Lesson 2 - Elementary
Memory Verse
“Olufẹ, máṣe afarawe ohun ti iṣe ibi” (3 Johannu 11).Notes
Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti O dá, si kiyesi i, daradara ni; O si sinmi ni ọjọ keje, O si busi i. Ọlọrun gbin ọgbà daradara kan fun Adamu ati awọn ti yoo wà pẹlu rè̩. O gbin igi eleso daradara, itanna oloorun didùn, ewebẹ ati ohun daradara miiran gbogbo sinu ọgba naa. Ọlọrun sọ fun Adamu pe ki o maa jẹ ẹ, gbogbo eso igi ọgbà afi ẹyọ kan bayii ni kò gbọdọ jẹ. Bi wọn ba jẹ é̩, wọn yoo kú. Wọn kò tilẹ gbọdọ fọwọ kan an.
Ọlọrun ko fẹ ki Adamu ki o nikan wà; nigba ti Adamu sùn, Ọlọrun yọ egungun kan lati iha rè̩ wá, O fi dá obinrin kan, O si fi i fun Adamu lati ṣe iyawo.
Oriṣiriṣi ẹranko ni o wà ninu ọgbà naa. Adamu ni o sọ wọn ni orukọ. Ki i ṣe gbogbo ejo ni o loro, ṣugbọn ejo kan wà ninu ọgbà naa ti o buru. Ejo buburu yii ni o sọ fun Efa lati jẹ eso ti Ọlọrun paṣẹ pe wọn kò gbọdọ jẹ. Efa jẹ é̩, o fún Adamu jẹ pẹlu; nipa bẹẹ wọn ṣaigbọran si Ọlọrun. Ọpọlọpọ igba ni awọn ẹlẹgbẹ wa i maa fẹ ki a ṣe ohun ti kò tọ, yala nibi eré tabi ni ile-iwe, ṣugbọn bi a ba fé̩ ni Jesu lọkan wa, a kò gbodọ gbọ ti wọn.
Ọlọrun a maa wá bá wọn ṣire ninu ọgbà. Dajudaju inu wọn ni lati dùn lati ni Ọlọrun lọdọ wọn. S̩ugbọn lẹyin ti wọn ṣaigbọran nipa jijẹ eso ti Ọlọrun ko fẹ ki wọn jẹ, ẹru bà wọn nigba ti wọn gbọ ohun Ọlọrun. Ọlọrun pè wọn. O beere bi wọn ba ti jẹ eso ti Oun palaṣẹ pe wọn ko gbọdọ jẹ. Wọn n ṣe awawi. Nigba ti eniyan ba ti ṣe ohun ti ko tọ ni o maa n ṣe awawi.
Ọlọrun lé wọn jade kuro ninu ọgba daradara yii nitori wọn ṣaigbọran, O si fi angẹli si ẹnu ọna lati maa ṣọ ọ.
Ohun buburu ni Adamu ati Efa ṣe nigba ti wọn ṣaigbọran si Ọlọrun; nitori eyi ni aisàn, ikú ati ohun buburu gbogbo ṣe wọ inu ayé. Apẹẹrẹ buburu ni a n fi lelẹ nigba ti a ba ṣe ibi, ṣugbọn bi a ba pe Jesu ninu ọkàn wa, Oun yoo ràn wá lọwọ lati ṣe ohun ti o tọna.
Questions
AWỌN IBEERE- 1. Njẹ gbogbo eso ti ó wà ninu ọgbà ni eniyan le jẹ?
- 2. Ta ni fun Efa ni eso naa jẹ?
- 3. Ki ni ṣe ti Adamu fi ara pamọ niwaju Ọlọrun?
- 4. Ki ni fa aisàn ati ikú wá si ayé?