Lesson 3 - Elementary
Memory Verse
“Ẹniti o ba korira arakunrin rè̩ o ngbe inu òkunkun” (1 Johannu 2:11).
Notes
Lẹyin ti Adamu ati Efa ṣaigbọran si Ọlọrun ti O si lé wọn jade kuro ninu ọgbà Edẹni daradara nì, wọn bi ọmọkunrin kan. Wọn pe orukọ rè̩ ni Kaini. Lẹyin naa wọn tún bi ọmọkunrin miiran, wọn pe orukọ rè̩ ni Abẹli. Awọn mejeeji wọnyii mọ nipa Ọlọrun.
Abẹli fẹran Ọlọrun lọpọlọpọ, o si n gbiyanju lati ṣe ohunkohun ti Ọlọrun ba fẹ ki o ṣe. Kaini kò fi taratara fẹran Ọlọrun, ṣugbọn o fẹ ki Ọlọrun fun oun ni ibukun, nitori naa o mú ọrẹ ẹbọ wá fun Ọlọrun. S̩ugbọn inu Ọlọrun kò dùn si ọrẹ ẹbọ Kaini. Ọlọrun fé̩ ki a ṣe ohunkohun ti a ba ṣe fun Un nitori a fẹ Ẹ. S̩ugbọn Kaini kò fẹran Ọlọrun.
Abẹli naa mú ọrẹ ẹbọ wá fun Ọlọrun. O fiyesi i pe ohun ti Ọlọrun n fé̩ gan an ni oun mú wá. O mú ọdọ-agutan ti o dara jù lọ ninu agbo ẹran rè̩ wá. O fẹran Ọlọrun to bẹẹ ti o fi mu eyi ti o dara jù lọ wá fun Ọlọrun. Inu Ọlọrun si dùn si ọrẹ ẹbọ Abẹli. Nigba ti Kaini ri i pe Ọlọrun kò té̩wọ gba ẹbọ oun, ti Ọlọrun si té̩wọ gba ẹbọ Abẹli, inu bi Kaini pupọ. I ba ṣe pe Kaini ti kaanu nitori ẹbọ rè̩ ti ko jé̩ itẹwọgba ki o si gbadura pe ki Ọlọrun ran oun lọwọ lati mú ọrẹ daradara wá, Ọlọrun i ba ran an lọwọ. S̩ugbọn inu bi Kaini bi ọmọ ti o ti bajẹ ti kò ri nnkan ti o fé̩ gbà.
Kaini ṣe ilara Abẹli arakunrin rè̩. O korira rẹ to bẹẹ gẹẹ ti o fi pa á.
Nigba ti Ọlọrun beere pé nibo ni Abẹli wà, Kaini purọ, o sọ pe oun kò mọ. Ẹṣẹ kan ti a ko ba kọ silẹ, a maa fa ni lọ si omiran. Lakọkọ Kaini binu o si ṣe ilara, lẹyin naa o pa arakunrin rè̩, lẹyin eyi o purọ.
Ilara a maa mú ki ọpọlọpọ eniyan ṣe ibi. Ọlọrun kọ wa lati bá arakunrin tabi arabinrin wa yọ nigba ti wọn ba ri ohun ti o dara ju ti wa gbà.
Questions
AWỌN IBEERE
- Orukọ wo ni Adamu ati Efa sọ awọn ọmọ wọn mejeeji?
- Ta ni fẹran Ọlọrun pupọ, Kaini tabi Abẹli?
- Ki ni ṣe ti Ọlọrun kò fi gba ẹbọ Kaini?
- Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi gba ẹbọ Abẹli?
- Ki ni ṣe ti inu bi Kaini nigba ti Ọlọrun té̩wọ gba ẹbọ Abẹli?
- Ki ni ilara fa Kaini lati ṣe si Abẹli?
- Ki ni a ni lati ṣe nigba ti arakunrin tabi arabinrin wa ba ri ohun ti o dara ju ti wa gbà?