Lesson 9 - Elementary
Memory Verse
“Yio tọ nyin si ọna otitọ gbogbo” (Johannu 16:13).Notes
Ọlọrun fun Abrahamu ni ọmọkunrin kan ti o pe orukọ rè̩ ni Isaaki. Isaaki dagba titi o di ọdọmọkunrin. O gbé ọmọbinrin kan ti a n pe ni Rebeka ni iyawo. Ki i ṣe ọmọ kan ṣoṣo ni Isaaki ati Rebeka bi, ṣugbọn wọn bi Ibeji! Rò ó wò! Ọmọ meji lẹẹkan ṣoṣo. Wọn pe orukọ wọn ni Esau ati Jakọbu.
Jakọbu fé̩ ibukun Ọlọrun, ṣugbọn Esau ro pe oun le ṣe bi oun ti fé̩. Kò naani lati beere fun iranlọwọ Ọlọrun. Lọjọ kan, Jakọbu ṣẹ arakunrin rè̩, iya rè̩ si gba a niyanju lati fi ile silẹ titi ibinu Esau yoo fi rọlẹ. Lai si aniani, iya Jakọbu ṣe ounjẹ fun un, o si mu ọna ajo rẹ pọn lati lọ si ọdọ ẹgbọn iya rè̩ ni ọna jijin rere.
Jakọbu a maa sùn nibikibi ti o ba ri. I baa ṣe inu iho apata, tabi abẹ igi ni gbangba tabi ni eti odo. Ni alẹ ọjọ kan, o ṣa okuta jọ, o fi ṣe irọri rẹ. Ó sùn lọ, o si lá àlá iyanu kan. O ri akasọ kan ti o ga de Ọrun. Awọn angẹli n goke, wọn si n sọkalẹ lori akasọ yii.
Ta ni iwọ rò pe ó ri ni oke akasọ naa? O ri Oluwa nibẹ, Oluwa Ọlọrun si bá Jakọbu sọrọ!
O sọ fun un pe Oun ni Ọlọrun baba ati baba nla rè̩, Oun yoo si jẹ Ọlọrun Jakọbu pẹlu. Ọlọrun ṣeleri lati wà pẹlu Jakọbu ni gbogbo irin ajo rè̩ ati pe Oun yoo si mu un pada ni alaafia.
Nigba ti Jakọbu ji, ẹnu ya a nipa ala iyanu ti ó ti lá.
O ri Oluwa, Oluwa si ti bá a sọrọ. Jakọbu wi pe: “OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ …. eyi ki iṣe ibi omiran, bikoṣe ile Ọlọrun, eyi si li ẹnubode ọrun” Jakọbu ṣọra lọpọlọpọ nitori iwaju Ọlọrun ni ó wà. A ni lati maa ṣọra pẹlu nigba ti a bá wà ni ile Ọlọrun nibi ti Ọlọrun n gbé.
Jakọbu dupẹ lọwọ Ọlọrun pe O wà pẹlu rè̩. O ṣeleri lati sin Ọlọrun ati lati san idamẹwa ohunkohun ti oun ba ri gbà. Eyi ni sisan idamẹwa, eyi ti awọn Onigbagbọ tootọ i maa ṣe lode oni. Ki i ṣe idamẹwa ohun ti a ni tabi eyi ti a ri gbà nikan ni Ọlọrun n fẹ ki a fi fun Oun, O fé̩ ayé wa pẹlu. Oun yoo si bukun fun wa siwaju ati siwaju.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ta ni iyawo Isaaki? Gẹnẹsisi 25:20
2 Ki ni orukọ ti Isaaki ati Rebekka fun awọn ibeji ti wọn bí? Gẹnẹsisi 25:25, 26
3 Ki ni ó ṣẹlẹ si Jakọbu ni òru ọjọ kan ni akoko irin-ajo rè̩ lọ si ọdọ ẹgbọn iya rè̩? Gẹnẹsisi 28:11
4 Ki ni Jakọbu rí ninu àlá rè̩? Gẹnẹsisi 28:12
5 Ki ni Ọlọrun sọ fun Jakọbu? Gẹnẹsisi 28:13
6 Ki Jakọbu ṣeleri fun Ọlọrun pé oun yoo ṣe? Gẹnẹsisi 28:12