1 Samuẹli 11:14, 15; 12:1-25

Lesson 206 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iwọ ti dan aiya mi wò, … iwọ ti wadi mi, iwọ kò ri nkan” (Orin Dafidi 17:3).
Notes

Ayọ Nlá ní Israẹli

Ayọ nlá ni ó wà laaarin awọn Ọmọ Israẹli. A ṣè̩ṣè̩ fi ọba wọn jẹ ni; ninu idanwo rè̩ akọkọ, o ti fi ara rè̩ hàn gẹgẹ bi ẹni ti o jé̩ akikanjú ninu ogun, tí ó lè ṣakoso, tí ó sì lè jẹ balogun ẹgbé̩ ogun nlá. Ọlọrun ti fun un ní iṣẹgun lori awọn ọmọ Ammoni; awọn Ọmọ Israẹli sì lè maa rò ninu ọkàn wọn pé, ọjọ iwajú yoo dara bí Saulu bá jẹ aṣiwaju wọn. Dajudaju ohun gbogbo tí wọn n fẹ ri ninu ọba ni Saulu ní.

S̩ugbọn, ayọ naa kò ti ọdọ Ọlọrun wá. Inú wọn dùn nitori pé, wọn ri ohun tí ọkàn wọn n fé̩. Ni ọjọ iwajú, ohun kan yoo ṣelẹ ti yoo mú wọn kabamọ fun orikunkun wọn.

Fífi Ọba Jẹ

Akoko tó fun Saulu lati gori oyè, Samuẹli si pe gbogbo eniyan jọ sí Gilgali fun ètò ati fi ọba jẹ. Nibẹ, niwajú Oluwa ati laaarin ọpọlọpọ irubọ ni a fi Saulu jọba Israẹli. “Gbogbo awọn ọkunrin Israẹli si yọ ayọ nlanla.”

Lẹyin tí wọn ti fi ọba jẹ tán, Samuẹli sọ ọrọ kan tí ó ṣe pataki. O rán awọn Ọmọ Israẹli leti pé, nisisiyii, wọn ti ní ọba, nitori wọn bè̩bè̩ lati ni ọkan, ki si i ṣe pé, nitori ó jé̩ ifẹ Ọlọrun, nitori naa wahala ki wahala tí ó bá ti ipa ijọba naa dé bá wọn yoo jé̩ àfọwọfà ti wọn. Lodikeji è̩wè̩, o sọ fun wọn bí oun ti ṣe akoso wọn ni igbọran si ifẹ Ọlọrun. Ní gbogbo ọjọ ayé rè̩ ni ó ti n rìn niwajú wọn tí kò si pa ohunkohun ti ó ṣe mọ fun wọn. Lati ìgbà tí ó wà ni ọmọde ni ó ti yọọda ìgbésí-ayé rè̩ fun ṣiṣe ìfé̩ Ọlọrun ati riran awọn eniyan lọwọ.

Njé̩ nisisiyii ti ọjọ ayé rè̩ n buṣe, o wí pé, ki awọn eniyan naa ṣe idajọ oun. O ha ti gba ohunkohun ti i ṣe ti wọn gẹgẹ bí alaṣẹ ti ó ni agbara lati ṣe bẹẹ? Ó ha ti gba abẹtẹlẹ ri, ki ó ba le gbè wọn ni idajọ? Kò si ìgbà kan tí ó fé̩ gba ohunkohun ti i ṣe ti wọn, bẹẹ ni kò ni wọn lara lọnàkọnà. S̩e awọn Ọmọ Israẹli yoo jẹri pé, oun ti jé̩ oloootọ ati olododo? Awọn eniyan naa gbà pé, Samuẹli jé̩ oloootọ gẹgẹ bí ó ti wí. Wọn kò rí nnkan wí sí ọnà tí ó ti fi ṣe akoso wọn.

Ki i ṣe awọn eniyan naa nikan ni Samuẹli pè lati ṣe idajọ iṣé̩ rè̩, ṣugbọn o pe Ọlọrun pẹlu, Ẹni ti O mọ èrò inú ati ète ọkàn, lati jẹri pé, nigbà gbogbo ni oun ti n ṣe ohun ti ó tọ. Ohun tí ó lekè lọkàn Samuẹli ni lati wu Ọlọrun. A kà ninu Ọrọ Mimọ Ọlọrun bayii: “Kò si aiṣedede kan lọdọ OLUWA Ọlọrun wa, tabi ojusaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ” (2 Kronika 19:7), Ọlọrun si n fé̩ ki awọn ọmọ Rè̩ dabi Rè̩ nihinyii, nigbà ti a wà ninu ayé yii. Bi a bá sọ fun Un, Ọlọrun yoo fun wa ni agbara lati ṣe gẹgẹ bi Samuẹli ti ṣe, to bẹẹ tí ẹnikẹni kò ní lè rí è̩sùn sùn wa nitootọ lori ohun tí a n ṣe.

