Lesson 209 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada” (Awọn Onidajọ 11:35).Notes
Ìlérí
Ọlọrun kò fé̩ ki a jé̩ òpè nipa è̩jé̩. Ọpọlọpọ eniyan ni o n jé̩ è̩jé̩ fun Ọlọrun ní ìgbà kan tabi omiran. È̩jé̩ ni ìlérí ninu eyi ti eniyan sọ ipinnu ọkàn rè̩ lati fi è̩bùn kan lelè̩, lati yẹra kuro ninu ṣiṣe ohun kan, tabi lati ṣe ohun kan fun ọlá Ọlọrun tabi ninu iṣé̩-ìsìn Ọlọrun. È̩jé̩ tayọ eyi ti a beere lọwọ wa lati ṣe. Eyi ti a fi silẹ lati inú ifẹ ọkàn wa tikara wa wá ni.
Dajúdajú iyatọ wà laaarin è̩jé̩ ati ifara-rubọ. È̩jé̩ ni ìlérí pataki kan ti eniyan fi de ara rè̩ fun Ọlọrun, eyi ti o ṣe e ṣe ki o ma si ninu ifi-ara-rubọ rè̩. Ọlọrun n fẹ ki a jọwọ ayé wa, talẹnti wa, ati akoko wa ni ifi-ara-rubọ fun Oun. Nigbà ti Ọlọrun bá pè wa si iṣé̩ ti o tobi ti o si lọlá ju ti àtè̩yìnwá lọ, a o jọwọ ara ẹni ni ifara-rubọ fun ifẹ Ọlọrun. Ifi-ara-rubọ jé̩ ọranyan fun wa lati muṣẹ, gẹgẹ bi mimu è̩jé̩ wa ṣẹ ti jé̩ ọranyan pẹlu.
Ní ìgbà wahala ni a maa n jé̩ è̩jé̩ pupọ jù lọ. A o ṣe ìlérí pe, bí Ọlọrun bá lè mú wahala naa kuro, a o ṣe ohun kan. Nigbà aisan, a maa n ṣe ìlérí fun Ọlọrun. Ìgbà miiran si tún wà, tí o jé̩ pé lati inú ifẹ si Ọlọrun ati ninu imoore si ohun tí Ọlọrun ṣe, eniyan a ṣèlérí apakan àkókò rè̩ tabi ohun rere kan ninu ayé rè̩ fun Ọlọrun.
Ọlọrun lè ṣe alai beere lọwọ rẹ pé, ki o jé̩ è̩jé̩ kan, ṣugbọn niwọn ìgbà tí o bá jé̩ è̩jé̩, Ọlọrun n pàṣẹ fun ọ pé, ki o mú ìlérí naa ṣẹ. Bibeli kò sọ pupọ nipa jíjé̩ è̩jé̩, ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun fi hàn gbangba nipa sísan è̩jé̩ wa. Ohun buburu ni lati kùnà lati san è̩jé̩ wa fun Ọlọrun. Nitootọ, “yio si di è̩ṣẹ si ọ lọrun” (Deuteronomi 23:21). Bí eniyan kò bá jé̩ è̩jé̩, ki yoo jasi è̩ṣè̩. Kikùnà lati san è̩jé̩ ni o n mú è̩ṣè̩ wá, ki i ṣe kikùnà lati jé̩ è̩jé̩.
