1 Samuẹli 8:1-22

Lesson 203 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Máṣe bọ si ipa-ọna enia buburu, má si ṣe rìn li ọna awọn enia ibi” (Owe 4:14).
Notes

Ijoolotọ Samuẹli

Wolii Samuẹli jé̩ ọkan ninu awọn eniyan ti ìwà ayé rè̩ wú ni lórí jù lọ ninu awọn ti a kà nipa rè̩ ninu Bibeli. A kò sọrọ buburu kan nipa ìgbésí-ayé rè̩ rí. Nigbà ti ó wà ni ọmọde, ó ya ara rè̩ ati iṣé̩-ìsìn rè̩ sọtọ fun Oluwa; nigbà ti o si n dàgbà si i, gbogbo ifẹ ọkàn rè̩ sibẹ ni lati wá Ọlọrun. Kò ba è̩jé̩ rè̩ jé̩ nigbà kan ri.

Samuẹli fẹran awọn Ọmọ Israẹli gẹgẹ bi baba ti i maa fẹran awọn ọmọ rè̩, inú rè̩ a si bajé̩ pupọ bi ẹnikẹni bá ṣe aigbọran. Iwuwo ọkàn rè̩ ni pé ki wọn lè rí igbala, o si fi ìtara gbadura fun wọn.

Awọn eniyan naa fẹran Samuẹli fun inurere ati otitọ rè̩; nigbà ti ó si di arúgbó, ti ó beere: “Tani mo rẹjẹ ri? tani mo jẹ ni iya ri? tabi lọwọ tali emi gbà owo abẹtẹlẹ kan ri lati fi bo ara mi loju?” Ni idahùn, awọn eniyan wí pé, “Iwọ kò ré̩ wa jẹ ri, bḝni iwọ kò jẹ ni ni ìya ri, bḝni iwọ kò gbà nkan lọwọ ẹnikẹni wa ri” (1 Samuẹli 12:3, 4). A kò lè rí pupọ ninu awọn alakoso orilẹ-ède ti o ni irú ẹri rere bayii ninu ìwé akọsilẹ.

Iyipada ninu Ijọba

Awọn eniyan naa ni itẹlọrun pé ki Samuẹli jé̩ onidajọ wọn ni gbogbo ọjọ ayé rè̩, ofin Ọlọrun ti o fi kọ wọn ni o si ṣe akoso ìgbésí-ayé wọn. S̩ugbọn nigbà ti Samuẹli di arúgbó, ti awọn ọmọ rè̩ kùnà lati maa hùwà rere gẹgẹ bi baba wọn ti ṣe, awọn Ọmọ Israẹli pinnu lati ṣe ti inú ara wọn lai duro de Ọlọrun, lati gbé onidajọ rere miiran dide.

Awọn Ọmọ Israẹli n fé̩ ọba. Eyi lòdì si ìfé̩ Ọlọrun, nitori Oun n fé̩ lati jé̩ Ọba wọn. Ninu gbogbo ìran wọn, lati ìgbà ti Israẹli ti jade ni Egipti - nigbà ìrìn-àjò wọn ninu aginju ati gbigba ilè̩ Kenaani - Ọlọrun ni o ti n ṣakoso wọn. Nigbà ti o bá tọ, Ọlọrun ni ó n yan onidajọ lati ṣakoso wọn ati lati fi òdodo kọ wọn. Ni gbogbo akoko wọnyii, Ọlọrun ni ó ti jé̩ Ọba wọn.

Ọlọrun gẹgẹ bi Ọba

Ọlọrun jé̩ Ọba ti Ó sàn lọpọlọpọ fun awọn eniyan naa ju bí ẹnikẹni ti lè jé̩, Ọlọrun mọ ohun gbogbo, Ó sì rí awọn idanwo ti yoo dé bá wọn, ki wọn tilẹ tó dé paapaa, Ó sì lè ran awọn eniyan naa lọwọ lati borí. Gbogbo agbara wà lọwọ Ọlọrun, Ó sì lè mú iṣẹgun wá fun awọn Ọmọ Israẹli nigbà tí ìrètí kò sí. Ọlọrun ti pèsè ounjẹ ati aṣọ ati ilé fun wọn, irú eyi ti ọba ayé kan kò lè ṣe. Fun ire awọn Ọmọ Israẹli ni ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe.

Ìkọsílè̩

Nisisiyii, Israẹli n kọ ẹyin wọn si Ọba wọn Ọrun, tí Ó kún fun oore-ọfẹ, alagbara jù lọ, Olufunni ni gbogbo è̩bùn rere ati è̩bùn pípé, wọn si n beere pé, ki a fi ẹni kan laaarin wọn ṣe alaṣẹ wọn. Ó mú ibanujẹ nlá bá ọkàn Samuẹli lati gbọ nipa ìlépa asán ti Israẹli n lepa yii. Ọlọrun jé̩ ọré̩ Samuẹli timọtimọ jù lọ, Samuẹli si n fé̩ ki awọn eniyan naa fẹran Rè̩ gẹgẹ bi oun. Dipo eyi, awọn eniyan naa n kọ Ẹni Mimọ Israẹli, wọn sì n beere fun ìfé̩ inú ti ara wọn.

