Lesson 208 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ọrọ na si di ara, on si mba wa gbé” (Johannu 1:14).Notes
Ọmọ Eniyan
Ẹkọ Keresimesi wa jé̩ nipa Jesu, Ẹni tí a bí ni Bẹtlẹhẹmu. A ti kọ rí nipa Jesu pé, Ọmọ Ọlọrun Mimọ ni O jé̩. È̩kọ yii n sọ fun wa pé, Jesu tún jé̩ Ọmọ eniyan. O gbé ara tí o ni ẹran ati è̩jè̩ wọ gẹgẹ bi ti rẹ. A “ṣe e ni awòran enia” (Filippi 2:7). Orí è̩kọ wa n sọ pé Jesu gbé ẹran-ara wọ ni awòran eniyan.
Ètò nlá ni Ọlọrun ní fun igbala arayé. Ninu rè̩ ni bíbí ti a bí Kristi ní Bẹtlẹhẹmu ní ọpọlọpọ ọdún sẹyin. Igbesi-ayé Rè̩ jé̩ apẹẹrẹ fun wa lati tẹle. Awọn è̩kọ Rè̩ ni a fi fun ni lati maa tẹle.
Ọrọ Ọlọrun
Nipa igbesi-ayé, apẹẹrẹ, ati awọn è̩kọ Kristi ni Ọlọrun ti bá wa sọrọ. “Ọlọrun, ẹni, ni igba pupọ ati li onirru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọrọ nigbāni, ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rè̩ ba wa sọrọ” (Heberu 1:1, 2). Ọlọrun a maa fi ifẹ Rè̩ hàn nipasẹ Ọmọ Rè̩ gẹgẹ bi “Ọrọ.” Ọlọrun paṣẹ fun wa lati maa gbọ ti Jesu Ọmọ Rè̩ ati Ọrọ Rè̩ (Matteu 17:5). “A si npè orukọ rè̩ ni Ọrọ Ọlọrun” (Ifihan 19:13). Johannu Baptisti wí pé, “Emi li ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù” (Johannu 1:23). Johannu Baptisti ni ohùn naa. Iṣé̩ ti o jé̩ ni Jesu, Ọrọ Ọlọrun.
Mẹta ninu Ọkan
Lati àtètèkọṣe, ani ki a tilẹ tó dá ayé (Johannu 17:5), Kristi ti wà gẹgẹ bí ẹni ẹmi. Kristi wà lọdọ Ọlọrun Baba (1 Johannu 1:2). Kristi jé̩ apá kan ninu Iwa-Ọlọrun, tabi Mẹtalọkan Mimọ - Baba, Ọmọ, ati Ẹmi Mimọ. Awọn mẹtẹẹta para pọ jé̩ ọkan ṣoṣo. “Nitoripe ẹni mẹta li o njẹri li ọrun, Baba Ọrọ, ati Ẹmi Mimọ: awọn mẹtẹta yi si jasi ọkan” (1 Johannu 5:7).
Nitori Jesu jé̩ ọkan ninu awọn mẹta naa, ti wọn para pọ jé̩ Ìwà-Ọlọrun, Bibeli sọ fun ni ninu è̩kọ wa pé “Ọlọrun si li Ọrọ nā.” Jesu ni Ọrọ Ọlọrun. Wolii Isaiah wí pé a o maa pe Jesu ni “Ọlọrun Alagbara” (Isaiah 9:6).
Ní Àtètèkọṣe
Ní ìgbà dídá ayé, ní àtètèkọṣe (Gẹnẹsisi 1:1), Jesu wà lọdọ Ọlọrun. Onisaamu wí pé, “Nipa ọrọ OLUWA li a da awọn ọrun” (Orin Dafidi 33:6). A kà ninu Heberu 1:2 nipa Ọmọ Ọlọrun, “nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu.” Oun ni O dá awọn ọrun ati awọn ayé - ní tootọ, Oun ni O mú ki ohun gbogbo tí o wà ninu wọn wà nibẹ. “Nipasẹ rè̩ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u” (Kolosse 1:16). Ọlọrun dá ohun gbogbo nipasẹ Ọrọ Rè̩ - Ọlọrun dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi (Efesu 3:9).
Ìyè ati Ìmọlè̩
Ninu Jesu nikan ni ìyè wà. Oun ni o fi ìyè fun eniyan gbogbo ati ohun gbogbo ni àtètèkọṣe, ní ìgbà dídá ayé. “Nitori pe pẹlu rẹ li orisun iye wà” (Orin Dafidi 36:9). “On li o fi iye ati ẽmi ati ohun gbogbo fun gbogbo enia” (Iṣe Awọn Aposteli 17:25).
