Lesson 6 - Elementary
Memory Verse
“Ẹ mā pa ara nyin mọ ninu ifẹ Ọlọrun” (Juda 21).Notes
Ọlọrun n fẹ ẹni ti yoo ṣe gẹgẹ bi Oun ti fé̩. Ọlọrun yan ọkunrin ti a n pè ni Abrahamu nitori o mọ pe Abrahamu fẹran Oun pupọ, o si gbọran. Abrahamu n gbé ni ilu kan ti a n pe ni Mesopotamia ni apá ila-oorun. Abọriṣa ni awọn ara ilu naa. S̩ugbọn Abrahamu fẹran Ọlọrun otitọ, o si n sin In.
Abrahamu fẹran awọn ara ile rè̩ ati ilu rè̩ pupọ. S̩ugbọn nigba ti Ọlọrun paṣẹ fun un lati kuro nibẹ ki o si lọ si ibomiran, Abrahamu kò wi pe, ‘Duro naa, n o lọ lai pẹ.’ O gbọran lẹsẹkẹsẹ. O mú awọn ohun ti yoo wulo fun un ni ọna ajo rè̩ lọwọ. O mu Sara aya rè̩ ati Lọti ọmọ aburo rè̩ pẹlu rè̩.
Nigba ti Abrahamu bá de ibikibi, ohun kin-in-ni ti i maa ṣe ni lati té̩ pẹpẹ, nibi ti oun i maa sin Ọlọrun ati lati dupẹ lọwọ Ọlọrun, ati lati beere pe ki Ọlọrun wà pẹlu oun. Abrahamu ni ọpọ rakunmi, ewurẹ, agutan, ati awọn ohun ọsin miiran gbogbo. Lọti ní ti rè̩ pẹlu. Awọn darandaran wọn bẹrẹ si jà nitori pápá oko fun awọn ẹran ọsin wọn.
Abrahamu sọ pe ko dara lati maa jà. O sọ fun Lọti pe wọn ni lati pinya ki àye pupọ le wà fun olukuluku. Abrahamu ki i ṣe anikanjọpọn. Bi o tilẹ jẹ pe o dagba ju Lọti, ṣugbọn o sọ fun Lọti pe ki o yan ibi ti o ba fé̩. Lọti fẹ lati tọju ohun ti i ṣe ti rè̩ ju lati ran Abrahamu ẹgbọn rè̩ lọwọ.
Lọti yan ilẹ ti o ni omi jù fun agbo ẹran rè̩, ṣugbọn ohun ti o yàn ko tọna. Awọn eniyan ti o wa nibẹ ko fẹran Ọlọrun, wọn ki i si sin In. Iwa wọn buru lọpọlọpọ, o si lewu lati wà ninu ẹgbé̩ buburu. Lọjọ kan, awọn ọba mẹrin ati awọn ọmọ-ogun wọn wá, wọn si kó Lọti ati ẹbi rè̩, ati agbo ẹran rè̩ lọ.
Nigba ti Abrahamu gbọ ohun ti o ṣẹlẹ si Lọti, o mu ọọdunrun eniyan o le mejidinlogun pẹlu ara rè̩, o si lepa awọn ọlọṣa naa, o si jẹ wọn niya, o si gba Lọti ati ẹbi rè̩ silẹ.
Ọba ilu ti Lọti n gbé, ẹni ti Abrahamu ràn lọwọ, fẹ lati fun Abrahamu ni owo, ṣugbọn Abrahamu ko jẹ gbowo fun iranlọwọ ti o ti ṣe.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi yan Abrahamu?
2 Ki ni Abrahamu ṣe nigba ti Ọlọrun sọ fun un pe ki o jade? Gẹnẹsisi 13:1
3 Ki ni ohun ekinni ti Abrahamu i maa ṣe nigba ti o ba dé ibi kan? Gẹnẹsisi 13:4
4 Ki ni Abrahamu ṣe nigba ti awọn darandaran bẹrẹ si jà? Genesisi 13:8, 9
5 Ki ni ohun ti Lọti yàn? Ki ni buru nibẹ?
6 Ki ni Abrahamu ṣe nigba ti o gbọ pe Lọti wà ninu wahala? Genesisi 14:15, 16