Ọlọrun mọ pé, Samuẹli ti sa gbogbo ipá rè̩ fun awọn Ọmọ Israẹli, Ó si mọ pé, ki i ṣe è̩bi Samuẹli pé awọn eniyan naa n beere fun ọba. Ọlọrun wí fun Samuẹli pé: “Iwọ ki nwọn kọ, ṣugbọn emi ni nwọn kọ lati jẹ ọba lori wọn.”

Ìgbà miiran ti wà bẹẹ, ti awọn eniyan Ọlọrun ti yi pada kuro lẹyin Rè̩, èrè kan naa ni o n ti ibè̩ jade: ẹnikẹni tabi orilẹ-ède ti o bá kọ Ọlọrun silè̩ yoo jìyà nitori rè̩.

Awọn Ọmọ Israẹli ṣe aṣepari ìkọsílè̩ wọn, nigbà ti wọn kan Jesu mọ agbelebu, Jesu ti fi ìtara sọrọ bayii: “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, … igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bò awọn ọmọ rè̩ labẹ apá rè̩, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!” (Matteu 23:37). Wo o bi ọkàn Olugbala wa ti n sọkún lori Jerusalẹmu ọlọtè̩! Sì gbọ ìdáhùn wọn: “Ki ẹjẹ rè̩ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa” (Matteu 27:25). Kò pé̩ lẹyin naa ni awọn Ju bè̩rè̩ si ijẹ ìyà nlá nlà, idajọ yii si n tọ wọn lẹyin titi di ọjọ oni. Èrè kikọ Oluwa silè̩ ni eyi nì; idajọ ti o tún tobi ju eyi lọ wà ni ọjọ ikẹyin.

A Mú Ibeere Wọn S̩ẹ

Ọlọrun ni ki Samuẹli sọ fun Israẹli pé, wọn lè ni ọba bí wọn bá n fé̩ bẹẹ. Ki i ṣe ifẹ Rè̩; ṣugbọn bí wọn bá takú, Ọlọrun yoo gbà wọn layè lati ṣe ifẹ inú wọn. Bi a bá bè̩rè̩ si i bẹ Ọlọrun fun ohun kan, Oun lè gbà fun wa lati ṣe ifẹ inú wa, bí ó tilè̩ jé̩ pé Oun mọ pé nnkan miiran wà tí ó dara ju eyi lọ fun wa. A lè maa yọ nigbà naa pé a mú ibeere wa ṣẹ; ṣugbọn lai pẹ, a o ri i pé ọkàn wa kò balè̩ si i, tabi ki a tilẹ jìyà paapaa; nigbà naa ni a o wa ri i pe awa i bá ti sọ fun Ọlọrun pé, ki Ó mú ifẹ Rè̩ ṣẹ. A ni lati maa gbadura bí Jesu ti gbadura, bí Ó si ti kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati maa gbadura, “Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe.”

Awọn Ọmọ Israẹli kò fé̩ lati mọ ifẹ Ọlọrun. Wọn n fé̩ ọba, wọn ki yoo si dáké̩ titi wọn yoo fi ni ọba naa. Wọn n fé̩ lati dabi awọn orilẹ-ède ìyókù tí ó yi wọn ká. Ni kukuru, a lè wí pé, wọn n fé̩ lati dabi ayé. Ni bibeere lọwọ Samuẹli fun ọba, ó dabi ẹni pé wọn n fé̩ ifohunsi Ọlọrun lori ifẹ ọkàn wọn.

S̩íṣe Bi Ti Ayé

A ri awọn eniyan loni ti wọn n fé̩ lati lọ sí Ọrun. Wọn n fé̩ lati jé̩ Onigbagbọ, ṣugbọn wọn kò fé̩ lati yàtọ si awọn ọré̩ wọn ti o n dẹṣè̩. Awọn ọmọbinrin miiran a maa jé̩ ki ohun kékèké, bi fifi nnkan kun ojú, ètè tabi ọwọ gẹgẹ bi ti ayé jé̩ ìdíwọ fun wọn lati jọwọ ọkàn wọn fun Jesu. È̩rù yè̩yé̩ tí awọn ọré̩ wọn ni ilé-ìwé, awọn tí a kò fi è̩kọ rere tọ yoo fi wọn ṣe a maa bà wọn. Awọn ọdọ miiran rò pé, awọn ní lati maa mu siga nitori “olukuluku eniyan ni o n ṣe e.” Awọn wọnyii dabi awọn ti ó n fé̩ ọba nitori awọn aladugbo wọn ni irú alakoso bẹẹ.