Ẹ jé̩ ki a kiyesi ẹmi ti Jesu n fi fun ni. Ọlọrun ti gba eniyan layè lati ṣe awọn ohun ribiribi, ṣugbọn kò si ẹni tí ó tii lè dá ẹmi. Ọmọ eniyan ni lati kọkọ ni èso nì - èso ìyè, eyi ti Ọlọrun n fi fun ni – ki o tó lè mú ki ẹmi bẹrẹ si i dagba. Bóyá o ti gbin irugbin rí, tí o dàgbà di igi ati èso. Iwọ kọ ni o dá wọn; o ti kọkọ ni irugbin ìyè ti o fi bẹrẹ. Lẹyin ti o tilẹ ti gbin èso naa, Ọlọrun rán òjò ati oòrùn, ooru ati imọlẹ tí o mú ki awọn irugbin naa rudi, ti o si mú ki ọgbìn naa dàgbà.
O ti kọ ni ile-iwe pé, gbogbo nnkan ni o gbọdọ ni imọlẹ ati ooru kí wọn ba le dàgbà daradara, ki wọn si lè wà láàyè sibẹ. Nigbà miiran, a maa n fi imọlẹ ati ooru atọwọda gbin ohun ọgbin - imọlẹ ati ooru iná mànàmáná (ẹlẹtriki) tabi iná ṣakabula - sibè̩ naa Ọlọrun ni O dá awọn ohun ti a fi ṣe wọn ti O si fi ọgbọn fun eniyan lati maa ṣe nnkan bẹẹ.
Nipa ti ara, ninu Oluwa ni a ti ni ìyè ati imọlẹ, lai si eyi ti a o kú. Nipa ti ẹmi pẹlu, ninu Rè̩ ni a ti ni ìyè ati imọlẹ lai si eyi ti a o kú ikú ti ẹmi. Jesu wí pé, “Emi wa ki nwọn le ni iye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ” (Johannu 10:10). Jesu n sọ nipa ìyè nipa ti ẹmi, eyi ti o n fun ni ni idagbasoke ati itẹsiwajú lọnà kan naa ti ìyè nipa ti ara n fun ni. Jesu wí pé, “Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ mi lẹhin ki yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye” (Johannu 8:12). Jesu wí pé, “Emi ni imọlẹ ti o wá si aiye, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ ki o máṣe wà li òkunkun” (Johannu 12:46).
Lai si Jesu, kò si ẹni ti o lè ri ìyè ti ẹmi. Ninu agbara ti rè̩, eniyan wà ninu òkùnkùn, kò si ni agbara rara lati mọ ọnà otitọ ati ìwà mimọ. Jesu a maa fi ara Rè̩ hàn fun olúkulùku eniyan. Jesu ni “Imọlẹ otitọ, ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:9). Ọrọ Ọlọrun – Jesu – di ara, O si n ba wa gbé ki a ba le ni imọlẹ ti ẹmi nipasẹ igbesi-ayé Rè̩ ati è̩kọ Rè̩. “Ọrọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ mi ati imọlẹ si ipa ọna mi” (Orin Dafidi 119:105). Gbogbo è̩kọ Jesu ati gbogbo apẹẹrẹ Rè̩ lọkọọkan ni o jé̩ itanṣan imọlẹ fun igbesi-ayé wa nipa ti ẹmi. Awọn eniyan ti ayé kò ni òye, bẹẹ ni wọn kò si mọ agbara ti o wà ninu imọlẹ ìyè ti ẹmi. Jesu wá gbé ninu ayé yii ki O ba le fi ọnà ìyè ainipẹkun hàn wa, pé nipasẹ Rè̩, ki a le ri igbala.
Onṣé̩ Kan
Oluwa ti ṣe ileri lati fi onṣé̩ kan ránṣé̩, ki o ba le tún ọnà ṣe niwaju Kristi (Malaki 3:1). Akoko dé ti Ọlọrun rán ọkunrin naa. A bi i diẹ ṣaajú ìbí Kristi. Onṣé̩ naa ni Johannu Baptisti, ẹni tí o kede bíbọ Jesu. Johannu Baptisti wí pé: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩ … Ẹ tún ọna Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju-ọna rè̩ tọ” (Matteu 3:2, 3). Johannu jẹri fun ayé ti o kún fun òkùnkùn, ki awọn eniyan bá le gbà Kristi gbọ, ki wọn si ni imọlẹ.
