Orin Dafidi 50:1-23

Lesson 204 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kepè mi li ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yin mi logo” (Orin Dafidi 50:15).
Notes

Ìjọsìn

Ni akoko yii ni ọdọọdun, Ijọba wa maa n ya ọjọ pataki kan sọtọ, ninu eyi ti gbogbo eniyan maa n fi ọpẹ fun Ọlọrun. È̩kọ wa oni n sọ fun wa irú ọpé̩ ati ìyìn wo ni o jé̩ itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun.

Gbogbo eniyan ni Oluwa n pe lati wa juba Rè̩. Ó fé̩ lati kọ wa ni ọnà ijọsin tootọ. Jesu sọ fun obinrin ara Samaria nì lẹba kanga pé awọn olusin tootọ yoo maa “sin Baba li ẹmí ati li otitọ” (Johannu 4:23). Irú awọn wọnyii ni Oluwa n wá ki o maa sin Oun - awọn tí yoo fi otitọ ọkàn sin In. “Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹni ti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ” (Johannu 4:24).

Lati Inú Ọkàn Wá

Lọjọ kan Ọlọrun n bọ ninu ìdájọ, gbogbo eniyan ni yoo si jihin bi wọn ti gbé layé, ati bí wọn si ṣe jọsin niwaju Rè̩. Awọn ti kò mọ Ọlọrun ati awọn alaigbọran ni iná yoo lù pa (2 Tẹssalonika 1:8). Awọn ọrun ati ayé yoo tako awọn tí kò jọsin gẹgẹ bi àṣẹ Ọlọrun. Ọlọrun funra Rè̩ yoo jẹri si awọn ti o bá kùnà lati sìn ní ẹmi ati otitọ. Ó ṣe danindanin pé ki ìyìn ati ọpẹ wa jé̩ irú eyi ti o jé̩ itẹwọgbà. Ọlọrun kò ni inú dídùn ninu ijọsin tí a ṣe bí ẹni pé ohun nlá kan ni a n ṣe fun Un, tabi nitori a rò pé, ó jé̩ ọranyàn lati yin Ọlọrun. Ìsìn òde ara ni irú ijọsin bẹẹ jé̩. Ọlọrun n fé̩ ìsìn tootọ, eyi tí ó ti inú ọkàn wá, eyi tí a ṣe ninu ifé̩ ati igbagbọ. Ọlọrun kò ni inú dídùn ninu awọn ti wọn n fi ahọn wọn yin In, ṣugbọn ti ọkàn wọn jìnnà si I (Isaiah 29:13).

Majẹmu nipa Ẹbọ

Awọn eniyan Ọlọrun, eyi ni awọn eniyan mimọ ni a o kojọ pọ si ọdọ Oluwa. Awọn eniyan mimọ ni awọn ti o ti fi ẹbọ ba A dá majẹmu. Awọn eniyan mimọ miiran kò si, yatọ si awọn ti àdéhùn wọn pẹlu Ọlọrun ti ná wọn ni ohun kan. Ninu Saamu ti o tẹle e, a kà bayii: “Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn” (Orin Dafidi 51:17). Ẹbọ ti Ọlọrun n fé̩ ni ẹmi ironupiwada tootọ. Irora àyà, eyi tí ó kaanu fun awọn è̩ṣè̩ tí ó ti dá, ni Oun ki yoo gàn. Ọlọrun a maa tẹwọgbà ẹbọ ti ó bá ná eniyan ni ohun kan. È̩ṣè̩ rè̩ ni oluwa rè̩ ni lati kọkọ fi rubọ.

Ironupiwada tootọ ni yíyí-pada kuro ninu è̩ṣè̩. Ní ìgbà Majẹmu Laelae paapaa nigbà tí a maa n ru ẹbọ è̩ṣè̩ lati ìgbà dé ìgbà, Oluwa wí pé, “Ẹ yipada kuro ninu ọna buburu nyin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ” (2 Awọn Ọba 17:13).

Ifararubọ

Awọn eniyan mimọ a maa rú ẹbọ miiran si Ọlọrun wọn – nipa fifi ayé wọn rubọ. Paulu kọwé sí awọn ara Romu nipa eyi; “Nitorina mo fi iyọnu Ọlọrun bè̩ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ āye, mimọ, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isin nyin ti o tọna” (Romu 12:1).

