Lesson 205 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli” (1 Samuẹli 15:17).Notes
Yíyàn ti Ọlọrun
Awọn Ọmọ Israẹli ti takú pé, awọn n fé̩ ọba kan lati maa ṣe akoso wọn, ki wọn ba le dabi awọn orilè̩-ède iyoku. Ọdọmọkunrin kan tí Ọlọrun yàn lati jẹ ọba jé̩ ọkan ninu awọn è̩yà Bẹnjamini, ọmọ Kiṣi, ẹni ti i ṣe ọkunrin alagbara kan. Saulu jé̩ ọmọkunrin ti ó tayọ laaarin ọpọ eniyan. A maa bọwọ fun baba rè̩. Ó jé̩ onirẹlè̩ ati ẹni ti ó ni ìtara fun ohun rere. Bi o ba jé̩ pé awọn eniyan naa ni o yan Saulu, o dajú pé nitori ìrí rè̩ ni wọn i ba ṣe yàn an, nitori Saulu jé̩ ẹni ti ó singbọnlẹ, ti ó si lagbara. O dajú pé Ọlọrun yan Saulu nitori O ri awọn ìwà ti O lè lò gẹgẹ bi ọba ninu ọkàn ọdọmọkunrin naa, ni akoko naa. Ni ọnà ti Ọlọrun, a mú Saulu wá siwaju Samuẹli, eniyan Ọlọrun, ẹni ti yoo fi ẹni ti Ọlọrun yàn gẹgẹ bi ọba hàn.
Onigbọran
A rán Saulu jade lati lọ wá kẹtẹkẹtẹ baba rè̩ tí ó sọnù. Ó gbọran sí àṣẹ baba rè̩, nitori kò gberaga pé, oun ti ga ju ẹni tí ó lè ṣe irú iṣé̩ bẹẹ. Awọn ọdọmọkunrin miiran lè dá baba wọn lohùn lọnà bayii: “Mo ni awọn nnkan miiran lati ṣe”; “Jé̩ kí ẹlomiran lọ wá wọn”; “Ki ni ṣe ti emi ni lati maa ṣiṣẹ nigbà ti a ni awọn ọmọ-ọdọ?” Nigbà tí Saulu gbọran sí àṣẹ baba rè̩, kò mọ ohun tí Ọlọrun ni lọkàn lati ṣe fun oun. Ó gbọran nitori ifẹ ati ọwọ wà ninu ọkàn rè̩ fun baba rè̩. Boya Ọlọrun ki bá ti yàn án ni ọba, bi ó bá ṣe pé kò gbọran si àṣẹ baba rè̩.
Iṣé̩rírán Kan
Saulu ati ọmọ-ọdọ kan lọ kaakiri si ibi pupọ ṣugbọn wọn kò ri awọn ẹranko ti o sọnu naa. Nikẹyin, Saulu pinnu lati pada si ilé, ki baba rè̩ ma baa maa daamu nitori wọn, nitori ó ti pé̩ ti wọn ti lọ. Ọmọ-ọdọ naa wí pé, eniyan Ọlọrun kan wà ni ìlú tí ó wà nitosi wọn. Ó damọran pé, boya Wolii naa yoo le sọ ọnà ti wọn o gbà fun wọn. Saulu wòye pé, amọran rere ni eyi, nitori naa wọn bè̩rè̩ si i wá Wolii naa lọ - tabi arina, gẹgẹ bi wọn ti maa n pe e ni ìgbà atijọ. Nigbà ti awọn ọkunrin meji naa dé tosi ìlú, wọn beere nipa Wolii naa. Wọn wi fun wọn pé, wọn rin si deedee akoko tí ó dara, nitori Woli naa fẹ lati rú “ẹbọ fun awọn enia.”