“Nitõtọ, ni Johannu fi baptismu ti ironupiwada baptisti, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu” (Iṣe Awọn Aposteli 19:4). Johannu kọ ni Imọlẹ naa, bẹẹ ni oun kò si pe ara rè̩ bẹẹ. Ki i ṣe imọlẹ èké ni Johannu, bí kò ṣe imọlẹ kekere ti o tàn wá lati ọdọ Imọlẹ tootọ, ti o si tọka si Jesu. Iṣé̩ Johannu ni lati tún ọnà ṣe de Jesu, iṣé̩ yii ni Johannu si fi otitọ ṣe. Johannu kò ṣe iṣé̩-iyanu kankan; n ṣe ni o jẹri pe Jesu n bọ. Johannu kilọ fun awọn eniyan ki wọn má ṣe ṣi oun pè ni Imọlẹ naa. “Bi Johannu si ti nlà ipa ti rè̩ já, o ni, Tali ẹnyin ṣebi emi iṣe? Emi ki iṣe on. S̩ugbọn ẹ kiyesi i, ẹnikan mbọ lẹhin mi, bata ẹsẹ ẹniti emi kò to itú” (Iṣe Awọn Aposteli 13:25).
Imọlẹ Tootọ
A bí Jesu gẹgẹ bi Ọmọ-ọwọ Betlehemu. O wá lati gbé ninu ayé ti O ti dá. Nigbà ti o ṣe, a fi Jesu hàn gẹgẹ bi imọlẹ tootọ, “imọlẹ awọn Keferi … igbala mi titi de opin aiye” (Isaiah 49:6). Ni oriṣiriṣi ọnà ni Jesu maa n fi ara Rè̩ hàn ti O si maa n fi oye yé ni. Oluwa a maa bá eniyan sọrọ nipasẹ ẹwà iṣé̩ ọwọ Rè̩. “Awọn ọrun nsọrọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣé̩ ọwọ rè̩ han” (Orin Dafidi 19:1).
Oluwa a maa bá eniyan sọrọ nipasẹ imọlẹ oye. A maa ṣi ojú ọkàn wọn, ki wọn ba le mọ “ohun ti ireti ipe rè̩ jẹ, ati ohun ti ọrọ ogo ini rè̩ ninu awọn enia mimọ jẹ” (Efesu 1:18).
Titàn ti Ihinrere Jesu n tàn kalẹ fun gbogbo eniyan ní anfaani lati gba Imọlọ otitọ naa. “A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de” (Matteu 24:14).
Nigbà ti a ṣi oye Paulu Aposteli si ọnà ìyè ainipẹkun, imọlẹ dídán kan tàn nitootọ lati Ọrun wá (Iṣe Awọn Aposteli 9:3). Nigbà tí Paulu dahun ìpè Jesu, a sọ fun un lati jé̩ iranṣẹ ati ẹlẹri si awọn eniyan. Jesu wí pé, Oun n rán Paulu si awọn Keferi, “lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji è̩ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ nipa igbagbọ ninu mi” (Iṣe Awọn Aposteli 26:16-18).
Titàn fun Jesu
Jesu wí pe, “Niwọn igbati mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye” (Johannu 9:5). Nigbà ti o ṣe, Jesu kuro ninu ayé, ṣugbọn O fi àṣẹ silẹ fun awọn ọmọlẹyin Rè̩. Jesu wí pé: “Ẹnyin ni imọlẹ aiye … Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobḝ niwaju enia, ki nwọn ki o le mā ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yin Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo” (Matteu 5:14-16). Bí awọn ọmọlẹyin Kristi ti n tan Ihinrere naa kalẹ ti wọn si n jé̩ ki imọlẹ wọn tàn, Oluwa n fi han awọn eniyan inú ayé pé, Jesu ni ọnà si ìyè ainipẹkun.
Oluwa tún maa n bá ni sọrọ nipasẹ Ẹmi Rè̩. “Ẹmi li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmi” (1 Johannu 5:7). “Iye awọn ti a nṣe amọna fun lati ọdọ Ẹmí Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun” (Romu 8:14). Nipasẹ awọn ọnà wọnyii, Oluwa maa n tan imọlẹ fun olukuluku eniyan ti o wá si ayé. S̩ugbọn ki i ṣe gbogbo eniyan ni n rìn ninu imọlẹ ti a fi fun un.
Nigbà tí Jesu wà ninu ayé, awọn eniyan kò mọ Ọn gẹgẹ bi Ẹlẹda wọn, ati Ọnà si ìyè ainipẹkun. Awọn eniyan Jesu paapaa, awọn Ju, gẹgẹ bí orilẹ-ède, kò mọ Ọn, bẹẹ ni wọn kò si gba A gẹgẹ bí Messia wọn. Awọn Ju kọ Jesu, wọn si wí pé, “Awa kò fẹ ki ọkọnrin yi jọba lori wa” (Luku 19:14).