Itọni Ọlọrun

Lẹyin eyi, Samuẹli sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pé, ki wọn ranti ìtàn ìran wọn. Ọlọrun ni Ẹni tí ó gbé Mose ati Aaroni dide lati mú awọn baba nlá wọn jade kuro ninu oko-ẹrú Egipti. Oluwa ni O ti wọ wọn laṣọ, tí Ó sì ti fun wọn ni ounjẹ jẹ laaarin ìrinkiri wọn fun ogoji ọdún ninu aginju. Nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli si ṣè̩, Ọlọrun ti jàre jijé̩ kí ìyà dé bá wọn lati fi hàn wọn pé, wọn ti dẹṣè̩. Ó ti ja ìjà wọn fun wọn, Ó sì ti mú wọn dé ilè̩ rere naa.

Samuẹli wa bi awọn Ọmọ Israẹli bí wọn kò bá lè ri pé Ọlọrun Olodumare kan ṣoṣo ni Ó wà, Ọlọrun kan ṣoṣo tí Ó fé̩ òdodo, tí Ó si ni aanu ati irọnu fun awọn eniyan Rè̩. Ọlọrun miiran wo ni ó lè ṣe itọjú awọn eniyan bi Ọlọrun ti ṣe itọjú awọn Ọmọ Israẹli?

Ọlọrun ti gbé awọn onidajọ dide lati maa ṣe akoso awọn Ọmọ Israẹli nigbà tí wọn ti ṣe alaini. Ọlọrun ti yan awọn balogun tí wọn kó awọn ogun wọn jade lati ní iṣẹgun tí ó dajú. Ọlọrun ti ṣe gbogbo eyi fun awọn eniyan Rè̩, nitori Ó fẹran wọn ati nitori majẹmu Rè̩ pẹlu Abrahamu.

Aimoore

Njé̩ awọn Ọmọ Israẹli moore? Rara o; wọn ti yí pada lẹyin Aṣiwajú wọn atọrunwá, wọn si ti beere fun ọba. “Njé̩ nisisiyi wo ọba na ti ẹnyin yàn, ati ti ẹnyin fẹ!” ni Samuẹli wí fun wọn. Ó fé̩ kí wọn mọ pé oun kò ni ọwọ ninu bibeere fun ọba.

Mose pẹlu ti ni lati bá irú ìwà aimoore bayii pade rí laaarin awọn Ọmọ Israẹli. Nigbà kan o beere pe, “Bayi li ẹnyin o ha san ẹsan fun OLUWA, ẹnyin aṣiwere enia ati alaigbọn? On ha kọ ni baba rẹ ti o rà ọ? on li o dá ọ, on li o si fi ẹsè̩ rẹ mulẹ?” (Deuteronomi 32:6).

A maa n kaanu fun awọn obi ti o jé̩ pé, ni akoko ogbó wọn, awọn ọmọ wọn ta wọn nù, awọn ọmọ tí wọn ti ṣe laalaa lé lori, tí wọn titori wọn fi ọpọlọpọ anfaani du ara wọn, tí wọn si ti fi ọpọlọpọ ifẹ hàn fún. S̩ugbọn bawo ni yoo ti ri lati ta Baba wa Ọrun nù, Ẹni ti n ṣe ohun gbogbo fun wa, bi a bá gbà fun Un lati ṣe e? O ti pe awọn Ọmọ Israẹli ní ọgbà Rè̩ ri, O si beere pe: “Emi bè̩ nyin, ṣe idajọ lārin mi, ati lārin ọgba àjara mi. Kini a ba ṣe si ọgba àjara mi ti emi kò ti ṣe ninu rè̩?” (Isaiah 5:3, 4). Ki ni Ọlọrun i ba tun ṣe lati pese wa silẹ fun Ọrun? O rán Ọmọ Rè̩ kan ṣoṣo lati wá kú fun wa; Jesu si yọọda ohun gbogbo ti O ní, O si ru è̩ṣè̩ wa ni Kalfari, ki a ba le ri igbala. O ti fi Ẹmi Rè̩ ranṣẹ sinu ayé lati rọ wá sinu Ijọba Ọlọrun, ati lati tọ wa sinu otitọ gbogbo. Ki ni I ba tun ṣe? A ha mọ riri ifẹ Rè̩ ati ifararubọ Rè̩?