Ọlọrun Ni Ó Rán an
Ọlọrun ti ṣè̩tò ipade Saulu ati Samuẹli Wolii. Bi o tilè̩ jé̩ pé, o dabi ẹni pé ó kan ṣẹlè̩ bẹẹ ni, Ọlọrun ni ó ti ṣè̩tò pipade wọn. Ní ọjọ tí ó ṣáájú eyi, Ọlọrun ti sọ fun Samuẹli pé, Oun yoo rán ọdọmọkunrin naa tí a o fi àmì òróró yà sọtọ lati jẹ olori ogun Israẹli. Ó dabi ẹni pé Saulu kò si ni ipò ọlá tabi ipò pataki kan ṣáájú akoko yii. Ọlọrun ni ó n gbe e ga lati jẹ ọba.
A ti darí Saulu si ọdọ Samuẹli; ṣugbọn nigbà tí ó ṣe alabapade Wolii naa, kò mọ ọn. S̩ugbọn Samuẹli mọ Saulu, nitori Ọlọrun ti wí pé, “Wo ọkunrin na ti mo ti sọrọ rè̩ fun ọ! on ni yio jọba awọn enia mi.”
Nigbà ti Saulu beere itọka ọnà si ilé Wolii naa, Samuẹli wí pé, “Emi ni arina na.” Samuẹli sọ nipa awọn kẹtẹkẹtẹ naa fun Saulu, ki ó tilè̩ tó beere nipa wọn. Ọlọrun ti sọ idáhùn naa fun Samuẹli. Samuẹli sọ fun Saulu pé, ki o gbàgbé nipa ti awọn kẹtẹkẹtẹ naa fun ìgbà diẹ na, pé a ti rí wọn. Samuẹli pé Saulu lati lọ si ibi irubọ, ki o jẹun, ki o si bá oun jokoo di ọjọ keji.
Ìrè̩lè̩
Ju bẹẹ lọ, Samuẹli wí pé, “gbogbo ifẹ Israẹli” wà lara Saulu ati ile baba rè̩. Ifẹ Israẹli ni fun ọba kan lati maa ṣe akoso lori wọn. Nitori naa, a sọ fun Saulu pé, a ti yàn an lati jẹ ọba fun Israẹli. Saulu fi ọkàn ìrè̩lè̩ dahùn. Ó ni lati inú è̩yà ti ó kere ju lọ ni oun ti wá, ati lati inú ìdílé tí ó rẹyin jù lọ. A rán Saulu ni iṣé̩ kan ni, lati wá awọn kẹtẹkẹtẹ baba rè̩; ṣugbọn ó fi ìrè̩lè̩ gbà ìpè tí ó ga yii.
Ọlá
Pẹlu gbogbo ọlá tí ó yẹ ẹni ti yoo jẹ ọba ni ọjọ iwajú, ni Samuẹli fi bá Saulu lò. A fun Saulu ni “ijoko lārin awọn agbagba ninu awọn ti a pè” - awọn tí ó tó ọgbọn eniyan. Ẹran ti o dara jù lọ ni a gbé ka iwajú rè̩ - ibi ejika. Lọnà bayii, nipa fifi Saulu si ipò tí ó dara jù lọ ati fifun un ni ounjẹ tí ó dara jù lọ, ni a fi hàn pé, ó jé̩ àlejò pataki ati ẹni ti a dá lọlá ju lọ laaarin wọn.
Ki wọn to sùn ni alé̩ ọjọ naa, Samuẹli bá Saulu sọrọ. Boya o bá Saulu sọ awọn ohun tí ó jé̩ ojuṣe rè̩ gẹgẹ bí alakoso ní Israẹli. Ó dajú pé, Samuẹli yoo bá Saulu sọrọ imulọkanle fun iṣé̩ tí ó wà niwaju rè̩. Ní kutukutu owurọ ni wọn ti jí ní ọjọ keji. Nigbà ti Saulu ati iranṣẹ rè̩ n lọ, Samuẹli sin wọn dé òpin ìlú. Wọn paṣẹ fun iranṣẹ naa lati kọja si iwajú wọn. Wolii naa wí fun Saulu pé, “Ki iwọ ki o duro diẹ, ki emi ki o le fi ọrọ Ọlọrun hàn ọ.”
Saulu kò mọ irú ibukun ti Ọlọrun ti pèsè silè̩ fun oun ni owurọ ọjọ yii. Saulu ati Wolii naa duro niwaju Oluwa. Gẹgẹ bí Ọlọrun ti dari rè̩, Samuẹli tú òróró sí Saulu ní orí lati fi òróró yàn an. Ọlọrun ti yan Saulu lati ṣe balogun lorí ìní Rè̩, ti i ṣe awọn Ọmọ Israẹli.