Aiṣootọ Kan
Nigbà ti eniyan kò bá san è̩jé̩ rè̩ fun Ọlọrun, oun kò sọ otitọ. Ẹlè̩tàn ni. Ki ni Bibeli sọ nipa èké ati è̩tàn? “Irira loju OLUWA li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rè̩” (Owe 12:22). Dafidi Onisaamu gbadura pé, kí Ọlọrun gba oun lọwọ “ète eke, ati lọwọ ahọn è̩tan” (Orin Dafidi 120:2). Dafidi kò fẹ ẹni ti ki i sọ otitọ nitosi rè̩. O wi pé, “Ẹniti o ba nṣe è̩tan, ki o gbe inu ile mi: ẹniti o ba nṣeke ki yio duro niwaju mi” (Orin Dafidi 101:7). Bibeli sọ ìjìyà ti o wà fun awọn ti kò ba sọ otitọ. “S̩ugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ, … ati awọn eke gbogbo, ni yio ni ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò” (Ifihan 21:8). Abajọ ti Onisaamu fi wi pé, “Emi o san ẹjé̩ mi fun ọ, ti ète mi ti jé̩, ti ẹnu si ti sọ, nigbati mo wà ninu ipọnju” (Orin Dafidi 66:13, 14).
Sisan an
“Máṣe duro pẹ lati san a.” Má ṣe duro pé̩ lati san an nipa aibikita tabi ijafara. Eniyan lè duro pé̩ lati san an nipa fifi sísan è̩jé̩ rè̩ falè̩. Awọn miiran wà ti wọn kò fẹ lati san è̩jé̩ wọn mọ lẹyìn ti Ọlọrun ti ṣe ipa ti Rè̩. Nigbà ti wọn n fé̩ iranwọ, wọn ṣetán lati ṣe ohunkohun, ṣugbọn lẹyìn ti Ọlọrun ti ràn wọn lọwọ tán, ti ohun gbogbo kò tún buru fun wọn bí o ti rí tẹlè̩, wọn kò tún ni ifẹ lati san è̩jé̩ naa mọ bí ìgbà àkọkọ. “OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rè̩ nitõtọ lọwọ rẹ” (Deuteronomi 23:21).
Àwáwí
Awọn miiran a maa ṣe àwáwí fun kikùnà lati san è̩jé̩ wọn fun Ọlọrun. Wọn lè sọ pé kò ṣe e ṣe fun wọn, tabi pé, kò mú ọgbọn dani fun wọn bi awọn bá san è̩jé̩ ti wọn ti jé̩. S̩ugbọn wọn ti ṣe ìlérí naa fun Ọlọrun. Ìdánú ara wọn ni wọn fi jé̩ ẹ. Ọlọrun kọ ni o beere rè̩ pé kí wọn jé̩ è̩jé̩. “San ẹjé̩ rẹ fun Ọga-ogo” (Orin Dafidi 50:14).
Iwarapàpà
Ọlọrun kìlọ nipasẹ ọrọ Solomoni pe, “máṣe fi ẹnu rẹ yara, ki o má si jẹ ki aiya rẹ ki o yara sọ ọrọ niwaju Ọlọrun” (Oniwasu 5:2). È̩jé̩ ti a jé̩ ninu iwarapàpà ni è̩jé̩ tí a dédé sọ jade ṣá, ninu aikiyesara, ati lai ronú jinlè̩. Eyi ni ìlérí ti a sọ jade lai kiyesara tabi lai ronu ohun ti o lè yọri si. Bi iwọ bá lọ siwajú Ọlọrun, ni ile Rè̩ tabi ni ibomiran, ninu adura tabi iṣe àṣàrò “mura ati gbọ” ju ati fi iwarapàpà jé̩ è̩jé̩ - ọrọ buburu, èké ati è̩sè̩ (Oniwasu 5:1). Ọlọrun beere pé, ki a san è̩jé̩ wa, yálà eyi ti a fi iwarapàpà jé̩ tabi eyi ti a fi tọkàntọkàn jé̩. Eniyan kò lè mú irú è̩jé̩ bẹẹ kuro nipa sisọ pé “èṣi li o ṣe” (Oniwasu 5:6). Ó sàn kí eniyan má jẹ è̩jé̩, ju pé kí o jé̩ è̩jé̩ ki o si yẹ ìlérí rè̩ (Oniwasu 5:5).