Ojúṣe Ọba

Sibẹ, Samuẹli fi ìrètí diẹ silẹ fun awọn Ọmọ Israẹli. Bi awọn eniyan naa ati ọba wọn bá pa ofin Ọlọrun mọ, Oun yoo bùkún fun wọn, yoo si ṣe ọnà wọn ni rere sibẹ. Bi ọba bá bè̩rù Ọlọrun, yoo ri ọgbọn gbà lati ṣe akoso daradara ati lati mú inú awọn iranṣẹ rè̩ dùn.

Ọlọrun ti mọ pé Israẹli yoo ṣafẹri ọba, O si ti paṣẹ fun Mose lati kọ akọsilẹ ohun ti yoo jé̩ ojuṣe irú ọba bẹẹ. Ohun tí Mose kọ niyii: “Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori ité̩ ijọba rè̩, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rè̩, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi: yio si wà lọdọ rè̩, on o si ma kà ninu rẹ li ọjọ aiye rè̩ gbogbo: ki o le ma kọ ati bè̩ru OLUWA Ọlọrun rè̩, lati ma pa gbogbo ọrọ ofin yi mọ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn: ki àiya rè̩ ki o má ba gbega jù awọn arakọnrin rè̩ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ ọtún, tabi si òsi” (Deuteronomi 17:18-20).

Òjò ni Ìgbà Ẹẹrun

Samuẹli ti fi hàn ni ọnà tí o yanjú fun awọn eniyan naa pé, Ọlọrun Ọrun ni Ọlọrun kan ṣoṣo tí O wà, sibẹ o tún fun wọn ni àmì kan sii. O jé̩ akoko ìkórè ọkà, nigbà tí òjò ki i rọ ní Palestini. S̩ugbọn ni akoko yii Samuẹli wi pé, “Emi o kepe OLUWA, yio si ran āra ati ojò.” Eyi jé̩ lati fi hàn awọn Ọmọ Israẹli bi wọn ti jé̩ aṣiwere tó lati kọ Ọlọrun Olodumare silẹ, Ẹni ti O ni agbara lori ohun gbogbo ati lati beere pé, ki eniyan lasan maa jọba lori wọn. Ọlọrun dahùn adura Samuẹli, O si rán ààrá ati òjò. È̩rù ba awọn eniyan naa to bẹẹ ti wọn fi rò pé awọn yoo kú. Ọkàn wọn dá wọn lẹbi fun aigbọran wọn, nigbà ti o dabi ẹni pe òjò idajọ Ọlọrun ni o n rọ.

Awọn Ọmọ Israẹli kigbe si Samuẹli pé: “Gbadura…fun awọn iranṣẹ rẹ.” Wọn gbà pé awọn ti dẹṣè̩ nipa bibeere fun ọba, wọn si n fẹ ki Samuẹli duro laaarin awọn ati Ọlọrun ti wọn ti ṣè̩. Samuẹli fi ọkàn wọn balẹ pé, Ọlọrun kò ni pa wọn run.

Nitootọ inú Ọlọrun kò dùn pe, wọn beere fun ọba; ṣugbọn niwọn bi wọn ti fi ọba wọn jẹ bayii, Ọlọrun yoo tun ṣe ojurere si wọn bí wọn o ba gbọràn si I ni ọjọ iwaju. Gbogbo ayé ni o n ṣakiyesi idagbasoke awọn Ọmọ Israẹli, nitori wọn mọ pé ayanfé̩ eniyan Ọlọrun ni wọn jé̩: nitori bẹẹ nitori ọlá ati ogo Rè̩, Oun yoo maa bùkún fun Israẹli nigbakuugba ti o ba ṣe e ṣe. S̩ugbọn ègbé ni fun wọn bi wọn ba tún ṣaigbọran!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Israẹli ṣe gba ọba wọn?
  2. Bawo ni Samuẹli ti ṣe ṣakoso Israẹli?
  3. Ki ni awọn eniyan naa sọ nipa iṣakoso Samuẹli?
  4. Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli fi n fé̩ ọba dipo aṣaaju gẹgẹ bi Samuẹli?
  5. Ki ni Samuẹli sọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati fi hàn pé Ọlọrun ti wà pẹlu wọn latẹyinwa?
  6. Àmi wo ni Samuẹli lò lati fi hàn pé Ọlọrun n gbọ ibeere wọn?
  7. Sọ ninu awọn ofin ti Ọlọrun sọ fun Mose pé ọba ni lati kọ sinu ìwé, fun awọn ọba lati maa tẹle?
  8. Ki ni ṣe ti Ọlọrun yoo fi maa bùkún fun Israẹli sibẹ, bi o tilẹ jé̩ pé wọn ti fi ọba jẹ?