Gẹnẹsisi 19:1-29

Lesson 7 - Elementary

Memory Verse
“Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye” (1 Johannu 2:15).
Notes

Lọti aburo Abrahamu ti yan ilẹ ti o dara fun agbo ẹran rè̩. Awọn eniyan buburu ni o wà nibẹ. Ọlọrun ri iwa buburu awọn eniyan naa, Ọlọrun korira è̩ṣẹ. Nigba ti awọn eniyan bá dẹṣẹ, wọn ṣaigbọran si Ọlọrun, wọn si ṣe ara wọn ni ibi. Ọlọrun ni lati jẹ wọn niya lati dá wọn lẹkun, ki wọn si le jé̩ ikilọ fun awọn ẹlomiran. Awọn ara Sodomu ati Gomora ti pinnu lati maa huwa ti kò dara. Wọn kò fẹ ronupiwada ki wọn si yipada si Ọlọrun.

Ọlọrun pinnu lati pa awọn ilu yii ati awọn eniyan buburu inu rè̩ run. Abrahamu gbadura, o si beere lọwọ Ọlọrun bi Oun yoo pa awọn eniyan rere run pẹlu, nigba ti a ba pa awọn eniyan buburu run. O beere lọwọ Ọlọrun bi Oun yoo dá ilu Sodomu si bi a ba le ri aadọta eniyan ti o ni igbala nibẹ; Ọlọrun ni Oun yoo dá ilu naa si. Abrahamu tun beere bi a o dá ilu naa si bi a ba ri ogoji olododo, tabi ọgbọn, lẹyin naa o din in kù dé ogún titi de mẹwaa. Ọlọrun ni Oun yoo dá ilu naa si bi a ba ri eniyan mẹwaa ti o ni igbala nibẹ.

Ni aṣalẹ ọjọ kan, Lọti joko ni ẹnu ọna Sodomu. O ri awọn angẹli meji n bọ lọna ọdọ rè̩. Awọn angẹli naa sọ fun Lọti pe ki ó kó awọn ẹbi rè̩ jade kuro ni ilu naa. Wọn buru to bẹẹ ti Ọlọrun rán awọn angẹli meji yii lati pa a run. Wọn sọ fun Lọti ati ẹbi rè̩ ki wọn yara salọ sori oke, ki wọn ma ṣe wo ẹyin wọn.

Lọti mú iyawo rè̩ ati awọn ọmọbinrin rè̩ meji, wọn si sá jade kuro ni ilu naa. Lẹyin naa ni iná bọ sori ilu naa, o si jó o. S̩ugbọn aya Lọti boju wo ẹyin. O ni lati jé̩ pe o fi awọn ohun ti o ṣọwọn fun un silẹ nibẹ tabi boya o fẹ mọ bi otitọ ni awọn angẹli Ọlọrun sọ tabi bẹẹ kọ. O di ọwọn iyọ. Lọti ati awọn ọmọbinrin rẹ meji ti wọn gba ọrọ awọn angẹli naa gbọ ti wọn si sare jade kuro ni ilu ti wọn kò si boju wo ẹyin, lọ ni alaafia.

Ọlọrun mọ ohun ti o dara fun wa, Oun ko ni sọ fun wa lati ṣe ohun ti ki i ṣe fun ire wa. Adamu ati Efa ṣaigbọran ninu ọgba Edeni, aigbọran wọn si Ọlọrun si fa è̩ṣẹ ati ibanujẹ wá si ayé. Jesu gbọran si Ọlọrun nigba gbogbo. Ọlọrun si sọ pe inu Oun dun gidigidi si Jesu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti Lọti fi yàn lati gbé ni ilu Sodomu?

  2. 2 Iru eniyan wo ni awọn ara Sodomu, rere tabi buburu?

  3. 3 Ki ni Ọlọrun pinnu lati ṣe nitori iwa buburu wọn?

  4. 4 Ki ni adura Abrahamu si Ọlọrun?

  5. 5 Ki ni Ọlọrun rán awọn angẹli lati sọ fun Lọti?

  6. 6 Ki ni aya Lọti ṣe?

  7. 7 Ki ni ṣẹlẹ si i nigba ti o ṣaigbọran?

  8. 8 Inu Ọlọrun a ha maa dùn bi a ba ṣaigbọran?