Jefta
Apẹẹrẹ kan wà ninu Bibeli, tí o fi òye yé ni bí è̩jé̩ fun Ọlọrun ti ṣe ohun tí ó wúwo tó. Ọkan ninu awọn onidajọ Israeli ni a n pè ni Jefta. Gẹgẹ bí a ti lè ri i si, ó jé̩ ẹni tí o gbẹkẹle Ọlọrun, kò si jé̩ tẹriba fun awọn ọtá, awọn ara Ammoni. Jefta ṣe aṣaaju awọn Ọmọ Israeli lọ si ogun lati bá awọn ara Ammoni jà, ki awọn Ọmọ Israeli ba le pa ilẹ naa mọ, eyi ti Ọlọrun fi fun wọn ni ìní ní ilè̩ Kenaani. Ninu ìtara ati àníyàn rè̩, Jefta jé̩ è̩jé̩ tí a lè pé ni è̩jé̩ wèrè. Ki i ṣe àṣẹ Ọlọrun ni Jefta n múṣẹ nigbà tí ó n jé̩ è̩jé̩ yi; èrò ọkàn ti rè̩ ni. Wọn ní anfaani lati gbẹkẹle Ọlọrun, o si ṣe e ṣe fun wọn lati ní iṣẹgun lai si è̩jé̩ yi.
È̩jé̩
Jefta wí fun Ọlọrun pé: “Bi iwọ ba jẹ fi awọn ọmọ Ammoni lé mi lọwọ, yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ li alafia, ti Oluwa ni yio jé̩, emi o si fi i ru ẹbọ sisun” (Awọn Onidajọ 11:30, 31).
Ohun tí ó wú ni lori nipa Jefta, ati apẹẹrẹ igbesi-ayé rè̩ ni pé, o san è̩jé̩ rè̩, bí o tilẹ jé̩ pé, o mú ọpọlọpọ ibanujé̩ ati irora àyà ba a. O wí pé “Emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada” (Awọn Onidajọ 11:35). Jefta yàn lati jiyà ju lati jé̩ alaiṣootọ si Ọlọrun.
È̩jé̩ yii wà laaarin Ọlọrun ati Jefta. Boya kò si ẹlomiran ti o mọ ohunkohun nipa rè̩, ṣugbọn Jefta kò jé̩ ba è̩jé̩ rè̩ jé̩ niwajú Ọlọrun. Ọmọbinrin Jefta kò sọrọ lòdì si baba rè̩, tabi ki ó kùn. Bí o tilè̩ jé̩ pé sísan è̩jé̩ naa ni ibanujé̩ ati ìjìyà ninu, o ran baba rè̩ lọwọ. O sọ ọrọ ìwúrí fun un bayii pé, “S̩e si mi gẹgẹ bi eyiti o ti ẹnu rẹ jade.”
A kò mú è̩kọ yii wá lati mú ki a fa sẹyìn kuro ninu jíjé̩ è̩jé̩ fun Ọlọrun. A mu un wá lati fun ọ ni ìkìlọ nipa è̩jé̩ wèrè, ati lati fun ọ ní imulọkanle lati mú è̩jé̩ ati ìlérí ti o ti ṣe fun Ọlọrun ṣẹ. È̩kọ yii n fi hàn pé, Ọlọrun ka è̩jé̩ si; ohun mimọ ni niwajú Rè̩, bẹẹ gẹgẹ ni o gbọdọ ri pẹlu wa.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni è̩jé̩?
- Ki ni è̩jé̩ wèrè?
- Njé̩ Ọlọrun a maa gbojú fo è̩jé̩ dá?
- Bawo ni eniyan ṣe lè fà sẹyìn ní sísan è̩jé̩ rè̩?
- Bawo ni kíkùnà lati san è̩jé̩ ṣe dabi sísọ èké?
- Dípò ki a ba è̩jé̩ wa jé̩, ki ni ohun ti o sàn lati ṣe?