Genesisi 8:1-22

Lesson 5 - Elementary

Memory Verse
“Ẹ tún ọna Oluwa ṣe” (Luku 3:4).
Notes

Ọlọrun ranti Noa ati ẹbi rè̩ ti o wà ninu ọkọ nla ni. O si dá omi ti o ti n ṣàn lori ayé duro. Ọlọrun paṣẹ fun afẹfẹ lati fé̩ sori ayé ki o si mu ki o gbẹ. Noa ṣi ferese ọkọ naa, o si rán oriri kan jade, ṣugbọn oriri kò pada wa. Boya o ri awọn igi gbigbẹ ati okú eniyan ninu omi ti o le ba le.

Lẹyin naa, Noa rán adaba kan jade. Bi ilẹ ba ti gbẹ, boya ki bá ti pada wá mọ, ṣugbọn o tun pada wá sinu ọkọ.

Diẹ diẹ ni omi bẹrẹ si ṣan lọ sinu awọn odo, adagun ati okun, ilẹ si bẹrẹ si i gbẹ.

Noa tun rán adaba kan jade, o si pada bọ pẹlu ewe olifi ni ẹnu rè̩. Lẹyin naa. Noa tun duro fun ọjọ meje o si tun rán adaba miiran jade.

Lakoko yii kò pada mọ. Noa mọ pe ilè̩ ti gbẹ wayii. Noa ati ẹbi rè̩ ati awọn ẹranko ti wà ninu ọkọ fun ọjọ pupọ. Oun ko wọ inu ọkọ ṣiwaju igba ti Ọlọrun ti paṣẹ fun un pe ki o wọ ọ, bẹẹ ni ko jade titi Ọlọrun fi paṣẹ fun un lati jade. Lẹyin naa. Ọlọrun sọ fun Noa lati kó awọn ẹbi rè̩ ati awọn ẹranko jade kuro ninu ọkọ ki wọn si maa gbé lori ilẹ.

Ohun kin-in-ni ti Noa ṣe nigba ti o sọkalẹ sori iyangbẹ ilẹ ni pe o kọkọ té̩ pẹpẹ nibi ti o le gbé gbadura si Ọlọrun. Dajudaju, Noa dupẹ lọwọ Ọlọrun ti O pa a mọ ni alaafia ni gbogbo akoko ti omi fi bo ilẹ ti gbogbo ohun alaaye si kú. Ọkan rè̩ ni lati fẹ Ọlọrun ju ti atẹyinwa lọ.

Ọlọrun ta oṣumare daradara kan soju ọrun ki Noa ati gbogbo araye le mọ pe Ọlọrun ti ṣeleri lati má tun fi omi pa ayé ré̩ mọ. Ọlọrun a maa mu ileri Rè̩ ṣẹ nigba gbogbo.

Gbogbo awọn eniyan buburu ti kú sinu omi wayii. Gbogbo nnkan ti yatọ loju Noa nitori ikun omi nla ti o ti n ṣan sihin sọhun, ti sọ ọpọ koto di gegele, o si ti mú ki ibi pupọ ga soke.

Lọjọ oni, a le ri karawun okun, awọn egungun ẹja ati awọn ohun ẹlẹmi miiran ti o n gbé inu okun, ati awọn ohun abami miiran lori awọn oke ati ninu apata. Omi nla ti akoko ikun omi ni o gbá wọn lọ sibẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni mu ki omi gbẹ kuro lori ilẹ? Gẹnẹsisi 8:1

  2. 2 Ta ni Ọlọrun ranti lẹyin ti o mu ki omi gbẹ?

  3. 3 Ki ni Noa kọkọ rán lati lọ wo boya omi ti gbẹ?

  4. 4 Ki ni Noa rán jade lẹyin ti o ti rán iwò?

  5. 5 Bawo ni Noa ṣe mọ pe omi ti n fà kuro lori ilẹ?

  6. 6 Bawo ni Noa ṣe mọ igba ti oun ni lati fi ọkọ silẹ?

  7. 7 Ami wo ni Ọlọrun fun wa lati mọ pe Oun ki yoo tun fi omi pa ayé ré̩ mọ?