1 Samuẹli 13:5-14; 15:1-35.

Lesson 207 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kiye si i, igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilè̩ si sàn jù ọra àgbo lọ” (1 Samuẹli 15:22).
Notes

Igbogunti awọn Filistini

Saulu ọba ṣe akoso daradara fun ọdún kan, gbogbo Israẹli si ni itẹlọrun. S̩ugbọn ni ọdún keji ni wahala dé. Awọn Filisitini, ọtá Israẹli gbá ẹgbé̩ ogun nlá nlà jọ ti i ṣe ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹkẹ, ẹgbaa mẹta (6,000) ẹlẹṣin, ati awọn jagun-jagun ẹlẹsè̩ tí o pọ ju eyi ti eniyan lè kà lọ, wọn si wá lati bá wọn jà. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli le ṣe lati ko irú ọtá bayii ni ojú ìjà? Bí o tilẹ jé̩ pé awọn eniyan naa ni ọba ti wọn n fé̩, lati maa ṣe aṣaajú wọn lọ si ogun, sibẹ è̩rù bà wọn, wọn si fi ara pamọ ninu igbó ati ninu ihò. Bawo ni i ba ti sàn ju eyi lọ tó, bi wọn ba gbẹkẹle Ọlọrun.

Ọlọrun ti ṣeleri pé, Oun yoo ran ọba Israẹli lọwọ bi gbogbo awọn eniyan Rè̩ yoo ba rìn ni ikiyesara niwaju Rè̩. Samuẹli a maa ṣe irubọ fun wọn, a si maa kọ wọn ni ifẹ Ọlọrun, wọn si ti n gbiyanju lati gbọran. Nisisiyii ti awọn Filistini wá gbogun ti Israẹli, wọn ni lati ṣe irubọ pupọ ki wọn si gbadura pupọ si Ọlọrun fun iranwọ, ọba Saulu ati ẹgbẹ-ogun rè̩ si pejọ pọ si Gilgali nibi ti Samuẹli n bọ wa lati bẹbẹ fun wọn.

Aimusuuru

Samuẹli ti ṣeleri pé oun o wá si Gilgali laaarin ọjọ meje, ṣugbọn nigbà ti o duro titi di ọjọ ti o kẹyin ki o tó dé, awọn ọmọ-ogun naa rẹwẹsi, awọn miiran ninu wọn si pada lọ si ile. Saulu kò gbẹkẹle Ọlọrun lati ṣe ètò ati yọ ninu wahala yii fun ire awọn Ọmọ Israẹli; nigbà ti o si ri ti awọn ọmọ-ogun rè̩ n dinkú siwaju ati siwaju, o pinnu pé, oun ni lati wá ohun kan ṣe. Dipo ti i ba fi duro de Samuẹli lati wa ṣe irubọ naa, Saulu ti ara rè̩ si ati ṣe ohun ti i ṣe iṣẹ alufaa lati ṣe.

Bi o ti n pari irubọ yii ni Samuẹli dé. O ri i pe, Saulu ti ṣe aigbọran, o si bi i leere pé, “Kini iwọ ṣe yi?” Saulu bẹrẹ si ṣe awawi: awọn Filistini ti mura tán lati bá wọn jà, awọn ọmọ-ogun naa si bẹrẹ si tuká lọ; Samuẹli pẹ ki o to de, Saulu si ti ti ara rè̩ si i lati ṣe ohun ti o rò pé o tọ fun imurasilẹ awọn eniyan rè̩ fun ogun.

Kì I Pé̩ Jù

Iṣé̩ Ọlọrun ni eyi, Oun si mọ bi akoko ti Oun ni ti pọ tó. Saulu ki bá ti daamu rara, bi o ba ṣe pé, o ti gbẹkẹle ọgbọn Ọlọrun. O dajú pé, Ọlọrun ki bá ti já a tilè̩ Oun i bá si jà fun wọn laaarin akoko pupọ. Wo o bi eniyan ti maa n ṣe alailè ni suuru tó ní ìgbà pupọ, nigbà tí o bá n duro de Oluwa - ṣugbọn Oun ki i pé̩ jù!

