Gẹnẹsisi 6 ati 7

Lesson 4 - Elementary

Memory Verse
“Yio paṣẹ fun awọn angẹli rè̩ nitori rẹ, lati ma ṣe itọju rẹ” (Luku 4:10).
Notes

Nigba ti Adamu ati Efa ṣaigbọran si Ọlọrun wọn fa è̩ṣẹ ati ikú wá sinu ayé. Nigba diẹ sii lẹyin eyi, iwa awọn eniyan buru to bẹẹ ti Ọlọrun fi pinnu lati rán ikún omi nla si ori ilẹ ayé lati pa ohun gbogbo run. S̩ugbọn ọkunrin kan wà, ani Noa ti o fẹran Ọlọrun ti o si n dù lati ṣe ohun ti o wu Ọlọrun; nitori naa Ọlọrun fẹ daabo bo oun ati ẹbi rè̩.

Ọlọrun paṣẹ fun Noa pe ki o kan ọkọ kan ti o tobi pupọpupọ fun oun ati ẹbi rè̩ lati maa gbé nigba ti ikún omi bá wà lori ilè̩. O ṣe apejuwe bi Noa yoo ti kan ọkọ naa ati bi yoo ti tobi tó.

A sọ fun Noa pe ki o mu ẹranko meji meji ni iru ti rè̩ wọ inu ọkọ naa, o si ni lati kó ounjẹ si inu ọkọ naa fun ẹbi rè̩ ati fun awọn ẹranko naa. Ninu awọn ẹranko ti o mọ, o ni lati mú meje meje takọ tabo. Noa ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun un. O gba a ni ọdun pupọ lati kan ọkọ nla naa. Boya awọn eniyan n fi rẹrin pe o n kan ọkọ nibi ti omi kò si, ṣugbọn Noa mọ ohun ti Ọlọrun sọ fun un pe ki o ṣe, o si tẹramọ kikan ọkọ naa.

Noa waasu fun awọn eniyan nipa ibi ti o n bọ wá bá wọn o si kilọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe huwa buburu mọ. Nigba ti o kan ọkọ naa pari, Ọlọrun sọ fun Noa ki o wọ inu ọkọ, oun ati aya ati gbogbo ẹbi rè̩. Lẹyin naa Ọlọrun ti ilẹkun ọkọ naa.

Fun ogoji ọsan ati ogoji oru ojo bẹrẹ si rọ lati oke wá. Omi bẹrẹ si tú jade lati inu ibú ati isun omi lati inu ilẹ ati okun.

Lẹyin naa awọn eniyan gba ohun ti Noa sọ fun wọn gbọ. Wọn n sọkun, wọn si n ké, wọn wá fé̩ ni igbala wayii. S̩ugbọn o ti pé̩ jù. Ọlọrun ti ti ilekun, Noa paapaa kò tilẹ le ṣi i. Awọn ti wọn ti n ṣe yẹyẹ kaakiri nigba ti o yẹ ki wọn gbadura wà lẹyin ode ninu omi, wọn si rì.

Bakan naa ni o ri lonii, ọpọlọpọ awọn eniyan ninu ayé ni wọn buru pupọ. Wọn ko fẹran Ọlọrun bẹẹ ni wọn kò si fẹ wu U. Iyọnu nla n bọ wá sori ayé nitori iwa buburu awọn eniyan.

Bi o ko ba ti ni igbala, yara gbadura ki o bẹ Jesu pe ki o gba ọkàn rẹ là, nitori Jesu n pada bọ lati wá kó awọn ti o fẹ Ẹ ti wọn si gbọran kuro ninu ayé, ki wọn ma ba ni ipin ninu iyọnu ti o n bọ wá dé bá ayé.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni yoo ṣẹlẹ nitori iwa buburu awọn eniyan?

  2. 2 Ta ni ọkunrin naa ti oun ati ẹbi rè̩ fẹran Ọlọrun ti wọn si gbọran si I?

  3. 3 Ki ni Ọlọrun paṣẹ fun Noa lati ṣe?

  4. 4 Ki ni Ọlọrun ṣe ki ikún omi to dé?

  5. 5 Ki ni awọn eniyan ṣe lẹyin ti ikún omi dé?

  6. 6 Ki ni a ni lati ṣe lati bọ kuro ninu wahala nla ti o n bọ wá si ayé ni aipẹ yii?