Awọn Ìlérí
Lati fi hàn pé Ọlọrun wà pẹlu Saulu, Wolii naa fun un ni àmì mẹta ti yoo ṣẹ. Àmì wọnyii sì tún jé̩ ìlérí. Ekinni, awọn ọkunrin meji yoo wá sọrọ fun un nipa awọn kẹtẹkẹtẹ tí ó n wá: “Nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ ti iwọ ti jade lọ iwá.” Ekeji, a o pese fun aini Saulu nipa ti ara lati ọwọ awọn ọkunrin mẹta ti yoo pade ní pẹtẹlẹ Tabori: “Nwọn o si ki ọ, nwọn o si fi iṣù akara meji fun ọ; iwọ o si gbà a lọwọ wọn.” Ẹkẹta, Saulu yoo di alagbara nipa ti ẹmi nigbà tí ó bá pade ẹgbé̩ wolii ni òkè Ọlọrun: “Ẹmi Oluwa yio si bà le ọ, iwọ o si ma ba wọn sọtẹlẹ … nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ.”
Dídúró Jẹẹ
Awọn ìlérí wọnyii ní lati jé̩ ìwúrí nlá nlà fun Saulu. Ranti pé, Ọlọrun rán awọn ìlérí wọnyii si i nigbà tí a sọ fun Saulu pé, kí ó dúró jẹẹ lati gbọ ọrọ Ọlọrun. Ki ni Ọlọrun yoo ṣe fun wa bí a bá dúró jé̩é̩ niwajú Rè̩? Ó lè dabi ohun ti ó ṣoro lati “duro jẹẹ” nigbà ti o ṣe pé, ariwo ati rudurudu ayé ati aisimi ni o wà yi wa ká. Awọn tí ó maa n gbadura tí wọn sì n ṣe àṣàrò niwajú Ọlọrun ni owurọ a maa ri i pé, Ọlọrun maa n fun wọn ni imulọkanle ninu iṣé̩ wọn ati ìrànwọ ní ìgbà àìní. Ọmọde tí ó bá n gbadura tí ó sì n ka Bibeli kí ó tó lọ sí ilé-è̩kọ yoo rí ìlérí pé Ọlọrun yoo wà pẹlu oun lati fun oun ní iṣẹgun lori ìdánwò gbogbo. Anfaani ni ó jé̩ fun wa lati ṣe àṣàrò ati lati ronu nipa awọn ohun ti Ọlọrun – lati “duro jẹẹ” niwajú Ọlọrun - ní ọsán gẹgẹ bí ni owurọ. Ibukún ni fun ọkunrin naa, ẹni ti “didùn-inu rè̩ wà li ofin OLUWA; ati ninu ofin rè̩ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru” (Orin Dafidi 1:1, 2).
Ọkàn Miiran
Ọlọrun ti pe Saulu lati dí àyè nlá kan. Ọlọrun ti fun Saulu ní awọn ìlérí ìyanu. A kò gbọ pe Saulu fi ohun ẹnu dahùn ìpè Ọlọrun, ṣugbọn ninu ọkàn rè̩, ó ti dahùn pé, “Bẹẹ ni” fun Ọlọrun. Bawo ni a ṣe mọ? Ẹmi Ọlọrun ba le e, o si yi pada – “O si di ẹlomiran.” Ẹmi Ọlọrun ki i deedee wá bá eniyan gbé, afi bí ẹni naa bá pe E tí ó si n fẹ Ẹ. Ọlọrun ki i gba eniyan là, afi bí ẹni naa bá n fé̩ lati rí igbala. Nigbà tí Ẹmi Ọlọrun bá wọ inú ọkàn eniyan kan, è̩ṣè̩ yoo kuro nibẹ, ẹni naa yoo si yipada. Ọlọrun fun Saulu ni “ọkàn miran” – “ọkàn titun”, gẹgẹ bí eyi tí Ọlọrun ṣeleri lati fun gbogbo awọn Ọmọ Israẹli, bí wọn bá yipada si I (Esekieli 36:26, 27), “ọkàn lati mọ mi, pe, Emi li OLUWA,” eyi ti Ọlọrun yoo fun ẹnikẹni tí ó bá yipada si I, pẹlu gbogbo ọkàn rè̩ (Jeremiah 24:7).