Jesu fi è̩kọ yii kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nigbà ti a pe E lati wá mú Lasaru lara dá, “Nitorina nigbati o ti gbọ pe, ara rè̩ ko dá, o gbé ijọ meji si i nibikanna ti o gbé wà” (Johannu 11:6). Awọn ọmọ-ẹyin lè maa rò ninu ọkàn wọn pé, ki ni ṣe ti Oun kò lọ lẹsẹ kan naa, nitori pé Lasaru le kú ki O to dé ibè̩.

Nitootọ, Lasaru kú ki Jesu tó dé, ṣugbọn kò pé̩ jù lati ṣe ohun ti Oluwa fẹ lati ṣe. Jesu n fẹ lati ṣe iṣẹ-iyanu kan fun ogo Ọlọrun, eyi ti yoo kọ awọn eniyan pé, Oun ni Olufunni ni ìyè, Oun ni ajinde kuro ninu okú. O fi hàn pé, Oun lè ji ẹni ti o kú nipa ti ara ati ẹni ti o kú nipa ti ẹmi dide. O pinnu lati wá si ibè̩ nigbà ti awọn eniyan rò pé, o ti pé̩ jù.

Ogún Naa Sọnù

Boya Samueli pinnu lati duro bẹẹ ni, lati wo ohun ti Saulu yoo ṣe. Inú rè̩ bajé̩ gidigidi si ìwà wèrè ati alailọgbọn ti Saulu hù. O fẹran Saulu, gẹgẹ bi ẹni àmì ororo Ọlọrun, Saulu si ti bẹrẹ ijọba rè̩ daradara. Ki ni ṣe ti o fi yara yi pada kuro ninu aṣẹ Ọlọrun bẹẹ? Bi oun ba ti jé̩ oloootọ ni, Ọlọrun i bá fi ìdí ijọba rè̩ mulè̩ laelae. Ọmọ rè̩ ni i bá jẹ ọba lẹyin rè̩, ati lẹyin eyi ọmọ-ọmọ rè̩, ati bẹẹ bẹẹ lọ titi ni gbogbo ìran rè̩, titi a bá fi bí Jesu sinu ìdílé wọn lati jẹ Ọba ayérayé.

Ronú ohun ti aigbọran kan mú bá Saulu. Nitootọ ni o wà ni ipò ọba ni gbogbo ọjọ ayé rè̩; ṣugbọn nipa iwa ṣiṣe tinu-ẹni yii, a ké ẹbí rè̩ kuro lati maa ṣe ìdílé ọba ni Israẹli. Ireti pé Messia yoo ti inú ìdílé wọn wá si sọnù laelae.

Ẹni Bi Ti Inú Ọlọrun

Samueli wi fun Saulu pe: “Nisisiyi ijọba rẹ ki yio duro pẹ: OLUWA ti wá fun ara rè̩ ọkọnrin ti o wù u li ọkàn rè̩, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rè̩, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti OLUWA fi fun ọ mọ.”

Anfaani Miiran

Ọjọ kan dé ninu eyi ti Saulu ni anfaani lati mú ọnà rè̩ tọ fun aijolootọ rè̩. Ọlọrun fun un ni iṣé̩ nlá kan lati ṣe. Gbogbo eyi ti Ọlọrun bá fun wa lati ṣe ni o ṣe pataki, bi o tilè̩ jé̩ pé, a kò le ri abayọrisi rè̩ bi o ti tó, eyi ti o le ti inú ijolootọ wa jade si eyi ti a rò pé o jé̩ iṣé̩ kekere lojú wa.

A rán Saulu pẹlu awọn ọmọ-ogun Israẹli lati pa awọn ara Amaleki run. Ki i ṣe ìjà kan lasan pẹlu orilẹ-ède Keferi nitosi wọn ti wọn n fẹ dalẹkun ki o má ba yọ wọn lẹnu. O jé̩ idajọ Ọlọrun lori orilẹ-ède kan ti o ti mú wahala pupọ bá awọn eniyan Ọlọrun ni akoko tí ó lé ni irinwo (400) ọdún sẹyin.

Nigbà ti awọn Ọmọ Israẹli jade ni Egipti, awọn ara Amaleki ti jade si wọn lati è̩yìn, wọn si ti pa awọn ti àárè̩ mú fun ìrìn-àjò tí wọn si wà lẹyin.