Nigbà ti eniyan kan bá n gbadura fun igbala, oun a fi ayé rè̩ rubọ fun Ọlọrun. Nigbà tí eniyan bá n wá isọdimimọ ati agbara Ẹmi Mimọ, yoo tilẹ walè̩ jìn ju bẹẹ lọ ninu ifararubọ. Ọlọrun lè lo akoko wa ati talẹnti wa. Bi a bá fi iwọnyi fun Ọlọrun pẹlu, Oun yoo pè wa si iṣé̩ tí ó ga ju eyi lọ fun Un. Ọlọrun n beere ifararubọ - ki i ṣe ni kìkì akoko tí eniyan bá n wa ìrírí kan nikan ṣoṣo, ṣugbọn ifararubọ ni ojoojumọ, lati wà laayè fun Oluwa ati lati ṣe ifẹ Rè̩. Ati ọmọde ati àgbà ni wọn lè ṣe ifararubọ wọnyii, ani, wọn tilẹ gbọdọ ṣe wọn, ki wọn ba le ṣe aṣeyọri ninu ìgbésí-ayé wọn gẹgẹ bi Onigbagbọ.

Agabagebe

Nipa bayii ni Ọlọrun n kọ wa ní irú ẹbọ ti ó jé̩ itẹwọgba niwajú Rè̩ - ni àkọkọ, ẹbọ iroupiwada; ekeji ni ifararubọ. S̩ugbọn lẹyin tí Ọlọrun tilẹ ti fun wa ni è̩kọ wọnyii, awọn eniyan kan wà tí ó jé̩ pé nipa iṣé̩ ode ara, wọn n fé̩ ki awọn ẹlomiran kà wọn si olododo. Agabagebe ni wọn, o kàn dabi ẹni pé wọn n rubọ ọpẹ si Ọlọrun ni. S̩ugbọn irú ìyìn wọn kò jé̩ itẹwọgbà.

Igbọran

Apẹẹrẹ ẹbọ ti Ọlọrun kọ ni a ri ni ti ọkan ninu awọn ọba Israẹli, ẹni ti o dá ohun ti Ọlọrun pàṣẹ pé kí ó parun sí. Ó gbiyanju lati ṣe àwáwí nipa sisọ pé fun irubọ si Oluwa ni oun ṣe dá awọn agutan ati akọ-maluu naa si. Wolii Samuẹli dahùn bayii: “Oluwa ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gbà ohùn Oluwa gbọ? Kiye si i igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilè̩ si sàn jù ọra àgbo lọ” (1 Samuẹli 15:22).

Ni akoko miiràn, nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli fara hàn bí ẹlẹsin nipa riru ẹbọ pupọ, Ọlọrun wí pé, “Emi kún fun ọrẹ sisun agbò … bḝni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ mal.” Ìsìn wọn ki i ṣe ìsìn otitọ. Ọlọrun gbà wọn ni imọran lati wè̩ ki wọn si mọ, lati mú buburu ìṣe wọn kuro, ki wọn dawọ duro lati ṣe buburu, ki wọn kọ lati ṣe rere (Isaiah 1:11-17).

Lati ẹnu Wolii Hosea, Ọlọrun wi pé, “nu ni mo fé̩, ki iṣe ẹbọ: ati ìmọ Ọlọrun jù ọrẹ-ẹbọ sisun lọ” (Hosea 6:6).

Ni akoko kan, wolii kan ni Israẹli beere bí o ti yẹ ki oun wa siwaju Oluwa. O beere bi inú Ọlọrun yoo ba dùn si “ẹgbẹgbè̩run àgbo, tabi si ẹgbẹgbārun iṣàn òroro” fun irekọja rè̩ ati è̩ṣè̩ ọkàn rè̩. Idahun ni yii: “A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ānu, ati ki o rìn ni irè̩lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?” (Mika 6:7, 8).

Iyìn

Onisaamu sọ fun wa lati “ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun.” Ẹbọ ọpẹ jé̩ itẹwọgbà. A si tún gbà wa niyanju siwaju si i lati san è̩jé̩ ti a jé̩. Dajudaju, olukuluku eniyan ni o ti gbadura ti o si ti bá Ọlọrun ṣe ileri nigbà ti ó wà ninu ipọnju (Orin Dafidi 66:13, 14). Ọlọrun ti duro lori ọrọ ti ẹni kọọkan ti sọ, O si n reti pé, ki a mú awọn è̩jé̩ wọnni ṣẹ. È̩jé̩ jé̩ igbese ti a ni lati san, a si gbọdọ ṣe ojuṣe wa. Ọlọrun ti ṣe ipa ti Rè̩. Njé̩ awa ha ti ṣe ti wa?