Iyipada Kan Naa
Ọlọrun a maa ṣe iyipada kan naa ni akoko yii; a maa yi ọkàn pada nigbà ti eniyan bá ri igbala. Kò si iyatọ - ẹni naa i ba jẹ ọmọde, tabi agbalagba. Ọlọrun a yọ ifẹ ibi ati ti è̩ṣè̩ kuro; a mú ifẹ si ohun afé̩ ayé kuro. Owú, ikorira, ibinu, “iwa ti ara” ati ohun gbogbo ti i ṣe buburu yoo rekọja. Ọlọrun yoo fi ifẹ Rè̩ sinu ọkàn naa, eyi yoo si maa mú ki ẹni naa maa ṣe rere, ki o si fẹ lati mọ Ọlọrun sii. Nigbà tí eniyan kan bá yipada, iwa ẹni naa yoo yàtọ. Awọn ẹlomiran yoo le wí pé, iyipada si rere ti ṣẹlẹ ninu ẹni naa.
Awọn àmì tí a sọ nipa Saulu ṣẹlẹ bẹẹ, awọn eniyan si ri iyipada ninu Saulu. Wọn wi pe, “Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?”
Kò Si Ibi Ifarapamọ
Saulu kò tilẹ sọ fun awọn ara ilé rè̩ paapaa, pe a ti fi òróró yan oun ni ọba. Nigbà ti akoko tó, Samuẹli kó awọn Ọmọ Israẹli jọ lati rán wọn leti pé, wọn ti kọ Ọlọrun silẹ, wọn si ti beere fun ọba. Akoko tó fun awọn eniyan naa lati mọ ẹni ti Ọlọrun yàn. Nigbà ti a sọ fun awọn eniyan pé, Saulu ni ẹni naa, wọn wo yika, wọn kò si ri i. Ninu ìrè̩lè̩ rè̩, o ti fi ara rè̩ pamọ. Saulu jé̩ ẹni ti o ga ju gbogbo wọn lọ lati ejika rè̩ soke, nitori naa kò ṣe i ṣe fun un lati fi ara rè̩ pamọ laaarin awọn eniyan. Saulu kò lè fi ara pamọ pẹ titi, nitori Ọlọrun mọ ibi ti o wà. Ọlọrun sọ nipa Saulu pé, “Wõ, o pa ara rè̩ mọ lārin ohun-elò.” A mú Saulu jade wá; Samuẹli si fi hàn niwaju gbogbo wọn gẹgẹ bí ọba wọn. Gbogbo awọn eniyan naa si hó yè.
Saulu pada si ile rè̩, awọn ẹgbé̩ ọkunrin tí ó ṣe oloootọ si i si ba a lọ. Bi a ti n kọ è̩kọ siwaju si i nipa ọba kin-in-ni fun awọn Ọmọ Israẹli yii, ẹ jé̩ ki a pa eyi mọ ninu ọkàn wa pé, a fun un ni anfaani ati ọlá nlá yii nigbà tí ó jé̩ ọkunrin onirè̩lè̩ pupọpupọ.
Questions
AWỌN IBEERE- È̩yà wo ní Israẹli ni Saulu ti wá?
- Iṣé̩ ìrè̩lè̩ wo ni a rán an?
- Ta ni Saulu tọ lọ?
- Ki ni Samuẹli ṣe fun Saulu?
- Awọn ìlérí wo ni a ṣe fun Saulu?
- Bawo ni Saulu ṣe fi ìrè̩lè̩ rè̩ hàn?
- Ki ni maa n ṣẹlẹ nigbà ti Ẹmi Ọlọrun bá wá sinu ọkàn eniyan?
- Ki ni ṣe ti awọn eniyan beere bí Saulu bá pẹlu awọn woli?