Gẹnẹsisi 37:1-36

Lesson 10 - Elementary

Memory Verse
“Ẹ fẹ awọn ọtá nyin” (Matteu 5:44).
Notes

Jakọbu bi ọmọkunrin mejila. O fẹran Josẹph pupọ nitori ó jé̩ ọmọ rere, o si gbọran. Awọn arakunrin Josẹfu korira rè̩ nitori wọn rò pe o jé̩ kori-kosun baba rè̩. Baba Josẹfu dá ẹwu alarabara kan fun un. Eyi mu ki awọn arakunrin rè̩ tubọ korira rè̩.

Josẹfu lá ala iyanu kan. Jakọbu gbagbọ pe Ọlọrun ni o fi ala yii han Josẹfu, ati pé Ọlọrun yoo mu un ṣẹ, ṣugbọn awọn arakunrin rè̩ tubọ korira rè̩ ju bẹẹ lọ. Awọn arakunrin Josẹfu ni ọpọlọpọ ewurẹ ati agutan ti wọn ni lati boju to.

Nigba ti awọn arakunrin Josẹfu ri i ti o n bọ lokeere, wọn di imọ pọ lati pa a. Kò tọ fun awọn arakunrin Josẹfu lati korira rè̩, nitori Ọlọrun paṣẹ fun wa pe ki a fẹran ọmọnikeji wa. A ni lati fẹran ọmọnikeji wa ki a si ran ara wa lọwọ.

Lai pẹ jọjọ, wọn ri awọn ero ti o gun rakunmi n bọ. Wọn n lọ si ilu okeere lati lọ ta awọn ọja wọn. Lẹyin naa Juda, ọkan ninu awọn arakunrin Josẹfu wi pe, “Njẹ kò sán lati ta Josẹfu fun awọn eniyan yii ju lati pa a lọ?” Awọn arakunrin rè̩ gba pe imọran Juda dara, nitori naa wọn ta a fun ogun owo fadaka. Lẹyin ti wọn ti bọ ẹwu alarabara rè̩, wọn fi i le awọn ti o rà á lọwọ. Wọn pa ewurẹ kan, wọn si fi ẹwu Josẹfu alarabara sinu ẹjẹ rè̩, wọn si mu un tọ baba wọn lọ. Wọn wi fun un pe, “A ri ẹwu yii. Njẹ iwọ rò pe ti Josẹfu ni?”

Jakọbu mọ ẹwu naa lẹsẹkẹsẹ. O dahun pe, “O ni lati jẹ pe ẹranko buburu ti pa a jẹ.” Wọn ko sọ fun un pe awọn ni wọn ta a. Inu Jakọbu bajẹ nitori oun ran Josẹfu nikan lọ.

Josẹfu gbẹkẹle Ọlọrun nitori o mọ pe Ọlọrun yoo tọju oun. Ẹ jẹ ki a ṣe bi Josẹfu. Awa ko fẹ jẹ opurọ bi awọn arakunrin rè̩. O yẹ ki a maa sọ otitọ fun awọn baba ati iya wa nigba gbogbo.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Jakọbu fi fẹran Josẹfu?
  2. Ki ni ṣe ti awọn arakunrin Josẹfu fi korira rè̩? Gẹnẹsisi 37:4, 5, 8
  3. Ki ni wọn pinnu lati ṣe fun un? Gẹnẹsisi 37:19, 20
  4. Eelo ni wọn tà á? Gẹnẹsisi 37:28
  5. Njẹ awọn arakunrin Josẹfu sọ otitọ?
  6. Njẹ Josẹfu gba Ọlọrun gbọ?