Ọlọrun ti ri ìwà ìkà awọn ara Amaleki, O si ti sọ fun Mose pé, ki o kọ ọ sinu ìwé kan, ki awọn Ọmọ Israẹli má ba gbagbé. O si wi pẹlu pé, “Emi o pa iranti Amaleki run patapata kuro labẹ ọrun” (Ẹksodu 17:14). Nigbà ti Mose n fun awọn Ọmọ Israẹli ni àṣẹ ikẹyin, o wi pe: “Ranti ohun ti Amaleki ṣe si ọ li ọna, nigbati ẹnyin nti ilẹ Egipti jade wá; bi o ti pade rẹ li ọna, ti o si kọlù awọn ti o kẹhin rẹ, ani gbogbo awọn ti o ṣe alailera lẹhin rẹ, nigbati ārẹ mú ọ tán, ti agara si dá ọ; ti on kò si bè̩ru Ọlọrun. Nitorina yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fun ọ ni isimi lọwọ gbogbo awọn ọtá rẹ yi ọ ká kiri, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni ini lati ní i, ki iwọ ki o si pa iranti Amaleki ré̩ kuro labẹ ọrun; iwọ kò gbọdọ gbagbé” (Deuteronomi 25:17-19).

Awọn ara Amaleki ti ní anfaani gbogbo ọdún wọnni lati ronupiwada, ki wọn si bè̩ru Ọlọrun, ṣugbọn wọn ko ronupiwada. Nisisiyii, Ọlọrun n rán Saulu lati mú idajọ wá si orí awọn ara Amaleki. Saulu ni anfaani lati pa è̩ṣẹ ti a to jọ fun irinwo (400) ọdún run - ṣugbọn o kùnà.

Ojusaju Eniyan

Saulu ati ẹgbé̩ ogun rè̩ bè̩rè̩ si i pa awọn ara Amaleki run, gẹgẹ bi a ti pàṣẹ, ṣugbọn ọpọlọpọ agutan ati maluu ti o dara wà nibẹ to bẹẹ ti Saulu fi pinnu pé, yoo jasi itiju lati pa gbogbo wọn run, o si pa awọn ti o dara jù lọ mọ. Lẹyin naa ni ọba Agagi, eniyan pataki, bóyá ẹni ti o ni ọrọ pupọ, Saulu si fi aanu hàn fun un. Ọlọrun ti sọ fun wọn pé, ki wọn dojuja kọ awọn ọtá wọnyii titi wọn o fi pa wọn run “patapata”. Agagi jé̩ ọkàn ninu awọn ẹlẹṣè̩ naa, o si jé̩ ọkàn ninu awọn ti idajọ naa wá si ori rè̩.

A kà ninu Ọrọ Ọlọrun pé: “Bi ẹnyin ba nṣe ojuṣaju enia, ẹnyin ndè̩ṣẹ, a si nda nyin lẹbi nipa ofin bi arufin. Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ, ti o si rú ọkan, o jẹbi gbogbo rè̩” (Jakọbu 2:9, 10). Ni ti igbọran si àṣẹ Ọlọrun, pipa ti Saulu kò pa ọba nì dabi ẹni pé, kò pa ẹnikẹni rara. O ti ṣe ojusaju eniyan, o si ti ṣè̩, bóyá ní ọnà kan yii; ṣugbọn irú eniyan wo ni eyi fi hàn pé o jé̩? Ọrọ Ọlọrun wi pé: o “jẹbi gbogbo rè̩.” O jẹbi bi ẹni pe o ti rú gbogbo ofin naa.

Àwáwí

Ọlọrun sọ fun Samuẹli nipa aigbọràn Saulu, inú Samuẹli bajẹ pupọ to bẹẹ tí ó fi ké, tí ó sì gbadura ní gbogbo òru. Nigbà ti o lọ pade ẹgbé̩ ọmọ-ogun tí o n pada bọ ní òwúrọ, ọrọ kin-in-ni tí Saulu sọ fun Samuẹli ni, “Emi ti ṣe eyi ti OLUWA ran mi.” Òye yé e ju eyi lọ; o mọ pé oun kò ṣe gbogbo ifẹ Ọlọrun, ṣugbọn o fé̩ lati mú Samuẹli rò pé, oun ti gbọran si gbogbo àṣẹ Oluwa patapata.