Yiyin Ọlọrun Logo

Nigbà ti ẹni kan bá mú ileri rè̩ fun Ọlọrun ṣẹ, igboya rè̩ ninu Oluwa yoo ti pọ tó! O mọ pé Ọlọrun yoo gbọ adura oun ati pé yoo si gbà oun ni akoko aini. Igbesẹ kan kù ti Ọlọrun tun n reti – “Iwọ o si ma yin mi logo.” Ijọsin ododo ni eyi, fifi ogo ati iyin fun Ọlọrun. A ti kọ nipa ìgbà ti Jesu wo awọn adé̩tè̩ mẹwaa sàn ni akoko kan. (Ẹkọ 127). Ẹni kan ṣoṣo ninu wọn ni o pada, “o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo … o ndupẹ li ọwọ rè̩.” Jesu wí pé, “Awọn mẹwa ki a sọ di mimọ? Awọn mẹsan iyokù ha dà? A kò ri ẹnikan ti o pada wá fi ogo fun Ọlọrun, bikoṣe alejò yi?” (Luku 17:15-18). Ó lè ma jé̩ arun è̩tè̩ ni Ọlọrun wosan lara wa, ṣugbọn gbogbo eniyan ni o ti ri ibukun gbà lati ọdọ Ọlọrun. Njé̩ a pada lati fi ogo fun Un? tabi a o ha kà wa mọ awọn mẹsan-an ti wọn bá ti wọn lọ, ti wọn kùnà lati yin In?

Ninu ìwé Paulu sí awọn ara Romu, o sọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ nigbà tí eniyan bá fa ọwọ idupẹ, iyìn ati imoore sẹyin kuro lọdọ Ọlọrun. Oluwa rè̩ a sọ ifé̩ Ọlọrun nù. A o jọwọ ẹni naa fun è̩ṣè̩ ati èrè è̩ṣè̩. “Igbati nwọn mọ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bḝni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn nwọn wa idasan ni ironu wọn, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣòkunkun” (Romu 1:21).

Ìdájọ

Awọn ẹlomiran fẹran ati maa pàṣẹ ki wọn sì maa sọ fun awọn ẹlomiran ohun ti wọn gbọdọ ṣe, ṣugbọn ninu ọkàn wọn, wọn korira àṣẹ Ọlọrun. Wọn a gbiyanju ni ọnà ti wọn lati jọsin fun Ọlọrun, dipo ki wọn kẹkọọ lọdọ Rè̩ nipa ọnà ijọsìn tootọ, Ọlọrun mọ gbogbo nnkan ti a ṣe lòdì si I, ati ki ni ète ti ó pilè̩ wọn gan an. Didakẹ ti O dakẹ titi di isisiyii kò fi hàn pé, Oun yoo dakẹ bẹẹ titi laelae lori nnkan wọnyii. “Nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pāpa lati huwa ibi” (Oniwasu 8:11). Nigbà pupọ ni awọn ẹlẹṣè̩ maa n ka idakẹjẹ Ọlọrun si itẹlọrun Rè̩. Ki a má ṣe tàn ọ jẹ; Ọlọrun ni akọsilẹ ti a o ṣi nigbà ti ọjọ bá pé. Ọlọrun n kilọ - má ṣe gbàgbé Ọlọrun – nitori gbigbagbe tabi ṣiṣe aibikita ni o n saaba maa n jé̩ gbòngbo è̩ṣè̩.

Bi a ti n kẹkọọ lori Orin Dafidi aadọta yii, ó mú wa lọkàn pé lati inú ọkàn wa ni ijọsin tootọ ti n jade. Awọn kan wa ti wọn n fi ẹnu wọn “fun buburu”, ti ahọn wọn si “npete è̩tan.” “Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rè̩ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá” (Matteu 12:35).

Ẹ jé̩ ki a fi ọkàn si ohun ti a ti kọ ninu è̩kọ yii, ki ìparun lile ti ó n duro de awọn agagbagebe, awọn ẹlè̩tàn ati gbogbo ẹlẹṣè̩, má ba jé̩ ìpín wa. O yẹ ki a fi ọkàn wa rubọ sí Ọlọrun; nipa iranwọ Rè̩, ki a si mú ọnà wa tọ, eyi ni ìgbésí-ayé wa, awọn ti a n ba da nnkan pọ, ìwà wa, ati ọrọ sisọ wa bakan naa. Ẹ má ṣe jé̩ ki a kùnà lati fi ogo ati iyìn ati ọpé̩ fun Ọlọrun - ijọsin tootọ - ni Ọjọ Idupẹ; bẹẹ ni, ani ni ọjọ gbogbo ninu ọdún. Ẹnikan ti sọ pé ki a maa fi ìwà ati ìṣe wa dupẹ, sàn jù ki a kàn maa dupẹ lọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Ọlọrun n pè lati sin In?
  2. Ta ni yoo jẹri ti yoo si takò awọn eniyan?
  3. Irú ẹbọ meji wo ni ó jé̩ itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun?
  4. Irú ijọsin wo ni kò jé̩ itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun?
  5. Awọn wo ni eniyan mimọ?
  6. Ki ni ṣe ti ó fi jé̩ danindanin lati san è̩jé̩?
  7. Bawo ni Ọlọrun ṣe n fẹ ki a sin Oun?
  8. Bawo ni a ṣe lè mú ìgbésí-ayé wa tọ?