Gẹnẹsisi 22:1-19

Lesson 8 - Elementary

Memory Verse
“Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn obi nyin li ohun gbogbo” (Kolosse 3:20).
Notes

Abrahamu gbọran si Ọlọrun o si ti lọ si ilẹ ti Ọlọrun fẹ ki o lọ. Ọlọrun fun Abrahamu ni ọpọlọpọ maluu ati agutan. Ọlọrun fun un ni wura ati fadaka lọpọlọpọ. Ọlọrun daabo bo Abrahamu. O si ràn án lọwọ.

Abrahamu ati Sara aya rè̩ ko bimọ. Ọlọrun fẹ ki wọn bi ọmọkunrin kan, nitori Ọlorun mọ pe Abrahamu yoo kọ ọmọ rè̩ lati fẹran Ọlọrun ati lati gbọran si I. Nigba naa Ọlọrun yoo le mú ki awọn ọmọ rè̩ ati ọpọlọpọ ọmọ ti wọn o bí ni idile wọn, jé̩ ibukun fun gbogbo ayé. Lati inu ọkan ninu awọṅ idile wọnyii, ni a o si ti bí Jesu.

Ọlọrun sọ fun Abrahamu pe Oun yoo fun un ni ọmọkunrin kan. Abrahamu gbagbọ pe Ọlọrun yoo ṣe e, nitori gbogbo ohun ti Ọlọrun ṣeleri ni O n muṣẹ. Abrahamu duro pé̩ titi kò bimọ, sibẹ o gbagbọ pe Ọlorun yoo mú ileri Rè̩ ṣẹ.

Lẹyin ọjọ pupọ, Ọlọrun fun Abrahamu ati Sara ni ọmọkunrin kan. Wọn pe orukọ rè̩ ni Isaaki. Abrahamu fẹran Isaaki pupọ, ọkàn rè̩ si dupẹ lọwọ Ọlọrun ti o fun un ni ọmọ yii.

Ni ọjọ kan, Ọlọrun beere pe ki Abrahamu fi Isaaki fun Oun. O ni lati jẹ ohun ti o ṣoro fun Abrahamu lati fẹ fi ọmọ rè̩ ọwọn silẹ, ṣugbọn nitori Ọlọrun ni O beere fun Isaaki, Abrahamu gbà lati fi i fun Ọlọrun. O gbagbọ pe bi Isaaki tilẹ kú, Ọlọrun le ji i dide. Inu Ọlọrun dùn si Abrahamu nitori o fẹ Ọlọrun to bẹẹ ti o gbà lati fi ohun ti o dara ti o si ṣọwọn fun un ju lọ fun Ọlọrun. S̩ugbọn Ọlọrun dá Isaaki si fun Abrahamu. O si wá fun un ni ọpọlọpọ ohun rere miiran pẹlu.

Ọlọrun fé̩ wa ju bi awa ti fé̩ Ẹ lọ. S̩ugbọn a le ni ọkàn ọpé̩ si Ọlọrun. A le fẹran Rè̩ ki a si maa ṣe ohun ti O wu U.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Bawo ni Abrahamu ti fẹran Ọlọrun to?

  2. 2 Ki ni ṣe ti Ọlọrun n fẹ ki Abrahamu bi ọmọkunrin kan?

  3. 3 Ta ni a oo bí lati idile Abrahamu nigbooṣe?

  4. 4 Ki ni orukọ ti Abrahamu ati Sara sọ ọmọ wọn?

  5. 5 Ki ni Ọlọrun ni ki Abrahamu fi Isaaki ṣe?

  6. 6 Ki ni ṣe ti Abrahamu gbà lati fi Isaaki fun Ọlọrun?

  7. 7 Ki ni a le fun Ọlọrun fun ọpọ ibukun Rè̩ ti a n ri gbà?