Nigbà pupọ ni a maa n ri awọn afasẹyin ti wọn ti kùnà lati gbọran si Ọlọrun lẹnu ninu ohun gbogbo, sibè̩ wọn a maa fi ẹnu jẹwọ pé, Onigbagbọ ni awọn, wọn a si maa gbiyanjú lati fi hàn pé awọn n ṣe gbogbo ifẹ Ọlọrun. S̩ugbọn ohun kan ti o kù wọn kù ti mú ki Ẹmi Ọlọrun fi wọn silẹ, wọn si jè̩bi gẹgẹ bi ẹlẹṣè̩ ti kò tilẹ fi agabagebe wi pé oun n sin Ọlọrun nigbà kan ri.

Bí Saulu bá ti gbọran si àṣẹ Ọlọrun ni tootọ, gẹgẹ bi o ti wí, èwo ni igbe agutan ati hihu awọn maluu ti Samuẹli n gbọ? Bí afasẹyin bá n ṣe ifẹ Ọlọrun, ki ni ṣe ti a ri awọn nnkan wọnni ninu ayé rè̩ ti kò jọ ti Kristi? Kò ṣe e ṣe fun eniyan lati gbé igbesi-ayé ti o ba è̩kọ Bibeli mu, a fi bi a ba ni Ẹmi Ọlọrun ninu wa. Bi Ẹmi Mimọ bá si ti jade nipa aigbọran kan, awọn iṣé̩ eṣu yoo bẹrẹ si i fi ara hàn lai pé̩. Ọba Agagi ati agutan ati maluu wà niwaju Samuẹli lati fi hàn pé, Saulu kò gbọran si àṣẹ Ọlọrun.

Lẹẹmeji ni Saulu gbiyanjú lati sọ fun Samuẹli pé, awọn eniyan naa ni wọn mú ikogun wọnni wálé. Nigbà ti a mu un ninu è̩ṣè̩ rè̩, o n fé̩ lati di è̩bi naa le ẹlomiran lori. Lẹyin eyi, o gbiyanjú lati sọ pé, wọn mú wọn wá fun ìdí rere – lati fi rubọ si Oluwa. S̩ugbọn asán ni lati maa ṣe irú àwáwí bẹẹ. Ọlọrun n fé̩ igbọran ju ohun gbogbo lọ. “Igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilè̩ si sàn jù ọra àgbo lọ.”

Ìtìjú Saulu

Nikẹyin, Saulu gbà pé oun ti ṣè̩, ṣugbọn kò ronupiwada. O bẹ Samuẹli pé, ki o bá oun pada lati rubọ si Oluwa, ki awọn eniyan má ba mọ pé oun wà ninu ìtìjú.

Kò si ẹmi igbọjẹgẹ ninu Samuẹli. O ti mura tán lati pa gbogbo è̩ṣè̩ run patapata. O pe ọba Agagi, o si ge e wẹwẹ, o mú idajọ kikún ti Ọlọrun ti pinnu wá si ori rè̩ ṣẹ.

Bí o tilẹ jé̩ pé, Samuẹli ti fẹran Saulu, ti o si ti kaanu lori ikọsilè̩ rè̩, sibè̩ oun kò tún ni ọwọ si ijọba rè̩ mọ. Samuẹli kaanu fun Saulu gẹgẹ bí apẹyinda, o si gbadura fun un; ṣugbọn ni gbogbo iyokù ọjọ ayé Samuẹli, kò tún lọ bẹ Saulu wò mọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Israẹli fi ni ọba?
  2. Bawo ni o ti rí fun awọn eniyan naa, nigbà ti awọn Filisitini wá gbogun ti wọn?
  3. Ki ni Saulu ṣe nigbà ti Samuẹli pé̩ lati wá si Gilgali?
  4. Ọrọ idalẹbi wo ni Samuẹli sọ fun un fun ìwà wèrè tí o hù?
  5. Ki ni ohun ti Ọlọrun i ba fun Saulu bí o bá ṣe pé, o jé̩ oloootọ?
  6. Anfani wo ni Saulu tún ni lati mú ofin Ọlọrun ṣẹ?
  7. Bawo ni Saulu ṣe mú ofin Ọlọrun ṣẹ daradara tó?
  8. Àwáwí wo ni o ṣe?
  9. Idalẹbi wo ni Samuẹli tún sọ fun Saulu?