ni Mispe?
  8. Ki ni ohun ti o ṣe ìdíwọ laaarin ìyìn Ọlọrun logo awọn Ọmọ Israẹli?
  9. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe fun awọn Filistini?
  10. Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli lagbara tó bẹẹ lati ṣẹgun awọn ọtá patapata?