Owó-Ibode Ọba

Samuẹli kìlọ fun awọn Ọmọ Israẹli pé ọba naa ti wọn n fé̩ yàn yoo beere pé kí wọn san owó pupọ. Yoo gba idamẹwa ọwọ-ẹran wọn ati idamẹwa agbo-ẹran wọn; yoo mú awọn ti ó dara jù lọ ninu awọn ọmọkunrin wọn fun awọn ọmọ-ogun rè̩, tabi ki ó fi ṣe iranṣẹ ninu aafin rè̩. Awọn ọmọbinrin wọn ni yoo maa ṣe alase ati oluṣe àkàrà. Yoo maa gbé inú ilé daradara, yoo si maa jẹ ounjẹ ti o dara jù lọ; yoo sì maa ná owó tí ó pọ lọpọlọpọ, eyi ti wọn yoo maa fi silè̩ lati inú aini wọn.

Dajudaju, eyi yii ki i ṣe ohun ti eniyan yoo fẹ ki o ṣẹlẹ si oun, ṣugbọn Samuẹli tún ṣe ìkìlọ miiran tí ó ba ni lẹrù. Nigbà ti akoko naa bá dé ti awọn eniyan naa yoo maa jìyà inilara bayii, Ọlọrun ki yoo gbọ ti wọn, nigbà ti wọn bá kepe E fun iranlọwọ. Olukuluku eniyan ni o n fé̩ iranlọwọ lọdọ Ọlọrun. Wo o bi yoo ti ri bí Ọlọrun kò bá ni feti si adura rẹ nigbà tí o bá wà ninu wahala, nigbà ti kò ni si ẹnikẹni lati tu ẹni ti n ṣọfọ ninu, tí kò ni si ẹnikan lati wo alaisan sàn, tí kò si ni si olutunu fun ọkàn tí ó ni ibanujẹ.

S̩ugbọn awọn Ọmọ Israẹli ti pinnu ohun tí wọn o ṣe. Wọn sa n fé̩ lati ni ọba, ohunkohun ti o wù ki ó lè ti ibè̩ jade. “Bḝkọ; awa o ni ọba lori wa.”

Jijọwọ Ifẹ Wa

Njé̩ a kò maa n rí awọn eniyan ti wọn yan ifẹ inú ara wọn ni àyíká wa nigbà gbogbo? Wọn mọ pé, awọn yoo jìyà ìparun ayérayé bí wọn bá ṣaigbọran si Ọlọrun, ṣugbọn wọn n hùwà bí ẹni pé wọn kò bikita. Ọjọ diẹ ti wọn o gbé nihin dabi ẹni pé ó ṣe pataki fun wọn ju ohun ti yoo jẹ ìpín wọn nigbà ti ayé bá kọja. Wọn kò duro jẹ lati ro o wo, pé, ìgbà inunibini diẹ nihin – lati “yatọ” fun ìgbà diẹ - ni a o gbagbe laaarin ìṣé̩jú kan nigbà tí a bá rí Jesu. Ju gbogbo eyi lọ nigbà ti eniyan bá ni igbala, oun ki i bikita nipa yiyọlẹnu ti awọn ẹlẹgbé̩ rè̩ yoo yọ ọ lẹnu nipa ìgbésí-ayé Onigbagbọ ti ó n gbé. Nigbà ti awọn eniyan tilẹ ni lati jìyà ipalara ti ara tabi ikú fun jijẹ oloootọ, ni mimu iduro fun igbagbọ, Jesu ti duro ti wọn pẹkipẹki lati ràn wọn lọwọ, lati ṣẹgun; a si ti jèrè awọn ẹlẹṣè̩ fun Olugbala nipa kikiyesi ayọ ti awọn ajẹrikú fi n kú dipo-pé, ki wọn sé̩ Oluwa ti ó gbà wọn.

Ohun kan ha wà ti a le san ti o pọ jù fun ìyè ainipẹkun? Ayọ naa yoo dun ti yoo jé̩ ti olukuluku Onigbagbọ ti yoo le duro ni idajọ pẹlu idaniloju pé eyi ni o ti jé̩ adura oun, “Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. S̩e apejuwe ìwà Samuẹli.
  2. Ki ni ipò Samuẹli ni Israẹli?
  3. Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli n fẹ ọba?
  4. Ki ni ọkàn Samuẹli ti ri nipa ifẹ ohun ti ayé ti awọn Ọmọ Israẹli n fé̩?
  5. Ki ni Ọlọrun sọ fun Samuẹli nipa ibeere awọn Ọmọ Israẹli?
  6. Ki ni ohun ti o n ṣẹlẹ si awọn ti o kọ Ọlọrun silè̩?
  7. Ki ni Samuẹli sọ fun awọn eniyan naa nipa ìgbésí-ayé wọn labé̩ akoso ọba?
  8. Èwo ninu adura Oluwa ni o yẹ ki awon Ọmọ Israẹli gbà ni akoko yii?