Àtúnbí
“S̩ugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rè̩ gbọ.” A ní anfaani ati è̩tọ lati di ọmọkunrin ati ọmọbinrin Ọlọrun nipa gbígba orukọ Ọmọ Rè̩ gbọ ati gbogbo nnkan tí o so mọ orukọ Rè̩, ati nipa níní awọn ìrírí tí O ní fun wa. “Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun” (1 Johannu 3:1). A lè jé̩ ọmọ Ọlọrun, ki i ṣe ninu orukọ nikan, ṣugbọn ninu ìwà pẹlu, didabi Kristi. Jesu kò di Ọmọ Ọlọrun, nitori nigbà gbogbo ni O ti jé̩ Ọmọ Ọlọrun. A maa n sọ pé Ọmọ Ọlọrun di Ọmọ eniyan ki awọn ọmọ eniyan ba le di ọmọ Ọlọrun.
Nipa ti ara tabi è̩dá, a bí wa nipa ti ara ati è̩jè̩. Nipa ti ẹmi, a gbọdọ “tun wa bi … nipa ọrọ Ọlọrun” (1 Peteru 1:23).
Agbara lati Di Ọmọ Ọlọrun
Ó wà ní ipá wa lati di ọmọ Ọlọrun. A ní agbara, o si wà ní ipá wa lati yàn lati jé̩ ọmọ Rè̩. Ọlọrun ti la ọnà silẹ nipasẹ Ọmọ Rè̩ Jesu Kristi, ti wa si ni lati rin ọnà naa, lati rìn ninu imọlẹ tí a ti tàn fun wa.
Bawo ni o ṣe lè di ọmọ Ọlọrun? “Olukuluku ẹniti o ba gbagbọ pe Jesu ni Kristi, a bi i nipa ti Ọlọrun” (1 Johannu 5:1). O ni lati gbadura pé ki Ọlọrun mú è̩ṣè̩ kuro ninu ọkàn ati igbesi-ayé rẹ, nitori pé “ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ” (1 Johannu 3:9). O ni lati fẹran Ọlọrun ki o si pa Ofin Rè̩ mọ (1 Johannu 5:2, 3).
Bí o bá jé̩ ọmọ Ọlọrun ti o si n gbọ ti Rè̩, o ni è̩tọ lati lọ si Ọrun. Bí o kò bá jé̩ ọmọ Rè̩, o kò le ba awọn eniyan Rè̩ gbé ni Ọrun. Jesu wí pé, “Bikoṣepe a fi omi ati Ẹmi bi enia, on kò le wọ ijọba Ọlọrun” (Johannu 3:5).
Jesu fi Ara Rè̩ Rubọ
“Ọrọ na si di ara, on si mba wa gbé.” Jesu gbé ẹran-ara wọ, ohun ti a lè fi ọwọ kàn lara eniyan. Ọlọrun rán Ọmọ Oun tikara Rè̩ ni aworan ara è̩ṣẹ (Romu 8:3), “ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rè̩” (2 Kọrinti 5:21).
Jesu fi gbogbo ogo Ọrun silè̩ lati wá gbé ninu ayé nihin, laaarin awọn ẹlẹṣè̩, gẹgẹ bí òtòṣì, nitori ti rẹ. Ki ni iwọ o fun Jesu ni akoko ọdún Keresimesi yii? Jesu fi ẹmi Rè̩ lelè̩ fun ọ. Iwọ ha n gbé igbesi-ayé rẹ fun Un bí?
Ogo Rè̩
Jesu yọọda fun diẹ ninu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati rí ogo ti i ṣe ti Rè̩ gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun. Wọn rí ogo ati ọlá nlá ifarahàn Rè̩ gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun ní ìgbà ipalarada (Matteu 17:2). A gbọdọ fun Jesu ni iyin, ọlá ati ogo nihin, bí a bá fẹ yẹ fun akoko ti gbogbo eniyan yoo rí ogo Rè̩ (Isaiah 40:5). Ẹ jé̩ ki a gba oore-ọfẹ ati otitọ nipa Ọmọ Ọlọrun, eyi tí yoo mú wa yẹ lati dàpọ mọ ẹgbé̩ awọn ti n kọ orin Halleluiah ni Ọrun (Ifihan 19:1).
Questions
AWỌN IBEERE- Ta ni wà pẹlu Ọlọrun ní ìgbà dídá ayé?
- Ta ni n fun ni ní ìyè?
- Bawo ni a ṣe lè ní ìyè nipa ti ẹmi?
- Ki ni iṣé̩ Johannu Baptisti?
- Bawo ni Jesu ṣe n tan imọlẹ fun olukuluku ẹni ti o wà ninu ayé?
- Ki ni a fi fun awọn ti o gba Jesu?
- Bawo ni a ṣe lè di ọmọ Ọlọrun?
- Ta ni Ọrọ tí Ó di ara tí Ó sì ba wa gbé?